Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Gbogbo Ìgbà Ni Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́

Gbogbo Ìgbà Ni Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́

INÚ mi dùn pé Jèhófà ni “Olùkọ́ [mi] Atóbilọ́lá.” (Àìsá. 30:20) Ó máa ń fi Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ohun tó dá àti ètò rẹ̀ kọ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ó tún máa ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, mo ṣì ń jẹ́ kí Jèhófà lo Bíbélì àtàwọn ará láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fún yín.

Ìdílé wa rèé lọ́dún 1948

Ìlú kékeré kan ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1927, nítòsí ìlú Chicago ní ìpínlẹ̀ Illinois, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwa márùn-ún làwọn òbí wa bí, Jetha, Don, èmi, Karl àti Joy. Gbogbo wa la pinnu pé tọkàntọkàn la máa fi sin Jèhófà. Ọdún 1943 ni wọ́n ṣe kíláàsì Gílíádì kejì, wọ́n sì pe Jetha lọ sí kíláàsì yẹn. Don lọ sí Bẹ́tẹ́lì nílùú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York lọ́dún 1944, Karl lọ lọ́dún 1947, Joy náà wá lọ lọ́dún 1951. Àpẹẹrẹ wọn àti tàwọn òbí mi jẹ́ kí n pinnu pé èmi náà máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.

BÍ ÌDÍLÉ WA ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Bàbá mi àti ìyá mi nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an, wọ́n máa ń ka Bíbélì, wọ́n sì kọ́ àwa náà pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Dádì mi wà lára àwọn sójà tó jagun nílẹ̀ Yúróòpù nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ṣùgbọ́n àtìgbà tí wọ́n ti dé látojú ogun ni wọn ò ti nífẹ̀ẹ́ ẹ̀sìn mọ́. Inú màmá mi dùn gan-an pé wọn ò kú sójú ogun, torí náà lọ́jọ́ kan màmá mi sọ fún Dádì pé: “Mo mọ̀ pé ó máa ń wù yín láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó yá ẹ jẹ́ ká lọ.” Dádì wá sọ pé: “Màá sìn ẹ́ débẹ̀, àmọ́ mi ò ní tẹ̀ lé ẹ wọlé.” Mọ́mì bi wọ́n pé: “Kí nìdí tẹ́ ò fi ní wọlé?” Wọ́n ní: “Nígbà tá à ń jagun, àwọn olórí ẹ̀sìn máa ń gbàdúrà fáwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè wọn tó ń bá àwọn orílẹ̀-èdè míì jà, wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà sórí àwọn ohun ìjà wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀sìn kan náà làwọn olórí ẹ̀sìn yẹn ń ṣe! Àdúrà ta ni Ọlọ́run máa wá gbọ́?”

Lọ́jọ́ kan tí màmá mi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé wa. Wọ́n fún bàbá mi ní ìwé alápá méjì tí wọ́n ń pè ní Light, ìwé náà sì ṣàlàyé ìwé Ìfihàn. Ọ̀rọ̀ wọn wọ bàbá mi lọ́kàn, wọ́n sì gba ìwé náà. Gbàrà tí màmá mi rí ìwé náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Lọ́jọ́ kan, wọ́n rí ìwé ìròyìn tí wọ́n fi ń pe àwọn èèyàn síbi tí wọ́n ti máa fi ìwé yìí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n pinnu pé àwọn máa lọ. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, obìnrin àgbàlagbà kan ló ṣílẹ̀kùn. Màmá mi na ọ̀kan lára ìwé náà sókè, wọ́n wá bi obìnrin náà pé, “Ṣé ibí la ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí?” Obìnrin náà sọ pé, “Ibí ni, ẹ wọlé.” Nígbà tó di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, màmá mi kó gbogbo àwa ọmọ ẹ̀ lọ síbẹ̀, àtìgbà yẹn la sì ti ń lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, ẹni tó ń darí ìpàdé náà ní kí n ka Sáàmù 144:15 tó sọ pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà máa ń láyọ̀. Ẹsẹ Bíbélì yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tún wọ̀ mí lọ́kàn ni 1 Tímótì 1:11 tó sọ pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà àti Éfésù 5:1 tó ní ká “máa fara wé Ọlọ́run.” Mo wá rí i pé ó yẹ kínú mi máa dùn bí mo ṣe ń sin Ẹlẹ́dàá mi, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó fún mi láǹfààní láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan méjì yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbèésí ayé mi.

Chicago ni ìjọ tó sún mọ́ wa jù wà, ibẹ̀ sì jẹ́ kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n (32) sí ilé wa. Síbẹ̀, a máa ń lọ sípàdé, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ nímọ̀ Bíbélì. Mo rántí pé lọ́jọ́ kan, ẹni tó ń darí ìpàdé pe Jetha pé kó dáhùn. Nígbà tí mo gbọ́ ohun tó sọ, mo wá sọ fúnra mi pé: ‘Èmi náà mọ ìdáhùn yẹn. Ká ní mo mọ̀ ni, mi ò bá ti nawọ́ láti dáhùn.’ Àtìgbà yẹn ni mo ti máa ń múra sílẹ̀, mo sì máa ń dáhùn nípàdé. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé mo túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà bíi tàwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi. Torí náà, nígbà tó dọdún 1941, mo ṣèrìbọmi.

JÈHÓFÀ KỌ́ MI LẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ÀPÉJỌ AGBÈGBÈ

Mi ò lè gbàgbé àpéjọ agbègbè tá a ṣe nílùú Cleveland ní ìpínlẹ̀ Ohio lọ́dún 1942. Ibi àádọ́ta (50) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látorí fóònù. Àwọn ará ṣètò ibì kan tí wọ́n máa ń gbé ọkọ̀ alágbèéká sí, ibẹ̀ sì ni ìdílé wa dé sí. Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó bá dọwọ́ alẹ́, àwọn ará máa ń páàkì mọ́tò wọn, wọ́n á sì kọjú ẹ̀ síta. Wọ́n sọ pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà nínú mọ́tò kọ̀ọ̀kan ní gbogbo òru mọ́jú. Táwọn kan bá fẹ́ wá fa wàhálà, gbogbo wọn máa tan iná iwájú mọ́tò wọn káwọn alátakò náà má bàa ríran, wọ́n á sì tẹ fèrè ọkọ̀. Táwọn ará tó kù bá ti gbọ́ ìró fèrè ọkọ̀ náà, wọ́n á bọ́ síta. Mo wá sọ fún ara mi pé ‘Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múra sílẹ̀ de gbogbo nǹkan.’ Torí náà, ọkàn mi máa ń balẹ̀, mo sì máa ń sùn dáadáa.

Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí mò ń ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ yẹn, mo rántí pé ẹ̀rù ò ba màmá mi rárá. Wọ́n fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀ pátápátá. Mi ò lè gbàgbé àpẹẹrẹ tó dáa tí wọ́n fi lélẹ̀ láé.

Nígbà tó kù díẹ̀ ká ṣe àpéjọ agbègbè yẹn, màmá mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà ní àpéjọ yẹn, wọ́n túbọ̀ fọkàn sí àwọn àsọyé tó dá lórí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tá à ń pa dà sílé, wọ́n sọ pé, “Ó wù mí pé kí n máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi nìṣó, àmọ́ kò ní rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí n sì tún máa ṣiṣẹ́ ilé.” Wọ́n wá bi wá pé ṣé a máa ran àwọn lọ́wọ́? A sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì yan yàrá kan tàbí méjì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti bójú tó ká tó jẹun àárọ̀. Lẹ́yìn tá a bá lọ sílé ìwé, wọ́n máa ń rí i pé gbogbo ilé mọ́ tónítóní, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n máa jáde lọ wàásù. Ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an, síbẹ̀ wọ́n máa ń bójú tó àwa ọmọ wọn dáadáa. Tá a bá wá jẹun nílé lọ́sàn-án tàbí tá a dé láti ilé ìwé, wọ́n máa ń tọ́jú wa. Tá a bá dé láti ilé ìwé nígbà míì, a jọ máa ń wàásù, ìyẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ mọ iṣẹ́ táwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń ṣe.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bàbá mi ò tíì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, àmọ́ inú wọn dùn pé mò ń wàásù. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ fún wọn pé mò ń gbìyànjú láti rí ẹni tí màá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ mi ò tíì rẹ́nì kankan. Lẹ́yìn ìyẹn, mo bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ máa gbà kí n máa kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́?” Wọ́n rò ó díẹ̀, wọ́n wá ní, “Kò sí nǹkan tó ń dí mi lọ́wọ́, ó dáa mo gbà.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, bàbá mi lẹni àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o!

Ìwé “The Truth Shall Make You Free” la fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Bí mo ṣe ń kọ́ bàbá mi lẹ́kọ̀ọ́ ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, kí n sì mọ̀ọ̀yàn kọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a ka ìpínrọ̀ kan tán nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n sọ fún mi pé: “Ohun tó wà nínú ìwé yìí yé mi, àmọ́ báwo lo ṣe mọ̀ pé òótọ́ ni?” Mi ò mọ ohun tí màá sọ, torí náà mo sọ fún wọn pé: “Mi ò mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn báyìí, àmọ́ tá a bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà míì, màá dáhùn ìbéèrè yín.” Mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Mo ṣèwádìí nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé nǹkan tá à ń jíròrò. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n túbọ̀ máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wa sílẹ̀, kí n sì máa ṣèwádìí. Ìyẹn jẹ́ kémi àti bàbá mi túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Wọ́n fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, wọ́n sì ṣèrìbọmi ní 1952.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Mo kúrò nílé nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Jetha a di míṣọ́nnárì, Don sì lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn wọn, ìyẹn sì wú mi lórí gan-an. Mo gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì àti ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, mo sì fi ọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn? Nígbà tó dọdún 1946, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì.

Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mo ṣe látọdún tí mo ti dé Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn sì ti mú kí n kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan. Ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni mo ti lò ní Bẹ́tẹ́lì báyìí, mo sì ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀wé àti iṣẹ́ ìṣirò. Mo tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń ra ọjà láti orílẹ̀-èdè míì àti bá a ṣe ń kó ẹrù ránṣẹ́ sórílẹ̀-èdè míì. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé Jèhófà ṣì ń kọ́ mi títí di báyìí, torí pé mo ṣì ń gbádùn ìjọsìn òwúrọ̀ àtàwọn àsọyé míì tí wọ́n máa ń sọ ní Bẹ́tẹ́lì.

Mò ń kọ́ àwọn alàgbà nílé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà

Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ lára Karl àbúrò mi tó wá sí Bẹ́tẹ́lì ní 1947. Ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, ó sì mọ̀ọ̀yàn kọ́. Ìgbà kan wà tí mo ní kó ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo fẹ́ sọ àsọyé. Mo sọ fún un pé mo ti ṣèwádìí gan-an, àmọ́ mi ò mọ bí màá ṣe lo àwọn ìwádìí yẹn. Ó béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ mi tó jẹ́ kí n mọ nǹkan tí màá ṣe. Ó ní “Joel, kí ni àkòrí àsọyé ẹ?” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lohun tó ń sọ yé mi, ìyẹn sì ni pé kí n lo àwọn nǹkan tó bá àsọyé mi mu, kí n sì fi àwọn tó kù sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ pàtàkì ló kọ́ mi yẹn, mi ò sì gbàgbé ẹ̀ láé.

Téèyàn bá fẹ́ láyọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, ó yẹ kó máa wàásù déédéé, ìyẹn á sì jẹ́ kó láwọn ìrírí tó ń gbéni ró. Mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà tá a lọ wàásù nílùú Bronx, ní ìpínlẹ̀ New York. Èmi àti arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ obìnrin kan tó gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! A kí i, a sì sọ fún un pé, “À ń kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní látinú Bíbélì, ìdí nìyẹn tá a fi wá.” Ó sọ pé, “Tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì lẹ bá wá, ẹ wọlé.” A ṣàlàyé ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ayé tuntun tá à ń retí. Ohun tó gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mélòó kan pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa. Nígbà tó yá, òun àti ọkọ ẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÌYÀWÓ MI

Ọdún mẹ́wàá ni mo fi wá ìyàwó kí n tó pàdé ìyàwó mi. Kí ló ràn mí lọ́wọ́ láti rí ìyàwó gidi? Mo gbàdúrà, mo sì bi ara mi pé ‘Kí ni mo fẹ́ ṣe lẹ́yìn tá a bá ṣègbéyàwó?’

Ìgbà témi àti Mary ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká

Lẹ́yìn àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 1953 ní Yankee Stadium, mo rí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mary Aniol. Òun àti Jetha jọ lọ sí kíláàsì kejì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì níbì kan náà. Inú Mary dùn gan-an bó ṣe ń sọ àwọn ìrírí tó ti ní lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣe ní erékùṣù Caribbean àtàwọn tó ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látọdún yìí wá. Bá a ṣe ń mọ ara wa sí i, àwa méjèèjì rí i pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà la fẹ́ fayé wa ṣe. A nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì ṣègbéyàwó ní April 1955. Ọ̀pọ̀ nǹkan nìyàwó mi ṣe tó jẹ́ kí n gbà pé Jèhófà dìídì fi ta mí lọ́rẹ ni, àpẹẹrẹ tó dáa ló sì máa ń fi lélẹ̀. Ó máa ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún un. Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ló sì máa ń fi ṣáájú láyé ẹ̀. (Mát. 6:33) Ọdún mẹ́ta la fi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, nígbà tó sì dọdún 1958, wọ́n ní káwa méjèèjì máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lára Mary. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, a jọ máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, a sì máa ń kà tó nǹkan bí ẹsẹ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Tá a bá ti ka Bíbélì náà tán, a máa sọ nǹkan tá a kọ́ àti bá a ṣe lè fi sílò nígbèésí ayé wa. Mary sábà máa ń sọ àwọn nǹkan tó kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì àti lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ẹ̀. Àwọn nǹkan tá a jọ ń sọ yìí máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ń múra àsọyé tàbí tí mo bá fẹ́ gba àwọn arábìnrin níyànjú.—Òwe 25:11.

Mary ìyàwó mi ọ̀wọ́n kú ní 2013. Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé káyé tuntun ti dé, ká tún lè jọ ríra! Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, mo ti pinnu pé màá jẹ́ kí Jèhófà máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, màá sì fi gbogbo ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé e. (Òwe 3:5, 6) Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń ronú nípa gbogbo nǹkan táwa èèyàn Jèhófà máa ṣe nínú ayé tuntun, ìyẹn sì máa ń tù mí nínú. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá ṣì máa kọ́ wa, ọ̀pọ̀ nǹkan la sì máa kọ́ nípa ẹ̀. Torí náà, mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti kọ́ mi àti bó ṣe fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí mi.

a Wo ìtàn ìgbésí ayé Jetha Sunal nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 2003, ojú ìwé 23-29.