Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50

Ìgbàgbọ́ àti Iṣẹ́ Máa Sọ Ẹ́ Di Olódodo

Ìgbàgbọ́ àti Iṣẹ́ Máa Sọ Ẹ́ Di Olódodo

‘Ẹ máa rìn létòlétò nínú ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní.’—RÓÒMÙ 4:12.

ORIN 119 Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Tá a bá ronú nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ìbéèrè wo la lè bi ara wa?

 BÓ TIẸ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbọ́ nípa Ábúráhámù, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò mọ̀ ọ́n dáadáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan nìwọ́ mọ̀ nípa Ábúráhámù. Bí àpẹẹrẹ, o mọ̀ pé Bíbélì pè é ní “baba gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:11) Torí náà, o lè máa ronú pé, ‘Ṣé mo lè tọ ipasẹ̀ Ábúráhámù, kí n sì nírú ìgbàgbọ́ tó ní?’ Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ṣe bẹ́ẹ̀.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ábúráhámù? (Jémíìsì 2:22, 23)

2 Tá a bá fẹ́ nígbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù, ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi gbé inú àgọ́, ó sì ṣe tán láti fi Ísákì ọmọ ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an rúbọ sí Ọlọ́run. Àwọn nǹkan tó ṣe yẹn fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára. Torí pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó sì ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn bẹ́ẹ̀, ó rí ojúure Ọlọ́run, ó sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Ka Jémíìsì 2:22, 23.) Jèhófà fẹ́ kí ìwọ náà rí ojúure òun, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ bíi ti Ábúráhámù. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí Róòmù orí kẹrin àti Jémíìsì orí kejì sọ nípa Ábúráhámù. Nínú àwọn orí Bíbélì yìí, Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì sọ àwọn nǹkan pàtàkì nípa ọkùnrin olóòótọ́ yìí.

3. Ẹsẹ Bíbélì wo ni Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì ti fa ọ̀rọ̀ yọ?

3 Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 15:6 tó sọ pé: “Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, Ó sì kà á sí òdodo fún un.” Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olódodo, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà rí ojúure Ọlọ́run, ó sì jẹ́ aláìlẹ́bi. Ẹ ò rí i pé ó yani lẹ́nu gan-an pé Ọlọ́run lè fojúure wo ẹni tó jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀! Ó dájú pé o fẹ́ kí Ọlọ́run pè ẹ́ ní olódodo, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo àtohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà lè pè wá ní olódodo.

A GBỌ́DỌ̀ NÍGBÀGBỌ́ KÁ TÓ LÈ JẸ́ OLÓDODO

4. Kí ni ò jẹ́ káwa èèyàn jẹ́ olódodo?

4 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Torí náà kí la lè ṣe, kí Ọlọ́run lè pè wá ní olódodo àti aláìlẹ́bi? Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Ábúráhámù máa jẹ́ káwa Kristẹni tòótọ́ lè dáhùn ìbéèrè yẹn.

5. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo? (Róòmù 4:2-4)

5 Jèhófà pe Ábúráhámù ní olódodo nígbà tó ń gbé ilẹ̀ Kénáánì. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo? Ṣé torí pé Ábúráhámù ń pa Òfin Mósè mọ́ ni? Rárá o. (Róòmù 4:13) Ó ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin (400) lọ lẹ́yìn tí Jèhófà pe Ábúráhámù ní olódodo kó tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin yẹn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo? Ìdí ni pé ó nígbàgbọ́, Jèhófà sì fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i.—Ka Róòmù 4:2-4.

6. Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń pe ẹlẹ́ṣẹ̀ ní olódodo?

6 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé tẹ́nì kan bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ‘a máa ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo.’ (Róòmù 4:5) Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Bí Dáfídì pẹ̀lú ṣe sọ nípa ayọ̀ ẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo láìka àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí, pé: ‘Aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀; aláyọ̀ ni ẹni tí Jèhófà kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.’” (Róòmù 4:6-8; Sm. 32:1, 2) Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ jì wọ́n. Ó máa ń dárí jì wọ́n pátápátá, kò sì ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. Jèhófà máa ń ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí aláìlẹ́bi àti olódodo torí pé wọ́n nígbàgbọ́.

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé olódodo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbà àtijọ́?

7 Jèhófà pe Ábúráhámù, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì ní olódodo, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Àmọ́ torí pé wọ́n nígbàgbọ́, Ọlọ́run kà wọ́n sí aláìlẹ́bi pàápàá tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run rárá. (Éfé. 2:12) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ Ábúráhámù àti Dáfídì ṣe rí nìyẹn. Torí pé àwa náà nígbàgbọ́, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

BÁWO NI ÌGBÀGBỌ́ ÀTI IṢẸ́ ṢE SO MỌ́ ARA WỌN?

8-9. Kí ló mú káwọn kan gbà pé ohun tí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì sọ ta kora, kí sì nìdí?

8 Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi jiyàn gan-an lórí bí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ ṣe so mọ́ ara wọn. Àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń kọ́ni pé tó o bá ṣáà ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, wàá rí ìgbàlà. O ti lè máa gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé, “Gba Jésù sáyé ẹ, kó o sì rí ìgbàlà.” Ó ṣeé ṣe káwọn olórí ẹ̀sìn fa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yọ pé: ‘Ọlọ́run máa ka ẹnì kan sí olódodo láìka àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí.’ (Róòmù 4:6) Ṣùgbọ́n àwọn kan sọ pé o lè “gba ara ẹ là” tó o bá ń rìnrìn àjò lọ síbi táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kà sí ibi mímọ́, tó o sì ń ṣe àwọn nǹkan rere tí ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé kó o máa ṣe. Wọ́n tiẹ̀ máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jémíìsì 2:24 pé: “Àwọn iṣẹ́ la fi ń ka èèyàn sí olódodo, kì í ṣe ìgbàgbọ́ nìkan.”

9 Torí pé ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Bíbélì kan gbà pé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì ta kora lórí ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́. Ìyẹn jẹ́ káwọn olórí ẹ̀sìn kan rò pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé láìsí iṣẹ́, Ọlọ́run máa ka ẹnì kan sí olódodo torí pé ó nígbàgbọ́, àmọ́ Jémíìsì sọ pé iṣẹ́ ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè rí ojúure Ọlọ́run. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀sìn sọ pé: “Jémíìsì ò mọ ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé Ọlọ́run máa [ka ẹnì kan sí olódodo] nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nìkan, láìsí iṣẹ́.” Àmọ́ Jèhófà ló fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn sílẹ̀. (2 Tím. 3:16) Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì ò ta kora? Bá a ṣe lè mọ̀ ni pé ká gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà ṣáájú ohun tí wọ́n sọ àtèyí tó wà lẹ́yìn wọn yẹ̀ wò.

Pọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ní Róòmù mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe àwọn nǹkan tí Òfin Mósè ní kí wọ́n máa ṣe (Wo ìpínrọ̀ 10) b

10. “Àwọn iṣẹ́” wo ni Pọ́ọ̀lù dìídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (Róòmù 3:21, 28) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 “Àwọn iṣẹ́” wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú Róòmù orí kẹta àti kẹrin? Ohun tí Pọ́ọ̀lù dìídì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni “àwọn iṣẹ́ òfin,” ìyẹn òfin tí Jèhófà fún Mósè lórí Òkè Sínáì. (Ka Róòmù 3:21, 28.) Ó jọ pé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn Júù kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ń sọ pé àwọn gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù láti fi hàn pé kì í ṣe “àwọn iṣẹ́ òfin” ló ń mú kẹ́nì kan jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ ni. Ìyẹn múnú wa dùn torí ó jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. A ṣeé ṣe fún wa láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi, á sì jẹ́ ká rí ojú rere Jèhófà.

Jémíìsì rọ àwa Kristẹni pé ká máa ṣe “àwọn iṣẹ́” tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ní ká máa ṣe rere sí gbogbo èèyàn láìṣe ojúsàájú (Wo ìpínrọ̀ 11-12) c

11. Irú “àwọn iṣẹ́” wo ni Jémíìsì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

11 “Àwọn iṣẹ́” tí Jémíìsì orí kejì sọ yàtọ̀ sí “àwọn iṣẹ́ òfin” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Iṣẹ́ tí Jémíìsì ń sọ ni àwọn nǹkan táwa Kristẹni máa ń ṣe déédéé. Irú àwọn iṣẹ́ yìí máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá Kristẹni kan nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lóòótọ́ tàbí kò ní. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe méjì tí Jémíìsì fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí.

12. Àlàyé wo ni Jémíìsì ṣe nípa bí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ ṣe so mọ́ra? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Nínú àpèjúwe tí Jémíìsì kọ́kọ́ lò, ó gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká má máa ṣe ojúsàájú. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣojúure sáwọn olówó, tó sì ń fojú pa àwọn tálákà rẹ́. Jémíìsì jẹ́ ká mọ̀ pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lè sọ pé òun nígbàgbọ́, àmọ́ kò ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. (Jém. 2:1-5, 9) Nínú àpèjúwe kejì, Jémíìsì sọ nípa ẹnì kan tó rí ‘arákùnrin tàbí arábìnrin tí ò láṣọ, tí ò sì ní oúnjẹ,’ àmọ́ tí ò ràn án lọ́wọ́. Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ pé òun nígbàgbọ́ àmọ́ tí ò ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ò wúlò. Torí náà, bí Jémíìsì ṣe sọ, “ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.”—Jém. 2:14-17.

13. Àpẹẹrẹ ta ni Jémíìsì sọ tó jẹ́ ká rí i pé a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́? (Jémíìsì 2:25, 26)

13 Jémíìsì sọ̀rọ̀ nípa Ráhábù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. (Ka Jémíìsì 2:25, 26.) Ráhábù ti gbọ́ nípa Jèhófà, ó sì mọ̀ pé òun ló ń ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. (Jóṣ. 2:9-11) Ó ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tí wọ́n lọ ṣe amí nígbà tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu. Torí ohun tí obìnrin aláìpé tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ṣe, a pè é ní olódodo bíi ti Ábúráhámù. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé a nígbàgbọ́.

14. Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì sọ ò ta kora?

14 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́, àlàyé tó yàtọ̀ síra ni wọ́n ṣe. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ni pé wọn ò ní lè rí ojúure Jèhófà tó bá jẹ́ pé Òfin Mósè ni wọ́n ń tẹ̀ lé, àmọ́ Jémíìsì ní tiẹ̀ ń jẹ́ kí gbogbo àwa Kristẹni mọ̀ pé tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nígbàgbọ́, àfi ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

Ṣé ìgbàgbọ́ tó o ní máa ń jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan tí inú Jèhófà dùn sí? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ṣe táá fi hàn pé a nígbàgbọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Jèhófà ò sọ pé ó dìgbà tá a bá ṣe ohun tí Ábúráhámù ṣe gangan kóun tó lè pè wá ní olódodo. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. Àwọn nǹkan tá a lè ṣe ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó wá sípàdé nígbà àkọ́kọ́ àti gbogbo àwọn ará, ká máa ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìní, ká sì máa ṣohun rere sáwọn tó wà nínú ìdílé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì bù kún wa. (Róòmù 15:7; 1 Tím. 5:4, 8; 1 Jòh. 3:18) Ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ ni pé a máa ń fìtara wàásù fáwọn èèyàn. (1 Tím. 4:16) Torí náà, gbogbo wa la lè ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ àti pé ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan ló dáa jù lọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run máa pè wá ní olódodo, àá sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀.

TÁ A BÁ NÍRÈTÍ, ÌGBÀGBỌ́ WA MÁA TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

16. Kí ni Ábúráhámù ń retí, kí ló sì gbà gbọ́ pé ó máa ṣẹlẹ̀?

16 Róòmù orí kẹrin sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì míì tá a kọ́ lára Ábúráhámù, ẹ̀kọ́ náà ni pé ìrètí ṣe pàtàkì. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún “ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè” nípasẹ̀ Ábúráhámù. Ẹ ò rí i pé nǹkan àgbàyanu ni Ábúráhámù ń retí yẹn! (Jẹ́n. 12:3; 15:5; 17:4; Róòmù 4:17) Síbẹ̀, nígbà tí Ábúráhámù pé ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí Sérà sì pé àádọ́rùn-ún (90) ọdún, wọn ò tíì bí ọmọ tá a ṣèlérí náà. Lójú èèyàn, ó jọ pé kò ṣeé ṣe fún Ábúráhámù àti Sérà láti bímọ mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò gan-an. “Síbẹ̀ lórí ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18, 19) Níkẹyìn, ohun tó ń retí tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ó bí Ísákì, ọmọ tí wọ́n ti ń retí tipẹ́.—Róòmù 4:20-22.

17. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run lè pè wá ní olódodo, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀?

17 A lè rí ojúure Ọlọ́run, kó kà wá sí olódodo, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ bíi ti Ábúráhámù. Ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ká mọ̀ nìyẹn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ọ̀rọ̀ tí a kọ pé ‘a kà á sí’ kì í ṣe nítorí [Ábúráhámù] nìkan, àmọ́ ó jẹ́ nítorí wa pẹ̀lú, àwa tí a máa kà sí olódodo, nítorí a nígbàgbọ́ nínú Ẹni tó gbé Jésù Olúwa wa dìde.” (Róòmù 4:23, 24) Bíi ti Ábúráhámù, ó yẹ káwa náà nígbàgbọ́, ká máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́, ká sì tún nírètí. Nínú Róòmù orí karùn-ún, Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ nípa ìrètí tá a ní, ohun tá a sì máa jíròrò nìyẹn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

a Gbogbo wa ló wù pé ká rí ojúure Ọlọ́run, kó sì pè wá ní olódodo. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí ohun tí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì sọ ṣe máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wa ṣe máa jẹ́ ká rí ojúure Jèhófà.

b ÀWÒRÁN:: Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni pé ìgbàgbọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe “àwọn iṣẹ́ òfin,” irú bíi kí wọ́n máa wọ aṣọ tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ búlúù ṣe, kí wọ́n máa ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá àti kí wọ́n máa fọwọ́ wọn dé ìgúnpá.

c ÀWÒRÁN: Jémíìsì sọ pé tá a bá ń ṣe rere sáwọn èèyàn, irú bíi ká máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́, á fi hàn pé a nígbàgbọ́.