Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrírí

Ìrírí

Máa Fàánú Hàn sí Gbogbo Èèyàn

Lọ́jọ́ kan, arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè New Zealand wo fídíò tá a pe àkòrí ẹ̀ ní Ẹ Máa Ṣìkẹ́ Ara Yín.’ Fídíò yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà máa ń káàánú wa nìkan ni, ó tún máa ń fàánú hàn sí wa. (Àìsá. 63:7-9) Arábìnrin yẹn wá pinnu pé òun á wá bí òun ṣe máa fàánú hàn sáwọn èèyàn. Nígbà tó lọ sọ́jà lọ́jọ́ yẹn kan náà, ó rí obìnrin kan tí ò nílé, ó sì bi í pé ṣé òun lè ra oúnjẹ fún un. Obìnrin náà gbà pé kó ra oúnjẹ fún òun. Nígbà tí arábìnrin yẹn gbé oúnjẹ náà dé, ó fi ìwé Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? wàásù fún obìnrin náà.

Ni obìnrin náà bá bú sẹ́kún. Ó ṣàlàyé fún arábìnrin yẹn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí òun, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lòun ti kúrò nínú òtítọ́. Ó wá sọ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, òun bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti pa dà sínú òtítọ́. Arábìnrin yẹn fún un ní Bíbélì, ó sì ṣètò bá á ṣe máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. a

Àwa náà lè jẹ́ aláàánú bíi ti Jèhófà, ká máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ. A tún lè fi hàn pé a jẹ́ aláàánú tá a bá ń wá bá a ṣe máa wàásù fáwọn èèyàn.

a Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi” nínú Ilé Ìṣọ́ June 2020.