Ǹjẹ́ O Rántí?
Nígbà tó o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí, ṣó o gbádùn ẹ̀? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tá a bá fẹ́ ‘yí èrò inú wa pa dà,’ kí ló yẹ ká ṣe? (Róòmù 12:2)
Ká yí èrò wa pa dà kọjá ká máa ṣe àwọn ohun rere kan. A gbọ́dọ̀ máa yẹ irú ẹni tá a jẹ́ wò, ká sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ, ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.—w23.01, ojú ìwé 8-9.
Báwo la ò ṣe ní ṣàṣejù tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé?
Ó máa ń wù wá láti rí bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí ṣe ń jẹ́ káwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Kò yẹ ká máa méfò lórí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ torí ó lè da ìjọ rú, nǹkan tí ètò Ọlọ́run sọ kẹ́yìn nípa ẹ̀ ló yẹ ká máa bá àwọn èèyàn sọ. (1 Kọ́r. 1:10)—w23.02, ojú ìwé 16.
Báwo ni ìrìbọmi àwa Kristẹni ṣe yàtọ̀ sí ti Jésù?
Jésù ò nílò láti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà bíi tiwa torí inú orílẹ̀-èdè tá a ti yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run la bí i sí. Kò nílò ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ torí ẹni pípé ni, kò sì dẹ́ṣẹ̀ kankan.—w23.03, ojú ìwé 5.
Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn míì máa dáhùn nípàdé?
Ká jẹ́ kí ìdáhùn wa ṣe ṣókí káwọn míì lè ráyè dáhùn. Yàtọ̀ síyẹn, ká má sọ kókó tó pọ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn yòókù á láǹfààní láti dáhùn.—w23.04, ojú ìwé 23.
Kí ni “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” tí Àìsáyà 35:8 sọ?
Ìgbà táwọn Júù ń pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti Bábílónì ni Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ yìí. Lákòókò wa yìí ńkọ́? Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú 1919, Jèhófà lo àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ láti tún ọ̀nà náà ṣe. Lára ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì, wọ́n sì ń tẹ̀ ẹ́. Àwa èèyàn Ọlọ́run ti ń rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn torí ó ń jẹ́ ká jọ́sìn Jèhófà, ó sì máa jẹ́ ká gbádùn àwọn ohun rere nínú Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú.—w23.05, ojú ìwé 15-19.
Obìnrin méjì wo ni Òwe orí 9 sọ̀rọ̀ nípa wọn, ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì sì fún wa?
Ìwé Òwe sọ̀rọ̀ nípa “òmùgọ̀ obìnrin” tó ń pe àwọn èèyàn lọ sí “Isà Òkú,” ó sì sọ̀rọ̀ nípa obìnrin míì tó fi wé “ọgbọ́n tòótọ́” tó ń pe àwọn èèyàn lọ sí “ọ̀nà òye” àti ìyè àìnípẹ̀kun. (Òwe 9:1, 6, 13, 18)—w23.06, ojú ìwé 22-24.
Kí ni Jèhófà ṣe fún Lọ́ọ̀tì tó fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì gba tiẹ̀ rò?
Jèhófà sọ fún Lọ́ọ̀tì pé kó sá kúrò nílùú Sódómù lọ sórí òkè ńlá kan. Àmọ́ Lọ́ọ̀tì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun sá lọ sí Sóárì, Jèhófà sì gbà kó ṣe bẹ́ẹ̀.—w23.07, ojú ìwé 21.
Kí ni aya kan lè ṣe tí ọkọ ẹ̀ bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe?
Ó yẹ kó máa fi sọ́kàn pé kì í ṣe òun lòun fà á. Ó yẹ kó máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó sì máa rántí àwọn obìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn pé Jèhófà tù nínú nígbà tí wọ́n níṣòro. Ó lè ran ọkọ ẹ̀ lọ́wọ́ láti yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú kó tún lọ wo àwòrán ìṣekúṣe.—w23.08, ojú ìwé 14-17.
Táwọn èèyàn bá béèrè ohun tá a gbà gbọ́, báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe máa jẹ́ ká dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́?
Dípò ká máa ronú pé ẹni tó bi wá ní ìbéèrè ń ta kò wá, ṣe ló yẹ ká rí i bí àǹfààní láti dáhùn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún wa láti fara balẹ̀ dá a lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́.—w23.09, ojú ìwé 17.
Kí la kọ́ nínú bí Màríà ṣe rí okun gbà?
Nígbà tí Màríà gbọ́ pé òun lòun máa bí Mèsáyà, ó jẹ́ káwọn míì fún òun lókun. Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì fún Màríà níṣìírí látinú Ìwé Mímọ́. Ó yẹ káwa náà jẹ́ káwọn ará wa ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa fún wa níṣìírí.—w23.10, ojú ìwé 15.
Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dáhùn àdúrà wa?
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Jer. 29:12) Bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà wa lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, àmọ́ ó dájú pé kò sígbà tó máa fi wá sílẹ̀.—w23.11, ojú ìwé 21-22.
Róòmù 5:2 sọ̀rọ̀ nípa “ìrètí,” àmọ́ kí ló fà á tó tún fi mẹ́nu kàn án ní ẹsẹ kẹrin?
Tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere, ó lè nírètí láti gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè. Àmọ́, nígbà tó níṣòro, tó sì fara dà á, ó rí bí inú Jèhófà ṣe dùn sí òun, ìrètí tó ní wá lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì dá a lójú gan-an.—w23.12, ojú ìwé 12-13.