Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48

ORIN 97 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè

Ohun Tá A Kọ́ Nígbà Tí Jésù Pèsè Búrẹ́dì Lọ́nà Ìyanu

Ohun Tá A Kọ́ Nígbà Tí Jésù Pèsè Búrẹ́dì Lọ́nà Ìyanu

“Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹnikẹ́ni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi ò ní pa á rárá.”JÒH. 6:35.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa sọ̀rọ̀ nípa ìtàn inú Jòhánù orí 6 níbi tí Jésù ti sọ búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ di púpọ̀ kó lè bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn àtohun tá a lè kọ́ nínú ẹ̀.

1. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo ni búrẹ́dì ti ṣe pàtàkì tó?

 LÁYÉ ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, búrẹ́dì wà lára oúnjẹ táwọn èèyàn máa ń jẹ jù. (Jẹ́n. 14:18; Lúùkù 4:4) Kódà, àwọn èèyàn mọ búrẹ́dì débi pé nígbà míì tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ, “búrẹ́dì” ló máa ń pè é. (Mát. 6:11; Ìṣe 20:7, wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí nínú nwtsty-E) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù fi búrẹ́dì bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, ìgbà méjì yẹn sì wà lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa. (Mát. 16:9, 10) Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu náà wà nínú Jòhánù orí 6. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu yìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú ẹ̀ lónìí.

2. Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi nílò oúnjẹ?

2 Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù dé látibi tí wọ́n ti lọ wàásù, àwọn àti Jésù wọkọ̀ lọ sí òdìkejì Òkun Gálílì kí wọ́n lè sinmi torí pé ó ti rẹ̀ wọ́n gan-an. (Máàkù 6:7, 30-32; Lúùkù 9:10) Wọ́n lọ síbì kan tó dá lágbègbè Bẹtisáídà. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni èrò rẹpẹtẹ débẹ̀, wọ́n sì yí wọn ká. Àmọ́ Jésù ò pa wọ́n tì. Ṣe ló fara balẹ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì wo àwọn aláìsàn sàn. Bí ilẹ̀ ṣe ń ṣú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé kí ni gbogbo àwọn èèyàn yìí máa jẹ? Ó ṣeé ṣe káwọn kan ní oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́, àmọ́ ó máa gba pé kí èyí tó pọ̀ jù lára wọn lọ ra oúnjẹ nínú abúlé. (Mát. 14:15; Jòh. 6:4, 5) Kí ni Jésù máa wá ṣe báyìí?

JÉSÙ FI BÚRẸ́DÌ BỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́NÀ ÌYANU

3. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí ebi ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn? (Wo àwòrán.)

3 Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” (Mát. 14:16) Àmọ́ ìṣòro ńlá nìyẹn o torí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀. Tá a bá wá fi àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ kún un, wọ́n á tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) tí wọ́n máa fún lóúnjẹ. (Mát. 14:21) Áńdérù wá sọ pé: “Ọmọdékùnrin kan nìyí tó ní búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì. Àmọ́ kí ni èyí já mọ́ láàárín àwọn tó pọ̀ tó yìí?” (Jòh. 6:9) Láyé ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tálákà ló sábà máa ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n fi ọkà báálì ṣe, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi iyọ̀ sí ẹja kéékèèké náà, kí wọ́n sì ti yan án gbẹ. Síbẹ̀, ẹja tí ọmọ náà ní ò lè tó láti bọ́ gbogbo èèyàn yẹn. Àbí ẹ rò pé ó lè tó?

Jésù pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn, ó sì tún kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 3)


4. Kí la kọ́ nínú Jòhánù 6:11-13? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Torí pé Jésù fẹ́ kí ara tu àwọn èèyàn náà, ó ní kí wọ́n jókòó ní àwùjọ àwùjọ sórí koríko. (Máàkù 6:39, 40; ka Jòhánù 6:11-13.) Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Jésù dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá ẹ̀ torí búrẹ́dì àti ẹja náà. Ó sì ṣe pàtàkì kó dúpẹ́ torí pé Jèhófà ló pèsè oúnjẹ náà. Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà máa gbàdúrà ká tó jẹun, bóyá a dá wà tàbí a wà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù ní káwọn ọmọlẹ́yìn òun pín oúnjẹ náà fáwọn èèyàn. Àwọn èèyàn jẹun, wọ́n sì yó bámú. Kódà, oúnjẹ náà ṣẹ́ kù, Jésù ò sì fẹ́ kí ohunkóhun ṣòfò. Torí náà, ó ní kí wọ́n kó oúnjẹ tó ṣẹ́ kù náà jọ torí kí wọ́n lè lò ó nígbà míì. Ohun tí Jésù ṣe yìí kọ́ wa pé kò yẹ ká máa fi nǹkan ṣòfò. Torí náà, tó o bá jẹ́ òbí, o ò ṣe jíròrò ìtàn yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ kí wọ́n lè mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà, kí wọ́n máa gba àwọn èèyàn lálejò, kí wọ́n sì máa ṣoore fáwọn èèyàn?

Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà kí n tó jẹun bíi Jésù?’ (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí Jésù ṣiṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ kí ni Jésù ṣe?

5 Inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an torí ohun tí Jésù kọ́ wọn yé wọn dáadáa, ó sì tún ṣiṣẹ́ ìyanu. Wọ́n mọ̀ pé Mósè ti sọ pé Ọlọ́run máa gbé wòlíì ńlá kan dìde. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa sọ pé ‘Àbí Jésù ni wòlíì náà?’ (Diu. 18:15-18) Tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n ń rò nìyẹn, wọ́n máa gbà pé Jésù ni alákòóso táá lè pèsè oúnjẹ fún gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbìmọ̀ pọ̀ láti ‘mú Jésù kí wọ́n lè fi jẹ ọba.’ (Jòh. 6:14, 15) Tí Jésù bá gbà, á jẹ́ pé ó ti ń dá sọ́rọ̀ òṣèlú táwọn Júù ń ṣe nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ará Róòmù ló ń ṣàkóso àwọn Júù nígbà yẹn. Àmọ́ ṣé ó gbà? Rárá o. Bíbélì sọ pé Jésù kúrò níbẹ̀, ó sì ‘lọ sórí òkè.’ Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fipá mú un láti dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ó kọ̀ jálẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn kọ́ wa!

6. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa ní ká sọ búrẹ́dì di púpọ̀ tàbí ká wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà ìyanu. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ní sọ pé ká wá di ọba tàbí olórí orílẹ̀-èdè. Àmọ́ wọ́n lè rọ̀ wá pé ká dìbò tàbí ká gbè sẹ́yìn ẹni tí wọ́n gbà pé ó máa jẹ́ alákòóso tó dáa. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ yé wa dáadáa. Kò dá sọ́rọ̀ òṣèlú, kódà nígbà tó yá ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòh. 17:14; 18:36) Lónìí, ó yẹ káwa Kristẹni máa ronú bíi Jésù, ká sì máa ṣe bíi tiẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká fara mọ́, ká máa wàásù fáwọn èèyàn nípa ẹ̀, ká sì máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé. (Mát. 6:10) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sórí iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìyẹn ìgbà tó fi búrẹ́dì bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn, ká sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tá a lè kọ́ nínú ẹ̀.

Jésù ò dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)


“OHUN TÍ BÚRẸ́DÌ NÁÀ TÚMỌ̀ SÍ”

7. Kí ni Jésù ṣe, kí sì làwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sọ? Àmọ́ kí ni ò yé wọn? (Jòhánù 6:16-20)

7 Lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tán, ó ní káwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wọkọ̀ ojú omi pa dà sí Kápánáúmù, àmọ́ òun lọ sórí òkè kan, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí kí wọ́n má bàa fi í jọba. (Ka Jòhánù 6:16-20.) Nígbà táwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nínú ọkọ̀ náà, òkun ru gùdù, ìjì líle kan sì jà. Jésù wá ń rìn bọ̀ wá bá wọn lórí omi, ó sì sọ fún Pétérù pé kóun náà máa rìn bọ̀ lórí omi. (Mát. 14:22-31) Bí Jésù ṣe wọnú ọkọ̀ báyìí ni ìjì náà dáwọ́ dúró. Làwọn ọmọ ẹ̀yìn bá sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.” a (Mát. 14:33) Ó máa yà yín lẹ́nu pé ẹ̀yìn tí Jésù rìn lórí omi làwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ ohun tí wọ́n sọ yìí, wọn ò sọ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó sọ búrẹ́dì di púpọ̀ lọ́nà ìyanu. Kódà, Máàkù fi kún un pé: “Èyí ya [àwọn àpọ́sítélì] lẹ́nu gan-an, torí wọn ò tíì mọ ohun tí búrẹ́dì náà túmọ̀ sí, ọkàn wọn ò sì tíì ní òye.” (Máàkù 6:50-52) Wọn ò mọ bí agbára tí Jèhófà fún Jésù láti ṣiṣẹ́ ìyanu ṣe pọ̀ tó. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, Jésù pa dà sọ̀rọ̀ nípa búrẹ́dì tó sọ di púpọ̀ lọ́nà ìyanu kó lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ míì tó ṣe pàtàkì.

8-9. Kí nìdí táwọn èèyàn yẹn fi ń wá Jésù? (Jòhánù 6:26, 27)

8 Torí oúnjẹ làwọn tí Jésù bọ́ ṣe ń wá a kiri. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lọ́jọ́ kejì, wọ́n rí i pé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ti kúrò níbẹ̀. Torí náà, wọ́n wọ àwọn ọkọ̀ ojú omi tó dé láti Tìbéríà, wọ́n sì lọ sí Kápánáúmù láti wá Jésù. (Jòh. 6:22-24) Ṣé torí kí wọ́n lè túbọ̀ gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ṣe lọ? Rárá o. Nǹkan tí wọ́n máa jẹ nìkan ni wọ́n ń wá. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn náà rí Jésù nítòsí Kápánáúmù. Jésù sọ fún wọn pé torí oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ jẹ ni wọ́n ṣe ń wá òun. Ó ní òótọ́ lẹ “jẹ nínú àwọn búrẹ́dì náà ẹ sì yó,” àmọ́ “oúnjẹ tó ń ṣègbé” nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n ṣiṣẹ́ fún “oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ka Jòhánù 6:26, 27.) Jésù wá sọ fún wọn pé Bàbá òun máa pèsè irú oúnjẹ yẹn fún wọn. Ó dájú pé ó máa yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ pé oúnjẹ máa jẹ́ káwọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. Irú oúnjẹ wo nìyẹn, báwo làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù sì ṣe lè rí i gbà?

10. Kí làwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ rí ìyè àìnípẹ̀kun?

10 Ó jọ pé àwọn Júù yẹn rò pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ kan káwọn tó lè rí irú oúnjẹ yẹn gbà. Wọ́n lè máa rò pé àwọn “iṣẹ́” tí Òfin Mósè ní kí wọ́n máa ṣe ló ń sọ. Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Iṣẹ́ Ọlọ́run ni pé, kí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán.” (Jòh. 6:28, 29) Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹni tí Ọlọ́run rán kí wọ́n tó lè “ní ìyè àìnípẹ̀kun,” Jésù sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Jòh. 3:16-18, 36) Nígbà tó yá, Jésù tún bá wọn sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.

11. Kí làwọn èèyàn náà tún ṣe tó fi hàn pé oúnjẹ nìkan ni wọ́n ń wá? (Sáàmù 78:24, 25)

11 Jésù sọ àwọn “iṣẹ́ Ọlọ́run” fáwọn Júù yẹn, àmọ́ wọn ò gbà á gbọ́. Wọ́n bi í pé: “Iṣẹ́ àmì wo lo máa ṣe, ká lè rí i, ká sì gbà ọ́ gbọ́?” (Jòh. 6:30) Wọ́n sọ pé nígbà ayé Mósè, Ọlọ́run pèsè mánà tó dà bíi búrẹ́dì fáwọn baba ńlá wọn. (Neh. 9:15; ka Sáàmù 78:24, 25.) Ó hàn gbangba pé oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ nìkan ni wọ́n ń rò. Kódà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run,” ìyẹn oúnjẹ tó máa fún wọn níyè àìnípẹ̀kun, tó sì ṣe pàtàkì ju mánà lọ, wọn ò ní kó ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn. (Jòh. 6:32) Oúnjẹ yẹn ni wọ́n ṣáà ń tẹnu mọ́ débi pé wọn ò tiẹ̀ fetí sí ohun tí Jésù fẹ́ kọ́ wọn. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?

OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ

12. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù?

12 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tá a kọ́ nínú Jòhánù orí 6. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù ni pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Ẹ rántí pé Jésù kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì yìí nígbà tí Sátánì dẹ ẹ́ wò, tó sì kọ ohun tí Sátánì ní kó ṣe. (Mát. 4:3, 4) Bákan náà, nínú Ìwàásù orí Òkè, ó sọ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù. (Mát. 5:3) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù àbí bí mo ṣe máa tẹ́ ara mi lọ́rùn?’

13. (a) Kí nìdí tí ò fi burú ká gbádùn oúnjẹ tí Jèhófà pèsè fún wa? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún wa? (1 Kọ́ríńtì 10:6, 7, 11)

13 Kò burú tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà pèsè ohun tá a máa jẹ, ká sì gbádùn oúnjẹ náà. (Lúùkù 11:3) Iṣẹ́ àṣekára máa ń jẹ́ ‘ká jẹ, ká mu,’ ká sì gbádùn ara wa nítorí pé “ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́” ló ti wá. (Oníw. 2:24; 8:15; Jém. 1:17) Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa di pé àwọn nǹkan tara ló máa ṣe pàtàkì jù láyé wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nígbà tó ń kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan búburú tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà kan, títí kan ohun tó ṣẹlẹ̀ nítòsí Òkè Sínáì. Ó kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé ‘kí àwọn ohun tó ń ṣeni léṣe má wù wọ́n, bó ṣe wu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’ (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:6, 7, 11.) Nígbà tí Jèhófà pèsè oúnjẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sọ oúnjẹ náà di “ohun tó ń ṣeni léṣe” torí ojúkòkòrò wọn. (Nọ́ń. 11:4-6, 31-34) Nígbà tí wọ́n sì ṣe ère ọmọ màlúù, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì gbádùn ara wọn. (Ẹ́kís. 32:4-6) Pọ́ọ̀lù fi àwọn àpẹẹrẹ yìí kìlọ̀ fáwọn Kristẹni tó gbé ayé nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 S.K. Àsìkò tí ayé yìí máa tó pa run làwa náà ń gbé báyìí, torí náà ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù.

14. Irú àwọn oúnjẹ wo la máa gbádùn nínú ayé tuntun?

14 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí,” ìgbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ “ní ayé, bíi ti ọ̀run” ló ń sọ. (Mát. 6:9-11) Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí nígbà yẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ara ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ni pé kó pèsè oúnjẹ tó dáa fún gbogbo èèyàn. Àìsáyà 25:6-8 sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tó dáa máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run. Sáàmù 72:16 náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀;ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.” Ṣé ìwọ náà ń fojú sọ́nà láti se oúnjẹ tó o fẹ́ràn jù tàbí kó o tiẹ̀ se àwọn oúnjẹ tó ò sè rí? Yàtọ̀ síyẹn, wàá gbin ọgbà àjàrà, wàá sì gbádùn èso àti wáìnì tó o bá kórè níbẹ̀. (Àìsá. 65:21, 22) Gbogbo èèyàn tó bá wà láyé nígbà yẹn ló máa gbádùn àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe ìwọ nìkan.

15. Kí làwọn tó bá jíǹde máa kọ́? (Jòhánù 6:35)

15 Ka Jòhánù 6:35. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó jẹ búrẹ́dì àti ẹja tí Jésù pèsè lọ́nà ìyanu? Ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn kan nínú wọn nígbà àjíǹde. Kódà, tí wọn ò bá tiẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù kí wọ́n tó kú, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà jí wọn dìde. (Jòh. 5:28, 29) Tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n máa mọ ìtumọ̀ ohun tí Jésù sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹnikẹ́ni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi ò ní pa á rárá.” Ó máa gba pé kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, kí wọ́n sì gbà pé torí wọn ló ṣe kú. Tó bá dìgbà yẹn, ètò kan máa wà láti kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ọmọ tá a máa bí. Inú wa máa dùn gan-an pé a wà lára àwọn tó máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́! Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú ẹ máa dùn ju ìgbà tó o jẹ oúnjẹ lásán lọ. Ẹ ò rí i pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà ló máa ṣe pàtàkì jù nígbà yẹn.

16. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

16 A ti jíròrò díẹ̀ nínú ohun tó wà ní Jòhánù orí 6, àmọ́ àwọn nǹkan míì ṣì wà tí Jésù sọ nípa “ìyè àìnípẹ̀kun.” Ó ṣe pàtàkì pé káwọn Júù yẹn tẹ́tí sí Jésù, ó sì yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. A máa jíròrò àwọn nǹkan míì tí Jésù sọ ní Jòhánù orí 6 nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

a Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ìtàn alárinrin yìí, wo ìwé Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè, ojú ìwé 131 àti ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn, ojú ìwé 185.