ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6
ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà
A Mọyì Ẹ̀ Gan-an Pé Jèhófà Ń Dárí Jì Wá
“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.”—JÒH. 3:16.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A mọyì ẹ̀ gan-an pé Jèhófà máa ń dárí jì wá. Àmọ́ tá a bá mọ àwọn nǹkan tó ṣe kó lè dárí jì wá, àá túbọ̀ mọyì ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀.
1-2. Báwo lọ̀rọ̀ àwa èèyàn ṣe jọ ti ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní ìpínrọ̀ kìíní?
FOJÚ inú wo ọ̀dọ́kùnrin kan táwọn òbí ẹ̀ lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, jàǹbá kan ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ̀, wọ́n sì kú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an. Àmọ́ kò mọ̀ pé òun ṣì máa gbọ́ ìròyìn míì tó máa bà á nínú jẹ́ jùyẹn lọ. Wọ́n sọ fún un pé àwọn òbí ẹ̀ ti ṣe owó ìdílé wọn báṣubàṣu, wọ́n sì tún jẹ gbèsè rẹpẹtẹ. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára ọ̀dọ́kùnrin yẹn. Dípò kó jogún dúkìá wọn, gbèsè ló bá nílẹ̀, àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè sì fẹ́ kó dá owó àwọn pa dà kíákíá. Èyí tó burú jù ni pé kò lè san gbèsè náà tán tó fi máa kú.
2 Ọ̀rọ̀ àwa àti ọ̀dọ́kùnrin yẹn jọra láwọn ọ̀nà kan. Ẹni pípé làwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, inú Párádísè tó rẹwà ni wọ́n sì ń gbé. (Jẹ́n. 1:27; 2:7-9) Wọ́n láǹfààní láti gbádùn ayé wọn títí láé. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí wọn. Wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù Párádísè tó rẹwà yẹn àti àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé. Ogún wo ni wọ́n máa wá fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn báyìí? Bíbélì sọ fún wa pé: “Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan [ìyẹn Ádámù] wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ogún tí Ádámù fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn ló sì fa ikú. Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún yìí dà bíi gbèsè rẹpẹtẹ tí kò sẹ́nì kankan tó lè san án.—Sm. 49:8.
3. Kí nìdí tá a ṣe fi ẹ̀ṣẹ̀ wé “gbèsè”?
3 Jésù fi ẹ̀ṣẹ̀ wé “gbèsè.” (Mát. 6:12; Lúùkù 11:4) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tá a jẹ Jèhófà ní gbèsè. Torí náà, Jèhófà lè sọ pé òun máa fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá. Tá ò bá sì rí gbèsè náà san, ẹ̀mí wa la máa fi dí i.—Róòmù 6:7, 23.
4. (a) Ká ní a ò rẹ́ni ràn wá lọ́wọ́, kí ni ì bá ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀? (Sáàmù 49:7-9) (b) Báwo ni wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” nínú Bíbélì? (Wo àpótí náà “ Ẹ̀ṣẹ̀.”)
4 Ṣé ó ṣeé ṣe ká pa dà rí ohun tí Ádámù àti Éfà pàdánù? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kì í ṣe ohun táwa èèyàn lè ṣe. (Ka Sáàmù 49:7-9.) Ká ní a ò rẹ́ni ràn wá lọ́wọ́, a ò ní lè wà láàyè lọ́jọ́ iwájú, àwọn tó ti kú ò sì ní lè jíǹde. Kódà, bí àwọn ẹranko ṣe ń kú làwa náà ì bá máa kú, tá ò sì ní jíǹde.—Oníw. 3:19; 2 Pét. 2:12.
5. Báwo ni Bàbá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún? (Wo àwòrán.)
5 Ẹ jẹ́ ká tún ronú nípa ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára ẹ̀ tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan bá sọ fún un pé òun máa bá a san gbogbo gbèsè náà? Ó dájú pé ọ̀dọ́kùnrin yẹn máa mọyì ẹ̀ pé ọkùnrin náà fi inú rere hàn sóun, á sì gbà kó bá òun san gbèsè náà. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ wa rí, Jèhófà Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa ti fún wa lẹ́bùn kan tó fi san gbèsè tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn náà, ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀bùn yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
6. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí tá a fi máa sọ̀rọ̀ nípa wọn?
6 Báwo la ṣe lè jàǹfààní ẹ̀bùn ńlá yìí, kí Jèhófà sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí “gbèsè” wa jì wá? Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni: ìpadàrẹ́, ètùtù, ìpẹ̀tù, ìràpadà, ìtúsílẹ̀ àti a pè wọ́n ní olódodo. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́. Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí wọn, àá túbọ̀ mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa.
JÈHÓFÀ FẸ́ KÁ PA DÀ BÁ ÒUN RẸ́
7. (a) Nǹkan míì wo ni Ádámù àti Éfà pàdánù? (b) Torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ni wá, kí ló pọn dandan pé ká ṣe? (Róòmù 5:10, 11)
7 Ádámù àti Éfà pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé. Nǹkan míì tí wọ́n pàdánù ni àjọṣe tó dáa tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà Bàbá wọn ọ̀run. Kí Ádámù àti Éfà tó dẹ́ṣẹ̀, ara ìdílé Ọlọ́run ni wọ́n. (Lúùkù 3:38) Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn, Jèhófà ní wọn kì í ṣe ara ìdílé òun mọ́, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. (Jẹ́n. 3:23, 24; 4:1) Torí pé àtọmọdọ́mọ wọn ni wá, ó gba pé ká pa dà bá Jèhófà rẹ́. (Ka Róòmù 5:10, 11.) Tá a bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà míì, a gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìpadàrẹ́,” ó ní ó lè túmọ̀ sí “kí ẹnì kan àti ọ̀tá ẹ̀ pa dà di ọ̀rẹ́.” Ó yà wá lẹ́nu pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló dìídì gbé ìgbésẹ̀ ká lè pa dà bá òun rẹ́. Báwo ló ṣe ṣe é?
JÈHÓFÀ ṢÈTÒ ÈTÙTÙ
8. Kí ni (a) ètùtù? (b) ìpẹ̀tù?
8 Ètùtù ni ètò tí Jèhófà ṣe káwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Ó gba pé kí wọ́n fi ohun kan tó ṣeyebíye pààrọ̀ ohun míì tó ṣeyebíye, nǹkan méjì náà sì gbọ́dọ̀ dọ́gba. Ìyẹn máa jẹ́ ká rí ohun tí Ádámù pàdánù gbà pa dà. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ míì tí ìtumọ̀ ẹ̀ jọ “ètùtù,” ọ̀rọ̀ náà ni ìpẹ̀tù. (Róòmù 3:25) Ìpẹ̀tù ni ohun tó mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.
9. Ètò tí kò ní máa wà títí lọ wo ni Jèhófà ṣe kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jì wọ́n?
9 Káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣètò kan tí kò ní máa wà títí lọ, táá jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń ṣe Ọjọ́ Ètùtù. Lọ́jọ́ yẹn, àlùfáà àgbà máa fi ẹran rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn náà. Ká sòótọ́, ẹran tí wọ́n fi rúbọ ò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò pátápátá torí ẹranko ò ṣeyebíye tó èèyàn. Àmọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣáà ti ronú pìwà dà, tí wọ́n sì rúbọ sí Jèhófà, Jèhófà máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. (Héb. 10:1-4) Ètò tí Jèhófà ṣe yìí àti ẹbọ tí wọ́n máa ń rú déédéé máa ń rán wọn létí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n nílò ohun tó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá.
10. Ètò tó wà títí lọ wo ni Jèhófà ṣe tó jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji aráyé?
10 Jèhófà ṣe ètò tó wà títí lọ tó jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji aráyé. Ó fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n “rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, kó lè ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Héb. 9:28) Torí náà, Jésù gbà láti fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mát. 20:28) Àmọ́, kí ni ìràpadà?
JÈHÓFÀ SAN ÌRÀPADÀ
11. (a) Bí Bíbélì ṣe sọ, kí ni ìràpadà? (b) Ta lẹni tó lè san ìràpadà náà?
11 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìràpadà ni ohun tẹ́nì kan san láti fi ṣe ètùtù àti ìpadàrẹ́. Jèhófà rí i pé ìràpadà ló máa jẹ́ ká rí ohun tá a ti pàdánù gbà. Báwo ló ṣe ṣe é? Rántí pé ẹni pípé ni Ádámù àti Éfà kí wọ́n tó di aláìpé, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé. Torí náà, ìràpadà àtohun tí wọ́n pàdánù gbọ́dọ̀ bára mu. (1 Tím. 2:6) Ẹni tó lè san ìràpadà náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkùnrin àgbàlagbà (1) tó jẹ́ ẹni pípé; (2) tó lè gbé ayé títí láé àti (3) tó ṣe tán láti kú kó lè gbà wá là. Àwọn nǹkan mẹ́ta yìí ló máa jẹ́ kí ẹni náà kúnjú ìwọ̀n láti san ìràpadà.
12. Kí ló mú kí Jésù lè san ìràpadà tá a nílò?
12 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó jẹ́ kí Jésù lè san ìràpadà. (1) Ẹni pípé ni, ìyẹn ni pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pét. 2:22) (2) Torí pé ẹni pípé ni, ó lè gbé ayé títí láé. (3) Ó ṣe tán láti kú nítorí wa. (Héb. 10:9, 10) Bí Jésù ṣe jẹ́ ẹni pípé náà ni Ádámù jẹ́ ẹni pípé kó tó dẹ́ṣẹ̀. (1 Kọ́r. 15:45) Bí Jésù ṣe kú jẹ́ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò, kó sì san ohun tó pàdánù. (Róòmù 5:19) Bí Jésù ṣe di “Ádámù ìkẹyìn” nìyẹn. A ò sì nílò ẹlòmíì tó jẹ́ ẹni pípé láti wá san ohun tí Ádámù pàdánù torí pé Jésù ti kú “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.”—Héb. 7:27; 10:12.
13. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ètùtù àti ìràpadà?
13 Níbi tá a dé yìí, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ètùtù àti ìràpadà? Ètùtù ni ohun tí Ọlọ́run ṣe láti jẹ́ kí àjọṣe òun àti aráyé pa dà gún régé. Ìràpadà ni ohun tí Ọlọ́run san láti fi ṣètùtù fún aráyé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ṣeyebíye tó dà jáde nítorí wa ni ohun tí Ọlọ́run san.—Éfé. 1:7; Héb. 9:14.
JÈHÓFÀ TÚ WA SÍLẸ̀, Ó SÌ PÈ WÁ NÍ OLÓDODO
14. Ní báyìí, kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí sì nìdí?
14 Kí ni àǹfààní ètùtù tí Jèhófà ṣètò? Óríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ni Bíbélì lò láti jẹ́ ká mọ àwọn àǹfààní náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà jọra, ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ká mọ bí apá kọ̀ọ̀kan nínú ètùtù náà ṣe ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti rí ìdáríjì Jèhófà gbà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà lọ́kọ̀ọ̀kan àti àǹfààní tá à ń rí níbẹ̀.
15-16. (a) Nínú Bíbélì, kí ni “ìtúsílẹ̀”? (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ̀ pé Jèhófà ti tú ẹ sílẹ̀?
15 Nínú Bíbélì, ìtúsílẹ̀ ni kí wọ́n dá ẹnì kan sílẹ̀ torí pé wọ́n san ohun kan láti ra ẹni náà pa dà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ìtúsílẹ̀, ó ní: “Ẹ mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ohun tó lè bà jẹ́, bíi fàdákà tàbí wúrà la fi tú yín sílẹ̀ [ní Grk., “la fi rà yín pa dà; dá yín nídè”] kúrò nínú ìgbésí ayé asán tí àwọn baba ńlá yín fi lé yín lọ́wọ́. Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ni, bí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò ní àbààwọ́n, tí kò sì ní èérí kankan, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ Kristi.”—1 Pét. 1:18, 19; àlàyé ìsàlẹ̀.
16 Torí pé Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà, ó ṣeé ṣe fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó ń pọ́n aráyé lójú. (Róòmù 5:21) Ká sòótọ́, ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù gan-an torí ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ṣeyebíye ló fi tú wa sílẹ̀.—1 Kọ́r. 15:22.
17-18. (a) Tá a bá pè wá ní olódodo, kí ló túmọ̀ sí? (b) Àǹfààní wo la máa rí tí Jèhófà bá pè wá ní olódodo?
17 A pè wa ní olódodo. Tá a bá pe ẹnì kan ní olódodo, ó túmọ̀ sí pé kò lẹ́sùn lọ́rùn mọ́, a sì ti pa ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ rẹ́. Bí Jèhófà ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́ kò fi hàn pé kì í ṣe onídàájọ́ òdodo. Kò pè wá ní olódodo torí pé ó tọ́ sí wa, ìyẹn ò sì túmọ̀ sí pé ó fọwọ́ sí i pé ká máa dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́ torí pé a nígbàgbọ́ nínú ètùtù àti ìràpadà tí Jèhófà san, ó pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́.—Róòmù 3:24; Gál. 2:16.
18 Àǹfààní wo la máa rí tí Jèhófà bá pè wá ní olódodo? Jèhófà ti yan àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run, ó sì ti pè wọ́n ní olódodo àti ọmọ òun. (Títù 3:7; 1 Jòh. 3:1) Ó ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Wọn ò ní àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, torí náà wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti wọ Ìjọba ọ̀run. (Róòmù 8:1, 2, 30) Ọlọ́run ti pe àwọn tó máa jogún ayé ní olódodo àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. (Jém. 2:21-23) Ogunlọ́gọ̀ èèyàn máa la Amágẹ́dọ́nì já, wọn ò sì ní kú mọ́. (Jòh. 11:26) “Àwọn olódodo” àti “àwọn aláìṣòdodo” tí wọ́n ti kú máa jíǹde. (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:28, 29) Níkẹyìn, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ onígbọràn máa “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni ètùtù yìí ṣe wá, ká lè pa dà bá Jèhófà Bàbá wa rẹ́!
19. Báwo lọ̀rọ̀ wa ṣe dayọ̀? (Wo àpótí náà “ Ohun Tí Jèhófà Ṣe Kó Lè Dárí Jì Wá.”)
19 Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ wa dà bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú táwọn òbí ẹ̀ ò fi ogún kankan sílẹ̀, tí wọ́n sì tún jẹ gbèsè tí ò lè san tán. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà tó ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ wa dayọ̀ torí pé Jèhófà ṣètò ètùtù, ó sì gbà kí Jésù Ọmọ ẹ̀ san ìràpadà. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí náà, Jèhófà máa dárí jì wá, ó sì máa pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́. Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé a ti láǹfààní láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà Baba wa ọ̀run.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Tá a bá ń ronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa, àá máa dúpẹ́, àá sì tọ́pẹ́ dá. (2 Kọ́r. 5:15) Tí kì í bá ṣe pé wọ́n ràn wá lọ́wọ́ ni, à bá má nírètí kankan! Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe ń dárí ji ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? Nǹkan tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.
ORIN 10 Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!