Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀

Àwọn Olóòótọ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń San Ẹ̀jẹ́ Wọn

Àwọn Olóòótọ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń San Ẹ̀jẹ́ Wọn

Ka Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40 kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin ẹ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kó o máa san ẹ̀jẹ́ ẹ.

Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Irú ọwọ́ wo làwọn olóòótọ́ ọmọ Ísírẹ́lì fi mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Jèhófà? (Nọ́ń. 30:2) Kí ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin ẹ̀ ṣe tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú Jèhófà?—Oníd. 11:9-11, 19-24, 36.

Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe fún Jèhófà, kí ló sì wà lọ́kàn ẹ̀? (w16.04 6 ¶12) Àwọn nǹkan wo ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin ẹ̀ yááfì kí Jẹ́fútà lè san ẹ̀jẹ́ ẹ̀? (w16.04 6-7 ¶14-16) Lónìí, àwọn ẹ̀jẹ́ wo làwa Kristẹni lè jẹ́?—w17.04 5-8 ¶10-19.

Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:

  • ‘Kí ló máa jẹ́ kí n mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́ ṣẹ?’ (w20.03 13 ¶20)

  • ‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè yááfì kí n lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà?’

  • ‘Kí ni mo lè ṣe kí n lè mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ nígbà tí mo ṣègbéyàwó ṣẹ?’ (Mát. 19:5, 6; Éfé. 5:28-33)