ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 52
Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Fara Dà Á Nígbà Ìṣòro
“Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún tó bá wà níkàáwọ́ rẹ láti ṣe é.”—ÒWE 3:27.
ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Báwo ni Jèhófà ṣe sábà máa ń dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
ǸJẸ́ o mọ̀ pé Jèhófà lè lò ẹ́ láti dáhùn àdúrà tí ìránṣẹ́ ẹ̀ kan gbà tọkàntọkàn? Kò sẹ́ni tí ò lè lò. Bóyá alàgbà ni wá, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí akéde nínú ìjọ. Ó sì lè lo ọmọdé, àgbàlagbà, arákùnrin tàbí arábìnrin. Tí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bá sọ pé kó ran òun lọ́wọ́, Jèhófà máa ń lo àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láti ‘tu ẹni náà nínú.’ (Kól. 4:11) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà ń lò wá láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́! A sì máa ń láǹfààní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, tí àjálù bá wáyé tàbí nígbà inúnibíni.
MÁA RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ NÍGBÀ TÍ ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN BÁ ṢẸLẸ̀
2. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn?
2 Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹlẹ̀, ó lè ṣòro láti ran ara wa lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè wù wá pé ká lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wa, àmọ́ ó léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún lè wù wá láti pe àwọn ará wa tí ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ pé kí wọ́n wá jẹun nílé wa, àmọ́ ìyẹn náà ò lè ṣeé ṣe. Ó lè wù wá láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, àmọ́ ó lè má rọrùn torí pé àwa náà fẹ́ bójú tó ìdílé wa. Láìka gbogbo ìyẹn sí, ó yẹ ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́, inú Jèhófà á sì dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 3:27; 19:17) Kí la lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?
3. Kí la rí kọ́ lára àwọn alàgbà tó wà níjọ Arábìnrin Desi? (Jeremáyà 23:4)
3 Ohun táwọn alàgbà lè ṣe. Tó o bá jẹ́ alàgbà, mọ àwọn ará tí Jèhófà ní kó o máa bójú tó dáadáa. (Ka Jeremáyà 23:4.) Arábìnrin Desi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Àwọn alàgbà tá a jọ wà nínú àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù máa ń lọ sóde ìwàásù pẹ̀lú wa déédéé, a sì tún jọ máa ń ṣeré ìnàjú.” b Ohun tí àwọn alàgbà ṣe yẹn mú kó rọrùn fún wọn láti ran Arábìnrin Desi lọ́wọ́ nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ṣẹlẹ̀ tó sì pa àwọn kan lára ìdílé ẹ̀.
4. Kí ló jẹ́ káwọn alàgbà lè ran Desi lọ́wọ́, kí la sì rí kọ́?
4 Desi sọ pé: “Torí pé àwọn alàgbà yẹn mú mi lọ́rẹ̀ẹ́, ó rọrùn fún mi láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi, kí n sì sọ àwọn ìṣòro mi fún wọn.” Ẹ̀kọ́ wo làwọn alàgbà rí kọ́? Ẹ máa bójú tó àwọn tí Jèhófà fi síkàáwọ́ yín kí ìṣòro tó dé. Ẹ mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Tí àjàkálẹ̀ àrùn ò bá jẹ́ kó o lọ sọ́dọ̀ wọn, o lè lo ọ̀nà míì láti kàn sí wọn. Desi tún sọ pé: “Àwọn alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń pè mí, wọ́n sì tún máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù lọ́jọ́ kan náà. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi tù mí nínú wọ̀ mí lọ́kàn gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀.”
5. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè mọ ohun táwọn ará fẹ́, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́?
5 Ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ ohun táwọn ará fẹ́ ni pé kó o fọgbọ́n bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 20:5) O lè bi wọ́n pé ṣé ẹ ní oúnjẹ, oògùn àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ nílò? Ṣé wọn ò máa dín àwọn òṣìsẹ́ kù níbi iṣẹ́ yín, ṣé ẹ ṣì ń rówó ilé san? O tún lè bi wọ́n pé ṣé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè rí nǹkan tí ìjọba ṣètò fáwọn aráàlú gbà? Àwọn ará fi nǹkan tí Desi nílò ránṣẹ́ sí i, ó sì rí i gbà. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ìtùnú táwọn alàgbà sọ fún un látinú Ìwé Mímọ́ ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn alàgbà gbàdúrà pẹ̀lú mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nínú àdúrà yẹn, mi ò gbàgbé bó ṣe mára tù mí. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún mi pé, ‘Mo wà pẹ̀lú ẹ.’ ”—Àìsá. 41:10, 13.
6. Kí ni ọ̀pọ̀ àwọn ará nínú ìjọ lè ṣe láti ran ara wọn lọ́wọ́? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ohun táwọn ará lè ṣe. Tó bá dọ̀rọ̀ ká ran àwọn ará lọ́wọ́, ó yẹ káwọn alàgbà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Àmọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa fún ara wa níṣìírí, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Kódà tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú díẹ̀ la sọ fún ẹnì kan tó ń ṣàìsàn, ó lè mú kára ẹ̀ yá gágá. Ọmọ kékeré kan lè fi káàdì tàbí àwòrán tó yà ránṣẹ́ sí arákùnrin kan láti fún un níṣìírí. Ọ̀dọ́ kan lè lọ bá arábìnrin kan jíṣẹ́ tàbí kó lọ bá a ra nǹkan lọ́jà. Àbí ṣé a lè se oúnjẹ fún ẹnì kan tí ara ẹ̀ ò yá, ká sì gbé e lọ fún un nílé? Ká sòótọ́, gbogbo wa la nílò ìrànlọ́wọ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn bá gbòde kan. A lè dúró pẹ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé ká lè bá àwọn ará sọ̀rọ̀ lójúkojú tàbí ká tan fídíò wa láti bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tá a parí ìpàdé lórí ìkànnì. Ó sì yẹ ká máa fún àwọn alàgbà náà níṣìírí. Àwọn ará kan ti fi lẹ́tà ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sáwọn alàgbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ kára lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn. Ẹ ò rí i pé ó máa dáa gan-an tá a bá ń ‘fún ara wa níṣìírí, tí a sì ń gbé ara wa ró’!—1 Tẹs. 5:11.
MÁA RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ NÍGBÀ ÀJÁLÙ
7. Kí ló lè mú kí nǹkan nira lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?
7 Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ó lè sọ ìgbésí ayé ẹni dìdàkudà. Àwọn kan lè pàdánù nǹkan ìní wọn, ilé wọn, kódà àwọn èèyàn wọn tiẹ̀ lè kú. Àwọn nǹkan yìí ò sì yẹ àwọn ará wa sílẹ̀. Torí náà, kí la lè ṣe láti ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà àjálù?
8. Kí làwọn alàgbà àtàwọn olórí ìdílé lè ṣe kí àjálù tó ṣẹlẹ̀?
8 Ohun táwọn alàgbà lè ṣe. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ran àwọn ará tó wà níjọ yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù. Ẹ rí i pé gbogbo àwọn ará mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti dáàbò bo ara wọn àti bí wọ́n ṣe máa kàn sáwọn alàgbà. Margaret tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Nígbà táwọn alàgbà wa ń sọ ohun tó ń fẹ́ àbójútó níjọ wa, wọ́n kìlọ̀ fún wa pé àsìkò tí iná máa ń jó, tó sì ń ba nǹkan jẹ́ la wà yìí. Wọ́n sọ pé tí ìjọba bá pàṣẹ pé ká sá kúrò lágbègbè tá à ń gbé tàbí tí ọwọ́ iná bá le, ká tètè ṣe bẹ́ẹ̀.” Ohun tí wọ́n sọ yẹn wúlò gan-an torí kò ju ọ̀sẹ̀ márùn-ún sígbà yẹn ni iná ńlá kan wáyé. Ẹ̀yin olórí ìdílé, ẹ lè jíròrò ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín máa ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé yín. Tẹ́yin àtàwọn ọmọ yín bá ń múra sílẹ̀ de àjálù, ọkàn yín máa balẹ̀ nígbà tó bá ṣẹlẹ̀.
9. Ètò wo lẹ̀yin alàgbà lè ṣe kí àjálù tó dé àti lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀?
9 Tó o bá jẹ́ alábòójútó àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù, rí i pé o gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù àwọn tó wà láwùjọ ẹ kí àjálù tó dé. Àmọ́, tí wọ́n bá láwọn ò fún ẹ, má fipá gbà á. Kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù wọn sílẹ̀, kó o sì máa béèrè lọ́wọ́ wọn látìgbàdégbà bóyá ó ti yí pa dà. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe kàn sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, fi àkọsílẹ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí olùṣekòkárí ìgbìmọ̀ alàgbà, kó lè fi ránṣẹ́ sí alábòójútó àyíká. Tí gbogbo yín bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lọ́nà yìí, ẹ̀ẹ́ lè ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà àjálù. Lẹ́yìn tí iná tí Margaret sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ wáyé, odindi wákàtí mẹ́rìndínlógójì (36) ni alábòójútó àyíká wọn ò fi sùn torí pé ó ń bójú tó àwọn alàgbà tó ń kàn sáwọn ará. Iye àwọn ará tó sá kúrò nílé torí iná náà tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ààbọ̀ (450). (2 Kọ́r. 11:27) Àwọn alàgbà yẹn rí i dájú pé àwọn ṣètò ibi tí gbogbo àwọn ará tí ò nílé mọ́ á máa gbé.
10. Kí nìdí táwọn alàgbà fi gbà pé ó ṣe pàtàkì káwọn máa bẹ àwọn ará wò? (Jòhánù 21:15)
10 Ara ojúṣe àwọn alàgbà ni láti máa fi Bíbélì tọ́ àwọn ará sọ́nà kí wọ́n sì máa tù wọ́n nínú nígbà ìṣòro. (1 Pét. 5:2) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ rí i dájú pé kò sí arákùnrin tàbí arábìnrin kankan nínú ewu àti pé gbogbo wọn ní oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí àjálù náà ti wáyé, àwọn ará ṣì máa nílò ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì. (Ka Jòhánù 21:15.) Arákùnrin Harold tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó sì ti bá ọ̀pọ̀ àwọn ará sọ̀rọ̀ nígbà tí àjálù dé bá wọn sọ pé: “Ó máa ń gba àkókò kí ẹ̀dùn ọkàn tí àjálù náà fà tó tán lára àwọn ará. Wọ́n ti lè máa gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn díẹ̀díẹ̀, àmọ́ wọ́n á ṣì máa rántí àwọn èèyàn wọn tó kú àtàwọn ohun ìní tí wọ́n pàdánù. Wọ́n sì tún lè máa rántí bí Jèhófà ṣe kó wọn yọ nínú àjálù náà. Àwọn nǹkan tí wọ́n ń rántí yìí tún lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Ìyẹn ò sì fi hàn pé wọn ò nígbàgbọ́ torí bó ṣe máa ń ṣe gbogbo èèyàn nìyẹn.”
11. Kí ló yẹ káwọn alàgbà máa ṣe fáwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ?
11 Àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Ó yẹ ká fi dá àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lójú pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn ará náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Àwọn alàgbà máa ran àwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, irú bíi kí wọ́n máa gbàdúrà, kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n máa lọ sípàdé, kí wọ́n sì máa wàásù fáwọn èèyàn. Àwọn alàgbà tún lè rọ àwọn òbí pé kí wọ́n ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa ronú nípa ohun tí àjálù ò lè bà jẹ́, ìyẹn àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ̀yin òbí, ẹ máa rán àwọn ọmọ yín létí nígbà gbogbo pé Jèhófà ni Ọ̀rẹ́ wọn, ó sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin wà kárí ayé tí wọ́n ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—1 Pét. 2:17.
12. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn ará lè ṣe nígbà àjálù? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Ohun táwọn ará lè ṣe. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nítòsí ibi tó ò ń gbé, béèrè àwọn nǹkan tó o lè ṣe lọ́wọ́ àwọn alàgbà. O lè ní káwọn tí ilé wọn bà jẹ́ tàbí àwọn tó sá kúrò nílé torí àjálù wá gbélé ẹ fúngbà díẹ̀, o sì tún lè gba àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣèrànwọ́ sílé ẹ. O tún lè máa bá wọn pín oúnjẹ àtàwọn ohun èlò míì fáwọn ará. Tó bá sì jẹ́ pé ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ jìnnà díẹ̀ síbi tó ò ń gbé, o ṣì lè ṣèrànwọ́. Lọ́nà wo? O lè máa gbàdúrà fáwọn tí àjálù dé bá. (2 Kọ́r. 1:8-11) O lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa kárí ayé kí wọ́n lè fi tọ́jú àwọn tí àjálù dé bá. (2 Kọ́r. 8:2-5) Tó o bá máa ráyè rìnrìn àjò lọ síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ láti ṣèrànwọ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá o lè yọ̀ǹda ara ẹ. Tí wọ́n bá pè ẹ́ pé kó o wá ṣèrànwọ́, wọ́n máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè lò ẹ́ níbi tó o ti máa wúlò gan-an.
MÁA RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ NÍGBÀ INÚNIBÍNI
13. Àwọn ìṣòro wo làwọn ará ní láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa?
13 Láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará níbẹ̀ máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ nira fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ṣòro fún wọn láti rówó gbọ́ bùkátà, wọ́n máa ń ṣàìsàn, àwọn èèyàn wọn sì ń kú. Torí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, kì í sábà rọrùn fáwọn alàgbà láti lọ wo àwọn ará, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí nígbà tí wọ́n nílò ẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí fún alàgbà kan tó ń jẹ́ Andrei tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nìyẹn. Arábìnrin kan tí wọ́n jọ wà nínú àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ò rówó gbọ́ bùkátà, jàǹbá ọkọ̀ tún ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin náà. Ó wá gba pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ lóríṣiríṣi fún un, yàtọ̀ síyẹn kò lè ṣiṣẹ́ kankan torí ara ẹ̀ tí ò yá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀, tí àjàkálẹ̀ àrùn sì ń lọ lọ́wọ́, Jèhófà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin yẹn, ó sì jẹ́ káwọn ará ràn án lọ́wọ́.
14. Tó bá dọ̀rọ̀ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀?
14 Ohun táwọn alàgbà lè ṣe. Arákùnrin Andrei gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà ẹ̀? Ó lo àwọn ará míì nínú ìjọ ẹ̀ láti ran arábìnrin náà lọ́wọ́ torí wọ́n lómìnira láti máa lọ káàkiri. Àwọn kan máa ń fi mọ́tò gbé arábìnrin náà lọ sílé ìwòsàn. Àwọn míì sì fún arábìnrin náà lówó. Jèhófà lò wọ́n láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran arábìnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. (Héb. 13:16) Torí náà, ẹ̀yin alàgbà, tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, tí ẹ ò sì lè máa lọ káàkiri, ẹ yan iṣẹ́ fáwọn míì. (Jer. 36:5, 6) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa.
15. Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, kí la lè ṣe tí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa ò fi ní bà jẹ́?
15 Ohun táwọn ará lè ṣe. Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ó lè gba pé ká máa pàdé ní àwùjọ kéékèèké. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an ká jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wa báyìí. Sátánì ni ọ̀tá tó yẹ ká bá jà, kì í ṣe àwọn ará wa. Máa gbójú fo àṣìṣe àwọn ará tàbí kó o tètè yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín yín. (Òwe 19:11; Éfé. 4:26) Tẹ́ ẹ bá rí i pé ó yẹ kẹ́ ẹ ran ara yín lọ́wọ́, ẹ tètè ṣe bẹ́ẹ̀. (Títù 3:14) Ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣe àwọn tí wọ́n jọ wà láwùjọ iṣẹ́ ìwàásù láǹfààní torí ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ wà níṣọ̀kan bí ìdílé kan.—Sm. 133:1.
16. Kí ni Kólósè 4:3, 18 sọ pé ká máa ṣe fáwọn ará tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí?
16 Àìmọye àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni wọ́n ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n ti ju àwọn kan sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ará yẹn àtàwọn ìdílé wọn títí kan àwọn ará tí wọ́n lo òmìnira wọn láti lọ bẹ̀ wọ́n wò bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba lè fi ọlọ́pàá mú wọn. Wọ́n máa ń mú ohun táwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n nílò lọ fún wọn. Wọ́n máa ń fi Bíbélì tù wọ́n nínú, wọ́n sì máa ń lọ gbèjà wọn nílé ẹjọ́. c (Ka Kólósè 4:3, 18.) Torí náà, máa gbàdúrà fáwọn ará torí iṣẹ́ kékeré kọ́ ni àdúrà ẹ ń ṣe!—2 Tẹs. 3:1, 2; 1 Tím. 2:1, 2.
17. Kí lo lè máa ṣe báyìí láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?
17 Ìwọ àti ìdílé ẹ lè múra sílẹ̀ de inúnibíni báyìí. (Ìṣe 14:22) Dípò kó o máa ronú nípa gbogbo ohun tí ò dáa tó lè ṣẹlẹ̀ nígbà inúnibíni, ṣe ni kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. (Sm. 62:7, 8) Kí ìwọ àti ìdílé ẹ jíròrò ìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. d Tí ìwọ àtàwọn ọmọ ẹ bá jọ múra sílẹ̀ de inúnibíni bẹ́ ẹ ṣe múra sílẹ̀ de àjálù, ó máa jẹ́ káwọn náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n nígboyà, kọ́kàn wọn sì balẹ̀.
18. Kí là ń retí lọ́jọ́ iwájú?
18 Àlàáfíà Ọlọ́run máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Bá a tiẹ̀ ń ṣàìsàn, tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí wa, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa, Jèhófà máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ torí pé Ọlọ́run àlàáfíà ni. Ó máa ń lo àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó wa. Ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa ran ara wa lọ́wọ́. Ní báyìí táwa èèyàn Jèhófà ṣì ń gbádùn àlàáfíà, a máa lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro ńlá tó ń bọ̀, títí kan “ìpọ́njú ńlá.” (Mát. 24:21) Lákòókò yẹn, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá fi wá lọ́kàn balẹ̀, ká sì ran àwọn ará lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá yẹn, àwọn ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè ò ní sí mọ́. Àá wá máa gbádùn ohun tí Jèhófà fẹ́ fún wa, ìyẹn àlàáfíà ayérayé.—Àìsá. 26:3, 4.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
a Jèhófà sábà máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láti ran àwọn ará wa tó níṣòro lọ́wọ́. Jèhófà sì lè lo ìwọ náà láti fún àwọn ará níṣìírí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn tó wà ní oríléeṣẹ́ wa ò ní lè fi lẹ́tà táwọn ará bá kọ ránṣẹ́ sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
d Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìsinsìnyí Gan-an Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2019.
e ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan gbé oúnjẹ wá fún ìdílé kan níbi tí wọ́n wà lẹ́yìn tí àjálù ṣẹlẹ̀.