Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò Ó?

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò Ó?

Ó DÁJÚ pé o mọyì gbogbo ẹ̀bùn rere tí Jèhófà ti fún ẹ títí kan òmìnira tó fún ẹ láti pinnu ohun tó o fẹ́, o sì ń gbádùn àwọn ẹ̀bùn yìí. Kò yà wá lẹ́nu pé Bíbélì sọ pé ẹ̀bùn ni wáìnì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Oúnjẹ wà fún ẹ̀rín, wáìnì sì ń mú kí èèyàn gbádùn ayé.” (Oníw. 10:19; Sm. 104:15) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé ọtí mímu ti di ìṣòro àwọn kan. Yàtọ̀ síyẹn, kárí ayé ni àṣà ìbílẹ̀ àti èrò àwọn èèyàn ti yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ọtí mímu?

Ibi yòówù ká máa gbé, àṣà ìbílẹ̀ yòówù ká sì ní, tá a bá jẹ́ kí Ọlọ́run darí èrò wa àtàwọn ìpinnu tá à ń ṣe, ó dájú pé a máa jàǹfààní, àá sì túbọ̀ láyọ̀.

Ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló máa ń mutí lámujù, wọ́n sì máa ń mu ún léraléra. Ìdí táwọn kan fi máa ń mu ún ni pé ó máa ń jẹ́ kára wọn balẹ̀. Àwọn míì sì máa ń sọ pé àwọn fi ń pàrònú rẹ́. Yàtọ̀ síyẹn láwọn ibì kan, àwọn èèyàn gbà pé àwọn tó bá ń mutí gan-an lèèyàn gidi, wọ́n sì gbayì.

Àmọ́, Jèhófà Ẹlẹ́dàá ti fún àwa Kristẹni ní ìtọ́sọ́nà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọtí àmujù lè ba ayé wa jẹ́. Àwa náà lè ti ka àlàyé tí Òwe 23:29-35 ṣe nípa ẹni tó mutí yó àti àjálù tó máa ń fà. a Daniel, alàgbà kan tó ń gbé nílẹ̀ Yúróòpù rántí ìgbésí ayé tó ń gbé kó tó di Kristẹni, ó ní: “Mo máa ń mutí lámujù, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa. Torí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí mi, inú mi sì máa ń bà jẹ́ gan-an tí mo bá ń rántí wọn.”

Báwo làwa Kristẹni ṣe lè lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti ṣe ìpinnu tó dáa nípa ọtí mímu, ká má sì kó síṣòro táwọn tó ń mutí jù máa ń kó sí? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká jẹ́ kí Jèhófà máa darí èrò wa nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe.

Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọtí mímu àti ìdí táwọn kan fi ń mutí.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ỌTÍ MÍMU

Bíbélì ò sọ pé ó burú tá a bá ń mutí níwọ̀nba. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wáìnì máa ń mú kéèyàn gbádùn ara ẹ̀. Ó sọ pé: “Máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi ìdùnnú mu wáìnì rẹ.” (Oníw. 9:7) Jésù máa ń mu wáìnì, àwọn èèyàn míì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà náà sì máa ń mu ún.—Mát. 26:27-29; Lúùkù 7:34; 1 Tím. 5:23.

Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn mutí níwọ̀nba àti kéèyàn mutí yó. Ó sọ ọ́ ní tààràtà pé: “Má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara.” (Éfé. 5:18) Kódà ó sọ pé “àwọn ọ̀mùtípara . . . kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 6:10) Ó hàn gbangba pé Jèhófà kórìíra kéèyàn máa mutí lámujù àti kéèyàn máa mutí yó. Dípò tí àá fi máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ wa lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu, ohun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí ló yẹ ká ṣe.

Àwọn kan rò pé àwọn lè mutí rẹpẹtẹ, kí ọtí má sì pa àwọn. Àmọ́, ìyẹn léwu gan-an. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá “jẹ́ ọ̀mùtí” ó lè ṣìwà hù, kó sì ba àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Títù 2:3; Òwe 20:1) Kódà, Jésù kìlọ̀ fún wa pé “ọtí àmujù” lè mú kéèyàn má wọ inú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Lúùkù 21:34-36) Kí ló máa wá ran Kristẹni kan lọ́wọ́ kó má bàa kó sínú ìṣòro ọtí mímu?

RONÚ LÓRÍ ÌDÍ TÓ O FI Ń MUTÍ ÀTI BÓHUN TÓ Ò Ń MU ṢE PỌ̀ TÓ

Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ọtí mímu, ó léwu tá a bá ń tẹ̀ lé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe níbi tá a dàgbà sí. Ohun tínú Jèhófà dùn sí làwọn Kristẹni máa ń ṣe tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ àti ohun mímu. Bíbélì rán wa létí pé: “Bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun míì, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn ìbéèrè tó máa ràn wá lọ́wọ́.

Ṣé torí káwọn èèyàn lè gba tèmi ni mo ṣe ń mutí? Ẹ́kísódù 23:2 sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn.” Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ fara wé àwọn tí ò ṣèfẹ́ òun. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fáwa Kristẹni náà lónìí. Tá a bá ń jẹ́ káwọn ojúgbà wa darí wa, kí wọ́n sì ṣèpinnu fún wa lórí ọ̀rọ̀ ọtí, ó lè mú ká jìnnà sí Jèhófà, ká sì ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́.—Róòmù 12:2.

Ṣé torí káwọn èèyàn lè mọ̀ pé mo lágbára ni mo ṣe ń mutí? Láwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń kan sáárá sáwọn tó bá ń mutí gan-an. (1 Pét. 4:3) Àmọ́ wo ohun tí 1 Kọ́ríńtì 16:13 sọ fún wa pé ká ṣe, ó ní: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bí ọkùnrin, ẹ di alágbára.” Ìbéèrè náà ni pé ṣé ọtí lè mú kéèyàn di alágbára? Rárá o. Ìdí ni pé ọtí kì í jẹ́ kéèyàn ronú dáadáa, kì í sì í jẹ́ kéèyàn ṣèpinnu tó tọ́. Torí náà, mímu ọtí àmujù ò fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ alágbára, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń fi hàn pé òmùgọ̀ ni. Àìsáyà 28:7 sọ pé ẹni tí ọtí ń pa máa ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, ó sì ń kọsẹ̀.

Jèhófà ló lè fún wa lágbára láti ṣe ohun tó tọ́, ó sì gba pé ká wà lójúfò, ká sì dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (Sm. 18:32) Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká yẹra fún ohun tó lè ṣe wá ní jàǹbá, ká má sì ṣe ohun tó máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un torí pé ó nígboyà láti ṣe ohun tó tọ́.

Ṣé torí kí n lè pàrònú rẹ́ ni mo ṣe ń mutí? Ẹ̀mí Ọlọ́run darí onísáàmù kan láti sọ pé: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, ìwọ [Jèhófà] tù mí nínú, o sì tù mí lára.” (Sm. 94:19) Tí ìṣòro bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè, Jèhófà ni kó o bẹ̀ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kì í ṣe ọtí ló yẹ kó o mu. Ohun tó dáa jù tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o tẹra mọ́ àdúrà sí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wọn kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó máa ń ṣe àwọn láǹfààní gan-an. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé téèyàn bá ń fọtí pàrònú rẹ́, kò ní rọrùn fún un láti sá fún ìṣekúṣe, kò sì ní lè ṣe ohun tó tọ́. (Hós. 4:11) Daniel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ọkàn mi kì í balẹ̀, mo sì máa ń dá ara mi lẹ́bi gan-an. Mo máa ń fọtí pàrònú rẹ́, àmọ́ kàkà kí ìṣòro mi dín kù, ṣe ló ń pọ̀ sí i. Ìyẹn ò wá jẹ́ kí n lọ́rẹ̀ẹ́ mọ́, àwọn èèyàn ò sì bọ̀wọ̀ fún mi mọ́.” Kí ló wá ran Daniel lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé Ọlọ́run nìkan ló lè ràn mí lọ́wọ́, kì í ṣe ọtí. Ìgbà tí mo wá mọ Jèhófà ni mo borí ìṣòro mi.” Ohun tó dájú ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́, kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìṣòro wa ò lójútùú.—Fílí. 4:6, 7; 1 Pét. 5:7.

Tó o bá ń mutí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí kó o lè mọ̀ bóyá o ti ń mutí jù: ‘Ṣé ẹnì kan nínú ìdílé mi tàbí ọ̀rẹ́ mi kan ti sọ fún mi rí pé mo ti ń mutí jù?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o ti níṣòro ọtí mímu, àmọ́ o ò tíì mọ̀. ‘Ṣé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mutí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?’ Bí àwọn tó máa ń mutí para ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nìyẹn. ‘Ṣé ara mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá tíì mutí lọ́jọ́ kan tàbí lọ́jọ́ mélòó kan?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ọtí mímu ti di bárakú fún ẹ nìyẹn. Kódà, ó lè gba pé kó o lọ rí dókítà, kó o lè mọ bí wàá ṣe borí ẹ̀.

Àwọn Kristẹni kan tiẹ̀ ti pinnu pé àwọn ò ní mutí rárá torí ewu tó wà nídìí ẹ̀ àti ìṣòro tó máa ń yọrí sí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn míì kì í mu ún torí pé wọn ò fẹ́ràn bó ṣe rí lẹ́nu. Tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá sọ pé òun ò fẹ́ mutí, á dáa kó o gbà pẹ̀lú ẹ̀ dípò kó o máa fúngun mọ́ ọn.

Ó sì lè jẹ́ pé o ti rí i pé á dáa kó o pinnu bí ọtí tó o máa mu ṣe máa pọ̀ tó. O lè pinnu àwọn ìgbà tí wàá máa mutí, bóyá ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ tàbí kó o kàn mu díẹ̀ nígbà oúnjẹ. Àwọn míì ti pinnu irú ọtí tí wọ́n máa mu, irú bíi wáìnì tàbí bíà, wọ́n sì ti sọ pé àwọn ò ní mu ọtí tó le gan-an tàbí ohun mímu tí wọ́n fi ọtí líle sí. Tẹ́nì kan bá ti pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu, á rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́. Tí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ bá ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, kò yẹ kó máa tijú tàbí kó máa ronú pé àwọn tó kù á máa fojú burúkú wo òun.

Tá a bá fẹ́ pinnu ìgbà tá a máa mutí àti bí ọtí tá a máa mu ṣe máa pọ̀ tó, á dáa ká tún gba tàwọn míì rò. Róòmù 14:21 sọ pé: “Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.” Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Tó o bá wà níbì kan pẹ̀lú àwọn mélòó kan, tó o sì rí i pé tó o bá mutí, kò ní bá àwọn kan lára mu, ṣé wàá pa ọtí náà tì torí ìfẹ́ tó o ní sí wọn? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o gba tàwọn míì rò, ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní lo sì ń wá, kì í ṣe àǹfààní tara ẹ.—1 Kọ́r. 10:24.

Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba lè ṣe àwọn òfin kan nípa ọtí mímu, ó sì yẹ káwa Kristẹni náà máa tẹ̀ lé àwọn òfin náà. Irú àwọn òfin yẹn lè sọ ọjọ́ orí tó yẹ kéèyàn jẹ́ kó tó lè mutí tàbí kí wọ́n sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ wa ọkọ̀, kò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹ̀rọ kan ṣiṣẹ́ tó bá ti mutí.—Róòmù 13:1-5.

Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa pọ̀ gan-an, ọ̀kan lára ẹ̀ sì ni pé ó fún wa lómìnira láti pinnu bá a ṣe máa lo àwọn ẹ̀bùn náà. Ìyẹn tún kan òmìnira tá a ní láti pinnu ohun tá a máa jẹ àtohun tá a máa mu. Àdúrà wa ni pé ká lo ẹ̀bùn òmìnira yìí lọ́nà táá múnú Jèhófà Baba wa ọ̀run dùn, ìyẹn lá sì fi hàn pé a mọyì òmìnira náà.

a Àjọ Centers for Disease Control and Prevention lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé téèyàn bá mutí para lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó lè mú kẹ́nì kan pa ẹlòmíì, kó fọwọ́ ara ẹ̀ pa ara ẹ̀ tàbí kó fipá bá ẹlòmíì lò pọ̀. Ó tún máa ń fa ìwà ipá láàárín tọkọtaya, ó máa ń mú kéèyàn gboyún ọmọ tí kò ní bàbá, ó sì lè mú kí oyún ṣẹ́ lára ẹnì kan.