Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé àsọdùn ni Dáfídì sọ nínú Sáàmù 61:8 nígbà tó sọ pé òun á máa yin orúkọ Ọlọ́run “títí láé”?

Rárá o, kì í ṣe àsọdùn. Òótọ́ ni ohun tí Dáfídì sọ.

Wo ohun tó sọ nínú ẹsẹ yẹn àtàwọn ẹsẹ míì tó sọ ohun tó jọ ọ́ nínú sáàmù. Ó sọ pé: “Màá fi orin yin orúkọ rẹ títí láé bí mo ṣe ń san àwọn ẹ̀jẹ́ mi láti ọjọ́ dé ọjọ́.” “Mo fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi, màá sì máa yin orúkọ rẹ lógo títí láé.” “Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.”​—Sm. 61:8; 86:12; 145:1, 2.

Kì í ṣe pé Dáfídì ń sọ pé òun ò ní kú láéláé. Ó mọ̀ pé Jèhófà ti sọ níbẹ̀rẹ̀ pé tèèyàn bá dẹ́ṣẹ̀, ó máa kú, Dáfídì sì mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun náà. (Jẹ́n. 3:3, 17-19; Sm. 51:4, 5) Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn tó rí ojú rere Ọlọ́run irú bí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ti kú. Dáfídì sì mọ̀ pé òun náà máa kú lọ́jọ́ kan. (Sm. 37:25; 39:4) Àmọ́ ohun tó sọ nínú Sáàmù 61:8 fi hàn pé ó ń wù ú kóun máa yin Jèhófà ní gbogbo ìgbà tóun fi wà láàyè, ó sì pinnu pé ohun tóun máa ṣe nìyẹn.​—2 Sám. 7:12.

ọ̀rọ̀ àkọlé tó wà ní Sáàmù 18, 51 àti 52 jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ni Dáfídì kọ, ó tún ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ní Sáàmù 23, Dáfídì fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn tó máa ń tọ́ àwọn àgùntàn sọ́nà, tó ń mára tù wọ́n, tó sì máa ń dáàbò bò wọ́n. Irú olùṣọ́ àgùntàn tí Dáfídì náà jẹ́ nìyẹn. Ó sì fẹ́ fi ‘gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀’ sin Ọlọ́run.​—Sm. 23:6.

Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà ló fẹ̀mí ẹ̀ darí Dáfídì láti kọ gbogbo ohun tó kọ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú wà lára àwọn ohun tó kọ. Bí àpẹẹrẹ ní Sáàmù 110, Dáfídì sọ nípa ìgbà tí Olúwa òun máa “jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún [Ọlọ́run]” ní ọ̀run, tó sì máa gba agbára ńlá. Kí ló máa fi agbára náà ṣe? Ó máa fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ó sì máa lò ó láti fi “mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè” ayé. Dáfídì ni baba ńlá Mèsáyà tó máa ṣàkóso láti ọ̀run, tó sì tún máa jẹ́ “àlùfáà títí láé.” (Sm. 110:1-6) Jésù sọ pé òun ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sáàmù 110 máa ṣẹ sí lára àti pé ọjọ́ iwájú ló máa ṣẹ.​—Mát. 22:41-45.

Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí Dáfídì láti kọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà láyé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nígbà tó bá jíǹde, tá á sì máa yin Jèhófà títí láé. Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí Sáàmù 37:10, 11, 29 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì àtijọ́ àtàwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Ọlọ́run bá mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ.​—Wo ìpínrọ̀ 8 nínú àpilẹ̀kọ náà, “O Máa Wà Pẹ̀lú Mi Ní Párádísè” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Sáàmù 61:8 àtàwọn ẹsẹ míì tó jọ ọ́ nínú sáàmù jẹ́ ká mọ̀ pé ó wu Dáfídì ní Ísírẹ́lì àtijọ́ láti máa yin Jèhófà lógo títí tá á fi kú. Àwọn ẹsẹ náà tún jẹ́ ká mọ ohun tí Dáfídì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Jèhófà bá jí i dìde sáyé.