Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50

ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Ìgbàgbọ́ Wọn Lè Túbọ̀ Lágbára

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Ìgbàgbọ́ Wọn Lè Túbọ̀ Lágbára

“Kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”RÓÒMÙ 12:2.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun táwọn òbí lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run àti Bíbélì, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè túbọ̀ lágbára.

1-2. Kí ló yẹ káwọn òbí ṣe táwọn ọmọ wọn bá béèrè ìbéèrè nípa Ọlọ́run àti Bíbélì?

 Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló gbà pé iṣẹ́ ọmọ títọ́ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Tó o bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́, a gbóríyìn fún ẹ torí ò ń ṣiṣẹ́ kára kí ìgbàgbọ́ ọmọ ẹ lè túbọ̀ lágbára. (Diu. 6:6, 7) Àmọ́, bọ́mọ ẹ bá ṣe ń dàgbà, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ohun tá a gbà gbọ́ àti ìdí tí Bíbélì fi sọ pé àwọn ìwà kan ò dáa.

2 Ẹ̀rù lè kọ́kọ́ bà ẹ́ tọ́mọ ẹ bá béèrè irú àwọn ìbéèrè yẹn. Kódà, àwọn ìbéèrè yẹn lè mú kó o ronú pé ọmọ ẹ ò tíì fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Bíbélì. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé tọ́mọ kan bá ń dàgbà, ó yẹ kó máa béèrè ìbéèrè kóhun tó gbà gbọ́ lè túbọ̀ dá a lójú. (1 Kọ́r. 13:11) Torí náà, kò yẹ kó o máa bẹ̀rù tọ́mọ ẹ bá béèrè ìbéèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o dáhùn ìbéèrè ẹ̀ lọ́nà táá fi ronú jinlẹ̀ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ nínú Ọlọ́run àti Bíbélì lè túbọ̀ dá a lójú.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa báwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn, (1) kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lè dá wọn lójú, (2) kí wọ́n lè mọ̀ pé ìlànà Bíbélì máa ṣe wọ́n láǹfààní àti (3) kí wọ́n lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Yàtọ̀ síyẹn, a máa sọ ìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa béèrè ìbéèrè. Àá tún sọ ohun tẹ́ ẹ lè jọ máa ṣe nínú ìdílé yín táá jẹ́ kẹ́ ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ nínú Bíbélì.

Ẹ JẸ́ KÍ OHUN TÍ WỌ́N GBÀ GBỌ́ DÁ WỌN LÓJÚ

4. Àwọn ìbéèrè wo làwọn ọmọ máa ń béèrè, kí sì nìdí?

4 Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni mọ̀ pé ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún táwọn lè fún ọmọ. A ò bí ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́ àwọn òbí, bẹ́ẹ̀ náà la ò bí i mọ́ ọmọ wọn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn ìbéèrè kan lè wà lọ́kàn àwọn ọmọ, irú bíi: ‘Ṣé ẹ̀rí wà pé Ọlọ́run wà? Ṣé mo lè gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́?’ Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ó yẹ ká máa lo “agbára ìrònú” wa, ká sì “máa wádìí ohun gbogbo dájú.” (Róòmù 12:1; 1 Tẹs. 5:21) Torí náà, báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ọmọ ẹ túbọ̀ lágbára?

5. Kí làwọn òbí lè ṣe táá mú káwọn ọmọ wọn gba Bíbélì gbọ́? (Róòmù 12:2)

5 Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kí òtítọ́ lè dá a lójú. (Ka Róòmù 12:2.) Tọ́mọ ẹ bá béèrè ìbéèrè, kọ́ ọ bó ṣe lè ṣèwádìí, ó lè lo ìwé ìwádìí irú bíi Watch Tower Publications Index àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní kó wo àkòrí náà “Bíbélì” nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lẹ́yìn náà kó wo ìsọ̀rí náà “Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run” kó lè rí ohun tó máa jẹ́ kó dá a lójú pé Bíbélì kì í ṣe ìwé kan lásán, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni. (1 Tẹs. 2:13) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ẹ lè ṣèwádìí nípa Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà nínú àwọn ìwé wa. Nígbà kan, àwọn tó ń ṣàríwísí Bíbélì sọ pé kò síbì kankan tó ń jẹ́ Nínéfè. Àmọ́ ní nǹkan bí ọdún 1850, wọ́n rí àwọn àwókù ìlú náà wà jáde tó jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Bíbélì sọ. (Sef. 2:13-15) Kí ọmọ náà lè mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ìparun Nínéfè ṣe ṣẹ, ó lè wo àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ O Mọ̀?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 2021. Tí ọmọ ẹ bá fi ohun tó kọ́ nínú ìwé ètò Ọlọ́run wé ohun tó kọ́ nínú àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ àtàwọn ìwé pàtàkì míì, á túbọ̀ gba Bíbélì gbọ́.

6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kó lè gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ìgbà làyè lè ṣí sílẹ̀ fáwọn òbí láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Bíbélì. Wọ́n lè lọ síbi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan àtijọ́ sí tàbí kí wọ́n lọ sí ọgbà ẹlẹ́wà tó ní oríṣiríṣi igi àti ewéko tàbí ibi tá a kó àwọn nǹkan tó jẹ́ ká mọ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́ ẹ bá lọ síbi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan àtijọ́ sí tàbí tẹ́ ẹ fi hàn án lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ẹ lè ní kó ka ìtàn àtijọ́ tí wọ́n kọ síbẹ̀ tàbí kó wo àwòrán nǹkan àtijọ́ tó máa mú kó túbọ̀ gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ. Ṣé ọmọ ẹ mọ̀ pé orúkọ Ọlọ́run wà lára Òkúta Móábù tó ti lo ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún láyé? Òkúta yìí wà ní Louvre Museum, ìyẹn ibi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan àtijọ́ sí ní Paris, lórílẹ̀-èdè Faransé. Ẹ tún lè rí Òkúta Móábù tí wọ́n ṣe tó jọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ níbi ìpàtẹ tá a pè ní “Bíbélì àti Orúkọ Ọlọ́run” ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Warwick, New York. Ohun tí wọ́n kọ sínú Òkúta Móábù jẹ́ ká mọ̀ pé Méṣà ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì. Ohun tí Bíbélì sì sọ nìyẹn. (2 Ọba 3:4, 5) Tí ọmọ ẹ bá rí i pé òótọ́ ni Bíbélì sọ, ìgbàgbọ́ ẹ̀ á túbọ̀ lágbára.—Fi wé 2 Kíróníkà 9:6.

Ṣé o lè fi ibi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan àtijọ́ sí han ọmọ ẹ tàbí kó wo àwòrán nǹkan àtijọ́ tó máa mú kó ronú jinlẹ̀ kó lè gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ? (Wo ìpínrọ̀ 6)


7-8. (a) Kí la lè kọ́ tá a bá kíyè sí bí àwọn nǹkan tó wà láyìíká wa ṣe lẹ́wà, tí wọ́n sì wà létòlétò? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo ló máa jẹ́ kí ọmọ ẹ túbọ̀ gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?

7 Gba ọmọ ẹ níyànjú pé kó máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Tó o bá ń rìn lọ ní ìgbèríko tàbí tó o bá ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà, sọ fún ọmọ ẹ pé kó wo bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe rẹwà tí wọ́n sì wà létòlétò. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Bí àwọn nǹkan náà ṣe wà létòlétò fi hàn pé ẹni tó gbọ́n ló dá wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan kan wà tí Ọlọ́run dá tó ní bátànì kan tí wọ́n ń pè ní spiral, irú bátànì yìí ni karawun ìgbín ní. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣèwádìí irú àwọn bátànì yẹn. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ Nicola Fameli ṣàlàyé pé téèyàn bá wo bátànì náà, ó máa rí i pé irú bátànì yìí náà wà lára àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run dá. Orúkọ tí wọ́n ń pe bátànì náà ni Fibonacci. A lè rí àwọn bátànì yìí lára ọ̀pọ̀ nǹkan bí ọ̀wọ́ ìràwọ̀, àwọn karawun kan, àwọn ewé àtàwọn òdòdó sunflower. a

8 Bí ọmọ ẹ bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sí i nílé ìwé, ó máa rí i pé àwọn bátànì míì tún wà lára àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run dá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn igi ní bátànì tiwọn, torí bí igi kan ṣe ń dàgbà ló ń ní ẹ̀ka, ewé àti ọ̀mùnú. Wọ́n máa ń pe irú bátànì yìí ní fractals. A tún lè rí irú bátànì yìí nínú àwọn nǹkan míì. Àmọ́ ta ló ṣe àwọn bátànì náà? Ṣé àwọn nǹkan náà ṣàdédé wà létòlétò lọ́nà àrà ni? Bọ́mọ ẹ bá ṣe ń ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí, ó lè mú kó túbọ̀ dá a lójú pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. (Héb. 3:4) Bó bá ṣe ń dàgbà sí i, o lè bi í pé, “Tá a bá gbà pé Ọlọ́run ló dá wa, ṣé o rò pé kò ní fún wa ní ìlànà táá jẹ́ káyé wa dáa, kínú wa sì máa dùn?” Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó mọ̀ pé inú Bíbélì la ti lè rí àwọn ìlànà yẹn.

NASA, ESA, and the Hubble Herige (STScl/AURA)-ESA/Hubble Collaboration

Ta lo rò pé ó ṣe àwọn bátànì tá à ń rí lára àwọn nǹkan? (Wo ìpínrọ̀ 7-8)


JẸ́ KÍ WỌ́N MỌ̀ PÉ ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÁA ṢE WỌ́N LÁǸFÀÀNÍ

9. Kí ló lè mú kọ́mọ ẹ máa béèrè ìdí tí Bíbélì fi sọ pé àwọn ìwà kan ò dáa?

9 Tọ́mọ ẹ bá béèrè ìdí tí Bíbélì fi sọ pé àwọn ìwà kan ò dáa, gbìyànjú láti mọ ìdí tó fi béèrè. Ṣé ohun tó fà á ni pé kò gbà pé ìmọ̀ràn Bíbélì máa ṣe wá láǹfààní? Tàbí ohun tó fà á ni pé kì í mọ ohun tó máa sọ táwọn èèyàn bá ní kó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́? Ohun yòówù kó fà á, o lè fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. b

10. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

10 Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Tó o bá ń kọ́ ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa lo àwọn àpèjúwe àtàwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. (Òwe 20:5) Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀kọ́ 8 fi Jèhófà wé ọ̀rẹ́ kan tó fẹ́ràn wa, tó sì máa ń fún wa nímọ̀ràn tó máa dáàbò bò wá táá sì ṣe wá láǹfààní. Lẹ́yìn tó o bá jíròrò ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 5:3, o lè bi í pé, “Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Ọ̀rẹ́ tó dáa ni Jèhófà, ojú wo ló yẹ ká fi wo ohun tó bá ní ká ṣe?” Ìbéèrè yẹn lè dà bí ìbéèrè tí ò le, àmọ́ ó máa jẹ́ kọ́mọ ẹ rí i pé àwọn òfin tí Jèhófà fún wa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.—Àìsá. 48:17, 18.

11. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè máa fi ìlànà Bíbélì sílò? (Òwe 2:10, 11)

11 Ẹ jíròrò àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ka Bíbélì tàbí ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, ẹ jíròrò àǹfààní tẹ́ ẹ rí nígbà tẹ́ ẹ fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ̀ pé tó bá jẹ́ òṣìṣẹ́ kára àti olóòótọ́, ó máa ṣe é láǹfààní. (Héb. 13:18) Yàtọ̀ síyẹn, o lè jẹ́ kó mọ̀ pé tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, á jẹ́ kí ìlera wa jí pépé, àá sì máa láyọ̀. (Òwe 14:29, 30) Tẹ́ ẹ bá jọ ń jíròrò àwọn ìlànà náà, á túbọ̀ mọyì ìmọ̀ràn inú Bíbélì.—Ka Òwe 2:10, 11.

12. Báwo ni Steve àti ìyàwó ẹ̀ ṣe jẹ́ kọ́mọ wọn mọ àǹfààní tó máa rí tó bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò?

12 Bàbá kan tó ń jẹ́ Steve láti orílẹ̀-èdè Faransé ṣàlàyé bí òun àti ìyàwó ẹ̀ ṣe ran Ethan ọmọkùnrin wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) lọ́wọ́, kó lè mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe fún wa lófin. Ó sọ pé: “A máa ń bi í láwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká fi ìlànà Bíbélì yìí sílò? Báwo nìyẹn ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ tí o ò bá fi ìlànà Bíbélì yìí sílò?’” Àwọn ìjíròrò yẹn ran Ethan lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo. Steve tún sọ pé: “A ti jẹ́ kí Ethan rí i pé ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì dáa ju ọgbọ́n èèyàn lọ fíìfíì.”

13. Sọ àpẹẹrẹ báwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa fi ìlànà Bíbélì sílò.

13 Kọ́ ọmọ ẹ kó lè máa fi ìlànà Bíbélì sílò. Ọ̀kan lára ìgbà tó o lè kọ́ ọmọ ẹ láti fi ìlànà Bíbélì sílò ni ìgbà tí wọ́n bá yan iṣẹ́ àṣetiléwá fún un nílé ìwé pé kó ka ìwé kan. Ìwé yẹn lè sọ ohun tó dáa nípa àwọn tó ń ṣèṣekúṣe tàbí àwọn tó ń hùwà ìkà, kó sì jẹ́ kí wọ́n máa rò pé ó yẹ káwọn máa ṣe bíi tiwọn. Bi ọmọ ẹ pé, ṣé inú Jèhófà máa dùn sáwọn tó ń hùwà burúkú tí ìwé náà sọ̀rọ̀ wọn? (Òwe 22:24, 25; 1 Kọ́r. 15:33; Fílí. 4:8) Ìyẹn á jẹ́ kó múra tán láti wàásù fún olùkọ́ ẹ̀ àtàwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò iṣẹ́ yẹn nínú kíláàsì.

KỌ́ ỌMỌ Ẹ KÓ LÈ ṢÀLÀYÉ OHUN TÓ GBÀ GBỌ́

14. Kí ló lè dẹ́rù ba ọ̀dọ́ Kristẹni kan, kí sì nìdí?

14 Nígbà míì, ẹ̀rù lè ba àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n nílé ìwé láti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan. Kí nìdí tẹ́rù fi lè bà wọ́n? Ìdí ni pé olùkọ́ wọn lè sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó dà bíi pé Ọlọ́run kọ́ ló dá àwọn nǹkan. Tó o bá jẹ́ òbí, báwo lo ṣe lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè nígboyà láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́?

15. Kí ló máa ran ọ̀dọ́ Kristẹni kan lọ́wọ́ kó lè nígboyà láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́?

15 Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ nígboyà láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́. Kò yẹ kójú ti ọmọ ẹ torí ó mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan. (2 Tím. 1:8) Kí nìdí tí ò fi yẹ kójú tì í? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé ewéko, àwọn ẹranko àtàwa èèyàn ò ṣàdédé wà. Wọ́n rí i pé àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú àwon nǹkan tí Ọlọ́run dá yìí ṣòro ṣàlàyé, torí náà wọ́n gbà pé ẹnì kan tó gbọ́n ló dá àwọn nǹkan yẹn. Ohun tí wọ́n mọ̀ yìí ni ò jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn nǹkan ṣàdédé wà báwọn ilé ìwé ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé. Ohun tó lè mú kí ìgbàgbọ́ ọmọ ẹ túbọ̀ lágbára ni pé kó mọ nǹkan tó mú káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan. c

16. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ìdí tó fi gbà pé Ọlọ́run wà? (1 Pétérù 3:15) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Kọ́ ọmọ ẹ bó ṣe lè ṣàlàyé ìdí tó fi gbà pé Ọlọ́run wà. (Ka 1 Pétérù 3:15.) Ó máa dáa tíwọ àtọmọ ẹ bá jíròrò ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó wà lórí jw.org tí àkòrí ẹ̀ sọ pé: “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?” Kẹ́ ẹ jọ jíròrò ohun tọ́mọ ẹ mọ̀ pé ó máa tètè mú káwọn èèyàn gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Rán an létí pé kò yẹ kó máa bá àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀ jiyàn. Sọ fún un pé kó máa ṣàlàyé lọ́nà tó rọrùn fún ẹni tó bá fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀ lè sọ pé: “Mi ò rí Ọlọ́run rí, ohun tí mo bá rí nìkan ni mo lè gbà gbọ́.” Ọ̀dọ́ Kristẹni náà lè dá a lóhùn pé: “Ká ní ò ń rìn gba inú igbó kìjikìji kan tó jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbé, o sì rí kànga kan tómi wà nínú ẹ̀. Kí lo máa rò? Ó dájú pé wàá gbà pé ẹnì kan ló gbẹ́ kànga yẹn. Lọ́nà kan náà, ó dájú pé ẹnì kan ló dá ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀!”

Ṣàlàyé lọ́nà tó rọrùn tó o bá ń bá ọmọ ilé ìwé ẹ sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 16-17) d


17. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kó lè máa sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ? Ṣàpèjúwe.

17 Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè máa sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (Róòmù 10:10) O lè fi bọ́mọ ẹ ṣe ń sapá láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ wé bẹ́nì kan ṣe ń sapá tó bá fẹ́ mọ béèyàn ṣe ń lo ohun ìkọrin. Orin tó rọrùn ló máa fi bẹ̀rẹ̀. Tó bá wá yá, á mọ béèyàn ṣe ń lo ohun ìkọrin náà dáadáa. Lọ́nà kan náà, ọ̀dọ́ Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ lọ́nà tó rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè bi ọmọ ilé ìwé ẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ohun tí Ọlọ́run dá làwọn ẹnjiníà máa ń wò fi ṣe nǹkan? Jẹ́ kí n fi fídíò kan tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ hàn ẹ́.” Lẹ́yìn tó bá fi ọ̀kan lára ọ̀wọ́ fídíò Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí? hàn án, ó lè béèrè pé: “Tó bá jẹ́ ohun tó wà tẹ́lẹ̀ làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń wò fi ṣe nǹkan tá a sì ń yìn wọ́n, ṣé kò wá yẹ ká yin ẹni tó dá àwọn nǹkan yẹn gangan?” Irú ìjíròrò ráńpẹ́ bẹ́ẹ̀ ti tó láti mú kí ọ̀dọ́ kan fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jèhófà.

MÁA RAN ỌMỌ Ẹ LỌ́WỌ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ Ẹ̀ LÈ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

18. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ gba Ọlọ́run gbọ́?

18 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gba Jèhófà gbọ́ láyé yìí. (2 Pét. 3:3) Torí náà, ẹ̀yin òbí tẹ́ ẹ bá ń kọ́ ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ sọ fún un pé kó ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó túbọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kó sì gbà pé òótọ́ lohun tó wà níbẹ̀. Ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè máa ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè lágbára. Jẹ́ kó mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ jọ máa gbàdúrà, tó o bá sì ń dá gbàdúrà, máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ fún Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà á jẹ́ kó o lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè túbọ̀ lágbára.—2 Kíró. 15:7.

ORIN 133 Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́

a Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo fídíò náà Àwọn Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Ń Fi Ògo Rẹ̀ Hàn​—Iṣẹ́ Ọnà lórí jw.org.

b Tí ọmọ rẹ bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tán, ẹ jọ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ kan ní apá 3 àti 4 tó ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì.

c Wo àpilẹ̀kọ náà “Why We Believe in a Creator” nínú Jí!, September 2006 lédè Gẹ̀ẹ́sì àti ìwé pẹlẹbẹ náà The Origin of Life—Five Questions Worth Asking. Tún wo ọ̀wọ́ fídíò náà, Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá lórí jw.org.

d ÀWÒRÁN: Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi ọ̀kan lára ọ̀wọ́ fídíò Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí? han ọmọ ilé ìwé ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ nǹkan táwọn ẹnjiníà ṣe.