Ǹjẹ́ O Rántí?
Nígbà tó o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí, ṣó o gbádùn ẹ̀? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn obìnrin?
Jèhófà ò ka ọkùnrin sí ju obìnrin lọ. Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí wọn, ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn obìnrin, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ó fọkàn tán wọn pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ tóun gbé fún wọn.—w24.01, ojú ìwé 15-16.
Báwo la ṣe lè lo ohun tó wà nínú Éfésù 5:7 tó sọ pé: “Ẹ má ṣe di alájọpín pẹ̀lú wọn”?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó máa jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Kì í ṣe àwọn tá à ń rí lójúkojú nìkan là ń bá ṣọ̀rẹ́, a tún máa ń bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò.—w24.03, ojú ìwé 22-23.
Àwọn ìròyìn èké wo la gbọ́dọ̀ sá fún?
A ò gbọ́dọ̀ ka ìròyìn tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ táwọn ọ̀rẹ́ wa fi ránṣẹ́ sí wa, ká má sì ka lẹ́tà orí ìkànnì táwọn tá ò mọ̀ rí fi ránṣẹ́. Bákan náà, ká máa sá fún àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń díbọ́n bíi pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—w24.04, ojú ìwé 12.
Àwọn nǹkan wo la mọ̀, kí la ò sì mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ Ọba Sólómọ́nì àtàwọn tó kú ní Sódómù àti Gòmórà títí kan àwọn tó kú nígbà Ìkún Omi?
A ò mọ̀ bóyá Jèhófà dá àwọn èèyàn náà lẹ́jọ́ ìparun ayérayé. Àmọ́, ohun tá a mọ̀ ni pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, ó sì mọ ohun tó tọ́.—w24.05, ojú ìwé 3-4.
Kí ló mú kọ́kàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ni “Àpáta” wa? (Diu. 32:4)
A lè fi Jèhófà ṣe ibi ààbò wa. Jèhófà ṣeé gbára lé, torí gbogbo ìgbà ló máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Bákan náà, Jèhófà kì í yí pa dà, Jèhófà ò ní yí ìwà ẹ̀ pa dà, kò sì ní yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà.—w24.06, ojú ìwé 26-28.
Kí ló máa jẹ́ kí ara ẹ tètè mọlé nínú ìjọ tuntun?
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́. Má fi ìjọ tuntun tó o wà báyìí wé ti tẹ́lẹ̀. Máa bá àwọn ará ìjọ ṣe nǹkan pọ̀, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun.—w24.07, ojú ìwé 26-28.
Kí la kọ́ nínú àwọn àpèjúwe mẹ́ta tó wà nínú Mátíù orí 25?
Àpèjúwe àgùntàn àti ewúrẹ́ kọ́ wa pé ká jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àpèjúwe àwọn wúńdíá olóye àtàwọn wúńdíá òmùgọ̀ jẹ́ ká rídìí tó fi ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀, ká sì wà lójúfò. Àpèjúwe tálẹ́ńtì jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára.—w24.09, ojú ìwé 20-24.
Báwo ni ibi àbáwọlé tó wà níwájú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ṣe ga tó?
Bó ṣe wà ní 2 Kíróníkà 3:4, àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan sọ pé gíga ibi àbáwọlé náà jẹ́ “ọgọ́fà (120) ìgbọ̀nwọ́” tàbí mítà mẹ́tàléláàádọ́ta (53), ìyẹn ni pé á ga tó ilé alájà mẹ́rìndínlógún (16)! Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tó ṣeé gbára lé sọ pé gíga rẹ̀ jẹ́ “ogún (20) ìgbọ̀nwọ́” tàbí mítà mẹ́sàn-án. Tá a bá wo bí fífẹ̀ ògiri àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà ṣe rí, ibi àbáwọlé náà ò lè ga tó ọgọ́fà (120) ìgbọ̀nwọ́, ìyẹn sì bá ohun tá a sọ kẹ́yìn mu.—w24.10, ojú ìwé 31.
Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó sọ pé “kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ”? (1 Tím. 3:12)
Ohun tó ń sọ ni pé obìnrin kan ṣoṣo ló máa fẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ ṣèṣekúṣe. Bákan náà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ìyàwó ẹ̀, kò sì gbọ́dọ̀ bá obìnrin míì tage.—w24.11, ojú ìwé 19.
Kí ló mú ká gbà pé ohun tó wà nínú Jòhánù 6:53 kì í ṣe bí Jésù ṣe fẹ́ ká máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
Jòhánù 6:53 sọ pé ká jẹ ẹran ara Jésù, ká sì mu ẹ̀jẹ̀ ẹ̀. Ọdún 32 S.K. ni Jésù sọ̀rọ̀ yìí ní Gálílì fáwọn Júù tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀, àmọ́ tí wọn ò tíì nígbàgbọ́ nínú ẹ̀. Àmọ́, ọdún kan lẹ́yìn náà ni Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn tí wọ́n sì jọ máa ṣàkóso ló ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn.—w24.12, ojú ìwé 10-11.