Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Onígbọràn Kó O sì Nígbàgbọ́ Bíi Ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù

Jẹ́ Onígbọràn Kó O sì Nígbàgbọ́ Bíi Ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù

“Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù, àwọn alára nítorí òdodo wọn yóò dá ọkàn wọn nídè.”​ÌSÍK. 14:14.

ORIN: 89, 119

1, 2. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? (b) Ibo ni Ìsíkíẹ́lì wà nígbà tó kọ ìwé Ìsíkíẹ́lì 14:​14, kí ló sì gbé e dẹ́bẹ̀?

ÀWỌN ìṣòro wo lò ń kojú? Ṣé àìlera ni, àìlówó lọ́wọ́ tàbí inúnibíni? Nígbà míì, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Aláìpé ni wọ́n, irú àwọn ìṣòro tá à ń kojú làwọn náà kojú, kódà wọ́n kojú àwọn ìṣòro tó lè gbẹ̀mí wọn. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà ò yingin, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.​—Ka Ìsíkíẹ́lì 14:​12-14.

2 Ìlú Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì ti kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà lọ́dún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. * (Ìsík. 1:1; 8:1) Ìyẹn ọdún díẹ̀ ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù tó wáyé lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn díẹ̀ ló jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù, àwọn olóòótọ́ yìí nìkan ló sì là á já. (Ìsík. 9:​1-5) Lára ìwọ̀nba àwọn olóòótọ́ yìí ni Jeremáyà, Bárúkù, Ebedi-mélékì àtàwọn ọmọ Rékábù.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Bíi ti ìgbà yẹn, àwọn tí Jèhófà bá kà sí olódodo bíi Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù nìkan ló máa la ayé búburú yìí já. (Ìṣí. 7:​9, 14) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jèhófà fi ka àwọn ọkùnrin yìí sí adúróṣinṣin. Bá a ṣe ń jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, a máa sọ (1) àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú àti (2) bá a ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.

NÓÀ JẸ́ ONÍGBỌRÀN ÀTI OLÓÒÓTỌ́ FÚN ỌGỌ́RÙN-ÚN MẸ́SÀN-ÁN ỌDÚN

4, 5. Àwọn ìṣòro wo ni Nóà kojú, kí ló sì jọni lójú nípa bó ṣe fara dà á?

4 Àwọn ìṣòro tí Nóà kojú. Nígbà ayé Énọ́kù baba ńlá Nóà, ìwà àwọn èèyàn ti burú kọjá àfẹnusọ. Kódà, wọ́n ń sọ àwọn “ohun amúnigbọ̀nrìrì” lòdì sí Jèhófà. (Júúdà 14, 15) Ojoojúmọ́ ni ìwà ipá wọn ń peléke sí i. Kódà nígbà tó máa fi di ìgbà ayé Nóà, ‘ilẹ̀ ayé ti kún fún ìwà ipá.’ Àwọn áńgẹ́lì búburú kan para dà di èèyàn, wọ́n fẹ́ ìyàwó, wọ́n sì bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó jẹ́ oníwà ipá. (Jẹ́n. 6:​2-4, 11, 12) Àmọ́ Nóà yàtọ̀ sí wọn ní tiẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà. . . . Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.”​—Jẹ́n. 6:​8, 9.

5 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Kì í wulẹ̀ ṣe àádọ́rin [70] ọdún tàbí ọgọ́rin [80] ọdún tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò láyé lónìí ni Nóà fi bá Ọlọ́run rìn nínú ayé burúkú yẹn, odindi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọdún ló fi bá Ọlọ́run rìn kí Ìkún Omi náà tó dé! (Jẹ́n. 7:11) Bákan náà, Nóà ò nírú àǹfààní táwa ní lónìí, a láwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tá a sì jọ ń gbé ara wa ró, àmọ́ Nóà ò ní irú ẹ̀ kódà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ kò sin Jèhófà. *

6. Báwo ni Nóà ṣe fi hàn pé òun nígboyà?

6 Kì í ṣe bí Nóà ṣe máa rí ojú rere Ọlọ́run nìkan ló jẹ ẹ́ lógún. Bíbélì tún sọ pé Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo,” torí ó fìgboyà sọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn. (2 Pét. 2:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi.” (Héb. 11:7) Ó ṣeé ṣe kí Nóà kojú àtakò kí wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́, kódà wọ́n tiẹ̀ lè halẹ̀ mọ́ ọn láwọn ìgbà míì. Àmọ́ kò ‘wárìrì nítorí àwọn èèyàn.’ (Òwe 29:25) Dípò kó máa bẹ̀rù, ṣe ló ń fìgboyà ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.

7. Àwọn ìṣòro wo ni Nóà kojú nígbà tó ń kan ọkọ̀ áàkì?

7 Lẹ́yìn tí Nóà ti bá Ọlọ́run rìn fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ọdún lọ, Ọlọ́run sọ fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì láti fi gba àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko là. (Jẹ́n. 5:32; 6:14) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ tó ń kani láyà gan-an ni, ṣe ló dà bíi pé kò ṣeé ṣe láé. Nóà sì mọ̀ pé iṣẹ́ yìí máa jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa fi òun ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀, ó lo ìgbàgbọ́, ó sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”​—Jẹ́n. 6:22.

8. Báwo ni Nóà ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè ohun tóun nílò?

8 Ìṣòro míì tí Nóà kojú ni bó ṣe máa pèsè jíjẹ àti mímu fún ìdílé rẹ̀. Kí Ìkún Omi tó dé, iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni Nóà àtàwọn èèyàn ìgbà yẹn máa ń ṣe kí wọ́n tó gbin oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ. (Jẹ́n. 5:​28, 29) Síbẹ̀, kì í ṣèyẹn ni Nóà gbájú mọ́, bó ṣe máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí i. Kódà láàárín ogójì [40] tàbí àádọ́ta [50] ọdún tó ṣeé ṣe kó fi kan ọkọ̀ áàkì yẹn, kò jẹ́ kí nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Bó sì ṣe jẹ́ olóòótọ́ nìyẹn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ [350] ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi. (Jẹ́n. 9:28) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa ló fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká jẹ́ onígbọràn ká sì nígbàgbọ́!

9, 10. (a) Báwo la ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀?

9 Bá a ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà. Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fi ara wa sábẹ́ àkóso Ọlọ́run, ká má ṣe jẹ́ apá kan ayé, ká sì fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. (Mát. 6:33; Jòh. 15:19) Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé, ṣé ohun táyé ń fẹ́ ni mò ń ṣe àbí ohun tí inú Jèhófà dùn sí? Ìyẹn sì ṣe pàtàkì torí ohun táyé ń gbé lárugẹ yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Jèhófà fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ kan ojú burúkú làwọn kan fi ń wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé à ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀. (Ka Málákì 3:​17, 18.) Àmọ́ bíi ti Nóà, Jèhófà là ń bẹ̀rù kì í ṣe àwọn èèyàn torí a mọ̀ pé òun nìkan ló lè fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—Lúùkù 12:​4, 5.

10 Àmọ́ ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá ṣì máa ‘bá Ọlọ́run rìn’ táwọn míì bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n sì ń ṣàríwísí ẹ? Ṣé wàá máa sin Jèhófà nìṣó tó bá ṣòro fún ẹ láti gbọ́ bùkátà, ṣé wàá gbà pé Olùpèsè ni Jèhófà? Tó o bá nígbàgbọ́, tó o sì jẹ́ onígbọràn bíi ti Nóà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bójú tó ẹ.​—Fílí. 4:​6, 7.

DÁNÍẸ́LÌ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI ONÍGBỌRÀN LÁÀÁRÍN ÀWỌN ÈÈYÀN BURÚKÚ

11. Àwọn ìṣòro ńlá wo ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kojú nílùú Bábílónì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Àwọn ìṣòro tí Dáníẹ́lì kojú. Ẹrú ni Dáníẹ́lì nílùú Bábílónì, àwọn abọ̀rìṣà àtàwọn abẹ́mìílò ló sì kún ibẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn Bábílónì máa ń fojú burúkú wo àwọn Júù, wọ́n máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń tẹ́ńbẹ́lú Jèhófà Ọlọ́run wọn. (Sm. 137:​1, 3) Ẹ wo bíyẹn ṣe máa ká Dáníẹ́lì àtàwọn Júù olóòótọ́ bíi tiẹ̀ lára! Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà tún kojú ìṣòro míì bí wọ́n ṣe ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di òṣìṣẹ́ láàfin Ọba. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣojú ọba ló ń pinnu oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tọ́rọ̀ oúnjẹ di wàhálà torí Dáníẹ́lì ti pinnu pé òun ò ní “sọ ara òun di eléèérí nípasẹ̀ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.”​—Dán. 1:​5-8, 14-17.

12. (a) Àwọn ànímọ́ rere wo ni Dáníẹ́lì ní? (b) Irú ẹni wo ni Jèhófà ka Dáníẹ́lì sí?

12 Ohun míì wà tó lè dán ìgbàgbọ́ Dáníẹ́lì wò. Dáníẹ́lì ní ọgbọ́n àti òye tó ṣàrà ọ̀tọ̀, èyí sì jẹ́ kó ní àwọn ojúṣe pàtàkì kó sì dẹni ńlá ní Bábílónì. (Dán. 1:​19, 20) Àmọ́ dípò kó máa gbéra ga tàbí kó máa pàṣẹ wàá, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, Jèhófà ló sì ń gbé gbogbo ògo fún. (Dán. 2:30) Kódà, ìgbà tí Dáníẹ́lì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ ni Jèhófà ti kà á mọ́ Nóà àti Jóòbù tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́. Ṣó tọ̀nà bí Ọlọ́run ṣe ka Dáníẹ́lì sí olódodo? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tọ̀nà! Ìdí sì ni pé Dáníẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn títí tó fi kú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó wà lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé: “Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.”​—Dán. 10:11.

13. Kí ló mú kí Dáníẹ́lì lè ran àwọn Júù bíi tiẹ̀ lọ́wọ́?

13 Torí pé Jèhófà bù kún Dáníẹ́lì, ó wà lára àwọn aláṣẹ onípò gíga jù lọ lábẹ́ ìṣàkóso Bábílónì àti Mídíà òun Páṣíà. (Dán. 1:21; 6:​1, 2) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Jèhófà jẹ́ kí Dáníẹ́lì wà nípò àṣẹ kó lè máa ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ bí Jósẹ́fù ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ nílẹ̀ Íjíbítì àti bí Ẹ́sítérì àti Módékáì náà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ nílẹ̀ Páṣíà. * (Dán. 2:48) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Ìsíkíẹ́lì àtàwọn Júù míì tó wà nígbèkùn bí wọ́n ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń lo Dáníẹ́lì àtàwọn míì láti ràn wọ́n lọ́wọ́!

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i (Wo ìpínrọ̀ 14 àti 15)

14, 15. (a) Báwo lọ̀rọ̀ wa ṣe jọ ti Dáníẹ́lì? (b) Ẹ̀kọ́ wo lẹ̀yin òbí lè rí kọ́ lára àwọn òbí Dáníẹ́lì?

14 Bá a ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Dáníẹ́lì. Inú ayé tó ti bàjẹ́ bàlùmọ̀ là ń gbé. Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé ti ba ayé yìí jẹ́ débi pé àwọn èèyàn ò ka ìṣekúṣe sí nǹkan bàbàrà mọ́, wọ́n sì ti mú káwọn èèyàn di ọ̀tá Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì sọ pé Bábílónì Ńlá ti di “ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Ìṣí. 18:2) Torí pé a yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé, ṣe ni wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. (Máàkù 13:13) Torí náà bíi ti Dáníẹ́lì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onígbọràn, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwa náà máa jẹ́ ẹni fífani lọ́kàn mọ́ra lójú rẹ̀.​—Hág. 2:7.

15 Ẹ̀yin òbí lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òbí Dáníẹ́lì. Lọ́nà wo? Láìka bí ìwà ìkà ṣe kún ilẹ̀ Júdà nígbà tí Dáníẹ́lì wà ní kékeré, Dáníẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kò kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ o, àwọn òbí rẹ̀ ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 22:6) Ìtumọ̀ orúkọ Dáníẹ́lì ni “Ọlọ́run Ni Onídàájọ́ Mi,” èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé olùjọ́sìn Ọlọ́run làwọn òbí rẹ̀. Torí náà ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ọmọ yín sú yín láé, ṣe ni kẹ́ ẹ máa fi sùúrù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Éfé. 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ máa gbàdúrà pẹ̀lú wọn, kẹ́ ẹ sì máa gbàdúrà fún wọn. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti gbin òtítọ́ Bíbélì sọ́kàn wọn, Jèhófà máa bù kún ìsapá yín.​—Sm. 37:5.

JÓÒBÙ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI ONÍGBỌRÀN NÍGBÀ DÍDÙN ÀTI NÍGBÀ KÍKAN

16, 17. Àwọn nǹkan wo ló dán ìgbàgbọ́ Jóòbù wò nígbà dídùn àti kíkan?

16 Àwọn ìṣòro tí Jóòbù kojú. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la rí kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé Jóòbù. Kí Jóòbù tó níṣòro, Bíbélì sọ pé òun ló lọ́lá jù nínú gbogbo àwọn èèyàn Ìlà-Oòrùn. (Jóòbù 1:3) Ó lówó, ó gbajúmọ̀, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an. (Jóòbù 29:​7-16) Síbẹ̀, Jóòbù kò tìtorí ìyẹn di agbéraga tàbí kó má rí ti Ọlọ́run rò. Kódà, Jèhófà pè é ní “ìránṣẹ́ mi,” ó sì tún fi kún un pé ó jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.”​—Jóòbù 1:8.

17 Láàárín àkókò díẹ̀, ìgbésí ayé Jóòbù yí pa dà pátápátá, ó di tálákà paraku, nǹkan sì tojú sú u. A mọ̀ pé Sátánì tó jẹ́ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ ló fẹ̀sùn kan Jóòbù pé torí àwọn nǹkan tó ń rí gbà ló ṣe ń sin Ọlọ́run. (Ka Jóòbù 1:​9, 10.) Jèhófà ò kàn gbé ẹ̀sùn yẹn dà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pé irọ́ ni Èṣù ń pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló jẹ́ kí Jóòbù fi hàn pé adúróṣinṣin lòun àti pé tọkàntọkàn lòun fi ń sin Ọlọ́run, kì í ṣe torí àwọn nǹkan tóun ń rí gbà.

18. (a) Kí ló wú ẹ lórí nípa bí Jóòbù ṣe jẹ́ adúróṣinṣin? (b) Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà látinú bó ṣe bá Jóòbù lò?

18 Sátánì mú kí ìyà jẹ Jóòbù gan-an débi pé Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Ọlọ́run ló ń fa ìṣòro òun. (Jóòbù 1:​13-21) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn olùtùnú èké mẹ́ta wá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Jóòbù, wọ́n sọ pé ohun tó tọ́ sí Jóòbù ni Ọlọ́run jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí i. (Jóòbù 2:11; 22:​1, 5-10) Síbẹ̀, Jóòbù jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lóòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Jóòbù sọ̀rọ̀ tí kò yẹ, àmọ́ Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. (Jóòbù 6:​1-3) Jèhófà rí i pé ẹ̀dùn ọkàn bá Jóòbù gan-an torí pé Sátánì parọ́ mọ́ ọn, ó sì tún fìyà jẹ ẹ́ bí ẹni máa kú. Láìka gbogbo ìyẹn sí, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀. Nígbà tí Jóòbù bọ́ nínú ìṣòro, Jèhófà fún un ní ìlọ́po méjì gbogbo ohun tó ní tẹ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ kó gbé fún ogóje [140] ọdún lẹ́yìn náà. (Ják. 5:11) Jóòbù ń bá a lọ láti fi ọkàn pípé sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀? Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jóòbù kú ni Ìsíkíẹ́lì kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà.

19, 20. (a) Báwo la ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù? (b) Báwo la ṣe lè fàánú hàn sáwọn ará wa bíi ti Jèhófà?

19 Bá a ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù. Láìka àwọn ìṣòro tá a lè máa kojú sí, ẹ jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lẹni tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì máa ṣègbọràn tọkàntọkàn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọ̀pọ̀ ìdí ló fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a ti wá mọ àwọn nǹkan tí Jóòbù ò mọ̀. A ti mọ àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò. (2 Kọ́r. 2:11) A ti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Jóòbù àtàwọn ìwé míì. Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣàkóso ayé yìí lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi. (Dán. 7:​13, 14) Ìjọba yìí ló sì máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé.

20 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa fàánú hàn sáwọn ará wa tó ń fara da ìṣòro. Bíi ti Jóòbù, àwọn míì nínú wọn lè sọ̀rọ̀ tí kò tọ́ nígbà míì. (Oníw. 7:7) Dípò ká máa dá wọn lẹ́jọ́, ẹ jẹ́ ká máa fàánú hàn sí wọn ká sì máa fòye bá wọn lò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú.​—Sm. 103:8.

JÈHÓFÀ MÁA “SỌ YÍN DI ALÁGBÁRA”

21. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù ṣe bá ohun tó wà nínú 1 Pétérù 5:10 mu?

21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù gbáyé, táwọn ìṣòro wọn sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló fara da àwọn ìṣòro náà. Ìtàn ìgbésí ayé wọn jẹ́ ká rántí ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo . . . yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”​—1 Pét. 5:10.

22. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

22 Ọ̀rọ̀ Pétérù jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa sọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ di alágbára, á sì jẹ́ kí wọ́n dúró gbọn-in. Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kan àwa náà lónìí. Gbogbo wa la fẹ́ kí Jèhófà sọ wá di alágbára kó sì fẹsẹ̀ wa múlẹ̀ gbọin-in nínú ìjọsìn rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká nígbàgbọ́, ká sì máa ṣègbọràn bíi ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù! Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí i pé ohun tó jẹ́ kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ni pé wọ́n mọ Jèhófà dáadáa wọ́n sì “lóye ohun gbogbo” tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Òwe 28:5) Ọ̀rọ̀ tiwa náà lè dà bíi tiwọn.

^ ìpínrọ̀ 2 Ọdún 617 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n mú Ìsíkíẹ́lì lọ sí ìgbèkùn. Àkọsílẹ̀ ìwé Ìsíkíẹ́lì 8:1–19:14 mẹ́nu kan “ọdún kẹfà” ìgbèkùn náà, ìyẹn ọdún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

^ ìpínrọ̀ 5 Olùjọ́sìn Jèhófà ni Lámékì bàbá Nóà, àmọ́ ọdún márùn-ún ṣáájú Ìkún Omi ló ti kú. Torí náà, ká tiẹ̀ ní màmá Nóà, àwọn ẹ̀gbọ́n Nóà àtàwọn àbúrò rẹ̀ bá ṣì wà láyé nígbà yẹn, ó dájú pé wọn ò la Ìkún Omi yẹn já.

^ ìpínrọ̀ 13 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jèhófà náà ló jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà nípò àṣẹ.​—Dán. 2:49.