Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50

“O Máa Wà Pẹ̀lú Mi Ní Párádísè”

“O Máa Wà Pẹ̀lú Mi Ní Párádísè”

“Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”​—LÚÙKÙ 23:43.

ORIN 145 Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí Jésù tó kú, kí ló sọ fún ọ̀daràn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀? (Lúùkù 23:39-43)

 JÉSÙ àtàwọn ọ̀daràn méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ ń jẹ̀rora bí wọ́n ṣe ń kú lọ. (Lúùkù 23:32, 33) Àwọn ọ̀daràn náà ń sọ̀rọ̀ burúkú sí Jésù, ìyẹn sì fi hàn pé wọn kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. (Mát. 27:44; Máàkù 15:32) Àmọ́ ọ̀kan lára wọn yí pa dà. Ó sọ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” Jésù wá dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Ka Lúùkù 23:39-43.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀daràn yẹn lè ti gbọ́ nípa “Ìjọba ọ̀run” tí Jésù wàásù ẹ̀, kò di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Jésù ò sì sọ pé ọkùnrin náà máa wà pẹ̀lú òun nínú Ìjọba ọ̀run. (Mát. 4:17) Àmọ́ Párádísè tó máa wà láyé lọ́jọ́ iwájú ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Kí la lè sọ nípa ọ̀daràn tó bá Jésù sọ̀rọ̀ àtohun tó mọ̀ nípa àjíǹde? (Wo ìpínrọ̀ 2-3)

2. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Júù ni ọ̀daràn tó ronú pìwà dà yẹn?

2 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà yẹn jẹ́ Júù torí ó sọ fún èkejì rẹ̀ pé: “Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, ní báyìí tó jẹ́ pé ìdájọ́ kan náà nìwọ náà gbà?” (Lúùkù 23:40) Ọlọ́run kan ṣoṣo làwọn Júù ń sìn, àmọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń sin ọ̀pọ̀ ọlọ́run. (Ẹ́kís. 20:2, 3; 1 Kọ́r. 8:5, 6) Tó bá jẹ́ pé àwọn ọ̀daràn yẹn kì í ṣe Júù ni, ìbéèrè tí ọ̀daràn yẹn ì bá béèrè ni pé, “Ṣé o ò bẹ̀rù àwọn ọlọ́run rárá ni?” Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ò rán Jésù sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” ló rán an sí. (Mát. 15:24) Ọlọ́run ti sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa jí àwọn òkú dìde, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa jí Jésù dìde láti ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé ọkùnrin náà nírètí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde.

3. Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà máa rò nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa Párádísè? Ṣàlàyé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15)

3 Tó bá jẹ́ pé Júù ni ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa Ádámù àti Éfà àti ọgbà Párádísè tí Jèhófà fi wọ́n sí. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé ọgbà kan tó rẹwà, tó sì wà láyé ni Párádísè tí Jésù ń sọ.​—Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:15.

4. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn náà máa jẹ́ ká ṣe?

4 Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ọ̀daràn náà mú ká ronú nípa bí ìgbésí ayé nínú Párádísè ṣe máa rí. A lè mọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè tá a bá wo bí àlàáfíà ṣe wà nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso. Bíbélì sọ pé Jésù tóbi ju Sólómọ́nì lọ, ìyẹn sì jẹ́ ká gbà pé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso máa sọ ayé yìí di Párádísè. (Mát. 12:42) Torí náà, ó yẹ kí “àwọn àgùntàn mìíràn” mọ ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè gbé ayé títí láé nínú Párádísè.​—Jòh. 10:16.

BÁWO NI ÌGBÉSÍ AYÉ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ ṢE MÁA RÍ?

5. Báwo lo ṣe rò pé ìgbésí ayé nínú Párádísè máa rí?

5 Báwo lo ṣe rò pé ìgbésí ayé nínú Párádísè máa rí? Ó ṣeé ṣe kó o máa wò ó pé ibì kan tó rẹwà bí ọgbà Édẹ́nì ni. (Jẹ́n. 2:7-9) Ó lè mú kó o rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Míkà sọ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run pé “kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.” (Míkà 4:3, 4) O tún lè rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà. (Sm. 72:16; Àìsá. 65:21, 22) Torí náà, o lè máa fojú inú wò ó pé o wà nínú ọgbà kan tó rẹwà, tó o jókòó sídìí tábìlì tí oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn wà lórí ẹ̀, tó o sì ń gbọ́ òórùn dídùn lára àwọn ewéko àti òdòdó. O tún lè fojú inú wò ó pé ò ń gbọ́ bí àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣe ń rẹ́rìn-ín, tí wọ́n sì ń bá ara wọn ṣeré pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti jí dìde lára wọn. Gbogbo nǹkan yìí kì í ṣe ohun tí ò lè ṣẹ. Ó dájú pé gbogbo ẹ̀ pátá ló máa ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Párádísè máa dùn gan-an torí gbogbo wa la máa gbádùn iṣẹ́ tá a bá ń ṣe níbẹ̀.

A máa dá àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn sì ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tá a máa ṣe (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Àwọn iṣẹ́ wo la máa ṣe nínú Párádísè? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Nígbà tí Jèhófà dá wa, ó fẹ́ ká máa gbádùn iṣẹ́ tá a bá ń ṣe. (Oníw. 2:24) Torí náà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Àwọn tó la ìpọ́njú ńlá já àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó máa jíǹde máa nílò aṣọ, oúnjẹ àti ibùgbé. Torí náà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la máa ṣe ká tó lè pèsè àwọn nǹkan yìí. Bí Ọlọ́run ṣe sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n máa tún ọgbà Édẹ́nì tó jẹ́ ilé wọn ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà máa tún ayé yìí ṣe títí á fi di Párádísè. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. A tún máa kọ́ àwọn olóòótọ́ tí wọ́n gbé ayé kí Jésù tó wá sáyé kí wọ́n lè mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kú.

7. Kí ló dá wa lójú nípa Párádísè, kí sì nìdí?

7 Ó dá wa lójú pé ìgbésí ayé nínú Párádísè máa dáa. Àá máa gbé ní àlàáfíà, àá ní gbogbo ohun tá a nílò, gbogbo nǹkan á sì wà létòlétò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà ti fi bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà àkóso Ọmọ rẹ̀ hàn wá. A rí àpẹẹrẹ ìyẹn nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso.

ÀKÓSO ỌBA SÓLÓMỌ́NÌ JẸ́ KÁ MỌ BÍ PÁRÁDÍSÈ ṢE MÁA RÍ

8. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 37:10, 11, 29 ṣe ṣẹ lẹ́yìn tí Ọba Dáfídì kọ ọ́? (Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.)

8 Ọlọ́run fẹ̀mí ẹ̀ darí Ọba Dáfídì láti sọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí ọba kan tó jẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n bá ń ṣàkóso lọ́jọ́ iwájú. (Ka Sáàmù 37:10, 11, 29.) A sábà máa ń ka Sáàmù 37:11 fáwọn èèyàn tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Párádísè tó ń bọ̀. Ìyẹn dáa gan-an torí Jésù náà lo ẹsẹ Bíbélì yẹn nínú Ìwàásù orí Òkè, tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 5:5) Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ tún jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Ọba Sólómọ́nì bá ń ṣàkóso. Nígbà tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn àlàáfíà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì rí gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò ní ilẹ̀ “tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.” Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi . . . , màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà, ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín.” (Léf. 20:24; 26:3, 6) Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ló ṣẹ nígbà àkóso Sólómọ́nì. (1 Kíró. 22:9; 29:26-28) Jèhófà tún ṣèlérí pé àwọn èèyàn burúkú “ò ní sí mọ́.” (Sm. 37:10) Torí náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 37:10, 11, 29 ṣẹ nígbà àtijọ́, ó sì tún máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.

9. Kí ni ọbabìnrin Ṣébà sọ nípa àkóso Ọba Sólómọ́nì?

9 Òkìkí kàn dé ọ̀dọ̀ ọbabìnrin Ṣébà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbádùn àlàáfíà, wọ́n sì ń rí gbogbo ohun tí wọ́n nílò bí Sólómọ́nì ṣe ń ṣàkóso wọn. Ni ọbabìnrin náà bá gbéra láti ìlú ẹ̀ tó jìnnà wá sí Jerúsálẹ́mù kó lè fojú ara ẹ̀ rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. (1 Ọba 10:1) Lẹ́yìn tó wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba Sólómọ́nì, ó sọ pé: “Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. . . . Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!” (1 Ọba 10:6-8) Àmọ́ ìtọ́wò lásán ni ohun táwọn èèyàn gbádùn nígbà àkóso Sólómọ́nì tá a bá fi wé ohun tí Jèhófà máa ṣe fáráyé nígbà tí Jésù Ọmọ rẹ̀ bá ń ṣàkóso.

10. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ju Sólómọ́nì lọ?

10 Gbogbo ọ̀nà ni Jésù fi ju Sólómọ́nì lọ. Aláìpé ni Sólómọ́nì, ó sì ṣe àwọn àṣìṣe ńlá tó kó àwọn èèyàn Ọlọ́run síṣòro. Àmọ́ alákòóso pípé ni Jésù, kì í sì í ṣàṣìṣe. (Lúùkù 1:32; Héb. 4:14, 15) Jésù borí gbogbo àdánwò tó le gan-an tí Sátánì gbé kò ó lójú. Jésù ti fi hàn pé òun ò lè dẹ́ṣẹ̀ tàbí ṣe ohunkóhun tó máa pa àwọn olóòótọ́ èèyàn lára nínú ìjọba rẹ̀. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run dá wa lọ́lá gan-an bó ṣe fi Jésù ṣe Ọba wa.

11. Àwọn wo ló máa ran Jésù lọ́wọ́ nígbà tó bá ń ṣàkóso?

11 Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ló máa bá Jésù ṣàkóso, wọ́n á jọ máa bójú tó aráyé, wọ́n á sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé. (Ìfi. 14:1-3) Wọ́n jìyà nígbà tí wọ́n wà láyé, wọ́n sì fara da ọ̀pọ̀ àdánwò. Torí náà, wọ́n á mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn, wọ́n á sì lè bá wa kẹ́dùn. Àmọ́ iṣẹ́ wo gan-an làwọn tó fẹ́ bá Jésù ṣàkóso yìí máa ṣe?

IṢẸ́ WO LÀWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ MÁA ṢE?

12. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà máa yàn fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì?

12 Iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso pọ̀ gan-an ju èyí tó yàn fún Sólómọ́nì lọ. Orílẹ̀-èdè kan péré ni gbogbo èèyàn tí Sólómọ́nì bójú tó ń gbé. Àmọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé làwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run máa bójú tó. Ẹ ò rí àǹfààní ńlá tí Jèhófà fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì!

13. Iṣẹ́ pàtàkì míì wo làwọn tó fẹ́ bá Jésù ṣàkóso máa ṣe?

13 Bíi ti Jésù, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa jẹ́ ọba àti àlùfáà. (Ìfi. 5:10) Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè sọ pé àwọn àlùfáà ni kó máa bójú tó ètò ìlera àwọn èèyàn, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn èèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí pé Òfin náà ni “òjìji àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,” ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso máa ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìlera pípé àti àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Héb. 10:1) A ò tíì mọ bí àwọn ọba àtàwọn àlùfáà yìí ṣe máa bá àwọn èèyàn tó wà láyé sọ̀rọ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run, ó dìgbà yẹn ká tó mọ̀. Àmọ́, ó dá wa lójú pé nínú Párádísè, Jèhófà máa ṣètò bí àwọn tó wà láyé á ṣe máa rí ìtọ́sọ́nà gbà.​—Ìfi. 21:3, 4.

KÍ NI “ÀWỌN ÀGÙNTÀN MÌÍRÀN” GBỌ́DỌ̀ ṢE KÍ WỌ́N LÈ MÁA GBÉ INÚ PÁRÁDÍSÈ?

14. Àjọṣe wo ló wà láàárín “àwọn àgùntàn mìíràn” àtàwọn arákùnrin Kristi?

14 Jésù pe àwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32) Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ míì tó pè ní “àwọn àgùntàn mìíràn.” Àwùjọ méjèèjì wà nínú agbo kan. (Jòh. 10:16) Àwùjọ méjèèjì sì ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lónìí, wọ́n á sì jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ títí dìgbà tí ayé máa di Párádísè. Ní àkókò yẹn, “agbo kékeré” máa wà ní ọ̀run, àmọ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” máa wà láyé, wọ́n á sì máa retí àtigbé ayé títí láé. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wà tí “àwọn àgùntàn mìíràn” gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè gbé inú Párádísè.

Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti máa ṣe ohun tó fi hàn pé a fẹ́ gbé inú Párádísè tó ń bọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 15) b

15. (a) Báwo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ṣe ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn? (b) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ arákùnrin tó wà nínú ilé ìtajà yẹn? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ọ̀daràn tó ronú pìwà dà yẹn kú láì láǹfààní láti fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa àgùntàn mìíràn ò rí bẹ́ẹ̀ torí a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní báyìí láti fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù bá a ṣe ń ṣohun tó dáa sáwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀. Jésù sọ pé ohun táwọn tó fìwà jọ àgùntàn bá ṣe sáwọn arákùnrin òun lòun máa fi ṣèdájọ́ wọn. (Mát. 25:31-40) Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe táá fi hàn pé à ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn ni pé ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:18-20) Torí náà, ó yẹ ká máa lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì irú bíi Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Tó ò bá tíì máa kọ́ ẹnì kankan lẹ́kọ̀ọ́, o ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ ọ̀pọ̀ èèyàn?

16. Kí la lè ṣe táá mú ká wà lára àwọn tó máa gbénú Ìjọba Ọlọ́run?

16 Kò yẹ ká dúró dìgbà tá a bá dénú Párádísè ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí Jèhófà fẹ́ ká máa hù níbẹ̀. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ká má sì ṣàṣejù nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe. Ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ọkọ tàbí aya wa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nínú ayé burúkú yìí, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn nínú Párádísè. Bákan náà, a lè kọ́ iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe nínú ayé tuntun, ká sì máa hùwà tó fi hàn pé a ti múra tán láti gbébẹ̀. Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé O Ti Múra Tán Láti ‘Jogún Ayé’?” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

17. Ṣé ó yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa? Ṣàlàyé.

17 Kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tá a ti dá sẹ́yìn. Àmọ́ ṣá, a ò gbọ́dọ̀ fi ẹbọ ìràpadà Jésù kẹ́wọ́ ká wá “mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà.” (Héb. 10:26-31) Ó dájú pé tá a bá ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a wá ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ àwọn alàgbà, tá a sì yí ìwà wa pa dà, Jèhófà ti dárí jì wá pátápátá nìyẹn. (Àìsá. 55:7; Ìṣe 3:19) Ẹ jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Farisí, ó ní: “Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Mát. 9:13) Torí náà, ẹbọ ìràpadà Jésù lágbára láti nu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò.

O LÈ GBÉ INÚ PÁRÁDÍSÈ TÍTÍ LÁÉ

18. Ìbéèrè wo ni wàá fẹ́ bi ọ̀daràn tí Jésù ṣèlérí fún?

18 Wò ó pé o wà nínú Párádísè, tó ò ń bá ọ̀daràn tí Jésù ṣèlérí fún yẹn sọ̀rọ̀. Ó dájú pé ẹ̀yin méjèèjì máa mọyì ẹbọ ìràpadà Jésù gan-an. Ó ṣeé ṣe kó o ní kó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní wákàtí díẹ̀ kí Jésù tó kú, kó o sì tún ní kó sọ bó ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí Jésù sọ fún un pé ó máa wà pẹ̀lú òun ní Párádísè. Ọ̀daràn náà lè bi ìwọ náà pé, báwo ni nǹkan ṣe rí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn nígbà tí Sátánì ń darí ayé. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ láti kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Éfé. 4:22-24.

Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, inú arákùnrin kan ń dùn bó ṣe ń yàwòrán torí ọjọ́ pẹ́ tó ti ń wù ú pé kóun mọ bí wọ́n ṣe ń yàwòrán (Wo ìpínrọ̀ 19)

19. Kí nìdí tí ìgbésí ayé nínú Párádísè kò fi ní sú wa? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

19 Ìgbésí ayé nínú Párádísè kò ní sú wa rárá. Ìgbà gbogbo làá máa bá àwọn èèyàn tó níwà rere pàdé, àá sì máa ṣe iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ojoojúmọ́ làá máa mọ Bàbá wa ọ̀run sí i, tá à sì máa gbádùn ohun tó pèsè fún wa. Àwọn ohun tá a máa kọ́ nípa Jèhófà ò ní lópin, a sì máa rí ohun púpọ̀ kọ́ lára àwọn nǹkan tó dá. Bá a bá ṣe ń pẹ́ láyé sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run á máa pọ̀ sí i. A mà dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù o, pé wọ́n jẹ́ ká nírètí láti gbé inú Párádísè títí láé!

ORIN 22 Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!

a Ṣé o máa ń ronú nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè? Ohun tó dáa lò ń ṣe yẹn. Ìdí ni pé bá a ṣe túbọ̀ ń ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, bẹ́ẹ̀ lá máa túbọ̀ yá wa lára láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láyé tuntun fáwọn èèyàn. Jésù ṣèlérí pé Párádísè ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí tí Jésù ṣe yẹn túbọ̀ lágbára.

b ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tó nírètí pé òun máa kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ báyìí.