ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8
Bá A Ṣe Lè Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ń Fara Da Ìṣòro
“Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.”—JÉM. 1:2.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. Kí ni Mátíù 5:11 sọ pé ká máa ṣe tá a bá ń kojú àdánwò?
JÉSÙ ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n máa láyọ̀, àmọ́ ó tún kìlọ̀ fún wọn pé wọ́n máa kojú àdánwò. (Mát. 10:22, 23; Lúùkù 6:20-23) Inú wa máa ń dùn gan-an pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, àmọ́ báwo ló ṣe máa rí lára wa tí àwọn tó wà nínú ìdílé wa bá ń ta kò wá, tí ìjọba ń ṣe inúnibíni sí wa, tí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọléèwé wa sì ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣe ohun tí kò tọ́? Ká sòótọ́, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kẹ́rù bà wá.
2 Ọ̀pọ̀ ò gbà pé èèyàn lè láyọ̀ tó bá ń kojú inúnibíni. Àmọ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká ṣe gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jémíìsì sọ pé dípò ká máa kọ́kàn sókè nítorí àwọn ìṣòro wa, ṣe ló yẹ ká máa láyọ̀. (Jém. 1:2, 12) Bákan náà, Jésù sọ pé ká máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. (Ka Mátíù 5:11.) Kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú àdánwò? Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ látinú lẹ́tà tí Jémíìsì kọ sáwọn Kristẹni ìgbàanì. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn Kristẹni yẹn kojú.
ÌṢÒRO WO LÀWỌN KRISTẸNI ÌGBÀANÌ KOJÚ?
3. Kí ló ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí Jémíìsì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
3 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jémíìsì àbúrò Jésù di ọmọ ẹ̀yìn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:14; 5:17, 18) Lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì “tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà,” kódà àwọn kan sá lọ sí Sápírọ́sì àti Áńtíókù. (Ìṣe 7:58–8:1; 11:19) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọmọlẹ́yìn yẹn kojú, síbẹ̀ wọ́n ń fìtara wàásù ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ, wọ́n sì ń dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń ṣàkóso. (1 Pét. 1:1) Àmọ́ kékeré làwọn ìṣòro yẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìṣòro tí wọ́n ṣì máa kojú.
4. Àwọn ìṣòro míì wo làwọn Kristẹni yẹn kojú?
4 Onírúurú ìṣòro làwọn Kristẹni yẹn kojú. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 50 S.K., Olú Ọba Kíláúdíù pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Júù fi ìlú Róòmù sílẹ̀. Torí náà, ó di dandan pé kí àwọn Júù tó ti di Kristẹni fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì kó lọ síbòmíì. (Ìṣe 18:1-3) Nígbà tó di nǹkan bíi 61 S.K., àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn èèyàn pẹ̀gàn àwọn Kristẹni ní gbangba, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn lẹ́rù. (Héb. 10:32-34) Yàtọ̀ síyẹn, bíi tàwọn èèyàn yòókù, àwọn Kristẹni náà fara da ipò òṣì àti àìsàn.—Róòmù 15:26; Fílí. 2:25-27.
5. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
5 Kí Jémíìsì tó kọ lẹ́tà rẹ̀ ṣáájú ọdún 62 S.K., ó mọ ìṣòro táwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń kojú. Jèhófà mí sí Jémíìsì láti kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni yẹn, ó sì fún wọn ní ìmọ̀ràn táá jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń kojú ìṣòro. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò lẹ́tà Jémíìsì, ká sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Irú ayọ̀ wo ni Jémíìsì ń sọ? Kí ló lè mú kí Kristẹni kan má láyọ̀ mọ́? Báwo ni ọgbọ́n, ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ṣe lè mú ká máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú onírúurú ìṣòro?
KÍ LÓ Ń MÚ KÍ KRISTẸNI KAN LÁYỌ̀?
6. Kí ni Lúùkù 6:22, 23 sọ pé á jẹ́ kí Kristẹni kan máa láyọ̀ tó bá tiẹ̀ ń kojú ìṣòro?
6 Àwọn kan ronú pé ó dìgbà tí ìlera àwọn bá jí pépé, táwọn lówó rẹpẹtẹ, tí Gál. 5:22) Ohun tó mú káwọn Kristẹni máa láyọ̀ ni pé wọ́n ń múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Ka Lúùkù 6:22, 23; Kól. 1:10, 11) A lè fi ayọ̀ wé iná tó ń jó nínú láńtánì kan. Ẹyin láńtánì náà ni ò ní jẹ́ kí atẹ́gùn tàbí òjò pa iná tó wà nínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro nígbèésí ayé wa. Ayọ̀ wa ò ní pẹ̀dín tá a bá ń ṣàìsàn tàbí tá ò lówó lọ́wọ́. Kódà, kò ní dín kù táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí ìdílé wa tàbí àwọn míì ń ta kò wá. Dípò káyọ̀ wa máa dín kù, ṣe lá máa pọ̀ sí i. Àwọn àtakò tá à ń kojú torí ohun tá a gbà gbọ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wá. (Mát. 10:22; 24:9; Jòh. 15:20) Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi sọ pé: “Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.”—Jém. 1:2.
ilé àwọn sì dùn káwọn tó lè láyọ̀. Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ ló ń mú kéèyàn ní irú ayọ̀ tí Jémíìsì ń sọ yìí, èèyàn sì lè láyọ̀ yìí láìka ìṣòro tó ní sí. (7-8. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ wa fi máa ń lágbára sí i tá a bá ń kojú àdánwò?
7 Jémíìsì sọ ìdí míì táwa Kristẹni fi máa ń fara da àdánwò. Ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.” (Jém. 1:3) A lè fi àdánwò wé iná tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi máa ń yọ́ irin. Lẹ́yìn tí wọ́n bá yọ irin náà kúrò nínú iná, tó sì tutù, á túbọ̀ lágbára. Lọ́nà kan náà, tá a bá fara da àdánwò, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo.” (Jém. 1:4) Bá a ṣe ń kíyè sí i pé ṣe làwọn àdánwò yẹn ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, àá túbọ̀ máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara dà á.
8 Nínú lẹ́tà tí Jémíìsì kọ, ó tún sọ àwọn nǹkan kan tó lè mú káyọ̀ wa pẹ̀dín. Kí làwọn nǹkan náà, báwo la sì ṣe lè borí wọn?
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÍ AYỌ̀ WA PẸ̀DÍN
9. Kí nìdí tá a fi nílò ọgbọ́n?
9 Ìṣòro: A ò mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Tá a bá ń kojú ìṣòro, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun táá múnú ẹ̀ dùn, táá ṣe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láǹfààní, táá sì mú ká jẹ́ olóòótọ́. (Jer. 10:23) A nílò ọgbọ́n ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tá a máa sọ fáwọn tó ń ta kò wá. Tá ò bá mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá wa, a sì lè má láyọ̀ mọ́.
10. Kí ni Jémíìsì 1:5 ní ká ṣe tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n?
Jémíìsì 1:5.) Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà wa? Jémíìsì sọ pé ká máa bẹ Ọlọ́run, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Jèhófà ò ní bínú tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó fún wa ní ọgbọ́n, kò sì ní pẹ̀gàn wa. Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa. (Sm. 25:12, 13) Ó mọ ohun tá à ń kojú, ó máa ń dùn ún pé à ń jìyà, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lọ́gbọ́n?
10 Ohun tá a lè ṣe sí ìṣòro náà: Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. Tá a bá fẹ́ máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da ìṣòro, ó yẹ ká kọ́kọ́ bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. (Ka11. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ọgbọ́n?
11 Jèhófà ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún wa ní ọgbọ́n. (Òwe 2:6) Ká tó lè ní ọgbọ́n yìí, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run déédéé. Àmọ́, kì í ṣe pé ká kàn rọ́ ìmọ̀ sórí o. Kí ọgbọ́n Ọlọ́run tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésí ayé wa. Jémíìsì sọ pé: “Ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán.” (Jém. 1:22) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò, àá lẹ́mìí àlàáfíà, àá máa fòye báni lò, àá sì máa ṣàánú. (Jém. 3:17) Èyí á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, a ò sì ní pàdánù ayọ̀ wa.
12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa?
12 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bíi dígí, ó ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a kù sí àtàwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. (Jém. 1:23-25) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè wá rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ máa mú sùúrù, ká má sì tètè máa bínú. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa mú sùúrù tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí àwọn èèyàn bá ṣe ohun tó lè mú wa bínú. Tá a bá ń ṣe sùúrù, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fara da ìṣòro. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè fara balẹ̀ ronú, àá sì ṣèpinnu tó tọ́. (Jém. 3:13) Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká lóye Bíbélì dáadáa!
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn?
13 Nígbà míì, ẹ̀yìn tá a bá ṣàṣìṣe la máa ń kọ́gbọ́n. Àmọ́, kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà rí ọgbọ́n Ọlọ́run ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó ṣe ohun tó dáa àtàwọn tó ṣàṣìṣe. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi gbà wá níyànjú pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn bí Ábúráhámù, Ráhábù, Jóòbù àti Èlíjà. (Jém. 2:21-26; 5:10, 11, 17, 18) Àwọn olóòótọ́ yìí kojú àwọn àdánwò tó le, síbẹ̀ wọn ò pàdánù ayọ̀ wọn. Bí wọ́n ṣe fara dà á jẹ́ ká rí i pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà lè fara da ìṣòro, ká sì máa láyọ̀.
14-15. Kí nìdí tó fi yẹ ká wá nǹkan ṣe tá a bá ń ṣiyèméjì?
14 Ìṣòro: Iyèméjì. Nígbà míì, a lè má lóye àwọn nǹkan kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó sì lè jẹ́ pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá a fẹ́. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú ká máa ṣiyèméjì. Tá ò bá ṣe ohunkóhun láti borí iyèméjì wa, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, ká má sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà mọ́. (Jém. 1:7, 8) Èyí tó wá burú jù ni pé a lè pàdánù ìrètí ọjọ́ iwájú.
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí wa wé ìdákọ̀ró. (Héb. 6:19) Ìdákọ̀ró ni kì í jẹ́ kí ọkọ̀ rì tàbí kọ lu àpáta tí ìjì bá ń jà. Àmọ́ kí ìdákọ̀ró kan tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ṣéènì tí wọ́n fi so ó mọ́ ọkọ̀ náà kò gbọ́dọ̀ já. Tí ṣéènì náà bá dógùn-ún, ìdákọ̀ró náà ò ní wúlò mọ́. Bákan náà, tá a bá ń ṣiyèméjì, ìgbàgbọ́ wa ò ní lágbára mọ́. Tẹ́ni tó ń ṣiyèméjì bá kojú ìṣòro, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá làwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ. Téèyàn ò bá ti nígbàgbọ́ mọ́, kò lè nírètí. Jémíìsì sọ pé ẹni tó ń ṣiyèméjì “dà bí ìgbì òkun tí atẹ́gùn ń fẹ́ káàkiri.” (Jém. 1:6) Ó dájú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè láyọ̀ láé!
16. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ń ṣiyèméjì?
16 Ohun tá a lè ṣe sí ìṣòro náà: Wá nǹkan ṣe sí ohun tó ń jẹ́ kó o ṣiyèméjì kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára sí i. Tètè gbé ìgbésẹ̀. Nígbà ayé wòlíì Èlíjà, àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣiyèméjì. Èlíjà wá sọ fún wọn pé: “Ìgbà wo lẹ máa ṣiyèméjì dà? Tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e; àmọ́ tó bá jẹ́ pé Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e!” (1 Ọba 18:21) Ó yẹ káwa náà tètè wá nǹkan ṣe tá a bá ń ṣiyèméjì. Ó yẹ ká ṣèwádìí kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì àti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. (1 Tẹs. 5:21) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣiyèméjì mọ́, ìgbàgbọ́ wa á sì lágbára. Àmọ́ tá ò bá mọ nǹkan tá a máa ṣe, ẹ jẹ́ ká sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Kò yẹ ká fọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rárá tá a bá fẹ́ máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó!
17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
17 Ìṣòro: Ìrẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.” (Òwe 24:10) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “rẹ̀wẹ̀sì” lè túmọ̀ sí pé kí “ọkàn èèyàn domi.” Téèyàn bá sì rẹ̀wẹ̀sì, kò ní láyọ̀ mọ́.
18. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn fara da nǹkan?
Jém. 5:11) Ọ̀rọ̀ tí Jémíìsì lò tá a tú sí “ìfaradà” túmọ̀ sí pé kéèyàn dúró láìyẹsẹ̀. Ṣe ló dà bí ọmọ ogun kan tó fìgboyà kojú àwọn ọ̀tá, tó dúró sí ààyè ẹ̀ láìyẹsẹ̀ láìka bí ogun náà ṣe le tó.
18 Ohun tá a lè ṣe sí ìṣòro náà: Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà kó o lè fara da ìṣòro. A nílò ìgboyà ká tó lè fara da ìṣòro. (19. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?
19 Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ tó bá di pé ká nígboyà ká sì fara da ìṣòro. Àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́, ó fara dà á torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun. (2 Kọ́r. 12:8-10; Fílí. 4:13) Àwa náà lè nírú ìgboyà àti okun tó ní tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́.—Jém. 4:10.
TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ KÓ O LÈ MÁA LÁYỌ̀
20-21. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?
20 Ó yẹ kó dá wa lójú pé kì í ṣe Jèhófà ló ń fìyà jẹ wá tá a bá ń kojú ìṣòro. Jémíìsì fi dá wa lójú pé: “Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ló ń dán mi wò.’ Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jém. 1:13) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà kọ́ ló ń dán wa wò, àá túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa.—Jém. 4:8.
21 Jèhófà “kì í yí pa dà, . . . kì í sì í sún kiri.” (Jém. 1:17) Ó ran àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro, ó sì dájú pé ohun tó máa ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa náà nìyẹn. Torí náà, bẹ Jèhófà taratara pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n, ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Á gbọ́ àdúrà rẹ. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé á jẹ́ kó o láyọ̀ bó o ṣe ń fara da ìṣòro rẹ!
ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
^ ìpínrọ̀ 5 Ìwé Jémíìsì sọ onírúurú nǹkan tá a lè ṣe tá a bá ń kojú àdánwò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn tí Jémíìsì fún wa. Àwọn ìmọ̀ràn yìí máa jẹ́ ká lè máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó bá a tiẹ̀ ń fara da àdánwò.
^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Àwọn ọlọ́pàá wá mú arákùnrin kan nílé ẹ̀. Ìyàwó àti ọmọ ẹ̀ sì ń wò ó bí wọ́n ṣe ń mú un lọ. Àwọn ará ń ṣe ìjọsìn ìdílé pẹ̀lú arábìnrin náà àti ọmọ ẹ̀ nígbà tí ọkọ ẹ̀ wà lẹ́wọ̀n. Gbogbo ìgbà ni arábìnrin náà àti ọmọ ẹ̀ ń bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn lókun káwọn lè fara dà á. Jèhófà mú kí ọkàn wọn balẹ̀, kí wọ́n sì nígboyà. Ìyẹn mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára, kí wọ́n sì láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fara dà á.