Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn Mú Kí Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀ ní Ireland

Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn Mú Kí Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀ ní Ireland

NÍ May 1910, Arákùnrin Charles T. Russell rìnrìn-àjò ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún lọ sí orílẹ̀-èdè Ireland nínú ọkọ̀ ojú omi ńlá kan. Nígbà tí wọ́n wà lórí omi Belfast Lough láàárọ̀ ọjọ́ tí wọ́n dé Ireland, àwọn èrò inú ọkọ̀ náà rí báwọn koríko tó wà lórí àpáta ṣe lọ súà. Ẹ̀yìn náà ni Arákùnrin Russell kíyè sí àwọn ọkọ̀ ojú omi gìrìwò méjì kan tí wọ́n ṣì ń kọ́ lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ ojú omi náà ni Titanic tí ìròyìn rẹ̀ tàn káyé nígbà kan, ọkọ̀ ojú omi kejì sì ni wọ́n pè ní Olympic. * Bí wọ́n ṣe sún mọ́ iwájú, wọ́n tún rí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n dúró sí ibùdókọ̀ ojú omi kí wọ́n lè kí Arákùnrin Russell káàbọ̀.

Ní nǹkan bí ogún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Arákùnrin Russell ronú bó ṣe lè wàásù yíká ayé, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn-àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì láti Amẹ́ríkà. Orílẹ̀-èdè Ireland ló kọ́kọ́ lọ ní July 1891. Látinú ọkọ̀ ojú omi City of Chicago, ó kíyè sí bójú ọjọ́ ṣe rẹwà lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n sún mọ́ ìlú Queenstown, ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kó rántí ìtàn táwọn òbí rẹ̀ sọ fún un nípa ìlú náà, torí pé ibẹ̀ làwọn òbí rẹ̀ ti wá. Bí Arákùnrin Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn-àjò ṣe ń la àwọn ìlú àtàwọn ìgbèríko tó rẹwà yẹn já, wọ́n rí i pé ṣe ló dà bíi pápá “tó ti tó kórè.”

Ẹ̀ẹ̀meje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Arákùnrin Russell lọ sórílẹ̀-èdè Ireland. Nígbà àkọ́kọ́ tó wàásù níbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbádùn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ló sì mú kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tẹ́tí sí i láwọn ìgbà tó pa dà lọ, ìgbà míì tiẹ̀ wà tí wọ́n tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Lẹ́ẹ̀kejì tó lọ, ìyẹn ní May 1903, wọ́n ní káwọn èèyàn wá gbọ́ àsọyé nílùú Belfast àti Dublin. Kódà, àwọn ìwé ìròyìn polongo ìkésíni yẹn fáyé gbọ́. Russell rántí pé àwọn èèyàn náà fara balẹ̀ gbọ́ àsọyé tóun sọ nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù àti bí Ọlọ́run ṣe máa bù kún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Àkòrí àsọyé náà ni “The Oath-Bound Promise.”

Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Arákùnrin Russell lórílẹ̀-èdè Ireland, ibẹ̀ wà lára àwọn ibi tó dé nígbà tó lọ wàásù láwọn ilẹ̀ Yúróòpù ní ẹ̀ẹ̀kẹta. Ní April 1908, ó dé sílùú Belfast, bó sì ṣe ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi làwọn arákùnrin márùn-ún kan wá kí i káàbọ̀. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, ó sọ àsọyé nípa bí Jèhófà ṣe máa pa ayé èṣù yìí run. Àkòrí àsọyé náà ni “The Overthrow of Satan’s Empire,” nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] èèyàn ló sì pésẹ̀ síbẹ̀. Nígbà tí ẹnì kan dìde láàárín èrò láti ṣàtakò, kíá ni wọ́n fi Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, tó sì panu mọ́. Nílùú Dublin, ọ̀gbẹ́ni O’Connor tó jẹ́ akọ̀wé àjọ YMCA tiẹ̀ gbójúgbóyà ní tiẹ̀. Ṣe lòun ń wá bó ṣe máa yí ọkàn àwọn tó lé lẹ́gbẹ̀rún kan pa dà kí wọ́n má bàa gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Ẹ jẹ́ ká ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ọkùnrin kan tó fẹ́ mọ òtítọ́ rí ìkésíni tí wọ́n fi pe àwọn èèyàn wá síbi àsọyé fún gbogbo èèyàn nínú ìwé ìròyìn The Irish Times, ó sì lọ síbẹ̀. Nígbà tó débẹ̀, tipátipá ló fi ríbi jókòó sí torí àwọn èèyàn ti kúnnú gbọ̀ngàn náà, ó sì fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀. Ọkùnrin kan tó nírùgbọ̀n funfun, tó wọ kóòtù dúdú ló sọ àsọyé lọ́jọ́ náà. Bí alásọyé náà ṣe ń rìn lọ sápá ọ̀tún ló ń rìn lọ sápá òsì lórí pèpéle, bẹ́ẹ̀ ló ń fẹ̀sọ̀ ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì. Gbogbo àlàyé rẹ̀ ló sì ń wọ ọkùnrin yìí lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn, gbogbo àwọn tó wà nínú gbọ̀ngàn yẹn ló ń gbóhùn alásọyé náà ketekete, odindi wákàtí kan àtààbọ̀ ló sì fi sọ̀rọ̀. Nígbà tí wọ́n dé apá ìbéèrè àti ìdáhùn, ọ̀gbẹ́ni O’Connor àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá ta ko alásọyé náà, àmọ́ alásọyé yẹn fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè wọn. Inú àwọn tó wà níbẹ̀ dùn gan-an, ṣe ni wọ́n pàtẹ́wọ́. Nígbà tí ariwo yẹn rọlẹ̀ tán, ọkùnrin tó fẹ́ mọ òtítọ́ yẹn lọ bá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Àwọn tọ́rọ̀ ṣojú wọn sọ pé ọ̀pọ̀ ló tipa báyìí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Nígbà tí Russell ń lọ sílùú Belfast nígbà kẹrin, ó wọ ọkọ̀ ojú omi Mauretania láti ìlú New York ní May 1909, ó sì mú Arákùnrin Huntsinger tó jẹ́ ayárakọ̀wé dání. Ìdí ni pé ó fẹ́ kó máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó máa jáde nínú Ilé Ìṣọ́ bóun ṣe ń sọ ọ́. Nígbà tí wọ́n dé Belfast, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àtààbọ̀ [450] ló wá gbọ́ àsọyé Arákùnrin Russell, àwọn bí ọgọ́rùn-ún [100] nínú wọn ló sì dúró torí pé wọn ò ríbi jókòó.

Arákùnrin C. T. Russell nínú ọkọ̀ ojú omi Lusitania

Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà karùn-ún tí wọ́n lọ síbẹ̀ náà nìyẹn. Lẹ́yìn àsọyé fún gbogbo èèyàn, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tí ọ̀gbẹ́ni O’Connor mú wá bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bo Russell, Russell sì fi Bíbélì dá a lóhùn, inú àwọn èèyàn dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, Russell àtàwọn yòókù wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sílùú Liverpool, lẹ́yìn ìyẹn wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi Lusitania lọ sílùú New York. *

Àsọyé fún gbogbo èèyàn tí wọ́n gbé sínú ìwé ìròyìn The Irish Times ní May 20, 1910

Nígbà tí Arákùnrin Russell lọ sórílẹ̀-èdè Ireland nígbà kẹfà àti keje lọ́dún 1911, ó tún sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ní April ọdún yẹn, àwọn ogún Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Belfast ṣètò bí àwọn ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn ṣe máa gbọ́ àsọyé “Hereafter.” Ọ̀gbẹ́ni O’Connor tún wá síbẹ̀ pẹ̀lú oníwàásù kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè, àmọ́ gbogbo ẹ̀ ni alásọyé dáhùn látinú Bíbélì, inú àwọn èèyàn dùn, ṣe ni wọ́n ń pàtẹ́wọ́ láìdáwọ́ dúró. Ní October àti November ọdún yẹn kan náà, Arákùnrin Russell tún lọ sáwọn ìlú míì lórílẹ̀-èdè yẹn, àwọn tó wá síbi àsọyé rẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Bí O’Connor àtàwọn ọgọ́rùn-ún míì ṣe tún gbìyànjú láti da ibẹ̀ rú, ṣe làwọn tó wà níbẹ̀ ń pàtẹ́wọ́ tí wọ́n sì ń gbè sẹ́yìn alásọyé náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Russell ló sábà máa ń sọ àsọyé nígbà yẹn, ó gbà pé “kò sẹ́ni tó lè sọ pé tí kò bá sí òun, iṣẹ́ náà kò ní di ṣíṣe” torí pé “iṣẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ èèyàn kankan, iṣẹ́ Ọlọ́run ni.” Bíi ti Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn tá à ń gbádùn lónìí, àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn tí wọ́n máa ń polongo nígbà yẹn nínú ìwé ìròyìn àti rédíò mú kí wọ́n lè ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì. Kí nìyẹn yọrí sí? Àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn ti mú kí ìhìn rere tàn kálẹ̀, ọ̀pọ̀ ìjọ ni wọ́n sì dá sílẹ̀ jákèjádò Ireland.​—Látinú àpamọ́ wa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

^ ìpínrọ̀ 3 Ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn ni ọkọ̀ Titanic rì.

^ ìpínrọ̀ 9 May 1915 ni wọ́n ju bọ́ǹbù lu ọkọ̀ ojú omi Lusitania ní ìhà gúúsù etíkun ilẹ̀ Ireland.