Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49

ORIN 147 Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun

Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé?

Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé?

“Gbogbo ẹni tó mọ Ọmọ, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ [máa] ní ìyè àìnípẹ̀kun.”JÒH. 6:40.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ṣe máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.

1. Kí nìdí táwọn kan fi rò pé èèyàn ò lè wà láàyè títí láé?

 Ọ̀PỌ̀ èèyàn máa ń jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, wọ́n sì tún máa ń ṣeré ìmárale kí ẹ̀mí wọn lè gùn. Àmọ́, wọ́n mọ̀ pé ìyẹn kọ́ ló máa jẹ́ káwọn wà láàyè títí láé. Wọ́n lè rò pé kò ṣeé ṣe fún èèyàn láti wà láàyè títí láé torí ìṣòro tí ọjọ́ ogbó ń fà. Àmọ́ Jésù sọ pé èèyàn lè ní “ìyè àìnípẹ̀kun” bí Jòhánù 3:16 àti 5:24 ṣe sọ.

2. Kí ni Jòhánù orí 6 sọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun? (Jòhánù 6:39, 40)

2 Ìgbà kan wà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó fi búrẹ́dì àti ẹja bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. a Ẹ ò rí i pé ìyẹn jọni lójú gan-an, àmọ́ ohun tó sọ lọ́jọ́ kejì ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Àwọn èèyàn náà tẹ̀ lé e dé Kápánáúmù nítòsí etíkun Gálílì, ibẹ̀ ló ti sọ fún wọn pé àwọn èèyàn máa jíǹde, wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ka Jòhánù 6:39, 40.) Ohun tí Jésù sọ yìí máa jẹ́ kó o rí i pé ìrètí wà fáwọn èèyàn ẹ tó ti kú. Ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti kú máa jíǹde, á sì ṣeé ṣe fún àwọn àtàwa láti wà láàyè títí láé. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lẹ́yìn náà nínú Jòhánù orí 6 kò yé ọ̀pọ̀ èèyàn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ Jésù yìí.

3. Kí ni Jésù sọ nípa ara ẹ̀ ní Jòhánù 6:51?

3 Jésù lọ sí Kápánáúmù lẹ́yìn tó bọ́ àwọn èèyàn. Àwọn tó bá sọ̀rọ̀ níbẹ̀ rántí bí Jèhófà ṣe fi mánà bọ́ àwọn baba ńlá wọn ní aginjù. Kódà, Bíbélì pe mánà náà ní “oúnjẹ láti ọ̀run.” (Sm. 105:40; Jòh. 6:31) Jésù wá fi ohun táwọn èèyàn náà mọ̀ nípa mánà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ló pèsè mánà náà fún wọn lọ́nà ìyanu, àwọn tó jẹ ẹ́ kú nígbà tó yá. (Jòh. 6:49) Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé òun ni “oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run,” “oúnjẹ Ọlọ́run” àti “oúnjẹ ìyè.” (Jòh. 6:32, 33, 35) Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín òun àti mánà. Ó sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ ààyè tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, ó máa wà láàyè títí láé.” (Ka Jòhánù 6:51.) Nígbà táwọn Júù gbọ́ ohun tó sọ, inú bí wọn. Wọ́n ní, báwo ni Jésù ṣe lè máa sọ pé òun ni “oúnjẹ” tó wá láti ọ̀run àti pé òun ṣe pàtàkì ju mánà tí Ọlọ́run pèsè lọ́nà ìyanu fáwọn baba ńlá wọn? Jésù wá dá wọn lóhùn pé: “Ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni.” Kí ni Jésù ń sọ? Ó yẹ ká mọ ohun tó ń sọ torí pé tá a bá mọ̀ ọ́n, á jẹ́ káwa àtàwọn èèyàn wa mọ bá a ṣe lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù ń sọ.

OÚNJẸ ÀÀYÈ ÀTI ẸRAN ARA JÉSÙ

4. Kí nìdí tí ohun tí Jésù sọ fi ya àwọn kan lẹ́nu?

4 Ẹnu ya àwọn kan nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jésù sọ pé, “ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni nítorí ìyè ayé.” Ṣé wọ́n rò pé ẹran ara ẹ̀ gangan ló máa gé fún wọn jẹ ni? (Jòh. 6:52) Jésù wá sọ nǹkan míì tó túbọ̀ yà wọ́n lẹ́nu, ó ní: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ èèyàn, tí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ ò ní ìyè kankan nínú ara yín.”—Jòh. 6:53.

5. Kí ló mú ká gbà pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ Jésù gangan ló fẹ́ káwọn èèyàn mu?

5 Nígbà ayé Nóà, Jèhófà sọ pé àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́n. 9:3, 4) Jèhófà tún sọ ohun kan náà nígbà tó ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin. Ó ní kí wọ́n “pa” ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹ̀jẹ̀. (Léf. 7:27) Jésù náà kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa Òfin Mósè mọ́. (Mát. 5:17-19) Torí náà, Jésù ò sọ fáwọn Júù pé kí wọ́n jẹ ẹran ara òun tàbí kí wọ́n mu ẹ̀jẹ̀ òun gangan. Àmọ́ ohun tó ń kọ́ àwọn èèyàn ni bí wọ́n ṣe máa ní “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:54.

6. Kí ló jẹ́ ká gbà pé àpèjúwe ni Jésù ń sọ nígbà tó ní káwọn èèyàn jẹ ẹran ara òun, kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun?

6 Kí ni Jésù ń sọ gan-an? Ó dájú pé àpèjúwe ni Jésù ń sọ bó ṣe ṣe nígbà tó sọ fún obìnrin ará Samáríà kan pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá mu látinú omi tí màá fún un, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé, àmọ́ omi tí màá fún un á di ìsun omi nínú rẹ̀, á sì máa tú yàà jáde láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 4:7, 14) b Jésù ò sọ pé obìnrin yẹn máa ní ìyè àìnípẹ̀kun tó bá mu omi inú kànga yẹn gangan. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sọ pé àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ ní Kápánáúmù máa ní ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n bá jẹ ẹran ara ẹ̀, tí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ gangan.

ÌYÀTỌ̀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ TÍ JÉSÙ SỌ

7. Báwo làwọn kan ṣe lóye ohun tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:53?

7Jòhánù 6:53, Jésù sọ pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara òun, kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun. Àmọ́ àwọn ẹlẹ́sìn kan gbà pé ohun tí Jésù fẹ́ ká máa ṣe níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà nìyẹn torí ọ̀rọ̀ tó lò nígbà méjèèjì jọra. (Mát. 26:26-28) Wọ́n sọ pé gbogbo èèyàn tó bá wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ló yẹ kó jẹ búrẹ́dì, kó sì mu wáìnì. Ṣé òótọ́ nìyẹn ṣá? Ó yẹ ká gbé ohun tí wọ́n sọ yìí yẹ̀ wò dáadáa torí pé lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń wá síbi tá a ti ń ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kárí ayé. A máa rí i pé ohun tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:53 yàtọ̀ pátápátá sóhun tó sọ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.

8. Àwọn ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ohun tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:53 àtohun tó sọ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìgbà méjèèjì yìí. Àkọ́kọ́, ìgbà wo ni Jésù sọ ohun tó wà ní Jòhánù 6:53-56, ibo ló sì ti sọ ọ́? Ọdún 32 S.K. ló sọ ọ́ ní Gálílì, àwọn Júù tó kóra jọ síbẹ̀ ló sì sọ ọ́ fún. Ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ọdún kan kó tó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ìkejì, àwọn wo ni Jésù dìídì ń bá sọ̀rọ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ní Gálílì ló jẹ́ pé kì í ṣe torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe wá, àmọ́ torí oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ jẹ. (Jòh. 6:26) Nígbà tí Jésù sọ nǹkan tí ò yé wọn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n fi í sílẹ̀, wọn ò sì nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ mọ́. Kódà, àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ò tẹ̀ lé e mọ́. (Jòh. 6:14, 36, 42, 60, 64, 66) Àmọ́, ẹ fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 33 S.K. nígbà tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀. Àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11) náà wà pẹ̀lú Jésù níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, wọn ò fi í sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun tó sọ kọ́ ló yé wọn. Síbẹ̀, wọn ò dà bí àwọn èèyàn Gálílì torí ó dá wọn lójú pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù. (Mát. 16:16) Ìdí nìyẹn tó fi gbóríyìn fún wọn pé: “Ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí nígbà àdánwò.” (Lúùkù 22:28) Àwọn ìyàtọ̀ tá a sọ yìí ti jẹ́ ká rí i pé ohun táwọn ẹlẹ́sìn yẹn sọ nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:53 kò tọ̀nà, kì í sì í ṣe bó ṣe fẹ́ ká máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa nìyẹn. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká tún gbé àwọn ẹ̀rí míì yẹ̀ wò.

Jòhánù orí 6 jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wà ní Gálílì (apá òsì). Ọdún kan lẹ́yìn náà, ó bá àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sọ̀rọ̀ ní Jerúsálẹ́mù (apá ọ̀tún) (Wo ìpínrọ̀ 8)


BÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ ṢE KÀN Ẹ́

9. Àwọn wo ni Jésù bá dá májẹ̀mú nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

9 Nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, Jésù gbé búrẹ́dì aláìwú fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sì sọ pé ó ṣàpẹẹrẹ ara òun. Lẹ́yìn náà, ó gbé wáìnì fún wọn, ó wá sọ pé ó ṣàpẹẹrẹ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú.” (Máàkù 14:22-25; Lúùkù 22:20; 1 Kọ́r. 11:24) Ohun tí Jésù sọ nípa májẹ̀mú yìí ṣe pàtàkì gan-an. “Ilé Ísírẹ́lì [tẹ̀mí]” ni Jésù bá dá májẹ̀mú tuntun yìí, àwọn ló sì máa bá a jọba lọ́run, kì í ṣe gbogbo èèyàn. (Héb. 8:6, 10; 9:15) Ohun tí Jésù sọ yìí ò yé àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ nígbà yẹn, àmọ́ ó máa tó yé wọn. Ìdí ni pé Ọlọ́run máa tó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, wọ́n á sì di ara àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun, kí wọ́n lè bá Jésù jọba lọ́run.—Jòh. 14:2, 3.

10. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ohun tí Jésù sọ ní Gálílì àtohun tó sọ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Kíyè sí i pé nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àwọn tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni “agbo kékeré.” Àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n wà pẹ̀lú ẹ̀ nínú yàrá yẹn ni àkọ́kọ́ lára agbo kékeré náà. (Lúùkù 12:32) Ìyẹn fi hàn pé àwọn míì ṣì máa wà lára agbo kékeré yìí tó bá yá. Àwọn ni Jésù retí pé kó jẹ búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu wáìnì. Àwọn ló máa láǹfààní láti bá Jésù jọba lọ́run. Torí náà, ohun tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa àtohun tó sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní Gálílì yàtọ̀ síra. Ohun tí Jésù sọ níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ ká rí i pé kìkì àwùjọ kékeré tó máa bá a jọba lọ́run ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ ní Gálílì, àwọn èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

Àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa ń jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì máa ń mu wáìnì níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àmọ́ “ẹnikẹ́ni” tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù máa rí ìyè àìnípẹ̀kun (Wo ìpínrọ̀ 10)


11. Kí ni Jésù sọ ní Gálílì tó jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

11 Nígbà tí Jésù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní Gálílì lọ́dún 32 S.K., kìkì àwọn Júù tó wá nítorí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ ló ń bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ. Ó sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó tún sọ fún wọn pé àwọn tó bá kú máa jíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn, wọ́n á sì wà láàyè títí láé. Torí náà, kì í ṣe àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, bó ṣe bá àwọn èèyàn díẹ̀ sọ̀rọ̀ níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa nígbà tó yá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun rere tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa gbádùn ló ń sọ nígbà tó wà ní Gálílì. Kódà, Jésù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, ó máa wà láàyè títí láé . . . ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni nítorí ìyè ayé.”Jòh. 6:51. c

12. Kí ni Jésù sọ pé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun?

12 Jésù ò sọ fáwọn Júù tó bá sọ̀rọ̀ ní Gálílì pé gbogbo èèyàn ló máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Kìkì àwọn tó bá ‘jẹ búrẹ́dì,’ ìyẹn àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù ló máa láǹfààní yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni rò pé àwọn máa rí ìgbàlà táwọn bá ṣáà ti “gba [Jésù] gbọ́,” táwọn sì gbà pé òun ni olùgbàlà àwọn. (Jòh. 6:29, Bíbélì Mímọ́) Ṣùgbọ́n, àwọn kan lára ọ̀pọ̀ tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ tẹ́lẹ̀ fi í sílẹ̀ nígbà tó yá. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?

13. Kí ló yẹ káwọn èèyàn ṣe kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Jésù?

13 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí Jésù bọ́ ni inú wọn dùn, wọ́n sì gbà láti máa tẹ̀ lé e torí pé wọ́n rí ohun tí wọ́n fẹ́. Ìdí tí wọ́n fi ń tẹ̀ lé Jésù ò ju pé ó ń wò wọ́n sàn lọ́nà ìyanu, ó ń fi oúnjẹ bọ́ wọn àti pé wọ́n ń gbádùn ohun tí Jésù ń kọ́ wọn. Àmọ́, Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ̀ pé kì í ṣe nǹkan tara nìkan ló yẹ kí wọ́n kà sí pàtàkì. Kì í sì í ṣe torí kóun lè pèsè àwọn nǹkan tara tí wọ́n nílò nìkan lòun ṣe wá sáyé. Ó fẹ́ kí wọ́n “wá sọ́dọ̀” òun, kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ òun, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sóun.—Jòh. 5:40; 6:44.

14. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ jàǹfààní ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù tó fi rúbọ?

14 Jésù jẹ́ káwọn èèyàn tó kọ́ mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n nígbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Ó fẹ́ kí wọ́n gbà gbọ́ pé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ tóun máa fi rúbọ nítorí wọn lágbára láti gbà wọ́n là. Ó ṣe pàtàkì káwọn Júù nígbàgbọ́ nínú Jésù, ó sì yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. (Jòh. 6:40) Torí náà bí Jòhánù 6:53 ṣe sọ, táwa náà bá fẹ́ jàǹfààní ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù tó fi rúbọ, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà ẹ̀. Àìmọye èèyàn ló sì lè jàǹfààní ẹ̀.—Éfé. 1:7.

15-16. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la kọ́ nínú Jòhánù orí 6?

15 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó máa ṣe wá láǹfààní ló wà nínú Jòhánù orí 6. Orí Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Nígbà tó wà ní Gálílì, ó wo àwọn èèyàn sàn, ó kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì fi oúnjẹ bọ́ wọn lásìkò tí wọ́n nílò ẹ̀. (Lúùkù 9:11; Jòh. 6:2, 11, 12) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó kọ́ wọn pé òun ni “oúnjẹ ìyè.”—Jòh. 6:35, 48.

16 Níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, Jésù sọ pé “àwọn àgùntàn mìíràn” ò gbọ́dọ̀ jẹ búrẹ́dì, wọn ò sì gbọ́dọ̀ mu wáìnì níbẹ̀. (Jòh. 10:16) Síbẹ̀, wọ́n ń jàǹfààní ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi tó fi rúbọ. Bí wọ́n ṣe ń jàǹfààní ẹ̀ ni pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà. (Jòh. 6:53) Àmọ́, àwọn tó bá jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì mu wáìnì ń fi hàn pé àwọn wà lára àwọn tí Jésù bá dá májẹ̀mú tuntun, wọ́n sì máa bá a jọba lọ́run. Torí náà, bóyá ẹni àmì òróró ni wá tàbí àgùntàn mìíràn, gbogbo wa ni ẹ̀kọ́ tó wà ní Jòhánù orí 6 máa ṣe láǹfààní. Orí Bíbélì yìí kọ́ wa pé ó ṣe pàtàkì ká nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, ká lè wà láàyè títí láé.

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

a Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò Jòhánù 6:5-35.

b Omi tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

c Jòhánù orí 6 lo ọ̀rọ̀ tá a lè tú sí “ẹnikẹ́ni” àti “gbogbo ẹni” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa wà láàyè títí láé.—Jòh. 6:35, 40, 47, 54, 56-58.