Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Ìdánilójú wo ni Jémíìsì 5:11 fún wa nígbà tó sọ pé Jèhófà “ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú”?

A mọ̀ pé torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó máa ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Jémíìsì 5:11 fi dá wa lójú pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ìyẹn sì ń mú kó ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ó yẹ káwa náà fara wé e.​—w21.01, ojú ìwé 21.

Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣètò ipò orí?

Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ipò orí yìí ló mú kí àwa tá a wà nínú ìdílé Jèhófà wà lálàáfíà kí nǹkan sì máa lọ létòlétò. Gbogbo ìdílé tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò ipò orí mọ ẹni tó yẹ kó máa ṣèpinnu, kó sì máa múpò iwájú nínú ohun tí wọ́n bá ń ṣe.​—w21.02, ojú ìwé 3.

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ṣọ́ra tá a bá ń lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́?

Tẹ́nì kan bá pinnu láti lo irú àwọn ètò ìṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó fọgbọ́n yan àwọn táá máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí. Ìyẹn sì lè ṣòro tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn lórí ìkànnì náà. (1 Tím. 5:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn máa ń tan ìròyìn tí ò dá wọn lójú kálẹ̀ níbẹ̀, àwọn ará kan sì máa ń lo ètò tó wà fún ìjọ láti polówó ọjà wọn, ìyẹn sì léwu gan-an.​—w21.03, ojú ìwé 31.

Kí ni díẹ̀ lára ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba pé kí Jésù jìyà kó sì kú?

Àkọ́kọ́, wọ́n ní láti gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi kó lè gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ ègún tó wà lórí wọn. (Gál. 3:10, 13) Ìdí kejì ni pé Jèhófà ń dá Ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè kúnjú ìwọ̀n láti di Àlùfáà Àgbà. Ìdí kẹta sì ni pé bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú jẹ́ kó ṣe kedere pé àwa èèyàn lè jẹ́ adúróṣinṣin lójú àdánwò tó lágbára. (Jóòbù 1:9-11)​—w21.04, ojú ìwé 16-17.

Kí lo lè ṣe tó bá ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín?

O lè gbìyànjú láti lọ lásìkò tó o mọ̀ pé wọ́n máa wà nílé. O tún lè lọ wàásù láwọn ibi tó o ti lè rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. O sì lè wàásù láwọn ọ̀nà míì bíi kó o kọ lẹ́tà.​—w21.05, ojú ìwé 15-16.

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Nípasẹ̀ òfin, mo ti di òkú sí òfin”? (Gál. 2:19)

Òfin Mósè jẹ́ kó ṣe kedere pé aláìpé làwa èèyàn, ó sì ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sọ́dọ̀ Kristi. (Gál. 3:19, 24) Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù gba Kristi gbọ́ nìyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù “di òkú sí òfin” Mósè, kò sì sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́.​—w21.06, ojú ìwé 31.

Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ ká ní ìfaradà?

Jèhófà ti fara da ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá orúkọ rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń ta ko ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, bí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀ ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, irọ́ tí Èṣù ń pa mọ́ ọn lemọ́lemọ́, bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ṣe ń jìyà, ikú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, bí àwọn ẹni burúkú ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn táwọn kan sì ń sọ ara wọn dìdàkudà àti báwọn èèyàn ṣe ń run ayé.​—w21.07, ojú ìwé 9-12.

Àpẹẹrẹ wo ni Jósẹ́fù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká máa mú sùúrù?

Jósẹ́fù fara da ìwà àìdáa táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ hù sí i. Ìyẹn mú kí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, tí wọ́n sì tún jù ú sẹ́wọ̀n ní Íjíbítì fún ọ̀pọ̀ ọdún.​—w21.08, ojú ìwé 12.

Ìmìtìtì wo ni Hágáì 2:6-9, 20-22 sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀?

Inú àwọn alákòóso ayé ò dùn sí ìhìn rere Ìjọba tá à ń wàásù rẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ti tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì wá sínú òtítọ́. Láìpẹ́, Jèhófà máa mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nígbà tó bá pa gbogbo wọn run.​—w21.09, ojú ìwé 15-19.

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá wa, inú ẹ̀ sì ń dùn sí wa. Tá ò bá jẹ́ kó sú wa tá ò sì bọ́hùn, a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.​—w21.10, ojú ìwé 25-26.

Báwo ni ìwé Léfítíkù orí 19 ṣe lè mú ká fi ìmọ̀ràn yìí sílò: Ẹ “di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín”? (1 Pét. 1:15)

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Léfítíkù 19:2 ni wọ́n ti fa ọ̀rọ̀ yìí jáde. Orí 19 jẹ́ ká rí onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Pétérù 1:15 sílò lójoojúmọ́.​—w21.12, ojú ìwé 3-4.