Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni “àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́” tí 1 Tímótì 5:21 sọ̀rọ̀ nípa wọn?

Nígbà tí Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí Tímótì tóun náà jẹ́ alàgbà, ó sọ pé: “Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́ pé kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.”—1 Tím. 5:21.

Lákọ̀ọ́kọ́, ká lè mọ àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ àyànfẹ́ yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ò sí lára wọn. Ó hàn gbangba pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ò sí lára wọn. Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí Tímótì, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jíǹde lọ sọ́run. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ẹni àmì òróró míì nígbà yẹn ò tíì di ẹni ẹ̀mí, torí náà wọn ò lè jẹ́ “àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́” tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ.—1 Kọ́r. 15:50-54; 1 Tẹs. 4:13-17; 1 Jòh. 3:2.

Bákan náà, “àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́” yìí ò lè jẹ́ àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn nígbà Ìkún Omi. Ìdí ni pé àwọn áńgẹ́lì yìí tẹ̀ lé Sátánì, wọ́n sì sọ ara wọn di ẹ̀mí èṣù àti ọ̀tá Jésù. (Jẹ́n. 6:2; Lúùkù 8:30, 31; 2 Pét. 2:4) Lọ́jọ́ iwájú, Jésù máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún, lẹ́yìn náà ó máa pa àwọn àti Sátánì Èṣù run pátápátá.—Júùdù 6; Ìfi. 20:1-3, 10.

“Àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí máa jẹ́ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run tí wọ́n ń bá “Ọlọ́run àti Kristi Jésù” ṣiṣẹ́.

Àìmọye àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ló wà. (Héb. 12:22, 23) Ó jọ pé iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà gbé fún wọn. (Ìfi. 14:17, 18) Ẹ rántí pé áńgẹ́lì kan ni Jèhófà ní kó pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọmọ ogun Ásíríà. (2 Ọba 19:35) Iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fáwọn àwọn áńgẹ́lì kan sì lè jẹ́ pé wọ́n máa “kó gbogbo ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àti àwọn arúfin jáde kúrò nínú Ìjọba [Jésù].” (Mát. 13:39-41) Iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì míì sì lè jẹ́ pé wọ́n máa “kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ” sí ọ̀run. (Mát. 24:31) Àwọn áńgẹ́lì kan tún wà tí wọ́n ‘máa ń ṣọ́ wa ní gbogbo ọ̀nà wa.’—Sm. 91:11; Mát. 18:10; fi wé Mátíù 4:11; Lúùkù 22:43.

Ó jọ pé iṣẹ́ “àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́” tí 1 Tímótì 5:21 sọ ni pé kí wọ́n máa ran ìjọ Ọlọ́run lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ fún àwọn alàgbà nímọ̀ràn nípa iṣẹ́ wọn, ó sì sọ fáwọn ará ìjọ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà. Lẹ́yìn náà, ó ní káwọn alàgbà máa bójú tó iṣẹ́ wọn “láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú,” kí wọ́n má sì kánjú ṣe ìpinnu. Ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ “níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́.” Torí náà, ó hàn gbangba pé iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì kan ni pé kí wọ́n máa ran ìjọ lọ́wọ́, irú bíi kí wọ́n máa dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run, kí wọ́n máa darí iṣẹ́ ìwàásù, kí wọ́n sì jábọ̀ fún Jèhófà.—Mát. 18:10; Ìfi. 14:6.