Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51

Ìrètí Tó O Ní Ò Ní Já Ẹ Kulẹ̀

Ìrètí Tó O Ní Ò Ní Já Ẹ Kulẹ̀

‘Ìrètí kì í yọrí sí ìjákulẹ̀.’—RÓÒMÙ 5:5.

ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ló mú kó dá Ábúráhámù lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ?

 JÈHÓFÀ sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ̀ Ábúráhámù pé ó máa bí ọmọ kan tí gbogbo orílẹ̀-èdè máa gba ìbùkún nípasẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́n. 15:5; 22:18) Torí pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, ó dá a lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Kódà, nígbà tí Ábúráhámù pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí ìyàwó ẹ̀ sì jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, tọkọtaya tó nígbàgbọ́ yìí ò tíì bímọ kankan. (Jẹ́n. 21:1-7) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Lórí ìrètí, [Ábúráhámù] ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti sọ.” (Róòmù 4:18) Ìwọ náà sì mọ̀ pé ohun tí Ábúráhámù ń retí yìí ṣẹ nígbà tó yá torí ó di bàbá Ísákì, ọmọkùnrin tó ti ń wá tipẹ́tipẹ́. Àmọ́, kí ló mú kí Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ?

2. Kí ló mú kí Ábúráhámù gbà pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ?

2 Torí pé Ábúráhámù ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó “dá a lójú hán-ún pé Ọlọ́run lè ṣe ohun tí Ó ṣèlérí.” (Róòmù 4:21) Inú Jèhófà dùn sí Ábúráhámù, ó sì pè é ní olódodo torí ìgbàgbọ́ tó ní. (Jém. 2:23) Bó ṣe wà nínú Róòmù 4:18, ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní ló jẹ́ kó máa retí ìlérí Ọlọ́run. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ẹ̀ nínú Róòmù orí 5.

3. Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe nípa ìrètí?

3 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ‘ìrètí kì í yọrí sí ìjákulẹ̀.’ (Róòmù 5:5) Ó tún sọ àwọn nǹkan tó lè jẹ́ kí ìrètí táwa Kristẹni ní túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 5:1-5, wo báwọn nǹkan yìí ṣe kan ìwọ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ìrètí tó o ní báyìí ti lágbára ju ti ìgbà tó o ṣèrìbọmi lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní báyìí túbọ̀ lágbára. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìrètí ológo tí Pọ́ọ̀lù sọ pé kò ní já wa kulẹ̀.

ÌRÈTÍ OLÓGO

4. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 5:1, 2?

4 Ka Róòmù 5:1, 2. Ìjọ tó wà ní Róòmù ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yẹn sí. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù, wọ́n ti nígbàgbọ́, wọ́n sì ti di Kristẹni. Torí náà, Ọlọ́run “pè [wọ́n] ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́” tí wọ́n ní, ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Ìyẹn jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa rí ohun tí wọ́n ń retí gbà.

5. Ìrètí wo làwọn ẹni àmì òróró ní?

5 Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Éfésù nípa ìrètí tí wọ́n ní. Ọ̀kan lára ìrètí náà ni “ọrọ̀ ológo tó fẹ́ fi ṣe ogún fún àwọn ẹni mímọ́.” (Éfé. 1:18) Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ káwọn ará tó wà ní Kólósè mọ ibi tí wọ́n á ti gba èrè wọn. Ó pè é ní “ìrètí tí a fi pa mọ́ dè yín ní ọ̀run.” (Kól. 1:4, 5) Ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní ni pé Ọlọ́run máa jí wọn dìde sí ọ̀run níbi tí wọ́n ti máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi, wọ́n sì máa wà láàyè títí láé.—1 Tẹs. 4:13-17; Ìfi. 20:6.

Arákùnrin F. W. Franz sọ bí ohun táwọn ẹni àmì òróró ń retí ṣe dá wọn lójú (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Kí ni arákùnrin ẹni àmì òróró kan sọ nípa ìrètí tó ní?

6 Àwọn ẹni àmì òróró mọyì ìrètí tí wọ́n ní yẹn. Arákùnrin Frederick Franz tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ bí ìrètí tó ní ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Ìrètí wa dájú, gbogbo àwa tá a wà lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa rí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wa gbà. Èrè yẹn sì dáa ju gbogbo ohun míì tá a ní lọ.” Lẹ́yìn tí Arákùnrin Franz ti fòótọ́ inú sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sọ lọ́dún 1991 pé: “Ìrètí tá a ní ṣe pàtàkì gan-an. . . . Bá a ṣe ń dúró dè é la túbọ̀ ń mọyì ẹ̀. Ohun tó yẹ ká máa retí ni tó bá tiẹ̀ gba ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọdún kó tó dé. Mo ti wá túbọ̀ mọyì ìrètí tá a ní yìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ.”

7-8. Ìrètí wo ni ọ̀pọ̀ wa ní? (Róòmù 8:20, 21)

7 Ìrètí tí ọ̀pọ̀ àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà ní lónìí yàtọ̀ síyẹn. Ìrètí yìí ni Ábúráhámù ní, ìyẹn ìrètí láti gbé ayé títí láé nínú Párádísè nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso. (Héb. 11:8-10, 13) Pọ́ọ̀lù sọ èrè tí àwọn tó ní ìrètí yìí máa gbà nínú Bíbélì. (Ka Róòmù 8:20, 21.) Nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa nínú Bíbélì, kí ló wú ẹ lórí jù nínú ẹ̀? Ṣé bó o ṣe mọ̀ pé tó bá dọjọ́ kan wàá di ẹni pípé, o ò sì ní dẹ́ṣẹ̀ mọ́ ni? Àbí bó o ṣe mọ̀ pé wàá pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú nínú Párádísè? À ń fojú sọ́nà fún gbogbo nǹkan yìí “nítorí ìrètí” tí Ọlọ́run fún wa.

8 Bóyá ọ̀run là ń retí láti gbé títí láé tàbí ayé, ìrètí ológo tá a ní ń fún wa láyọ̀. Ìrètí tá a ní yìí sì lè túbọ̀ dá wa lójú. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ lẹ́yìn ìyẹn jẹ́ ká mọ bíyẹn ṣe lè ṣeé ṣe. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tá a ní. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ dá wa lójú pé a máa rí àwọn ohun tá à ń retí gbà.

BÍ OHUN TÁ À Ń RETÍ ṢE LÈ TÚBỌ̀ DÁ WA LÓJÚ

Gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi ni ìpọ́njú lè dé bá (Wo ìpínrọ̀ 9-10)

9-10. Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀ sáwa Kristẹni náà? (Róòmù 5:3) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Ka Róòmù 5:3. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá jìyà, àwọn ohun tá à ń retí máa túbọ̀ dá wa lójú. Ṣé ìyẹn ò yà wá lẹ́nu? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi la máa rí ìpọ́njú. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù. Ó sọ fáwọn tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń sọ fún yín pé a máa ní ìpọ́njú, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn.” (1 Tẹs. 3:4) Ó sì sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “A fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìpọ́njú tó bá wa . . . a ò tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.”—2 Kọ́r. 1:8; 11:23-27.

10 Àwa Kristẹni lónìí náà mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìpọ́njú lè dé bá wa. (2 Tím. 3:12) Ṣé ó ti ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ṣé àwọn èèyàn ti ń ṣenúnibíni sí ẹ torí pé o nígbàgbọ́ nínú Jésù, o sì ń tẹ̀ lé e? Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ lè máa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ẹ. Kódà, wọ́n lè máa gbógun tì ẹ́. Ṣé àwọn ará ibi iṣẹ́ ẹ ti ń fúngun mọ́ ẹ torí pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo? (Héb. 13:18) Àbí àwọn aláṣẹ ìjọba ń ta kò ẹ́ torí pé ò ń wàásù? Láìka ìpọ́njú yòówù kó dé bá wa sí, Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa yọ̀. Kí nìdí?

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu pé a máa fara da ìpọ́njú yòówù kó dé bá wa?

11 A lè láyọ̀ tá a bá tiẹ̀ níṣòro torí a mọ̀ pé ìṣòro yẹn máa jẹ́ ká nífaradà. Róòmù 5:3 sọ pé “ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá.” Gbogbo àwa Kristẹni la máa ní ìpọ́njú, torí náà, gbogbo wa ló yẹ ká nífaradà. Ó yẹ ká pinnu pé kò sí ìpọ́njú tó dé bá wa tá ò ní fara dà. Ìdí sì ni pé tá a bá fara dà á, tá a sì ń sin Jèhófà nìṣó la máa rí ohun tá à ń retí gbà. A ò fẹ́ dà bí àwọn tí Jésù sọ pé wọ́n dà bí irúgbìn tó bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n gbà á tayọ̀tayọ̀, àmọ́ “lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni” dé, wọ́n kọsẹ̀. (Mát. 13:5, 6, 20, 21) Òótọ́ ni pé kì í rọrùn rárá tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa tàbí tí àdánwò bá dé bá wa, àmọ́, ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí tá a bá fara dà á. Lọ́nà wo?

12. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá nífaradà?

12 Jémíìsì sọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń fara da àdánwò. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.” (Jém. 1:2-4) Jémíìsì sọ pé ìfaradà ní iṣẹ́ pàtàkì tó máa ṣe láyé wa. Iṣẹ́ wo nìyẹn? Ó lè jẹ́ kó o túbọ̀ ní sùúrù, kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, kó o sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àmọ́, àǹfààní pàtàkì míì wà tá a máa rí tá a bá nífaradà.

13-14. Kí ni ìfaradà máa ń mú wá, báwo sì nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rí ohun tá à ń retí gbà? (Róòmù 5:4)

13 Ka Róòmù 5:4. Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfaradà máa ń mú ìtẹ́wọ́gbà” wá. Tó o bá nífaradà, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Àmọ́ kì í ṣe torí pé o níṣòro tàbí torí àdánwò tó dé bá ẹ ni Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Ìwọ ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, kì í ṣe àwọn ìṣòro ẹ. Torí pé o nífaradà ni inú Jèhófà ṣe ń dùn sí ẹ. Ṣéyẹn ò múnú ẹ dùn?—Sm. 5:12.

14 Rántí pé Ábúráhámù fara da àwọn àdánwò tó dé bá a, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gbà á. Jèhófà pè é ní olódodo, ó sì sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jẹ́n. 15:6; Róòmù 4:13, 22) Ọlọ́run lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà. Kì í ṣe irú iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run tàbí bí iṣẹ́ tá à ń ṣe ṣe pọ̀ tó ni Ọlọ́run máa fi tẹ́wọ́ gbà wá. Ohun tó ń múnú Jèhófà dùn sí wa ni pé a jẹ́ olóòótọ́, a sì nífaradà. Láìka ọjọ́ orí wa, ohun tí agbára wa gbé tàbí ipò wa sí, gbogbo wa la lè nífaradà. Ṣé àdánwò kan wà tó ò ń fara dà lọ́wọ́lọ́wọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, máa rántí pé inú Ọlọ́run ń dùn sí ẹ, kó o sì jẹ́ kíyẹn máa mára tù ẹ́. Bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ọwọ́ wa máa tẹ àwọn ohun rere lọ́jọ́ iwájú.

JẸ́ KÍ ÌRÈTÍ Ẹ TÚBỌ̀ DÁJÚ

15. Kí ni Pọ́ọ̀lù tún sọ, kí sì nìdí tíyẹn fi lè ya àwọn kan lẹ́nu?

15 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá jẹ́ olóòótọ́, tá a sì fara da àdánwò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pọ́ọ̀lù tún sọ, ó ní: “Ìtẹ́wọ́gbà sì ń mú ìrètí wá, ìrètí kì í sì í yọrí sí ìjákulẹ̀.” (Róòmù 5:4, 5) Ìyẹn lè ya àwọn kan lẹ́nu. Kí nìdí? Ìdí ni pé ní Róòmù 5:2, Pọ́ọ̀lù ti sọ pé àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ti ní “ìrètí ògo Ọlọ́run.” Torí náà, ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Táwọn Kristẹni yẹn bá ti nírètí, kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé wọ́n ṣì nílò ìrètí?’

Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà ni ìrètí tó o ní túbọ̀ ń dá ẹ lójú, o sì túbọ̀ mọyì ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16. Kí ló máa mú kí ohun tẹ́nì kan ń retí túbọ̀ dá a lójú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ máa yé wa tá a bá gbà pé ohun tẹ́nì kan ń retí lè túbọ̀ dá a lójú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o rántí ìgbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn ìrètí ológo tó wà nínú Bíbélì? Nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kó o máa rò pé àlá lásán ni pé a máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. Àmọ́, bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà àtàwọn ìlérí míì tó wà nínú Bíbélì, ó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àwọn ohun tó ò ń retí máa dé.

17. Kí ló máa mú kí ìrètí ẹ túbọ̀ máa lágbára lẹ́yìn tó o ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ṣèrìbọmi?

17 Kódà lẹ́yìn tó o ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ṣèrìbọmi, o túbọ̀ mọ Jèhófà, o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ohun tó ò ń retí sì túbọ̀ ń dá ẹ lójú. (Héb. 5:13–6:1) Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Róòmù 5:2-4 sọ ti ṣẹlẹ̀ síwọ náà. Nígbà tó o níṣòro, tó o sì fara dà á, o rí bí inú Jèhófà ṣe dùn sí ẹ. Torí pé o rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá rí àwọn nǹkan tó ò ń retí gbà. Ìrètí tó o ní ti wá lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì dá ẹ lójú gan-an. Kódà, ó hàn nínú gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe, bó o ṣe ń hùwà sí ìdílé ẹ, bó o ṣe ń ṣe ìpinnu àti bó o ṣe ń lo àkókò ẹ.

18. Kí ni Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú?

18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ nǹkan pàtàkì míì nípa ìrètí tó o ní lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Ó jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ohun tó ò ń retí máa dé. Kí ló mú kó dá ẹ lójú? Ohun tó jẹ́ kó dá ẹ lójú ni ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti sọ, ó ní: “Ìrètí kì í sì í yọrí sí ìjákulẹ̀; nítorí pé a ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fún wa.” (Róòmù 5:5) Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún ẹ máa ṣẹlẹ̀.

19. Kí ló dájú nípa ohun tó ò ń retí?

19 Ronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù àti bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gbà á, tó sì pè é ní ọ̀rẹ́ òun. Ìrètí Ábúráhámù ò já sásán. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí Ábúráhámù ní sùúrù, ó rí ìlérí yìí gbà.” (Héb. 6:15; 11:9, 18; Róòmù 4:20-22) Ó dájú pé Jèhófà ò já a kulẹ̀. Tíwọ náà bá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀, ó dájú pé Jèhófà ò ní já ẹ kulẹ̀, wàá sì rí èrè náà gbà. Ohun tó ò ń retí dájú, á máa fún ẹ láyọ̀, kò sì ní já ẹ kulẹ̀. (Róòmù 12:12) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí fi gbogbo ayọ̀ àti àlàáfíà kún inú yín nítorí ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e, kí ìrètí yín lè túbọ̀ dájú nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.”—Róòmù 15:13.

ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun táwa Kristẹni ń retí àti bá a ṣe lè jẹ́ káwọn nǹkan náà dá wa lójú. Ìwé Róòmù orí 5 máa jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìrètí tá a ní báyìí àti ìrètí tá a ní nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.