Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

Jèhófà Mọ Ohun Tó Ń Pa Ẹ́ Lẹ́kún

Jèhófà Mọ Ohun Tó Ń Pa Ẹ́ Lẹ́kún

“Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?”SM. 56:8.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọ̀ tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, ó sì máa tù wá nínú kí ọkàn wa lè balẹ̀.

1-2. Àwọn nǹkan wo ló lè pa wá lẹ́kún?

 GBOGBO wa lohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí rí tó sì mú ká sunkún. A máa ń sunkún ayọ̀ tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ tó múnú wa dùn. A máa ń sunkún tí nǹkan pàtàkì tàbí nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń sunkún ayọ̀ tá a bá bímọ tuntun, tá a bá rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó múnú wa dùn tàbí tá a pàdé ọ̀rẹ́ wa kan tá a ti rí tipẹ́.

2 Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń sunkún torí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ dùn wá gan-an. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń sunkún gan-an tẹ́nì kan bá já wa kulẹ̀. A máa ń sunkún tá a bá ń jẹ̀rora torí àìsàn tó ń ṣe wá tàbí tí èèyàn wa bá kú. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, àwa náà lè sunkún bíi ti Jeremáyà nígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Ó sọ pé: “Omi ń ṣàn wálẹ̀ ní ojú mi . . . Omijé ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀, kò dáwọ́ dúró.”—Ìdárò 3:48, 49.

3. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá rí báwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ṣe ń jìyà? (Àìsáyà 63:9)

3 Jèhófà mọye ìgbà tá a ti sunkún torí àwọn ìṣòro tó dé bá wa. Bíbélì sọ pé Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì máa ń gbọ́ wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 34:15) Jèhófà ń rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bí òbí kan ṣe máa ń mọ̀ ọ́n lára tọ́mọ ẹ̀ bá ń sunkún tó sì máa ń rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa mọ̀ ọ́n lára tá a bá níṣòro tó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́.—Ka Àìsáyà 63:9.

4. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo la máa gbé yẹ̀ wò?

4 Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà máa ń ṣe tó bá rí i táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń sunkún. A lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hánà, Dáfídì àti Ọba Hẹsikáyà. Kí ló pa wọ́n lẹ́kún? Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí wọ́n ní kó ran àwọn lọ́wọ́? Báwo ni àpẹẹrẹ wọn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń sunkún torí pé a ní ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n dalẹ̀ wa tàbí tá a bá níṣòro tó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ?

TÁ A BÁ NÍ Ẹ̀DÙN ỌKÀN, A MÁA Ń SUNKÚN

5. Báwo ni ìṣòro tí Hánà ní ṣe rí lára ẹ̀?

5 Oríṣiríṣi ìṣòro ni Hánà ní tó bà á nínú jẹ́, tó sì mú kó sunkún. Ọ̀kan lára ìṣòro náà ni pé ọkọ ẹ̀ ní ìyàwó míì, orúkọ ẹ̀ ni Pẹ̀nínà, ó sì kórìíra Hánà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Hánà tún yàgàn, àmọ́ Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ. (1 Sám. 1:1, 2) Pẹ̀nínà máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́ ṣáá torí pé kò bímọ. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Hánà, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ọ̀rọ̀ náà dùn ún gan-an débi pé “ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun,” inú ẹ̀ sì máa ń “bà jẹ́ gan-an.”—1 Sám. 1:6, 7, 10.

6. Kí ni Hánà ṣe tó jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀?

6 Kí ni Hánà ṣe tó jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀? Ohun tó ṣe ni pé ó lọ sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn. Nígbà tó débẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtòsí ẹnu ọ̀nà àgbàlá àgọ́ ìjọsìn ló lọ, “ó [wá] bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ń sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.” Ó bẹ Jèhófà pé: ‘Bojú wo ìnira tó dé bá ìránṣẹ́ rẹ, kí o sì rántí mi.’ (1 Sám. 1:10b, 11) Hánà gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó máa dun Jèhófà gan-an nígbà tó rí ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí tó ń sunkún! Ó dájú pé Jèhófà máa tù ú nínú.

7. Báwo ni Jèhófà ṣe tu Hánà nínú lẹ́yìn tó gbàdúrà?

7 Báwo ló ṣe rí lára Hánà lẹ́yìn tó sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà, tí Àlùfáà Àgbà Élì sì sọ̀rọ̀ tó fi í lọ́kàn balẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Obìnrin náà sì bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.” (1 Sám. 1:17, 18) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń ba Hánà nínú jẹ́ ò tíì lọ, ara tù ú. Ó mọ̀ pé Jèhófà rí ẹ̀dùn ọkàn òun, ó sì máa ran òun lọ́wọ́. Jèhófà rí ohun tó ń dà á láàmú, ó gbọ́ igbe ẹkún ẹ̀, nígbà tó sì yá ó sọ̀rọ̀ ẹ̀ dayọ̀ torí pé ó lóyún.—1 Sám. 1:19, 20; 2:21.

8-9.Hébérù 10:24, 25 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa wá sípàdé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Ohun tá a rí kọ́. Ṣé o ní ìṣòro kan tó ń pa ẹ́ lẹ́kún? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnì kan nínú ìdílé ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ ló kú, tíyẹn sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, o lè fẹ́ dá wà láì bá ẹnì kankan sọ̀rọ̀, gbogbo èèyàn ló sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Hánà ṣe rí ìtùnú gbà tọ́kàn ẹ̀ sì balẹ̀ nígbà tó lọ sí àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà máa tu ìwọ náà nínú tó o bá wá sípàdé. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Bó o ṣe ń gbọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ń kà nípàdé, Jèhófà máa tù ẹ́ nínú, á sì jẹ́ kó o fi èrò tó tọ́ rọ́pò èrò tí ò tọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa ìṣòro ẹ mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀ lè má lọ tán lẹ́ẹ̀kan náà.

9 Tá a bá lọ sípàdé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń sọ̀rọ̀ tó ń gbé wa ró, wọ́n máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. (1 Tẹs. 5:11, 14) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tí ìyàwó ẹ̀ kú. Ó sọ pé: “Mo ṣì máa ń sunkún. Nígbà míì, màá kàn wá ibì kan jókòó sí, màá sì bú sẹ́kún. Àmọ́ tí mo bá lọ sípàdé, mo máa ń rí ìṣírí gbà. Ọ̀rọ̀ ìtùnú táwọn ará máa ń sọ fún mi máa ń tù mí lára gan-an. Tọ́kàn mi ò bá tiẹ̀ balẹ̀ kí n tó lọ sípàdé, tí mo bá débẹ̀, ara máa ń tù mí.” Torí náà tá a bá lọ sípàdé, Jèhófà máa lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti ràn wá lọ́wọ́.

Àwọn ará máa ń tù wá nínú (Wo ìpínrọ̀ 8-9)


10. Báwo ni àpẹẹrẹ Hánà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn?

10 Jèhófà tu Hánà nínú nígbà tó gbàdúrà. Ìwọ náà lè ‘kó gbogbo àníyàn ẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà,’ sì mọ̀ dájú pé ó máa gbọ́ ẹ. (1 Pét. 5:7) Arábìnrin kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn olè pa ọkọ ẹ̀, ó ní: “Ọkàn mi gbọgbẹ́ débi pé mo máa ń rò pé inú mi ò lè dùn mọ́ láé. Àmọ́ tí mo bá gbàdúrà sí Jèhófà, ọkàn mi máa ń balẹ̀, ara sì máa ń tù mí torí mo mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi. Nígbà míì tí mo bá ń gbàdúrà, mo lè má mọ nǹkan tí màá sọ, àmọ́ Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi. Tọ́rọ̀ náà bá kó mi lọ́kàn sókè gan-an, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó fi mí lọ́kàn balẹ̀. Lẹ́yìn náà, ara máa ń tù mí, màá sì lè ṣe gbogbo nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe lọ́jọ́ yẹn.” Tó o bá sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà, ó máa bá ẹ kẹ́dùn torí ó mọ bó ṣe ń ṣe ẹ́. Kódà tí ìṣòro ẹ ò bá lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. (Sm. 94:19; Fílí. 4:6, 7) Ó máa bù kún ẹ torí pé o jẹ́ olóòótọ́, o sì nífaradà.—Héb. 11:6.

TÍ WỌ́N BÁ DALẸ̀ WA, A MÁA Ń SUNKÚN

11. Báwo ló ṣe rí lára Dáfídì nígbà tí wọ́n hùwà tí ò dáa sí i?

11 Nígbà ayé Dáfídì, ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ní tó mú kó sunkún. Àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀, kódà àwọn ará ilé ẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan dalẹ̀ ẹ̀. (1 Sám. 19:10, 11; 2 Sám. 15:10-14, 30) Nígbà kan, ó sọ pé: “Àárẹ̀ ti mú mi nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi; láti òru mọ́jú ni omijé mi ń rin ibùsùn mi gbingbin; ẹkún mi ti fi omi kún àga tìmùtìmù mi.” Kí nìdí tí Dáfídì fi ní ẹ̀dùn ọkàn? Ẹ gbọ́ ohun tó sọ, ó ní: “Nítorí gbogbo àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi.” (Sm. 6:6, 7) Nǹkan táwọn èèyàn ṣe sí Dáfídì kó ẹ̀dùn ọkàn bá a débi pé ńṣe ló ń wa ẹkún mu.

12. Kí ni Sáàmù 56:8 sọ pé ó dá Dáfídì lójú?

12 Láìka gbogbo ìṣòro tí Dáfídì ní sí, ó dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sọ pé: “Jèhófà yóò gbọ́ igbe ẹkún mi.” (Sm. 6:8) Ìgbà kan tún wà tí Dáfídì sọ ohun tó jọ ọ̀rọ̀ yìí nínú Sáàmù 56:8. (Kà á.) Ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa. Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń gba omijé ẹ̀ sínú ìgò kan tàbí tó ń kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i sínú ìwé kan. Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sóun, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn òun. Dáfídì mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tójú òun ti rí nìkan ni, ó tún mọ bó ṣe rí lára òun.

13. Táwọn èèyàn bá já wa kulẹ̀, kí lá jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Ohun tá a rí kọ́. Ṣé o ní ẹ̀dùn ọkàn torí pé ẹnì kan tó o fọkàn tán dà ẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àfẹ́sọ́nà ẹ ló já ẹ kulẹ̀, ẹni tẹ́ ẹ jọ ṣègbéyàwó lè ti fi ẹ́ sílẹ̀ tàbí kí ẹni tó o fẹ́ràn má sin Jèhófà mọ́. Arákùnrin kan tí ìyàwó ẹ̀ ṣàgbèrè, tí obìnrin náà sì já a jù sílẹ̀ sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an, kódà mi ò gbà pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí mi. Ṣe ló dà bíi pé mi ò wúlò, mo ní ẹ̀dùn ọkàn, inú mi ò sì dùn rárá.” Táwọn èèyàn bá já ẹ kulẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. Arákùnrin náà sọ pé: “Mo ti wá rí i pé àwọn èèyàn lè já wa kulẹ̀, àmọ́ Jèhófà tó jẹ́ Àpáta wa ò lè já wa kulẹ̀ láé. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, kò ní fi wá sílẹ̀. Kódà, Bíbélì sọ pé kò ní fi àwọn adúróṣinṣin sílẹ̀.” (Sm. 37:28) Máa rántí pé kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ wa tó Jèhófà. Táwọn èèyàn tá a fẹ́ràn bá já wa kulẹ̀ tàbí tí wọ́n dalẹ̀ wa, ó máa ń dùn wá gan-an. Àmọ́ ìyẹn ò ní kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ wa mọ́ torí pé a ṣeyebíye lójú ẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Kókó ibẹ̀ ni pé: Ohun yòówù káwọn èèyàn ṣe sí ẹ, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an.

Ìwé Sáàmù fi dá wa lójú pé Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn (Wo ìpínrọ̀ 13)


14. Kí ni Sáàmù 34:18 fi dá wa lójú?

14 Táwọn èèyàn bá dalẹ̀ ẹ, ohun tí Dáfídì sọ ní Sáàmù 34:18 máa tù ẹ́ nínú. (Kà á.) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ míì tá a lè lò fáwọn tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn” ni “àwọn tó rò pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́.” Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn tó nírú ẹ̀dùn ọkàn báyìí lọ́wọ́? Báwọn òbí ṣe máa ń tu ọmọ wọn nínú tó bá ń sunkún, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà “wà nítòsí” wa láti tù wá nínú, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n bá já wa kulẹ̀. Ó máa ń wù ú láti tù wá nínú, ó sì máa ń wo ọgbẹ́ ọkàn wa sàn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún jẹ́ ká mọ àwọn ohun rere tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Àìsá. 65:17.

A MÁA Ń SUNKÚN TÓ BÁ DÀ BÍI PÉ KÒ SỌ́NÀ ÀBÁYỌ

15. Kí ló mú kí Hẹsikáyà sunkún?

15 Nígbà tí Hẹsikáyà ọba Júdà pé ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39), ó ṣàìsàn kan tó le. Jèhófà wá rán wòlíì Àìsáyà kó lọ sọ fún un pé àìsàn yẹn ló máa pa á. (2 Ọba 20:1) Ó jọ pé kò sọ́nà àbáyọ fún Hẹsikáyà. Ọ̀rọ̀ yẹn bà á nínú jẹ́ gan-an, ló bá bú sẹ́kún. Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn.—2 Ọba 20:2, 3.

16. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tó rí i tí Hẹsikáyà ń gbàdúrà tó sì ń sunkún?

16 Nígbà tí Jèhófà rí Hẹsikáyà tó ń gbàdúrà tó sì ń sunkún, ó káàánú ẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ. Wò ó, màá mú ọ lára dá.” Jèhófà ní kí Àìsáyà sọ fún un pé kò ní kú, òun máa fi kún ọjọ́ ayé ẹ̀, òun á sì gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà.—2 Ọba 20:4-6.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń ṣàìsàn tó le gan-an? (Sáàmù 41:3) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ohun tá a rí kọ́. Ṣé àìsàn kan ń ṣe ẹ́ tó o rò pé kò lè lọ láé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà, kódà o lè sunkún sí i lọ́rùn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ni Jèhófà, ó sì máa ń tù wá nínú nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ní báyìí, a ò retí pé kí Jèhófà mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. (Ka Sáàmù 41:3.) Ohun tó máa ń ṣe ni pé ó máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ láti fún wa lókun, ọgbọ́n àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ká lè máa fara dà á nìṣó. (Òwe 18:14; Fílí. 4:13) Jèhófà tún jẹ́ ká mọ̀ pé àìsàn ò ní ṣe wá mọ́ lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn sì máa ń tù wá nínú.—Àìsá. 33:24.

Ohun táá jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà dáhùn àdúrà wa ni pé á fún wa ní okun, ọgbọ́n àti ìfọ̀kànbalẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Ẹsẹ Bíbélì wo ló máa ń tù ẹ́ nínú tó o bá níṣòro tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè? (Wo àpótí náà “ Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Máa Fi Wá Lọ́kàn Balẹ̀.”)

18 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Hẹsikáyà jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀. Táwa náà bá ń ka Bíbélì, Jèhófà máa tù wá nínú. Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tù wá nínú nígbà ìṣòro sínú Bíbélì. (Róòmù 15:4) Arábìnrin kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà máa ń sunkún gan-an lẹ́yìn tí dókítà sọ fún un pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó ní: “Ẹsẹ Bíbélì tó sábà máa ń tù mí nínú ni Àìsáyà 26:3. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè má lágbára láti mú ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ ká lè fara da ìṣòro náà.” Ṣé ẹsẹ Bíbélì kan wà tó máa ń fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ tó o bá níṣòro tó le gan-an?

19. Kí ni Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú?

19 Òpin ayé burúkú yìí máa tó dé, ó sì dájú pé àwọn nǹkan tó lè pa wá lẹ́kún á túbọ̀ máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́ bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Hánà, Dáfídì àti Ọba Hẹsikáyà, Jèhófà ń rí ẹkún wa, àánú wa máa ń ṣe é, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọyì bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dùn wá. Torí náà, tá a bá níṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, ó yẹ ká sọ bó ṣe ń ṣe wá fún Jèhófà. Kò sì yẹ ká máa yẹra fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ. Bákan náà, ẹ jẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Tá a bá ń fara dà á nìṣó tá a sì jẹ́ olóòótọ́, ó dájú pé Jèhófà máa san èrè fún wa. Lára ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa ni pé ó máa mú àwọn nǹkan tó ń pa wá lẹ́kún kúrò pátápátá, kò ní síṣòro èyíkéyìí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sẹ́ni tó máa dalẹ̀ wa. (Ìfi. 21:4) Tó bá dìgbà yẹn, ẹkún ayọ̀ nìkan làá máa sun.

ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”