ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49
Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé
“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”—JÒH. 17:3.
ORIN 147 Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Tá a bá ń ronú lórí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé a máa wà láàyè títí láé, kí nìyẹn máa mú ká ṣe?
JÈHÓFÀ ṣèlérí pé àwọn tó bá ń gbọ́ràn sí òun lẹ́nu ló máa rí “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Róòmù 6:23) Tá a bá ń ronú lórí ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa yìí, ó dájú pé ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Rò ó wò ná: Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi tó fi ṣèlérí pé títí láé lòun á máa wà pẹ̀lú wa.
2. Àǹfààní wo ni ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun ń ṣe fún wa?
2 Ìlérí tí Jèhófà ṣe pé a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun ń mú ká fara da àwọn ìṣòro wa. Kódà táwọn ọ̀tá wa bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà dójú ikú, ó dá wa lójú pé ó máa jí wa dìde, a ó sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Jòh. 5:28, 29; 1 Kọ́r. 15:55-58; Héb. 2:15) Kí ló mú kó dá wa lójú pé a lè wà láàyè títí láé? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí kan yẹ̀ wò.
JÈHÓFÀ Ò LÈ KÚ LÁÉ
3. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà lè mú ká wà láàyè títí láé? (Sáàmù 102:12, 24, 27)
3 A mọ̀ pé Jèhófà lè mú ká wà láàyè títí láé torí pé Òun ló fún wa ní ẹ̀mí, kò sì lè kú láé àti láéláé. (Sm. 36:9) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹsẹ Bíbélì díẹ̀ tó jẹ́ ká rí i pé láti ayérayé ni Jèhófà ti wà, kò sì lè kú láé. Sáàmù 90:2 sọ pé “láti ayérayé dé ayérayé” ni Jèhófà ti wà. Sáàmù 102 náà sọ nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. (Ka Sáàmù 102:12, 24, 27.) Wòlíì Hábákúkù náà sọ nípa Baba wa ọ̀run pé: “Jèhófà, ṣebí láti ayérayé ni ìwọ ti wà? Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.”—Háb. 1:12.
4. Ṣé ó yẹ ká máa da ara wa láàmú tó bá ṣòro fún wa láti gbà pé Jèhófà ti wà láàyè láti ayérayé? Ṣàlàyé.
4 Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti wà láti ayérayé, tó sì máa wà “títí ayé”? (Àìsá. 40:28) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣòro fún láti gbà bẹ́ẹ̀. Élíhù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Iye àwọn ọdún rẹ̀ kọjá òye wa.” (Jóòbù 36:26) Àmọ́ torí pé nǹkan kan ò yé wa ò túmọ̀ sí pé nǹkan yẹn ò sí. Bí àpẹẹrẹ, a lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí iná mànàmáná ṣe ń ṣiṣẹ́, àmọ́ ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò síná mànàmáná? Rárá! Lọ́nà kan náà, àwa èèyàn ò lè mọ ìdí tó fi jẹ́ pé láti ayérayé ni Jèhófà ti wà àti pé kò lè kú láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò yé wa délẹ̀délẹ̀, ìyẹn ò sọ pé Jèhófà ò ní wà láàyè títí láé. Agbára Jèhófà ò mọ síbi tí òye wa dé. (Róòmù 11:33-36) Kódà, kí àwọn nǹkan tó wà lágbàáyé yìí tó wà ni Jèhófà ti wà. Bí àpẹẹrẹ, kí oòrùn tó wà ni Jèhófà ti wà. Bíbélì tiẹ̀ fi dá wa lójú pé Jèhófà ni “Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a.” Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti wà kó tó “na ọ̀run bí aṣọ.” (Jer. 51:15; Ìṣe 17:24) Ẹ̀rí míì wo ló wà tó jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè wà láàyè títí láé?
JÈHÓFÀ DÁ WA PÉ KÁ WÀ LÁÀYÈ TÍTÍ LÁÉ
5. Àǹfààní wo ni tọkọtaya àkọ́kọ́ ní?
5 Nígbà tí Jèhófà ń dá àwọn ohun alààyè sáyé, àwa èèyàn nìkan ló dá pé ká wà láàyè títí láé. Ó dá wa lọ́nà tá ò fi ní kú. Àmọ́, ó kìlọ̀ fún Ádámù pé: “O ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.” (Jẹ́n. 2:17) Ká ní Ádámù àti Éfà gbọ́ràn sí Jèhófà ni, wọn ò bá má kú. Ká sọ pé wọ́n ṣègbọràn ni, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà ní kí wọ́n jẹ nínú “igi ìyè” náà tó bá yá. Ìyẹn sì ni ò bá jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn máa “wà láàyè títí láé.” b—Jẹ́n. 3:22.
6-7. (a) Ẹ̀rí míì wo ló fi hàn pé Jèhófà ò fẹ́ ká máa kú? (b) Kí làwọn nǹkan tó wù ẹ́ pé kó o ṣe nínú ayé tuntun? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ 7.)
6 Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ṣe fi hàn pé ọpọlọ wa lè gba nǹkan tó pọ̀ gan-an, kódà tá a bá lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, ọpọlọ wa ò lè kún títí tá a fi máa kú. Lọ́dún 2010, àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Scientific American Mind sọ pé nígbà tí wọ́n ṣírò ohun tí ọpọlọ wa lè gbà, wọ́n rí i pé ó lè gba nǹkan tó pọ̀ tó fídíò téèyàn máa fi mílíọ̀nù mẹ́ta wákàtí wò. Ìyẹn sì máa ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún lọ. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí ọpọlọ wa gba nǹkan tó jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa. Síbẹ̀, àwọn nǹkan yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà dá ọpọlọ wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé tá a bá tiẹ̀ lo àádọ́rin (70) tàbí ọgọ́rin (80) ọdún láyé, kò lè kún.—Sm. 90:10.
7 Jèhófà tún dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé kì í wù wá pé ká kú. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ti “fi ayérayé sí [wa] lọ́kàn.” (Oníw. 3:11) Ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé ọ̀tá wa ni ikú. (1 Kọ́r. 15:26) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣàìsàn kan tó le, ṣé àá máa wo ara wa níran títí tá a fi máa kú? Rárá. Ó dájú pé a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà, àá sì lo àwọn oògùn tí wọ́n bá fún wa kí àìsàn náà lè lọ. Kódà, gbogbo nǹkan tó bá gbà la máa ṣe ká má bàa kú. Tẹ́nì kan tá a fẹ́ràn bá sì kú, bóyá ọmọdé ni tàbí àgbàlagbà, ó ṣì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Jòh. 11:32, 33) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ò ní fi sí wa lọ́kàn pé ká wà láàyè títí láé tóun fúnra ẹ̀ ò bá fẹ́ ká wà láàyè títí láé. Àmọ́ àwọn ẹ̀rí míì wà tó jẹ́ ká gbà pé a lè wà láàyè títí láé. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe nígbà àtijọ́ àtàwọn ohun tó ń ṣe báyìí tó fi hàn pé ó ṣì fẹ́ káwa èèyàn wà láàyè títí láé.
OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́ FÁWA ÈÈYÀN Ò YÍ PA DÀ
8. Kí ni Àìsáyà 55:11 sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe ohun tó fẹ́ fún wa?
8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, tí ìyẹn sì mú káwọn ọmọ wọn máa kú, ohun tí Jèhófà fẹ́ fáwa èèyàn ò yí pa dà. (Ka Àìsáyà 55:11.) Ó ṣì ń wù ú pé káwọn olóòótọ́ èèyàn wà láàyè títí láé. Ohun tó sì jẹ́ ká gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ ni àwọn nǹkan tó ti sọ àtàwọn nǹkan tó ti ṣe.
9. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe? (Dáníẹ́lì 12:2, 13)
9 Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jí àwọn tó ti kú dìde, òun sì máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣe 24:15; Títù 1:1, 2) Ó dá ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù lójú pé ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. (Jóòbù 14:14, 15) Wòlíì Dáníẹ́lì náà mọ̀ pé Jèhófà máa jí àwọn tó ti kú dìde, á sì fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Sm. 37:29; ka Dáníẹ́lì 12:2, 13.) Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn Júù náà mọ̀ pé Jèhófà lè mú káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ rí “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Lúùkù 10:25; 18:18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí, kódà nígbà tí Jésù fúnra ẹ̀ kú, Jèhófà Bàbá rẹ̀ ló jí i dìde.—Mát. 19:29; 22:31, 32; Lúùkù 18:30; Jòh. 11:25.
10. Kí làwọn àjíǹde tó ti wáyé sẹ́yìn jẹ́ ká mọ̀? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ 10.)
10 Jèhófà ni Olùfúnni-ní-Ìyè, ó sì lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ó fún wòlíì Èlíjà lágbára láti jí ọmọkùnrin opó Sáréfátì dìde. (1 Ọba 17:21-23) Nígbà tó yá, Ọlọ́run ran wòlíì Èlíṣà lọ́wọ́ láti jí ọmọkùnrin obìnrin ará Ṣúnémù kan dìde. (2 Ọba 4:18-20, 34-37) Àwọn àjíǹde yìí àtàwọn àjíǹde míì tó wáyé nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé Bàbá òun ti fún òun lágbára láti jí àwọn èèyàn dìde. (Jòh. 11:23-25, 43, 44) Ní báyìí tí Jésù ti wà lọ́run, “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé” ni Bàbá rẹ̀ ti fún un. Torí náà, ipò tí Jésù wà lọ́run báyìí máa jẹ́ kó lè mú ìlérí Jèhófà ṣẹ pé “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí” máa jíǹde, wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé.—Mát. 28:18; Jòh. 5:25-29.
11. Báwo ni ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé?
11 Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kú ikú oró? Jésù jẹ́ ká mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á, ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ kú kó lè rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìyẹn ló jẹ́ ká nírètí pé a máa wà láàyè títí láé. (Mát. 20:28) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fáwa èèyàn, ó ní: “Bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan, àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan. Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.”—1 Kọ́r. 15:21, 22.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe ohun tó fẹ́ fún aráyé?
12 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé àti pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ayé. (Mát. 6:9, 10) Ara ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fáwa èèyàn ni pé ká máa gbé ayé títí láé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà ti yan Ọmọ ẹ̀ láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Ọlọ́run sì ti ń kó àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) jọ lára àwa tá a wà láyé, kí wọ́n lè bá Jésù ṣàkóso láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.—Ìfi. 5:9, 10.
13. Kí ni Jèhófà ń ṣe báyìí, kí ló sì yẹ káwa náà máa ṣe?
13 Jèhófà ti ń kó “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” jọ báyìí, ó sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti gbé lábẹ́ Ìjọba rẹ̀. (Ìfi. 7:9, 10; Jém. 2:8) Lónìí, ogun ò jẹ́ káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan mọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n máa bẹ̀rù ara wọn. Àmọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí, ẹ̀yà wọn tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti ń fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀ báyìí. (Míkà 4:3) Dípò tí wọ́n á fi máa jagun tó ń fẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣòfò, ṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, kí wọ́n lè ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tím. 6:19) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lè ta kò wọ́n tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ torí pé Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fara mọ́, Jèhófà ń rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ni òun ń pèsè fún wọn. (Mát. 6:25, 30-33; Lúùkù 18:29, 30) Àwọn nǹkan yìí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú àwọn ìṣòro wa àti pé Ìjọba yìí ni Jèhófà máa lò láti ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́ fún aráyé.
À Ń RETÍ ỌJỌ́ Ọ̀LA TÓ DÁA
14-15. Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé ikú ò ní sí mọ́ ṣe máa ṣẹ?
14 Jésù ti di Ọba lọ́run báyìí, ó sì máa mú gbogbo ìlérí Jèhófà ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:20) Àtọdún 1914 ni Jésù ti ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Sm. 110:1, 2) Òun àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso máa tó parí ìṣẹ́gun wọn, wọ́n sì máa pa gbogbo àwọn èèyàn burúkú run.—Ìfi. 6:2.
15 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa jí àwọn tó ti kú dìde, ó sì máa sọ gbogbo àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn di pípé. Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn, àwọn tí Jèhófà bá sọ pé wọ́n jẹ́ olódodo ló máa “jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sm. 37:10, 11, 29) Torí náà, “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn” máa “di asán.” Ìyẹn mà múnú wa dùn gan-an o.—1 Kọ́r. 15:26.
16. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìdí pàtàkì tá a fi ń sin Jèhófà?
16 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa gbé ayé títí láé. Ìrètí tá a ní yìí máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Kì í kàn ṣe torí pé ó wù wá láti wà láàyè títí láé ló ṣe yẹ ká máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Jésù ni pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tọkàntọkàn. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, ìyẹn ń jẹ́ ká máa fara wé wọn, ká sì máa wàásù fáwọn èèyàn nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. (Róòmù 10:13-15) Torí náà, tá ò bá mọ tara wa nìkan, inú Jèhófà máa dùn sí wa, ó sì máa di ọ̀rẹ́ wa títí láé.—Héb. 13:16.
17. Ìpinnu wo ni kálukú wa máa ṣe? (Mátíù 7:13, 14)
17 Ṣé o máa wà lára àwọn tó máa rí ìyè àìnípẹ̀kun? Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe ká lè wà lára wọn. Torí náà, ọwọ́ wa ló kù sí bóyá a ó máa rìn ní ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun, tá ò sì ní kúrò níbẹ̀. (Ka Mátíù 7:13, 14.) Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà táwa èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé títí láé? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 141 Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́
a Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o wà láàyè títí láé? Jèhófà ti ṣèlérí fún wa pé tó bá dọjọ́ kan, a máa wà láàyè títí láé, a ò sì ní kú mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú ká gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ.
b Wo àpótí náà “ Bí Wọ́n Ṣe Lo Ọ̀rọ̀ Náà ‘Títí Láé’ Nínú Bíbélì.”
c ÀWÒRÁN: Arákùnrin àgbàlagbà kan ń ronú nípa àwọn nǹkan tó máa fẹ́ ṣe nígbà tó bá láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun.