Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

Máa Ṣe Ohun Tí Jèhófà Bá Sọ

Máa Ṣe Ohun Tí Jèhófà Bá Sọ

“Èmi, Jèhófà, ni . . . ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”ÀÌSÁ. 48:17.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà lónìí àtàwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣe ohun tó sọ.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

 KÁ SỌ pé o ti sọ nù sínú igbó kìjikìji kan. Àwọn nǹkan tó lè ṣe ẹ́ ní jàǹbá ló yí ẹ ká, irú bí àwọn ẹranko ẹhànnà, àwọn kòkòrò tó ní àrùn lára, àwọn ewéko tó ní májèlé àtàwọn kòtò ńlá tó o lè já sínú ẹ̀ láìmọ̀. Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá rí ẹni tó mọ̀nà, tí ò sì ní jẹ́ kí ohun burúkú kankan ṣẹlẹ̀ sí ẹ. A lè fi ayé yìí wé igbó kìjikìji yẹn. Àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ló kúnnú ayé yìí. Àmọ́ inú wa dùn pé a ní Jèhófà tó ń tọ́ wa sọ́nà. Ó máa ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́, ó sì ń sìn wá lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà?

2 Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà? Ohun àkọ́kọ́ tó máa ń lò ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ ó tún máa ń lo àwọn èèyàn láti tọ́ wa sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wa, ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. (Mát. 24:45) Jèhófà tún máa ń lo àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti tọ́ wa sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ máa ń fún wa níṣìírí, wọ́n sì máa ń tọ́ wa sọ́nà nígbà ìṣòro. A mà mọyì bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí o! Àwọn ìtọ́sọ́nà yìí máa ń jẹ́ ká rójú rere Jèhófà, ó sì ń jẹ́ ká máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Síbẹ̀, ó lè má rọrùn láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ pàápàá tó bá jẹ́ pé èèyàn aláìpé bíi tiwa ló sọ pé ká ṣe nǹkan náà. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ohun tí wọ́n sọ yẹn lè má bá wa lára mu. A sì lè máa rò pé ohun tí wọ́n sọ yẹn ò bọ́gbọ́n mu, torí náà kò lè jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Irú àwọn àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé òun ló ń darí àwọn èèyàn ẹ̀, tá a bá sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀, a máa jàǹfààní gan-an. Ká lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí: (1) bí Jèhófà ṣe tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà nígbà àtijọ́, (2) bó ṣe ń tọ́ wa sọ́nà lónìí àti (3) àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ.

Látìgbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí dòní, Jèhófà ṣì ń lo àwọn èèyàn láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 3)


BÍ JÈHÓFÀ ṢE TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ SỌ́NÀ

4-5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ń lo Mósè láti tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

4 Jèhófà yan Mósè láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Ó sì jẹ́ kí wọ́n rí àwọn ohun tó fi hàn pé Mósè ni òun ń lò láti tọ́ wọn sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń fi ọwọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, ó sì ń fi ọwọ̀n iná darí wọn lálẹ́. (Ẹ́kís. 13:21) Mósè tẹ̀ lé ọwọ̀n náà, ọwọ̀n yẹn ló sì darí òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Òkun Pupa. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lé wọn bọ̀, tí wọ́n sì rí Òkun Pupa níwájú. Wọ́n gbà pé àṣìṣe ni Mósè ṣe bó ṣe kó wọn wá sí Òkun Pupa. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Jèhófà ló mọ̀ọ́mọ̀ lo Mósè láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ lọ síbẹ̀. (Ẹ́kís. 14:2) Torí náà, Ọlọ́run gbà wọ́n là lọ́nà ìyanu.—Ẹ́kís. 14:26-28.

Mósè gbà pé ọwọ̀n ìkùukùu tí Jèhófà pèsè lòun á máa tẹ̀ lé láti darí àwọn èèyàn Ọlọ́run nínú aginjù (Wo ìpínrọ̀ 4-5)


5 Odindi ogójì (40) ọdún ni Mósè fi tẹ̀ lé ọwọ̀n ìkùukùu náà, ó sì gbà pé òun ni Jèhófà ń lò láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ nínú aginjù. a Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé orí àgọ́ Mósè ni Jèhófà jẹ́ kí ọwọ̀n náà dúró sí kí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa rí i. (Ẹ́kís. 33:7, 9, 10) Jèhófà máa ń bá Mósè sọ̀rọ̀ látinú ọwọ̀n náà, Mósè á wá lọ sọ ohun tí Jèhófà sọ fún un fáwọn èèyàn náà. (Sm. 99:7) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ṣe láti jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Mósè ni òun ń lò láti darí wọn.

Mósè àti Jóṣúà tó gbéṣẹ́ fún (Wo ìpínrọ̀ 5, 7)


6. Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tó fi hàn pé wọn ò gba ìtọ́sọ́nà Jèhófà? (Nọ́ńbà 14:2, 10, 11)

6 Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò gba ẹ̀rí tí Jèhófà ń fi hàn wọ́n pé Mósè ni òun ń lò láti darí wọn. (Ka Nọ́ńbà 14:2, 10, 11.) Léraléra ni wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé wọn ò gbà pé Jèhófà ń lo Mósè. Torí náà, Jèhófà ò gbà kí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Nọ́ń. 14:30.

7. Sọ àpẹẹrẹ àwọn tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. (Nọ́ńbà 14:24) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé: “Kélẹ́bù . . . ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi.” (Ka Nọ́ńbà 14:24.) Jèhófà bù kún Kélẹ́bù, kódà ilẹ̀ tó wù ú ni Jèhófà fún un ní Kénáánì. (Jóṣ. 14:12-14) Ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó tẹ̀ lé ìyẹn náà ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn. Nígbà tí Jèhófà fi Jóṣúà rọ́pò Mósè, tó sì ní kó máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n “bọ̀wọ̀ fún un gan-an ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (Jóṣ. 4:14) Torí náà, Jèhófà bù kún wọn torí ó jẹ́ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí tó ṣèlérí fún wọn.—Jóṣ. 21:43, 44.

8. Ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe darí àwọn èèyàn ẹ̀ lásìkò táwọn ọba ń jẹ ní Ísírẹ́lì. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé àwọn onídàájọ́ dìde kí wọ́n lè máa tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, lásìkò táwọn ọba ń jẹ ní Ísírẹ́lì, Jèhófà yan àwọn wòlíì láti máa tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń ṣe ohun táwọn wòlíì yẹn bá sọ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí wòlíì Nátánì fún un. (2 Sám. 12:7, 13; 1 Kíró. 17:3, 4) Ọba Jèhóṣáfátì gbà kí wòlíì Jáhásíẹ́lì tọ́ òun sọ́nà, ó sì gba àwọn èèyàn Júdà níyànjú pé kí wọ́n “ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì” Ọlọ́run. (2 Kíró. 20:14, 15, 20) Nígbà tí ìdààmú bá Ọba Hẹsikáyà, ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wòlíì Àìsáyà. (Àìsá. 37:1-6) Gbogbo ìgbà táwọn ọba yẹn bá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn ni Jèhófà máa ń bù kún wọn, ó sì máa ń dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn. (2 Kíró. 20:29, 30; 32:22) Torí náà, ó yẹ kí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rí i pé Jèhófà ń lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti tọ́ àwọn sọ́nà. Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọba àtàwọn èèyàn yẹn ni ò gba àwọn wòlíì Jèhófà gbọ́.—Jer. 35:12-15.

Ọba Hẹsikáyà àti wòlíì Àìsáyà (Wo ìpínrọ̀ 8)


BÍ JÈHÓFÀ ṢE TỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN Ẹ̀ SỌ́NÀ NÍGBÀ AYÉ ÀWỌN KRISTẸNI ÀKỌ́BẸ̀RẸ̀

9. Àwọn wo ni Jèhófà lò láti darí àwọn èèyàn ẹ̀ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Àmọ́ báwo ló ṣe darí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn? Ó yan Jésù láti jẹ́ orí ìjọ. (Éfé. 5:23) Ṣùgbọ́n Jésù kì í bá ọmọ ẹ̀yìn kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ ní tààràtà tàbí kó sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló máa ń lò láti darí àwọn èèyàn ẹ̀. (Ìṣe 15:1, 2) Bákan náà, wọ́n máa ń yan àwọn alàgbà táá máa bójú tó ìjọ kọ̀ọ̀kan.—1 Tẹs. 5:12; Títù 1:5.

Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù (Wo ìpínrọ̀ 9)


10. (a) Kí ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń ṣe táwọn àpọ́sítélì bá tọ́ wọn sọ́nà? (Ìṣe 15:30, 31) (b) Kí nìdí táwọn kan ò fi gba àwọn tí Jèhófà ní kó máa darí wọn? (Wo àpótí náà, “ Ìdí Táwọn Kan Ò Fi Gbà Pé Jèhófà Ń Lo Àwọn Ìránṣẹ́ Ẹ̀ Kan Láti Darí Wa.”)

10 Kí làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń ṣe táwọn àpọ́sítélì bá tọ́ wọn sọ́nà? Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló máa ń fara mọ́ ohun tí wọ́n bá sọ fún wọn. Kódà, “ìṣírí tí wọ́n rí gbà mú inú wọn dùn.” (Ka Ìṣe 15:30, 31.) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe ń darí àwa èèyàn ẹ̀ lónìí?

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń TỌ́ WA SỌ́NÀ LÓNÌÍ

11. Sọ àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ́nà láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 1870.

11 Jèhófà ló ṣì ń tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà lónìí. Ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń lo Jésù Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ orí ìjọ láti darí wa. Ṣé ẹ̀rí wà pé Jèhófà ṣì ń lo àwọn èèyàn láti darí wa? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 1870. Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fòye mọ̀ pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. (Dán. 4:25, 26) Ohun tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ṣèwádìí nínú Bíbélì, wọ́n sì gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ẹ̀ máa ṣẹ. Ṣé Jèhófà ń tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ṣe ń ṣèwádìí nínú Bíbélì? Ó dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé lọ́dún 1914 jẹ́ kó hàn gbangba pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Ọdún yẹn ni wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní, lẹ́yìn náà àjàkálẹ̀ àrùn, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àìtó oúnjẹ wáyé. (Lúùkù 21:10, 11) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lo àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà.

12-13. Kí làwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ká lè túbọ̀ máa wàásù?

12 Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Lẹ́yìn táwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ní oríléeṣẹ́ fara balẹ̀ ṣèwádìí nípa Ìfihàn 17:8, wọ́n mọ̀ pé ogun yẹn kọ́ ló máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Àmọ́ wọ́n rí i pé àlàáfíà máa wà lẹ́yìn tí wọ́n bá ja ogun náà tán, ìyẹn sì máa mú káwa èèyàn Jèhófà ráyè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Torí náà, ètò Ọlọ́run dá ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible College of Gilead sílẹ̀ (tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì báyìí) kí wọ́n lè dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ láti lọ wàásù kárí ayé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé lójú èèyàn ohun tí wọ́n ṣe yìí lè má bọ́gbọ́n mu. Wọ́n rán àwọn míṣọ́nnárì jáde kódà nígbà tí ogun náà ṣì ń lọ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹrú olóòótọ́ àti olóye tún ṣètò ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n pè ní Course in Theocratic Ministry b láti dá gbogbo àwọn ará ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí jẹ́ káwa èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ kúnjú ìwọ̀n láti ṣiṣẹ́ tó wà níwájú wa.

13 Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, àá rí i pé Jèhófà tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà láwọn àsìkò tí nǹkan nira gan-an yẹn. Àtìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí làwa èèyàn Jèhófà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń gbádùn àlàáfíà déwọ̀n àyè kan, a sì lómìnira láti wàásù. Kódà, kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà ti ń wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti wá mọ Jèhófà.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run àtàwọn alàgbà bá sọ? (Ìfihàn 2:1) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Lónìí, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń jẹ́ kí Kristi tọ́ àwọn sọ́nà. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ohun táwọn ará máa ṣe, wọ́n máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí Jèhófà àti Kristi fẹ́ làwọn máa sọ fáwọn ará. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèpinnu náà tán, wọ́n máa ń ní káwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà fi jíṣẹ́ fáwọn ará nínú ìjọ. c Ó ṣe tán, àwọn alàgbà tó jẹ́ ẹni àmì òróró títí kan gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ló wà ní “ọwọ́ ọ̀tún” Kristi. (Ka Ìfihàn 2:1.) Ká sòótọ́, aláìpé làwọn alàgbà yìí, wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe. Àwọn ìgbà kan wà tí Mósè àti Jóṣúà ṣàṣìṣe, àwọn àpọ́sítélì náà sì ṣàṣìṣe. (Nọ́ń. 20:12; Jóṣ. 9:14, 15; Róòmù 3:23) Síbẹ̀, Kristi ṣì ń fìfẹ́ bójú tó ẹrú olóòótọ́ àtàwọn alàgbà, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ “ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Torí náà, kò sídìí tí ò fi yẹ ká ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa torí Kristi ló ń darí wọn.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti òde òní (Wo ìpínrọ̀ 14)


A MÁA JÀǸFÀÀNÍ TÁ A BÁ Ń JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ TỌ́ WA SỌ́NÀ

15-16. Kí lo kọ́ nínú ìrírí àwọn tó ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ?

15 Tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa gbádùn kódà ní báyìí. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Andy àti Robyn ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ pé ká jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mátíù 6:22, nwtsty-E.) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn jẹ́ kí wọ́n lè yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run. Robyn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti gbé nílé tó kéré gan-an tí ò nílé ìdáná rárá. Yàtọ̀ síyẹn, mo fẹ́ràn iṣẹ́ fọ́tò yíyà tí mò ń ṣe, àmọ́ mo ní láti ta èyí tó pọ̀ jù lára àwọn nǹkan tí mo fi ń ṣiṣẹ́ náà. Ó dùn mí gan-an débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún nígbà tí mo tà wọ́n. Àmọ́ bíi ti Sérà ìyàwó Ábúráhámù, mi ò kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tí mo ṣe, ńṣe ni mò ń láyọ̀.” (Héb. 11:15) Àǹfààní wo ni tọkọtaya yìí ti rí? Robyn sọ pé: “Inú wa dùn, ọkàn wa sì balẹ̀ torí a mọ̀ pé gbogbo ohun tá a ní la fún Jèhófà. Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé, àwọn nǹkan tá à ń ṣe máa ń jẹ́ ká rí bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun.” Andy fara mọ́ ohun tí ìyàwó ẹ̀ sọ, ó ní: “Inú wa dùn pé à ń lo gbogbo okun àti àkókò wa láti ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn.”

16 Àǹfààní míì wo la máa rí tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà? Lẹ́yìn tí Marcia parí ilé ìwé girama, ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí ètò Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. (Mát. 6:33; Róòmù 12:11) Ó sọ pé: “Wọ́n ní kí n wá kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ fún ọdún mẹ́rin ní yunifásítì. Àmọ́, ohun tó wù mí ni pé kí n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, mo lọ sílé ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ kí n lè kọ́ṣẹ́ tí màá fi máa gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi. Ọ̀kan lára àwọn ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe láyé mi nìyẹn. Ní báyìí, mò ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, iṣẹ́ tí mò ń ṣe sì gbà mí láyè láti máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì láwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, mò ń gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì nínú ètò Ọlọ́run.”

17. Àwọn àǹfààní míì wo la máa rí tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà? (Àìsáyà 48:17, 18)

17 Nígbà míì, ètò Ọlọ́run máa ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì máa ń dáàbò bò wá ká má bàa nífẹ̀ẹ́ owó tàbí ká ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká rú òfin Ọlọ́run. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa láwọn apá yìí, Jèhófà máa bù kún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a ò sì ní kó síṣòro tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. (1 Tím. 6:9, 10) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ọkàn wa làá máa fi ṣe ìjọsìn Jèhófà, ìyẹn nìkan ló sì lè fún wa láyọ̀, ìbàlẹ̀ ọkàn àti àlàáfíà.—Ka Àìsáyà 48:17, 18.

18. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ ẹ sọ́nà?

18 Kò sí àní-àní pé Jèhófà á ṣì máa lo àwọn èèyàn láti tọ́ wa sọ́nà nígbà ìpọ́njú ńlá títí dìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Sm. 45:16) Ṣé àá ṣì máa ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa kódà tó bá jẹ́ pé ohun míì ló wù wá pé ká ṣe? Ó máa rọrùn fún wa nígbà yẹn tá a bá ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wa báyìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà nígbà gbogbo títí kan èyí tí àwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wa bá fún wa. (Àìsá. 32:1, 2; Héb. 13:17) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa fọkàn tán Jèhófà Ẹni tó ń tọ́ wa sọ́nà, tó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́, tó sì máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe darí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀?

  • Àwọn àǹfààní wo la máa rí báyìí tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà?

ORIN 48 Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́

a Jèhófà tún yan áńgẹ́lì kan tó “ń lọ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” tó sì ń darí wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù tó ń jẹ́ Máíkẹ́lì ni áńgẹ́lì yẹn, kò sì tíì wá sáyé nígbà yẹn.—Ẹ́kís. 14:19; 32:34.

b Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ní báyìí, ó ti wà lára ìpàdé tá à ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀.

c Wo àpótí náà, “Ojúṣe Ìgbìmọ̀ Olùdarí” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2021, ojú ìwé 18.