Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 53

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Jẹ́ Kí Òtítọ́ Jinlẹ̀ Nínú Yín

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Jẹ́ Kí Òtítọ́ Jinlẹ̀ Nínú Yín

“Jẹ́ alágbára, kí o sì ṣe bí ọkùnrin.”—1 ỌBA 2:2.

ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Táwọn ọkùnrin Kristẹni bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?

 ỌBA Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì pé: “Jẹ́ alágbára, kí o sì ṣe bí ọkùnrin.” (1 Ọba 2:1-3) Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn ọkùnrin Kristẹni fi ìmọ̀ràn yìí sílò lónìí. Kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí, ó yẹ kí wọ́n kọ́ bí wọ́n á ṣe máa pa òfin Ọlọ́run mọ́, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. (Lúùkù 2:52) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọ̀dọ́kùnrin di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn?

2-3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọ̀dọ́kùnrin di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn?

2 Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ làwọn ọkùnrin Kristẹni máa ń ṣe nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti máa ronú nípa àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú. Ó lè wù ẹ́ kó o di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Ó tún ṣeé ṣe kó o fẹ́ láya, kó o sì bímọ. (Éfé. 6:4; 1 Tím. 3:1) Tó o bá fẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn nǹkan yìí, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ. b

3 Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? Àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì tó yẹ kó o kọ́. Torí náà, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe báyìí láti múra sílẹ̀ kó o lè ṣe àwọn ojúṣe tó o máa ní lọ́jọ́ iwájú dáadáa?

ÀWỌN NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÓ O DI KRISTẸNI TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀

Tó o bá kọ́ àwọn ànímọ́ Jésù tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Ibo lo ti lè rí àwọn àpẹẹrẹ tó dáa tó o lè tẹ̀ lé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Fara wé àwọn tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin lè fara wé. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ yìí nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, oríṣiríṣi iṣẹ́ ni wọ́n sì ṣe láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. O tún lè rí àwọn ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tó o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn nínú ìdílé ẹ àti nínú ìjọ. (Héb. 13:7) O sì tún lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tí Jésù fi lélẹ̀. (1 Pét. 2:21) Bó o ṣe ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, kíyè sí àwọn ànímọ́ tí wọ́n ní tó wù ẹ́. (Héb. 12:1, 2) Lẹ́yìn náà kó o wo bó o ṣe lè fara wé wọn.

5. Báwo lo ṣe lè ní làákàyè, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì? (Sáàmù 119:9)

5 ‘Ní làákàyè, má sì jẹ́ kó bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.’ (Òwe 3:21) Ẹni tó ní làákàyè máa ń ronú dáadáa kó tó ṣèpinnu. Torí náà, ṣiṣẹ́ kára kó o lè ní ànímọ́ yìí, kó o má sì jẹ́ kó bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ń tẹ̀ lé èrò tara wọn, tí wọ́n sì máa ń fi bí nǹkan ṣe rí lára wọn hùwà ló pọ̀ láyé lónìí. (Òwe 7:7; 29:11) Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè ṣàkóbá fún un. Àmọ́ báwo lo ṣe lè ní làákàyè? Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o mọ àwọn ìlànà Bíbélì, kó o sì ronú nípa àwọn àǹfààní tó o máa rí tó o bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Lẹ́yìn náà, lo àwọn ìlànà yẹn láti ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. (Ka Sáàmù 119:9.) Tó o bá ní ànímọ́ pàtàkì yìí, wàá di ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Òwe 2:11, 12; Héb. 5:14) Jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tó o lè gbà jàǹfààní tó o bá ní làákàyè: (1) bó o ṣe ń ṣe sáwọn arábìnrin (2) tó o bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tó o máa wọ̀ àti ìrísí ẹ.

6. Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ní làákàyè, báwo nìyẹn á ṣe jẹ́ kó máa bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin?

6 Tó o bá ní làákàyè, wàá máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin. Kò sóhun tó burú níbẹ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá fẹ́ sún mọ́ arábìnrin kan kó lè mọ̀ ọ́n dáadáa. Àmọ́, tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ní làákàyè, kò ní sọ ohun tó lè mú kí arábìnrin yẹn rò pé ó fẹ́ fẹ́ òun, kò sì ní máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i ṣáá tàbí kó máa ṣe àwọn nǹkan míì, tó sì mọ̀ pé òun ò ní fẹ́ arábìnrin náà. (1 Tím. 5:1, 2) Tó bá sì ń fẹ́ arábìnrin kan sọ́nà, kò ní máa dá wà pẹ̀lú ẹ̀ nìkan láìsí ẹlòmíì níbẹ̀, kí orúkọ rere tí arábìnrin náà ní má bàa bà jẹ́.—1 Kọ́r. 6:18.

7. Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ní làákàyè, báwo nìyẹn á ṣe ràn án lọ́wọ́ tó bá fẹ́ yan aṣọ tó máa wọ̀ àti irun tó máa gẹ̀?

7 Nǹkan míì tó máa fi hàn pé arákùnrin kan ní làákàyè ni bó ṣe ń múra àti irú irun tó ń gẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe ló máa ń ṣe àwọn aṣọ tuntun jáde, tí wọ́n sì máa ń polówó ẹ̀. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn aṣọ tó ń fún mọ́ èèyàn lára àti aṣọ tó ń jẹ́ káwọn ọkùnrin dà bí obìnrin fi hàn pé ìṣekúṣe ló wà lọ́kàn wọn. Torí náà, àwọn ìlànà Bíbélì ló yẹ kí ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni kan máa tẹ̀ lé tó bá fẹ́ yan irú aṣọ tó máa wọ̀, kó sì tún máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ń wọṣọ tó dáa nínú ìjọ. Ó lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Ṣé àwọn aṣọ tí mò ń wọ̀ fi hàn pé mo láròjinlẹ̀, mo sì ń gba tàwọn ẹlòmíì rò? Ṣé àwọn aṣọ tí mò ń wọ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé olùjọsìn Ọlọ́run ni mí lóòótọ́?’ (1 Kọ́r. 10:31-33; Títù 2:6) Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ní làákàyè, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin á máa bọ̀wọ̀ fún un, á sì tún rí ojúure Jèhófà.

8. Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe lè jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán?

8 Jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán. Ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni tó ṣe é fọkàn tán máa ń bójú tó gbogbo ojúṣe ẹ̀. (Lúùkù 16:10) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ tó dáa tí Jésù fi lélẹ̀ yẹ̀ wò. Ọwọ́ pàtàkì ló fi máa ń múṣẹ́, kò sì ya ọ̀lẹ. Gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un ló ṣe, kódà nígbà tí kò rọrùn fún un. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì tún kú nítorí wọn. (Jòh. 13:1) Bíi ti Jésù, tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún ẹ, rí i pé o ṣe é dáadáa. Tó ò bá mọ bó o ṣe máa ṣe é, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó o sọ fún àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má kàn ṣe iṣẹ́ náà láàbọ̀. (Róòmù 12:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o parí ẹ̀ torí “Jèhófà [lò] ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.” (Kól. 3:23) Lóòótọ́, o kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ ó yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ, kó o sì gba àwọn àṣìṣe tó o bá ṣe.—Òwe 11:2.

KỌ́ ÀWỌN NǸKAN TÓ MÁA ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

9. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọ̀dọ́kùnrin kan kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe é láǹfààní?

9 Kó o tó lè di ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ dáadáa nínú ìjọ, á jẹ́ kó o ríṣẹ́ tí wàá fi máa bójú tó ara ẹ tàbí ìdílé ẹ, á sì jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíì gún. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì tó yẹ kó o kọ́.

Tó o bá mọ̀wé kọ tó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, wàá ṣe ara ẹ àti ìjọ láǹfààní (Wo ìpínrọ̀ 10-11)

10-11. Tí arákùnrin kan bá mọ̀wé kọ tó sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe òun àtàwọn ará ìjọ láǹfààní? (Sáàmù 1:1-3) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Bíbélì sọ pé tí ẹnì kan bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tó sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, ó máa láyọ̀, gbogbo ohun tó bá ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Torí náà, tó bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, á máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, á sì jẹ́ kó mọ bó ṣe máa fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. (Òwe 1:3, 4) Irú àwọn arákùnrin yìí la nílò nínú ìjọ. Kí nìdí?

11 Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nílò àwọn ọkùnrin tó lè fi Bíbélì kọ́ni dáadáa, kí wọ́n sì fi gbà wọ́n níyànjú. (Títù 1:9) Tó o bá mọ̀wé kọ tó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, wàá lè múra àsọyé àti ìdáhùn tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, tí wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tó ò ń gbọ́ àsọyé nínú ìjọ, láwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè, wàá lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn àkọsílẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, wàá sì lè fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí.

12. Báwo lo ṣe lè mọ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀?

12 Kọ́ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀. Arákùnrin kan gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀. Ó gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, kó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì. (Òwe 20:5) Ó yẹ kó máa kíyè sí ohùn tẹ́nì kan fi sọ̀rọ̀, bó ṣe ṣojú àti ìṣesí ẹ̀. O ò lè kíyè sí àwọn nǹkan yìí tó ò bá kí í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà lò ń fi fóònù bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, tó o sì ń lò ó láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó máa nira fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Torí náà, máa wáyè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú.—2 Jòh. 12.

Á dáa kó o kọ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè ríṣẹ́ ṣe (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Kí ni nǹkan míì tó yẹ kí ọ̀dọ́kùnrin kan kọ́? (1 Tímótì 5:8) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Kọ́ iṣẹ́ tí wàá fi máa bójú tó ara ẹ. Ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ gbọ́dọ̀ lè bójú tó ara ẹ̀ àti ìdílé ẹ̀. (Ka 1 Tímótì 5:8.) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa ń kọ́ṣẹ́ tí wọ́n máa fi bójú tó ara wọn lọ́dọ̀ bàbá wọn tàbí lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Láwọn orílẹ̀-èdè míì, àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń tajà tàbí kí wọ́n kọ́ṣẹ́ ọwọ́ nígbà tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́ girama. Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tó dáa jù ni pé kó o kọ́ṣẹ́ táá jẹ́ kó o máa ríṣẹ́ ṣe. (Ìṣe 18:2, 3; 20:34; Éfé. 4:28) Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òṣìṣẹ́ kára ni ẹ́, tó o bá sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan, o máa ń parí ẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ríṣẹ́, kó má sì bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin Kristẹni kan láwọn ànímọ́ tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó lè ṣe àwọn ojúṣe tó máa ní lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ojúṣe náà.

MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ

14. Kí ni ọ̀dọ́kùnrin kan lè ṣe kó lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?

14 O lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́. Tí ọ̀dọ́ kan bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó mọ bó ṣe lè bá onírúurú èèyàn ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kó mọ bá a ṣe ń ṣówó ná. (Fílí. 4:11-13) Tó o bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lo máa kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fúngbà díẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Tó o bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó o láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè di ọ̀kan lára àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run tàbí kó o máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì.

15-16. Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe lè kúnjú ìwọ̀n láti sìn nínú ìjọ?

15 O lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Ó yẹ káwọn arákùnrin máa ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà, á sì jẹ́ kí wọ́n lè sin àwọn ará nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé táwọn arákùnrin bá ń ṣiṣẹ́ kára láti di alábòójútó, ‘iṣẹ́ rere ni wọ́n fẹ́ ṣe.’ (1 Tím. 3:1) Kí arákùnrin kan tó lè di alàgbà, ó máa kọ́kọ́ kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Onírúurú ọ̀nà làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń gbà ran àwọn alàgbà lọ́wọ́. Torí pé àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nírẹ̀lẹ̀, wọ́n ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́, wọ́n sì ń fìtara wàásù pẹ̀lú wọn. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n bá ti pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n dáadáa lè di alàgbà tí wọ́n bá ti pé ẹni ogún (20) ọdún.

16 Báwo lo ṣe lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà? Kò sọ́nà míì ju pé kó o láwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó o kúnjú ìwọ̀n. Àwọn nǹkan tá à ń béèrè lọ́wọ́ arákùnrin tó bá fẹ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà wà nínú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìdílé ẹ àti ìjọ. (1 Tím. 3:1-13; Títù 1:6-9; 1 Pét. 5:2, 3) Ṣiṣẹ́ kára láti lóye àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó o kúnjú ìwọ̀n dáadáa. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè láwọn ànímọ́ yẹn. c

Jèhófà fẹ́ kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀, kó máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn, kó máa ṣìkẹ́ wọn, kó sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Àwọn nǹkan wo ni ọ̀dọ́kùnrin kan gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ di ọkọ àti olórí ìdílé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 O lè di olórí ìdílé. Bí Jésù ṣe sọ, àwọn arákùnrin kan lè pinnu pé àwọn ò ní láya. (Mát. 19:12) Àmọ́ tó o bá láya, o máa di olórí ìdílé, ojúṣe ẹ sì ń pọ̀ sí i nìyẹn. (1 Kọ́r. 11:3) Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kó máa pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún un, kó máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Éfé. 5:28, 29) Àwọn ànímọ́ àtàwọn nǹkan tó o lè kọ́ tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, irú bíi kó o ní àròjinlẹ̀, kó o máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa jẹ́ kó o di ọkọ rere. Ìyẹn á sì jẹ́ kó o lè ṣe ojúṣe ẹ dáadáa tó o bá di ọkọ àti olórí ìdílé.

18. Àwọn nǹkan wo ni ọ̀dọ́kùnrin kan gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ di bàbá?

18 O lè di bàbá. Lẹ́yìn tó o bá láya, ó ṣeé ṣe kó o bímọ. Tó o bá fẹ́ jẹ́ bàbá rere, ẹ̀kọ́ wo lo lè kọ́ lára Jèhófà? Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lo lè rí kọ́. (Éfé. 6:4) Jèhófà sọ fún Jésù Ọmọ ẹ̀ ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17) Torí náà, tó o bá bímọ, rí i dájú pé gbogbo ìgbà lò ń sọ fáwọn ọmọ ẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa, gbóríyìn fún wọn látọkànwá. Àwọn bàbá tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí de ojúṣe yìí, bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fìfẹ́ bójú tó àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ará ìjọ, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn. (Jòh. 15:9) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọkọ àti olórí ìdílé tó dáa. Àmọ́ ní báyìí, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wúlò fún Jèhófà, kó o sì máa ran àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ará ìjọ lọ́wọ́.

KÍ LO MÁA ṢE BÁYÌÍ?

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn (Wo ìpínrọ̀ 19-20)

19-20. Kí ló máa ran ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

19 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, òtítọ́ ò lè ṣàdédé jinlẹ̀ nínú yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kẹ́ ẹ fara wé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, kẹ́ ẹ ní àròjinlẹ̀, kẹ́ ẹ ṣeé fọkàn tán, kẹ́ ẹ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe yín láǹfààní, kẹ́ ẹ sì múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú.

20 Tó o bá ronú nípa gbogbo nǹkan tó yẹ kó o ṣe yìí, ó lè kà ẹ́ láyà. Àmọ́, o lè ṣàṣeyọrí. Máa rántí pé ó wu Jèhófà láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10, 13) Ó sì dájú pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá di Kristẹni ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ayé ẹ máa dáa, wàá sì láyọ̀. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin wa, a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an! Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.—Òwe 22:4.

ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!

a A nílò àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn nínú ìjọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin lè ṣe kẹ́ ẹ lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.

b Wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀” nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú.

c Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 5-6.