Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49

Ohun Tí Ìwé Léfítíkù Kọ́ Wa Nípa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn

Ohun Tí Ìwé Léfítíkù Kọ́ Wa Nípa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn

‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’​—LÉF. 19:18.

ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Àwọn nǹkan wo la jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 NÍNÚ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìmọ̀ràn tó dáa tá a lè lò nínú ìwé Léfítíkù orí kọkàndínlógún (19). Bí àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ kẹta, Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn. A tún sọ̀rọ̀ nípa bí àwa náà lónìí ṣe lè fi ìmọ̀ràn ẹsẹ Bíbélì yẹn sílò pé ká máa pèsè nǹkan tara fáwọn òbí wa, ká máa tù wọ́n nínú, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Nínú ẹsẹ yẹn kan náà, Ọlọ́run rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ó yẹ kí wọ́n máa pa Sábáàtì mọ́. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwa Kristẹni kì í pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́ lónìí, àmọ́ ohun tá a lè ṣe láti máa pa ìlànà tó wà nínú òfin yẹn mọ́ ni pé ká máa rí i pé à ń ṣe ìjọsìn Jèhófà déédéé. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, à ń fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ mímọ́ bí Léfítíkù 19:2 àti 1 Pétérù 1:15 ṣe gbà wá nímọ̀ràn.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ó máa sọ̀rọ̀ nípa Léfítíkù orí kọkàndínlógún (19) nìṣó. Nínú orí Bíbélì yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa gba tàwọn aláìlera rò, bá a ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ nínú iṣẹ́ wa àti bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. A fẹ́ jẹ́ mímọ́ torí pé Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́.

Ẹ MÁA GBA TÀWỌN TÓ NÍ ÀÌLERA RÒ

Kí ni Léfítíkù 19:14 rọ̀ wá pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe sáwọn adití àtàwọn afọ́jú? (Wo ìpínrọ̀ 3-5) *

3-4.Léfítíkù 19:14 ṣe sọ, báwo la ṣe lè fi inúure hàn sáwọn adití àtàwọn afọ́jú?

3 Ka Léfítíkù 19:14. Jèhófà fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fi inúure hàn sáwọn tó ní àìlera. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún adití. Tẹ́nì kan bá ń ṣépè fún adití tàbí tó ń sọ ohun tí kò dáa sí i, ṣe ló ń fẹ́ kí ohun burúkú ṣẹlẹ̀ sí i. Ìyẹn mà burú gan-an o! Torí pé kò gbọ́ nǹkan táwọn èèyàn ń sọ nípa òun, kò ní lè gbèjà ara ẹ̀.

4 Bákan náà, ẹsẹ kẹrìnlá (14) sọ pé àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ “fi ohun ìdènà síwájú afọ́jú.” Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ní àìlera sọ pé: “Wọ́n máa ń yàn wọ́n jẹ, wọ́n sì máa ń hùwà ìkà sí wọn ní apá Ìlà Oòrùn ayé.” Àwọn èèyàn kan tí ò láàánú máa ń gbé ohun ìdènà síwájú àwọn afọ́jú kí wọ́n lè ṣe wọ́n léṣe tàbí kí wọ́n lè máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà nìyẹn! Àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn èèyàn rẹ̀ yìí jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó yẹ kí wọ́n máa fi àánú hàn sí àwọn tó ní àìlera.

5. Báwo la ṣe lè fi àánú hàn sáwọn tó ní àìlera?

5 Jésù fi àánú hàn sáwọn tó ní àìlera. Ṣé ẹ rántí ìròyìn tí Jésù ní kí wọ́n lọ sọ fún Jòhánù Arinibọmi? Ó ní kí wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí, àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, [a sì] ń jí àwọn òkú dìde.” Nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí, “gbogbo èèyàn yin Ọlọ́run.” (Lúùkù 7:20-22; 18:43) Inú àwa Kristẹni máa ń dùn torí à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó ní ká máa fi àánú hàn sí àwọn tó ní àìlera. Torí náà a máa ń ṣàánú wọn, a máa ń gba tiwọn rò, a sì máa ń mú sùúrù fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò fún wa lágbára láti wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà ìyanu bíi ti Jésù, a láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere fáwọn afọ́jú àtàwọn tí kò mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. À ń sọ fún wọn nípa Párádísè, níbi tí gbogbo èèyàn ti máa ní ìlera tó dáa, tí wọ́n á sì mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Lúùkù 4:18) Kódà ní báyìí, ìhìn rere tá à ń wàásù ẹ̀ ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa yin Ọlọ́run lógo.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ NÍNÚ IṢẸ́ RẸ

6. Báwo ni ohun tó wà nínú Léfítíkù orí 19 ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí Òfin Mẹ́wàá sọ?

6 Àwọn ẹsẹ kan nínú Léfítíkù orí 19 ṣàlàyé ohun tó wà nínú Òfin Mẹ́wàá. Bí àpẹẹrẹ, òfin kẹjọ sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ jalè.” (Ẹ́kís. 20:15) Ẹnì kan lè rò pé tóun ò bá ti mú nǹkan tí kì í ṣe tòun, òun ti pa òfin náà mọ́ nìyẹn. Àmọ́, ó lè máa jalè láwọn ọ̀nà míì.

7. Báwo ni oníṣòwò kan ṣe lè rú òfin kẹjọ tó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jalè?

7 Oníṣòwò kan lè máa fọ́nnu pé òun kì í mú nǹkan tí kì í ṣe tòun. Àmọ́, ṣé ó máa ń ṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òwò rẹ̀? Nínú Léfítíkù 19:35, 36, Jèhófà sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lo ìwọ̀n èké tí ẹ bá ń díwọ̀n bí ohun kan ṣe gùn tó, bó ṣe wúwo tó tàbí bó ṣe pọ̀ tó. Kí ẹ máa lo òṣùwọ̀n tó péye, ìwọ̀n tó péye, òṣùwọ̀n tó péye fún ohun tí kò lómi àti òṣùwọ̀n tó péye fún nǹkan olómi.” Torí náà, tí oníṣòwò kan bá lo òṣùwọ̀n tí ò péye láti tan àwọn oníbàárà rẹ̀ jẹ, olè ló jà yẹn. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan nínú Léfítíkù orí 19 ló jẹ́ ká lóye ìyẹn.

Ìbéèrè wo ni Kristẹni kan lè bi ara ẹ̀ nípa iṣẹ́ rẹ̀ tó bá ronú lórí Léfítíkù 19:11-13? (Wo ìpínrọ̀ 8-10) *

8. Báwo ni ohun tó wà nínú Léfítíkù 19:11-13 ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ìlànà tó wà nínú òfin kẹjọ, àǹfààní wo ló sì máa ṣe wá?

8 Ka Léfítíkù 19:11-13. Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Léfítíkù 19:11 sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jalè.” Ẹsẹ 13 jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ìyàtọ̀ nínú kéèyàn jalè àti kéèyàn lu jìbìtì, ó ní: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì yín ní jìbìtì.” Torí náà, téèyàn bá lu jìbìtì nínú iṣẹ́ ẹ̀, olè ló jà yẹn, ó sì tún fipá gba nǹkan tí kì í ṣe tiẹ̀. Òfin kẹjọ sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jalè, àmọ́ àlàyé tó wà nínú ìwé Léfítíkù ló jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe máa lo ìlànà tó wà nínú òfin náà. Á ṣe wá láǹfààní tá a bá ń ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo jìbìtì àti olè jíjà. A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Tí mo bá ronú lórí ohun tí Léfítíkù 19:11-13 sọ, ṣé àwọn nǹkan kan wà tí mò ń ṣe tó gba pé kí n ṣàtúnṣe? Ṣé ó yẹ kí n ṣe àtúnṣe kan nínú iṣẹ́ mi tàbí nínú ọ̀nà tí mò ń gbà ṣiṣẹ́?’

9. Báwo ni òfin tó wà ní Léfítíkù 19:13 ṣe ń dáàbò bo àwọn òṣìṣẹ́?

9 Ohun kan tún wà tí Kristẹni kan tó gba èèyàn síṣẹ́ gbọ́dọ̀ ṣe táá fi hàn pé olóòótọ́ ni. Léfítíkù 19:13 sọ pé: “Owó iṣẹ́ alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ wà lọ́wọ́ yín di àárọ̀ ọjọ́ kejì.” Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe, wọ́n sì máa ń sanwó fún alágbàṣe lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Tí wọn ò bá sanwó fún alágbàṣe kan, kò ní rówó tó fi máa bọ́ ìdílé ẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Torí náà, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.”​—Diu. 24:14, 15; Mát. 20:8.

10. Kí la rí kọ́ nínú Léfítíkù 19:13?

10 Lóde òní, ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n máa ń sanwó fún ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ lóṣù, kì í ṣe ojoojúmọ́. Síbẹ̀, ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:13 ṣì wúlò lásìkò yìí. Àwọn kan tó gba àwọn èèyàn síṣẹ́ máa ń rẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ wọn jẹ torí owó tí wọ́n ń san fún wọn kéré gan-an. Kò sóhun táwọn òṣìṣẹ́ yìí lè ṣe sọ́rọ̀ náà àfi kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rówó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n á fi máa jẹun. Ohun tí àwọn agbanisíṣẹ́ kan ń ṣe nìyẹn tá a fi lè sọ pé wọn kì í san ‘owó iṣẹ́ alágbàṣe.’ Kristẹni kan tó gba àwọn èèyàn síṣẹ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ṣẹ̀tọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ òun. Ẹ jẹ́ ká tún wo ẹ̀kọ́ míì tá a lè kọ́ nínú Léfítíkù orí 19.

NÍFẸ̀Ẹ́ ỌMỌNÌKEJÌ RẸ BÍ ARA RẸ

11-12. Kí ni Jésù fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Léfítíkù 19:17, 18?

11 Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa hùwà ìkà sáwọn èèyàn, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó fẹ́ ká máa ṣe. Àwọn nǹkan náà wà nínú Léfítíkù 19:17, 18. (Kà á.) Kíyè sí àṣẹ tó pa pé: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ Nǹkan pàtàkì tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nípa bí àṣẹ tó wà nínú Léfítíkù 19:18 ti ṣe pàtàkì tó. Ìgbà kan wà tí Farisí kan bi Jésù pé: “Àṣẹ wo ló tóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù sọ fún un pé “àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́” ni pé ká fi gbogbo ọkàn wa, gbogbo ara wa àti gbogbo èrò wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn náà, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Léfítíkù 19:18 pé: “Ìkejì tó dà bíi rẹ̀ nìyí: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ” (Mát. 22:35-40) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa, àmọ́ a lè kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀nà míì nínú Léfítíkù orí 19.

13. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká lóye ohun tó wà nínú Léfítíkù 19:18?

13 Ọ̀nà kan tá a lè gbà fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa ni pé ká tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:18. Ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di ọmọ àwọn èèyàn rẹ sínú.” Ọ̀pọ̀ lára wa ti rí ẹni tó di ẹnìkejì rẹ̀ sínú fún ọ̀pọ̀ ọdún, irú bí ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ ilé ìwé ẹ̀, mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àti ará ilé ẹ̀. Ṣé ẹ rántí pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù dì í sínú? Nígbà tó yá, ìyẹn mú kí wọ́n hùwà ìkà sí i. (Jẹ́n. 37:2-8, 25-28) Ẹ ò rí i pé ìwà Jósẹ́fù yàtọ̀, kò sì bínú sí wọn! Nígbà tó dé ipò àṣẹ, tó sì yẹ kó gbẹ̀san lára wọn, kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fàánú hàn sí wọn, kò sì dì wọ́n sínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Léfítíkù 19:18.​—Jẹ́n. 50:19-21.

14. Kí ló fi hàn pé ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:18 ṣì wúlò lóde òní?

14 Ohun tá a rí kọ́ lára Jósẹ́fù ni pé tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó yẹ ká máa dárí jini dípò ká di ara wa sínú tàbí ká máa gbẹ̀san. Èyí tún bá ohun tó wà nínú àdúrà Olúwa mu. Jésù rọ̀ wá nínú àdúrà náà pé ká máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Mát. 6:9, 12) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́.” (Róòmù 12:19) Ó tún rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.” (Kól. 3:13) Ìlànà Jèhófà kì í yí pa dà. Torí náà, ó yẹ ká ṣì máa tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:18.

Bó ṣe jẹ́ pé kò dáa ká máa fọwọ́ tẹ ojú ọgbẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni kò dáa ká máa ronú nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ wá. Ńṣe ló yẹ ká gbàgbé ẹ̀. (Wo ìpínrọ̀ 15) *

15. Àpèjúwe wo la lè fi ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá?

15 Wo àpèjúwe yìí. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, ó dà bí ìgbà tí nǹkan gé wa lọ́wọ́. Ojú ibi tí nǹkan ti gé wa lè kéré tàbí kó tóbi. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀bẹ lè géni lọ́wọ́ fẹ́rẹ́. Ó máa ń dunni gan-an, àmọ́ kò ní pẹ́ rárá táá fi jiná. Ká tó rí ọjọ́ mélòó kan, á ti sàn, a sì lè má rí ojú àpá náà mọ́. Lọ́nà kan náà, ohun táwọn èèyàn ṣe fún wa lè má tó nǹkan. Ọ̀rẹ́ wa lè sọ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá, àmọ́ a máa ń tètè dárí jì í. Ṣùgbọ́n ká sọ pé ojú ibi tí ọ̀bẹ ti gé wa tóbi, ó lè gba pé kí dókítà bá wa rán an, kó sì fi báńdééjì wé e. Tá a bá wá ń fọwọ́ tẹ ojú ọgbẹ́ náà, àá ṣe ara wa léṣe. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí fún ẹnì kan tí wọ́n ṣẹ̀, tí nǹkan náà sì dùn ún gan-an. Tó bá jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe fún un ló ń rò ṣáá àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn ún tó, ńṣe lá kàn máa ba ara ẹ̀ nínú jẹ́. Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Léfítíkù 19:18!

16. Bó ṣe wà ní Léfítíkù 19:33, 34, báwo ló ṣe yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe sáwọn àjèjì tó ń gbé nílẹ̀ wọn, kí la sì rí kọ́ nínú ìyẹn?

16 Nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, kì í ṣe ẹ̀yà wọn tàbí orílẹ̀-èdè wọn nìkan ló ní lọ́kàn. Ó tún sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn. Ohun tó wà nínú Léfítíkù 19:33, 34 sì yé wọn dáadáa. (Kà á.) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa hùwà sí àjèjì bí “ọmọ ìbílẹ̀,” wọ́n sì gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀” bí ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti gba àjèjì àtàwọn aláìní láàyè láti máa pèéṣẹ́ nínú oko wọn. (Léf. 19:9, 10) Ìlànà tó sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì kan àwa Kristẹni náà lóde òní. (Lúùkù 10:30-37) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àìmọye àwọn àjèjì ló wà kárí ayé lónìí, àwọn kan sì lè máa gbé nítòsí wa. Ó yẹ ká máa hùwà tó dáa sí wọn, lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÓ WÀ NÍNÚ LÉFÍTÍKÙ ORÍ 19

17-18. (a) Kí ni Léfítíkù 19:2 àti 1 Pétérù 1:15 rọ̀ wá pé ká ṣe? (b) Iṣẹ́ pàtàkì wo ni àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé ká ṣe?

17 Nínú Bíbélì, Léfítíkù 19:2 àti 1 Pétérù 1:15 rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n jẹ́ mímọ́. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ míì nínú Léfítíkù orí 19 jẹ́ ká rí ohun tí a lè ṣe ká lè rí ojú rere Jèhófà. A ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ tó jẹ́ ká mọ àwọn ohun rere tá a lè ṣe àtàwọn ohun tá ò gbọ́dọ̀ ṣe. * Bákan náà, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi hàn pé ó yẹ ká máa lo àwọn ìlànà yẹn nígbèésí ayé wa. Àmọ́ àpọ́sítélì Pétérù sọ nǹkan míì tá a lè ṣe.

18 A lè máa kópa déédéé nínú ìjọsìn Jèhófà, ká sì máa ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere. Àmọ́ Pétérù sọ ohun pàtàkì kan tó yẹ káwa Kristẹni ṣe. Kí Pétérù tó rọ̀ wá pé ká jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa, ó sọ pé: “Ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́.” (1 Pét. 1:13, 15) Iṣẹ́ wo ló ń sọ? Pétérù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi máa “‘kéde káàkiri [nípa] àwọn ọlá ńlá’ Ẹni tó pè” wọ́n. (1 Pét. 2:9) Ká sòótọ́, gbogbo àwọn Kristẹni ló láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù yìí, tó sì ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní jù lọ. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwa èèyàn mímọ́ ń fìtara wàásù, a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn! (Máàkù 13:10) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Léfítíkù orí 19, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. A sì máa fi hàn pé a fẹ́ “jẹ́ mímọ́” nínú gbogbo ìwà wa.

ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

^ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni ò tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́, síbẹ̀, òfin yẹn mẹ́nu kan àwọn nǹkan tó yẹ ká máa ṣe àtèyí tí kò yẹ ká ṣe. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ó sì tún máa jẹ́ ká ṣe ohun táá múnú Ọlọ́run dùn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Léfítíkù orí kọkàndínlógún (19) àtàwọn àǹfààní tó máa ṣe wá.

^ Àwọn ẹsẹ míì nínú Léfítíkù orí 19 tá ò mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí sọ pé ojúsàájú, bíba orúkọ èèyàn jẹ́ àti jíjẹ ẹ̀jẹ̀ kò dáa, ó sì tún sọ pé lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn, wíwádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ woṣẹ́woṣẹ́ àti ìṣekúṣe kò dáa.​—Léf. 19:15, 16, 26-29, 31.​—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú ìwé yìí.

^ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń ran arákùnrin míì tó jẹ́ adití lọ́wọ́ láti bá dókítà sọ̀rọ̀.

^ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tó gba ẹnì kan síṣẹ́ kunlékunlé ń sanwó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.

^ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan lè tètè gbàgbé ibi tí ọ̀bẹ ti gé e lọ́wọ́ fẹ́rẹ́. Ṣé kò yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀ tí ojú ọgbẹ́ náà bá tóbi?