Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6

ORIN 10 Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!

“Ẹ Yin Orúkọ Jèhófà”

“Ẹ Yin Orúkọ Jèhófà”

“Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà, Ẹ yin orúkọ Jèhófà.”SM. 113:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn nǹkan tó ń mú ká yin orúkọ mímọ́ Jèhófà nígbà gbogbo.

1-2. Àpèjúwe wo ló jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n bà á lórúkọ jẹ́?

 KÁ SỌ pé ọ̀rẹ́ ẹ sọ ohun tí ò dáa nípa ẹ. O mọ̀ pé irọ́ ló pa mọ́ ẹ, àmọ́ àwọn kan gbà á gbọ́. Ohun tó burú jù níbẹ̀ ni pé àwọn kan tún ń tan irọ́ náà kiri, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń gbà á gbọ́. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára ẹ? Irọ́ yẹn máa bà ẹ́ nínú jẹ́ gan-an torí o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, o ò sì fẹ́ kí orúkọ rere ẹ bà jẹ́.—Òwe 22:1.

2 Àpèjúwe yìí máa jẹ́ ká mọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí áńgẹ́lì kan bà á lórúkọ jẹ́. Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ pa irọ́ mọ́ ọn lọ́dọ̀ Éfà obìnrin àkọ́kọ́. Éfà gba irọ́ náà gbọ́. Irọ́ yẹn sì mú kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Báwa èèyàn ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀, tá a sì ń kú nìyẹn. (Jẹ́n. 3:1-6; Róòmù 5:12) Irọ́ tí Sátánì pa nínú ọgbà Édẹ́nì ló fa ikú, ogun, ìṣẹ́ àti gbogbo ìṣòro tó wà láyé báyìí. Ṣé gbogbo irọ́ tí wọ́n pa mọ́ Jèhófà àtàwọn nǹkan tí irọ́ náà fà bà á nínú jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n Jèhófà ò torí ìyẹn bínú. Kódà “Ọlọ́run aláyọ̀” ṣì ni.—1 Tím. 1:11.

3. Àǹfààní wo la ní?

3 A láǹfààní láti dá orúkọ Jèhófà láre tá a bá pa àṣẹ ẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ yin orúkọ Jèhófà.” (Sm. 113:1) Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa sọ ohun tó dáa nípa Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ mímọ́ náà. Ṣé wàá ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan pàtàkì mẹ́ta tó máa jẹ́ ká máa yin orúkọ Ọlọ́run wa tọkàntọkàn.

A MÁA MÚNÚ JÈHÓFÀ DÙN TÁ A BÁ Ń YIN ORÚKỌ RẸ̀

4. Kí nìdí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn tá a bá ń yìn ín? Sọ àpèjúwe kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 A máa múnú Baba wa ọ̀run dùn tá a bá ń yin orúkọ rẹ̀. (Sm. 119:108) Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé Ọlọ́run Olódùmarè dà bí àwa èèyàn aláìpé tá à ń fẹ́ káwọn èèyàn máa yìn wá kínú wa lè máa dùn? Rárá o. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ọmọbìnrin kékeré kan dì mọ́ bàbá ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ni bàbá tó dáa jù lọ láyé!” Bàbá ẹ̀ rẹ́rìn-ín, inú ẹ̀ sì dùn gan-an. Kí nìdí? Ṣé a lè sọ pé inú bàbá yẹn ò dùn àfi ìgbà tọ́mọ ẹ̀ yìn ín? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé bàbá dáadáa ni, inú ẹ̀ sì ń dùn torí pé ọmọ ẹ̀ moore ohun tó ti ṣe fún un. Ó mọ̀ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kọ́mọ òun máa láyọ̀ bó ṣe ń dàgbà. Lọ́nà kan náà, inú Jèhófà Bàbá wa tó dáa jù lọ máa ń dùn tá a bá ń yìn ín torí gbogbo oore tó ṣe fún wa.

Bí inú bàbá kan ṣe máa ń dùn tó bá rí i pé ọmọ òun nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì mọyì ohun tóun ṣe fún un, bẹ́ẹ̀ náà ni inú Jèhófà máa dùn tá a bá ń yin orúkọ rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Irọ́ Sátánì wo la máa já tá a bá ń yin orúkọ Ọlọ́run?

5 Tá a bá ń yin Bàbá wa ọ̀run, à ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Sátánì sọ pé kò sẹ́ni tó máa sọ nǹkan rere nípa orúkọ Ọlọ́run. Ó tún sọ pé kò sẹ́nì kankan tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé gbogbo wa la máa kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tá a bá gbà pé ìyẹn ló máa ṣe wá láǹfààní. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Àmọ́ Jóòbù olóòótọ́ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ṣé ìwọ náà máa jẹ́ olóòótọ́? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá ń sọ nǹkan rere nípa orúkọ rẹ̀, tá a sì ń múnú ẹ̀ dùn bá a ṣe ń sìn ín tọkàntọkàn. (Òwe 27:11) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.

6. Báwo la ṣe lè fara wé Ọba Dáfídì àtàwọn ọmọ Léfì? (Nehemáyà 9:5)

6 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń yin orúkọ ẹ̀ tọkàntọkàn. Ọba Dáfídì sọ pé: “Jẹ́ kí n yin Jèhófà; kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.” (Sm. 103:1) Dáfídì mọ̀ pé tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, Jèhófà náà là ń yìn yẹn. Tá a bá gbọ́ orúkọ Jèhófà, ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ìwà rere tó ní àti àwọn ohun rere tó máa ń ṣe. Ó wu Dáfídì pé kó ya orúkọ Bàbá ẹ̀ sí mímọ́, kó sì máa yìn ín. Ó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn pẹ̀lú “gbogbo ohun tó wà nínú” ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ Léfì ló máa ń ṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ yin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé kò sí báwọn ṣe lè yin Jèhófà tó bó ṣe yẹ káwọn yìn ín. (Ka Nehemáyà 9:5.) Ó dájú pé bí wọ́n ṣe fìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe é tọkàntọkàn máa múnú ẹ̀ dùn gan an.

7. Báwo la ṣe lè máa yin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ohun tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́?

7 Lónìí, a lè múnú Jèhófà dùn tá a bá ń dúpẹ́ oore tó ṣe wá, tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a bá ń wàásù ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan an. (Jém. 4:8) Inú wa máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, onídàájọ́ òdodo ni, ó gbọ́n, ó lágbára, ó sì tún láwọn ànímọ́ míì tó jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn. A tún máa ń yin Jèhófà, a sì máa ń múnú ẹ̀ dùn bá a ṣe ń sapá láti fara wé e. (Éfé. 5:1) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn máa kíyè sí pé ìwà wa yàtọ̀ sí tàwọn tí ò mọ Jèhófà nínú ayé burúkú yìí. (Mát. 5:14-16) Bá a ṣe ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, á ṣeé ṣe fún wa láti ṣàlàyé ìdí tí ìwà wa fi yàtọ̀, ìyẹn á sì mú káwọn olóòótọ́ ọkàn wá sin Jèhófà. Tá a bá ń yin Jèhófà lọ́nà yìí, inú ẹ̀ á máa dùn sí wa.—1 Tím. 2:3, 4.

INÚ JÉSÙ MÁA DÙN TÁ A BÁ Ń YIN ORÚKỌ JÈHÓFÀ

8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù lẹni tó fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa yin orúkọ Jèhófà?

8 Nínú gbogbo àwọn tí Ọlọ́run dá sọ́run àti ayé, kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n bíi Jésù Ọmọ rẹ̀. (Mát. 11:27) Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀, òun ló sì fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa yin orúkọ Jèhófà. (Jòh. 14:31) Nígbà tó ń gbàdúrà sí Bàbá ẹ̀ lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀, ó ṣàkópọ̀ àwọn iṣẹ́ tó ṣe nígbà tó wà láyé. Ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.” (Jòh. 17:26) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí?

9. Àpèjúwe wo ni Jésù lò láti fi ṣàlàyé ẹni tí Bàbá ẹ̀ jẹ́?

9 Jésù ò kàn sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run torí pé àwọn Júù tí Jésù ń kọ́ ti mọ orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Jésù ni “ẹni tó ṣàlàyé” ẹni tí Jèhófà jẹ́ lọ́nà tó dáa jù. (Jòh. 1:17, 18) Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń gba tẹni rò. (Ẹ́kís. 34:5-7) Jésù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé wa dáadáa nígbà tó sọ àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá àti bàbá ẹ̀. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì ń gba tẹni rò. Nígbà tí bàbá yìí rí ọmọ ẹ̀ tó ti ronú pìwà dà tó “ń bọ̀ ní òkèèrè,” ó sáré lọ pàdé ẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì dárí jì í tọkàntọkàn. (Lúùkù 15:11-32) Torí náà, Jésù ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an.

10. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù lo orúkọ Bàbá ẹ̀, ó sì fẹ́ káwọn èèyàn máa lò ó? (Máàkù 5:19) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Kí ni Jésù fẹ́ ká máa ṣe lónìí?

10 Ṣé Jésù náà fẹ́ káwọn èèyàn máa lo orúkọ Bàbá ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn olórí ẹ̀sìn kan tí wọ́n ka ara wọn sí olódodo sọ pé orúkọ Ọlọ́run mọ́ ju kéèyàn máa pè é lọ, àmọ́ Jésù ò jẹ́ kí àṣà tí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí yẹn dí òun lọ́wọ́ láti bọlá fún orúkọ Bàbá òun. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbà kan tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan ní agbègbè àwọn ará Gérásà. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà gan-an, torí náà wọ́n sọ pé kí Jésù máa lọ, ó sì kúrò níbẹ̀. (Máàkù 5:16, 17) Síbẹ̀, Jésù fẹ́ káwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn mọ orúkọ Jèhófà. Torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé kó sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ló wo òun sàn. (Ka Máàkù 5:19.) a Ohun tó fẹ́ káwa náà ṣe lónìí nìyẹn, ó fẹ́ ká sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ fún gbogbo èèyàn! (Mát. 24:14; 28:19, 20) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jésù Ọba wa dùn.

Jésù sọ fún ọkùnrin tó lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ẹ̀ pé kó sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ló wo òun sàn (Wo ìpínrọ̀ 10)


11. Kí ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun fi sínú àdúrà wọn, kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ náà fi ṣe pàtàkì? (Ìsíkíẹ́lì 36:23)

11 Jésù mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí orúkọ ẹ̀ di mímọ́, kó sì mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lára orúkọ náà. Ìdí nìyẹn tí Jésù Ọ̀gá wa fi kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Jésù mọ̀ pé ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù lójú gbogbo èèyàn ni bí wọ́n ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Ka Ìsíkíẹ́lì 36:23.) Láyé àtọ̀run, kò sẹ́ni tó sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ tó Jésù. Àmọ́ nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù, ẹ̀sùn wo làwọn ọ̀tá ẹ̀ fi kàn án? Wọ́n ní ó tàbùkù sí Ọlọ́run! Jésù mọ̀ dájú pé kéèyàn ba orúkọ Bàbá ẹ̀ mímọ́ jẹ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù lọ. Ó dùn ún gan-an pé ẹ̀sùn burúkú yìí ni wọ́n fi kan òun tí wọ́n sì sọ pé òun jẹ̀bi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló mú kí “ìdààmú bá a gan-an” nígbà tí wọ́n fẹ́ mú un.—Lúùkù 22:41-44.

12. Báwo ni Jésù ṣe sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ di mímọ́ lásìkò tí nǹkan nira fún un?

12 Kí Jésù lè sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ di mímọ́, ó fara da ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, ọ̀rọ̀ èébú tí wọ́n sọ sí i àti bí wọ́n ṣe bà á lórúkọ jẹ́. Ó mọ̀ pé òun ti ṣe gbogbo ohun tí Bàbá òun sọ pé kóun ṣe, ìdí nìyẹn tí ojú ò fi tì í torí ohun tí wọ́n ṣe fún un. (Héb. 12:2) Ó tún mọ̀ pé Sátánì ló ń fa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tí nǹkan nira fóun yẹn. (Lúùkù 22:2-4; 23:33, 34) Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé kí Jésù má jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà mọ́, àmọ́ kò rí i ṣe! Jésù fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé òpùrọ́ ni Sátánì àti pé a lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá tiẹ̀ ń kojú àdánwò tó le gan an!

13. Báwo lo ṣe lè máa múnú Jésù Ọba wa dùn?

13 Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o múnú Jésù Ọba wa dùn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa yin orúkọ Jèhófà, kó o sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó jẹ́ àtàwọn ànímọ́ tó ní. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Jésù lò ń tẹ̀ lé yẹn. (1 Pét. 2:21) Bíi ti Jésù, wàá máa múnú Jèhófà dùn, wàá sì fi hàn pé òpùrọ́ gbáà ni Sátánì tó ń ta ko Jèhófà!

TÁ A BÁ Ń YIN ORÚKỌ JÈHÓFÀ, A MÁA GBA Ẹ̀MÍ ÀWỌN ÈÈYÀN LÀ

14-15. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, àwọn nǹkan àgbàyanu wo ni wọ́n á mọ̀ nípa ẹ̀?

14 Tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, ńṣe là ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rígbàlà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ṣẹ́ ẹ rí i, Sátánì “ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́r. 4:4) Ìyẹn ti jẹ́ káwọn èèyàn gba irọ́ tí Sátánì pa mọ́ Ọlọ́run gbọ́. Àwọn irọ́ náà ni: Kò sí Ọlọ́run, kò ṣe é sún mọ́ kò sì rí tiwa rò, ìkà ni, ó sì máa ń dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lóró títí láé. Ìdí tó fi pa gbogbo irọ́ yìí ni pé ó fẹ́ ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ yẹn, kí wọ́n má bàa sún mọ́ ọn. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn, ńṣe là ń tú àṣírí irọ́ Sátánì. À ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ẹni tí Jèhófà jẹ́, a sì ń yin orúkọ mímọ́ rẹ̀. Kí nìyẹn wá yọrí sí?

15 Òtítọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ó sì lágbára gan-an. Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà àti irú ẹni tó jẹ́, ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀ ń yà wọ́n lẹ́nu. Ohun tí wọ́n ń kọ́ yẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé irọ́ ni Sátánì ń pa, wọ́n wá mọ̀ pé Jèhófà láwọn ànímọ́ tó dáa. Ẹnu yà wọ́n gan-an nítorí agbára ẹ̀ tí ò láàlà. (Àìsá. 40:26) Ohun tí wọ́n kọ́ jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́kẹ̀ lé e torí wọ́n rí i pé onídàájọ́ òdodo ni. (Diu. 32:4) Wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ pé òun ló gbọ́n jù lọ. (Àìsá. 55:9; Róòmù 11:33) Ara tù wọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Bí wọ́n ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń dá wọn lójú pé àwọn máa wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run! Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa pè wá ní “alábàáṣiṣẹ́” òun.—1 Kọ́r. 3:5, 9.

16. Báwo ló ṣe rí lára àwọn kan nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Tá a bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, a máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ ohun tó máa mú kí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá sin Jèhófà nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó tọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Aaliyah b dàgbà kì í ṣe Kristẹni. Àmọ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ ọ nínú ẹ̀sìn wọn ò tẹ́ ẹ lọ́rùn torí kò jẹ́ kó sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ nǹkan yí pa dà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá rí i pé òun lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tó mọ̀ pé àwọn èèyàn ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n sì ti fi orúkọ oyè míì bí Olúwa rọ́pò rẹ̀. Nígbà tó wá mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ìgbésí ayé ẹ̀ yí pa dà. Ó sọ pé: “Àṣé Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ní orúkọ!” Kí nìyẹn yọrí sí? Ó ní: “Ọkàn mi ti wá balẹ̀ báyìí. Mo sì gbà pé àǹfààní ńlá ni mo ní.” Olórin ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Steve, ẹlẹ́sìn Júù paraku sì làwọn tó tọ́ ọ dàgbà. Kò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn kankan torí ó ti rí i pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn, ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ nígbà tí ìyá ẹ̀ kú, ó gbà láti dara pọ̀ níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe pẹ̀lú ẹnì kan. Inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó mọ orúkọ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ.” Ó tún sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láyé mi tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́! Mo ti mọ irú Ẹni tó jẹ́ báyìí. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé mo ti ní Ọ̀rẹ́ gidi.”

17. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa yin orúkọ Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Tó o bá ń wàásù tó o sì ń kọ́ni, ṣé o máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ mímọ́ Jèhófà? Ṣé o máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àtàwọn ànímọ́ tó ní? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń yin orúkọ Ọlọ́run nìyẹn. Má jẹ́ kó sú ẹ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, torí ìyẹn lá jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn rígbàlà. Wàá tún fi hàn pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi Ọba wa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá múnú Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ dùn. Àdúrà wa ni pé kí gbogbo wa máa “yin orúkọ [rẹ̀] títí láé àti láéláé”!—Sm. 145:2.

Tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà àtàwọn ànímọ́ tó ní, à ń yin Jèhófà nìyẹn (Wo ìpínrọ̀ 17)

TÁ A BÁ Ń YIN ORÚKỌ ỌLỌ́RUN, BÁWO NÌYẸN ṢE MÁA . . .

  • múnú Jèhófà dùn?

  • múnú Jésù Kristi dùn?

  • gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là?

ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

a Àwọn ẹ̀rí wà tó jẹ́ ká gbà pé nígbà tí Máàkù kọ lẹ́tà rẹ̀, ó lo orúkọ Jèhófà nínú ẹsẹ yìí nígbà tó ń ròyìn ohun tí Jésù sọ. Torí náà, a ti dá orúkọ náà pa dà sínú ẹsẹ yìí nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, nwtsty-E.

b A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.