Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
ṢÉ O ti níṣòro kan rí, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lè dá yanjú ẹ̀? ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ la wà yìí, ìyẹn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, kó sì máa ṣe wá bíi pé a dá wà. (2 Tím. 3:1) Àmọ́ tá a bá níṣòro, ó yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé ó yẹ ká láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.
BÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ ṢE MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń rìnrìn àjò lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n ràn án lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà. (Kól. 4:7-11) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ló bá a ṣe àwọn iṣẹ́ tóun fúnra ẹ̀ ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ará Fílípì fi àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù nílò ránṣẹ́, Ẹpafíródítù ló kó àwọn nǹkan náà lọ fún un. (Fílí. 4:18) Bákan náà, Tíkíkù ló fi àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ jíṣẹ́ fáwọn ìjọ. (Kól. 4:7; wo àlàyé ẹsẹ Bíbélì yìí nínú nwtsty-E.) Nígbà tí wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé àtìgbà tó wà lẹ́wọ̀n, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ló ràn án lọ́wọ́ kó lè bójú tó àwọn ará ìjọ. Báwo nìwọ náà ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi lásìkò wa yìí?
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lásìkò wa yìí náà ń ṣe nǹkan tó fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Elisabet lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó sọ bí arábìnrin kan ṣe ran òun lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Àyẹ̀wò ilé ìwòsàn fi hàn pé ìyá Elisabet ní àrùn jẹjẹrẹ tó lè gbẹ̀mí ẹ̀. Nígbà tí arábìnrin yẹn gbọ́, ó fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí Elisabet, ó sì kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa tù ú nínú síbẹ̀. Elisabet sọ pé: “Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí arábìnrin yẹn fi ránṣẹ́ sí mi jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹnì kan rí tèmi rò, ìyẹn sì jẹ́ kí n rí i pé mi ò dá wà.”—Òwe 18:24.
Ohun míì táá fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi fáwọn ará ni pé ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wàásù tàbí kí wọ́n lè máa wá sípàdé. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ní mọ́tò tàbí ọ̀kadà, ṣé o lè fi gbé arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan wá sípàdé tàbí lọ wàásù? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fún wọn níṣìírí, àwọn náà á sì fún ẹ níṣìírí. (Róòmù 1:12) Àmọ́ o, àwọn ará wa kan wà tí ò lè jáde nílé. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́?
RAN ÀWỌN TÍ Ò LÈ JÁDE NÍLÉ LỌ́WỌ́
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan wà tí àìlera tàbí àwọn ìṣòro míì ò jẹ́ kí wọ́n lè wá sípàdé lójúkojú. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin David. Àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó lé lóṣù mẹ́fà tó fi ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn. Ní gbogbo àsìkò tí David fi ń gbàtọ́jú, orí ìkànnì lòun àti Lidia ìyàwó ẹ̀ ti ń ṣèpàdé.
Báwo làwọn ará ìjọ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Lẹ́yìn ìpàdé, àwọn ará kan tí wọ́n wá sí Ilé Ìpàdé máa ń gbìyànjú láti bá David àti Lidia
sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì, wọ́n á sì sọ pé kí wọ́n tan fídíò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, tí David àti Lidia bá dáhùn nípàdé, àwọn ará máa ń fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ láti gbóríyìn fún wọn. Ohun táwọn ará ṣe yìí ni ò jẹ́ kí David àti Lidia rò pé àwọn dá wà.Ṣé àwa náà lè sọ fáwọn tí ò lè jáde nílé tí wọ́n wà níjọ wa pé ká jọ wàásù lọ́jọ́ kan? A lè ṣètò pé ká jọ wàásù, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á rí i pé a ò gbàgbé wọn. (Òwe 3:27) A tún lè ṣètò pé ká jọ kọ lẹ́tà láti wàásù tàbí ká wàásù látorí fóònù. Àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí àwọn tí ò lè jáde nílé dara pọ̀ mọ́ ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù lórí ìkànnì, wọ́n sì lè tan fídíò kí wọ́n lè ríra wọn. Nígbà tí ìjọ David àti Lidia ṣe irú ètò yìí, wọ́n mọyì ẹ̀ gan-an. David sọ pé: “Tá a bá wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń jíròrò Bíbélì ráńpẹ́, a máa ń gbàdúrà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kára tù wá.” Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣé o lè sọ fún arákùnrin tàbí arábìnrin tí ò lè jáde nílé pé o fẹ́ mú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sílé ẹ̀ kẹ́ ẹ lè jọ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?
Nígbà tá a bá wà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí ò lè jáde nílé, àá rí àwọn ìwà tó dáa tí wọ́n ní, ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wàásù pẹ̀lú wọn, tá a sì rí bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ tó sì yé àwọn èèyàn dáadáa, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì wọn. Torí náà, tó o bá ń wàásù déédéé pẹ̀lú àwọn ará, tó o sì ń wá sípàdé, wàá láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i.—2 Kọ́r. 6:13.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù níṣòro, ara tù ú gan-an nígbà tí Títù ọ̀rẹ́ ẹ̀ wá bẹ̀ ẹ́ wò. (2 Kọ́r. 7:5-7) Ohun tí Títù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé táwọn ará wa bá níṣòro, ó yẹ ká lọ bẹ̀ wọ́n wò, ká tù wọ́n nínú, ká bá wọn kẹ́dùn, ká sì pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò.—1 Jòh. 3:18.
JẸ́ Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ NÍGBÀ INÚNIBÍNI
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà inúnibíni, ó sì yẹ káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Sergey àti Tatyana ìyàwó ẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá wá tú ilé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n mú wọn lọ sí àgọ́ wọn láti fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Tatyana ni wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀, ó sì pa dà sílé. Sergey sọ pé: “Gbàrà tí [Tatyana] délé, arábìnrin kan tó nígboyà wá a lọ sílé. Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin míì dé, wọ́n bá wa tún ilé wa tò, ó sì mọ́ tónítóní.”
Sergey tún sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì tí mo sábà máa ń rántí ni Òwe 17:17 tó sọ pé: ‘Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.’ Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà inúnibíni torí pé lásìkò yẹn, ìṣòro náà ju agbára mi lọ, àmọ́ a láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Jèhófà ló rán àwọn ọ̀rẹ́ tó nígboyà yìí sí wa kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́.” a
Bí nǹkan ṣe ń burú sí i, ó gba pé ká mú àwọn ará lọ́rẹ̀ẹ́ báyìí, ká sì jẹ́ kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. A sì tún máa nílò wọn gan-an nígbà ìpọ́njú ńlá torí àwọn ló máa jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe báyìí ká lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, ká sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́!—1 Pét. 4:7, 8.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Jehovah Has Provided Friends Who Are Fearlessly at My Side” lédè Gẹ̀ẹ́sì, lórí jw.org.