ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51
Bí Ọkàn Ẹ Ṣe Lè Balẹ̀ Nígbà Rògbòdìyàn
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.”—JÒH. 14:27.
ORIN 112 Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí ni “àlàáfíà Ọlọ́run,” àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ní in? (Fílípì 4:6, 7)
ÀLÀÁFÍÀ kan wà tí ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí ò mọ̀. Ìyẹn ni “àlàáfíà Ọlọ́run” tó máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ torí pé a ní àjọse tó dáa pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run. Tá a bá ní àlàáfíà Ọlọ́run, ọkàn wa máa balẹ̀. (Ka Fílípì 4:6, 7.) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. A sì tún máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú “Ọlọ́run àlàáfíà” fúnra rẹ̀. (1 Tẹs. 5:23) Torí náà, tá a bá mọ Bàbá wa ọ̀run, tá a gbẹ́kẹ̀ lé e, tá a sì ń ṣègbọràn sí i, àlàáfíà Ọlọ́run máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ tí ìṣòro bá dé bá wa.
2. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè ní àlàáfíà Ọlọ́run?
2 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká ní àlàáfíà Ọlọ́run, kí ọkàn wa sì balẹ̀ tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀ ládùúgbò wa, tí wọ́n bá ń jagun abẹ́lé tàbí tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa? Tí ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà wá gan-an. Àmọ́ Jésù ti sọ fáwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.” (Jòh. 14:27) Inú wa dùn pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù yìí lónìí. Bí wọ́n ṣe ń fara da onírúurú ìṣòro ni Jèhófà ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ìyẹn sì ń mú kí ọkàn wọn balẹ̀.
BÁ A ṢE LÈ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÍ ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN BÁ ṢẸLẸ̀
3. Báwo ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe lè kó wa lọ́kàn sókè?
3 Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa, ó lè jẹ́ kí nǹkan nira gan-an fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo nǹkan tí àrùn Kòrónà fojú àwọn èèyàn rí. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, àwọn tó ju ìdajì lọ ni ò rórun sùn nígbà àjàkálẹ̀ àrùn náà. Ìyẹn ti jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa kọ́kàn sókè, kí wọ́n sorí kọ́, kí wọ́n mutí àmujù, kí wọ́n lo oògùn olóró, kí wọ́n sì hùwà ipá. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ gbìyànjú àtigbẹ̀mí ara wọn. Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀ ládùúgbò ibi tó ò ń gbé, kí ló máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀, kó o sì ní àlàáfíà Ọlọ́run?
4. Nígbà tá a mọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, báwo nìyẹn ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
4 Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àjàkálẹ̀ àrùn máa wà “láti ibì kan dé ibòmíì.” (Lúùkù 21:11) Báwo lohun tí Jésù sọ yìí ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀? Kì í yà wá lẹ́nu tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀. A mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ló ń ṣẹ. Torí náà, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwa tá à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ ò bẹ̀rù.”—Mát. 24:6.
5. (a) Kí ni Fílípì 4:8, 9 sọ pé ká máa gbàdúrà nípa ẹ̀ tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀? (b) Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń tẹ́tí sí Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀?
5 Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, ó lè kó wa lọ́kàn sókè gan-an, kí ìdààmú sì bá wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Desi nìyẹn. b Lẹ́yìn tí àrùn Kòrónà pa àbúrò bàbá ẹ̀, ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá ẹ̀ àti dókítà ẹ̀, àyà ẹ̀ já pé òun náà máa kó àrùn yẹn, òun á sì kó o ran ìyá òun tó ti dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, àyà ẹ̀ ń já pé ìgbàkigbà niṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ òun àti pé òun lè má rówó ilé san tàbí rówó ra oúnjẹ. Àwọn nǹkan yìí kó o lọ́kàn sókè débi pé kò rórun sùn mọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ọkàn Desi balẹ̀. Kí ló jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀? Ó dìídì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀, kóun sì yéé ro èròkerò. (Ka Fílípì 4:8, 9.) Ó máa ń jẹ́ kí Jèhófà bá òun sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Ohùn jẹ́jẹ́ táwọn tó ń ka Bíbélì yẹn fi ń kà á máa ń tù mí lára, ó sì ń jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.”—Sm. 94:19.
6. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tó o sì ń lọ sípàdé déédéé?
6 Ó dájú pé tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, àwọn ohun kan wà tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ tó ò ní lè ṣe mọ́. Àmọ́, má jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí lọ sípàdé. Àwọn ìtàn ìgbésí ayé tó wà nínú àwọn ìwé àtàwọn fídíò wa máa ń rán wa létí pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tí wọ́n nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 5:9) Tó o bá lọ sípàdé, àwọn nǹkan tó o bá gbọ́ níbẹ̀ máa fún ẹ níṣìírí, kò sì ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò. Yàtọ̀ síyẹn, wàá láǹfààní láti tu àwọn ará nínú, àwọn náà á sì tù ẹ́ nínú. (Róòmù 1:11, 12) Tó o bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tára wọn ò yá, nígbà tí wọ́n ń bẹ̀rù tàbí nígbà tí wọ́n ronú pé àwọn dá wà, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dúró ti ìwọ náà.
7. Kí la rí kọ́ lára àpọ́sítélì Jòhánù?
7 Máa bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ sọ̀rọ̀. Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, ó lè gba pé ká má sún mọ́ àwọn èèyàn jù, títí kan àwọn ará wa. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó lè ṣe wá bó ṣe ṣe àpọ́sítélì Jòhánù. Ó wù ú pé kó rí Gáyọ́sì ọ̀rẹ́ ẹ̀ lójúkojú. (3 Jòh. 13, 14) Àmọ́ Jòhánù rí i pé kò ní ṣeé ṣe fóun láti rí Gáyọ́sì lásìkò yẹn. Kò sóhun tí Jòhánù lè ṣe ju pé kó kọ lẹ́tà sí i. Torí náà, tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti lọ kí àwọn ará nílé, máa pè wọ́n lórí fóònù, máa pè wọ́n lórí ìkànnì kẹ́ ẹ sì tan fídíò yín, kó o sì tún máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn. Tó o bá ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ déédéé, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. Bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ tó o bá ń ṣàníyàn, kó o sì gba ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ.—Àìsá. 32:1, 2.
BÁ A ṢE LÈ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÍ ÀJÁLÙ BÁ ṢẸLẸ̀
8. Báwo ni àjálù ṣe lè kó wa lọ́kàn sókè?
8 Tí omíyalé tàbí ìmìtìtì ilẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ lágbègbè yín tàbí tí iná bá jó ilé yín, ó ṣeé ṣe káyà ẹ ṣì máa já kódà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún ti kọjá. Táwọn èèyàn ẹ kan bá kú tàbí tí àjálù ba àwọn nǹkan ẹ jẹ́, ó lè kó ìdààmú bá ẹ, inú lè bí ẹ tàbí kó o tiẹ̀ sọ̀rètí nù. Ìyẹn ò sọ pé o nífẹ̀ẹ́ nǹkan tara tàbí pé o ò nígbàgbọ́. Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ yẹn ò rọrùn rárá, torí náà kò ní ya àwọn èèyàn lẹ́nu tí wọ́n bá rí i pé ọ̀rọ̀ náà dùn ẹ́ gan-an. (Jóòbù 1:11) Àmọ́ láìka gbogbo nǹkan yẹn sí, ọkàn ẹ ṣì lè balẹ̀. Lọ́nà wo?
9. Kí ni Jésù sọ tí ò ní jẹ́ ká kọ́kàn sókè tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?
9 Máa rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ. Àwọn èèyàn kan rò pé àjálù ò lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láé, àmọ́ àwa mọ̀ pé àjálù á máa ṣẹlẹ̀, ó sì lè kan àwa náà. Jésù ti sọ fáwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé “ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára” àtàwọn àjálù míì máa ṣẹlẹ̀ kí òpin tó dé. (Lúùkù 21:11) Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i,” àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ń ṣẹ lónìí torí pé ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá àtàwọn afẹ̀míṣòfò túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Mát. 24:12) Jésù ò sọ pé àwọn tí ò ṣèfẹ́ Ọlọ́run nìkan làwọn àjálù yìí á máa ṣẹlẹ̀ sí. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni àjálù ti ṣẹlẹ̀ sí. (Àìsá. 57:1; 2 Kọ́r. 11:25) Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó dájú pé ó máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò kọ́kàn wa lè balẹ̀, ká sì wà ní àlàáfíà.
10. Tá a bá ń múra sílẹ̀ de àjálù, báwo nìyẹn ṣe ń fi hàn pé a nígbàgbọ́? (Òwe 22:3)
10 Tá a bá ti múra sílẹ̀ de àjálù, a ò ní kọ́kàn sókè tí àjálù bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ lójijì. Àmọ́ tá a bá múra sílẹ̀ de àjálù, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá? Rárá o. Kódà, bá a ṣe múra sílẹ̀ de àjálù yẹn gan-an ló fi hàn pé a gbà pé Jèhófà máa bójú tó wa. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa múra sílẹ̀ de àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀. (Ka Òwe 22:3.) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni ètò Ọlọ́run máa ń gbà wá níyànjú pé ká múra sílẹ̀ de àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ lójijì. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìwé wa, nípàdé ìjọ àti nínú àwọn ìfilọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe. c Ṣé lóòótọ́ la fọkàn tán Jèhófà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká múra sílẹ̀ báyìí kí àjálù tó dé.
11. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Margaret ṣe?
11 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Margaret. Àwọn aláṣẹ ìjọba sọ fún un pé kó kúrò nílé ẹ̀ torí iná ńlá tó ń jó lágbègbè yẹn. Àmọ́ torí pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ sá kúrò lẹ́ẹ̀kan náà, ọ̀nà dí pa, kò sì síbi táwọn èèyàn lè gbà mọ́. Èéfín gba àdúgbò náà kan, gbogbo ẹ̀ sì dúdú kirikiri, kódà Margaret ò lè gbé ọkọ̀ ẹ̀ kọjá níbẹ̀. Àmọ́ ó la ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn já torí pé ó ti múra sílẹ̀. Ó ti tọ́jú ìwé ajúwe ọ̀nà kan sínú pọ́ọ̀sì ẹ̀, ìwé náà sì jẹ́ kó mọ ọ̀nà míì tó lè gbà sá lọ. Kódà ó ti wa mọ́tò ẹ̀ gba ọ̀nà yẹn rí, kó lè rọrùn fún un láti mọ bó ṣe máa kọjá tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ lójijì. A dúpẹ́ pé Margaret múra sílẹ̀, ohun tí ò sì jẹ́ kí ẹ̀mí ẹ̀ lọ sí i nìyẹn.
12. Tí wọ́n bá sọ ohun tá a máa ṣe fún wa nígbà àjálù, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe é?
12 Nígbà míì, ìjọba máa ń sọ fún wa pé àwọn àsìkò kan la lè jáde nílé, wọ́n sì lè ní ká sá kúrò ládùúgbò wa tàbí ká ṣe àwọn nǹkan míì tó máa gbẹ̀mí wa là. Tí wọ́n bá tọ́ àwọn kan sọ́nà, wọn kì í tètè tẹ̀ lé e, wọ́n sì lè máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la torí pé wọn ò fẹ́ fi àwọn nǹkan ìní wọn sílẹ̀. Àmọ́ kí làwa Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣe tí ìjọba bá tọ́ wa sọ́nà? Bíbélì sọ fún wa pé: “Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí èèyàn dá sílẹ̀, ì báà jẹ́ ọba torí pé ó jẹ́ aláṣẹ tàbí àwọn gómìnà tó rán níṣẹ́.” (1 Pét. 2:13, 14) Ètò Ọlọ́run náà tún máa ń tọ́ wa sọ́nà ká má bàa kó sínú ewu. Léraléra ni wọ́n ń rán wa létí pé ká fún àwọn alàgbà ní nọ́ńbà fóònù àti àdírẹ́sì ilé wa, kó lè rọrùn fún wọn láti kàn sí wa tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ lójijì. Ṣé o ti ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n tún lè sọ fún wa pé ká má jáde kúrò nílé wa tàbí kí wọ́n ní ká tètè kúrò nílé kíákíá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè jẹ́ ká mọ ibi tá a ti máa rí àwọn nǹkan tá a nílò gbà, bá a ṣe máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ àtìgbà tó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Tá ò bá tẹ̀ lé ohun tí wọ́n sọ fún wa, a lè fi ẹ̀mí ara wa àti tàwọn alàgbà sínú ewu. Ìdí sì ni pé wọn ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wa. (Héb. 13:17) Margaret tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo gbà pé bí mo ṣe tẹ̀ lé ohun táwọn alàgbà àti ètò Ọlọ́run sọ fún wa ló dá ẹ̀mí mi sí.”
13. Kí ló jẹ́ kọ́kàn ọ̀pọ̀ Kristẹni tí àjálù lé kúrò nílé balẹ̀, tó sì jẹ́ kí wọ́n lálàáfíà?
13 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti kúrò nílé wọn nítorí àjálù, ogun tàbí rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn. Tí wọ́n bá dé ibi tí wọ́n sá lọ, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kára wọn lè mọlé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì máa ń bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn Jèhófà níbẹ̀. Àwọn náà máa ń “kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà” bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n tú ká káàkiri nítorí inúnibíni. (Ìṣe 8:4) Bí wọ́n ṣe ń wàásù yẹn ń jẹ́ kí wọ́n máa ronú nípa Ìjọba Ọlọ́run, dípò kí wọ́n máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wọn. Ìyẹn ló ń jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, kọ́kàn wọn sì balẹ̀.
BÁ A ṢE LÈ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÍ WỌ́N BÁ Ń ṢE INÚNIBÍNI SÍ WA
14. Kí nìdí tí inúnibíni fi máa ń kó wa lọ́kàn sókè?
14 Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, ó lè má ṣeé ṣe fún wa mọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó ń fún wa láyọ̀. Inú wa máa ń dùn tá a bá ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará déédéé, tá à ń wàásù níbi gbogbo, tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan míì láìbẹ̀rù pé ọlọ́pàá lè mú wa. Táwọn aláṣẹ ò bá jẹ́ ká ṣe àwọn nǹkan yẹn mọ́, ẹ̀rù lè máa bà wá torí a ò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí wa. Kò sóhun tó burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó yẹ ká wà lójúfò torí Jésù sọ pé inúnibíni lè mú káwọn ọmọlẹ́yìn òun kọsẹ̀. (Jòh. 16:1, 2) Torí náà, kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa?
15. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa bẹ̀rù inúnibíni? (Jòhánù 15:20; 16:33)
15 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:12) Kò rọrùn fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Andrei láti gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè ẹ̀. Ó ń ronú pé: ‘Àwa Ẹlẹ́rìí tó wà níbí pọ̀ gan-an, wọn ò ṣáà lè fi ọlọ́pàá mú gbogbo wa.’ Dípò kíyẹn fi í lọ́kàn balẹ̀, ṣe ló ń kó o lọ́kàn sókè ṣáá. Àwọn ará yòókù ò dara wọn láàmú, ṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, wọn ò sì ronú pé ọlọ́pàá ò ní mú àwọn. Wọ́n gbà pé ọlọ́pàá lè mú àwọn náà, àmọ́ ọkàn wọn balẹ̀ ju ti Andrei lọ. Torí náà, Andrei yí èrò ẹ̀ pa dà, ó sì fọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Kò pẹ́ tọ́kàn ẹ̀ fi balẹ̀, tó sì ń láyọ̀ láìka gbogbo ìṣòro yẹn sí. Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Lóòótọ́, Jésù sọ pé ká máa retí inúnibíni, síbẹ̀ ó fi dá wa lójú pé a ṣì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.—Ka Jòhánù 15:20; 16:33.
16. Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, kí ló yẹ ká ṣe tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe àwọn nǹkan kan?
16 Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn alàgbà lè sọ fún wa pé ká ṣe àwọn nǹkan kan. Àwọn ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe máa dáàbò bò wá, wọ́n máa ń jẹ́ ká rí ìwé àti fídíò tó dá lórí Bíbélì gbà, wọ́n sì máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa wàásù nìṣó débi tí àyè bá gbà wá dé. Torí náà, rí i pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ohun tí wọ́n bá sọ kódà tó ò bá mọ ìdí tí wọ́n fi sọ ọ́. (Jém. 3:17) Bákan náà, o ò gbọ́dọ̀ sọ ohunkóhun nípa àwọn ará tàbí nípa bá a ṣe ń ṣe nǹkan nínú ìjọ fáwọn tí ò yẹ kó o sọ ọ́ fún.—Oníw. 3:7.
17. Bíi tàwọn àpọ́sítélì, kí làwa náà ti pinnu pé a máa ṣe?
17 Ọ̀kan lára ìdí tí Sátánì fi ń ṣe inúnibíni sí wa ni pé ‘àwa là ń jẹ́rìí nípa Jésù.’ (Ìfi. 12:17) O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Sátánì àtàwọn èèyàn dẹ́rù bà ẹ́. Bí wọ́n tiẹ̀ ń ta kò wá, tá a bá ń wàásù tá a sì ń kọ́ni, ó máa ń fún wa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀. Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ táwọn aláṣẹ Júù sọ pé káwọn àpọ́sítélì má wàásù mọ́, àwọn àpọ́sítélì yẹn pinnu pé Ọlọ́run làwọn máa ṣègbọràn sí. Wọ́n ń wàásù nìṣó, iṣẹ́ yẹn sì ń fún wọn láyọ̀. (Ìṣe 5:27-29, 41, 42) Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n wàásù tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa. (Mát. 10:16) Àmọ́ tá a bá ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe, ọkàn wa máa balẹ̀ pé à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe àti pé à ń kéde ìhìn rere tó máa gbẹ̀mí là.
‘ỌLỌ́RUN ÀLÀÁFÍÀ MÁA WÀ PẸ̀LÚ Ẹ’
18. Kí ló yẹ ká máa rántí nípa ẹni tó lè fún wa ní àlàáfíà tòótọ́?
18 Lásìkò tí nǹkan bá le gan-an, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ṣì lè ní àlàáfíà tòótọ́. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, máa rántí pé àlàáfíà tó o nílò ni àlàáfíà Ọlọ́run, ìyẹn àlàáfíà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè fúnni. Torí náà, gbára lé Jèhófà nígbà àjàkálẹ̀ àrùn, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ. Má fi àwọn ará àti ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Máa ronú nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘Ọlọ́run àlàáfíà máa wà pẹ̀lú ẹ.’ (Fílí. 4:9) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bá a ṣe lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro káwọn náà lè ní àlàáfíà Ọlọ́run.
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
a Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jẹ́ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun ní àlàáfíà. Irú àlàáfíà wo ni Ọlọ́run máa ń fúnni, báwo la sì ṣe lè ní in? Báwo ni “àlàáfíà Ọlọ́run” ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là” nínú Jí! No. 5 2017.