ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
Bá A Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Wa Bí Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jì Wá
“Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.”—KÓL. 3:13.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe láti dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá.
1-2. (a) Ìgbà wo ló máa ń ṣòro jù fún wa láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá? (b) Báwo ni Denise ṣe dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́?
ṢÉ Ó máa ń ṣòro fún ẹ láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́? Ká sòótọ́, kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá pàápàá tí ẹni náà bá ṣe ohun tó dùn wá gan-an. Àmọ́ ṣá o, a lè gbójú fo ohun tí ẹni náà ṣe, ká sì dárí jì í. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin wa kan tó ń jẹ́ Denise. a Ó dárí ji ẹnì kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tẹ́ni náà ṣe burú jáì. Lọ́dún 2017, Denise àti ìdílé ẹ̀ lọ ṣèbẹ̀wò sí Oríléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Nígbà tí wọ́n ń pa dà sílé, awakọ̀ kan ṣèèṣì kọ lu mọ́tò wọn. Nígbà tí jàǹbá ọkọ̀ náà ṣẹlẹ̀, Denise ò mọ nǹkan kan mọ́ rárá. Lẹ́yìn tó jí, wọ́n sọ fún un pé àwọn ọmọ ẹ̀ fara pa yánnayànna, ọkọ ẹ̀ Brian sì ti kú. Nígbà tí Denise ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Gbogbo nǹkan tojú sú mi, mi ò sì mọ ohun tí màá ṣe.” Nígbà tó yá, ó gbọ́ pé awakọ̀ náà ò mutí yó, kì í sì í ṣe pé kò kọjú síbi tó ń lọ ló jẹ́ kó kọ lù wọ́n, torí náà ó gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ kóun má bàa ṣìwà hù.
2 Wọ́n fi ọlọ́pàá mú awakọ̀ náà, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó pààyàn. Tí ilé ẹjọ́ bá rí i pé ó jẹ̀bi, wọ́n lè sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Àmọ́, ilé ẹjọ́ sọ fún Denise pé torí pé ọ̀rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, ohun tó bá sọ ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá ọkùnrin náà máa lọ sẹ́wọ̀n àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Denise sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ló bà mí nínú jẹ́ jù láyé mi. Bí wọ́n ṣe ní kí n tún wá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ dà bí ìgbà tẹ́nì kan ṣí ojú ọgbẹ́ mi, tó sì da iyọ̀ tó pọ̀ sí i.” Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Denise wà nílé ẹjọ́ kó lè ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ níṣojú ọkùnrin tó fa wàhálà bá ìdílé ẹ̀. Kí ni Denise sọ? Ó sọ fún adájọ́ náà pé kó ṣàánú ọkùnrin náà. b Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ńṣe ni adájọ́ náà bú sẹ́kún. Ó ní: “Láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tí mo ti ń dájọ́ nílé ẹjọ́ yìí, irú nǹkan yìí ò tíì ṣẹlẹ̀ rí. Mi ò gbọ́ ọ rí pé kí ìdílé tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀ pé kí n ṣàánú ẹni tó fa jàǹbá náà. Mi ò tún gbọ́ ọ rí pé wọ́n ṣe ohun tó burú jáì sẹ́nì kan, kó sì sọ pé òun dárí ji ẹni tó ṣe nǹkan náà, ìfẹ́ yìí mà lágbára o!”
3. Kí ló jẹ́ kí Denise dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́?
3 Kí ló jẹ́ kí Denise dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́? Ó ronú nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá. (Míkà 7:18) Tá a bá mọyì bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá, á jẹ́ káwa náà máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá.
4. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe? (Éfésù 4:32)
4 Jèhófà fẹ́ ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá fàlàlà bóun náà ṣe máa ń dárí jì wá fàlàlà. (Ka Éfésù 4:32.) Ó fẹ́ ká dárí ji àwọn èèyàn nígbàkigbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. (Sm. 86:5; Lúùkù 17:4) Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó máa jẹ́ ká túbọ̀ máa dárí ji àwọn èèyàn.
WÁ NǸKAN ṢE SÓHUN TÓ Ń KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ Ẹ
5. Bí Òwe 12:18 ṣe sọ, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá?
5 Ó lè dùn wá gan-an tẹ́nì kan bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, pàápàá tẹ́ni náà bá jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ará ilé wa. (Sm. 55:12-14) Nígbà míì, ẹ̀dùn ọkàn tá a máa ń ní máa ń dà bí ìgbà tí wọ́n fi idà gún wa. (Ka Òwe 12:18.) A lè fẹ́ pa á mọ́ra tàbí ká má ṣe nǹkan kan sí i. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tẹ́nì kan gún wa lọ́bẹ, tí kò sì yọ ọ́ kúrò níbẹ̀. Lọ́nà kan náà, a ò lè retí pé kí ẹ̀dùn ọkàn wa lọ tá ò bá wá nǹkan ṣe sí i.
6. Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, kí la lè fẹ́ ṣe?
6 Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a lè kọ́kọ́ fẹ́ fara ya. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé inú lè bí wa. Àmọ́ Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká má jẹ́ kí ìbínú yẹn mú ká dẹ́ṣẹ̀. (Sm. 4:4; Éfé. 4:26) Kí nìdí? Ìdí ni pé bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára wa la máa fi ń hùwà. Tẹ́nì kan bá tètè ń bínú, ohun tí ò dáa lá máa ṣe. (Jém. 1:20) Ẹ má gbàgbé pé tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, a lè fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hàn, àmọ́ kò yẹ ká fàáké kọ́rí, ká wá máa bínú sẹ́ni náà títí lọ.
A lè fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hàn, àmọ́ kò yẹ ká fàáké kọ́rí, ká wá máa bínú sẹ́ni náà títí lọ
7. Kí ló lè dá kún ẹ̀dùn ọkàn wa tí wọ́n bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa?
7 Tí wọ́n bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, nǹkan míì wà tó lè dá kún ẹ̀dùn ọkàn tá a ní. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ann sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, bàbá mi fi ìyá mi sílẹ̀, wọ́n sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ń sanwó fún pé kó máa tọ́jú mi. Ó wá ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Lẹ́yìn tí wọ́n bímọ, ó dà bíi pé àwọn ọmọ náà ti gbapò mi. Bí mo sì ṣe ń dàgbà, ó ń ṣe mí bíi pé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò.” Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Georgette sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí ọkọ ẹ̀ ṣèṣekúṣe, ó ní: “Àtikékeré la ti ń bára wa bọ̀. A jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni! Ohun tó ṣe yẹn bà mí nínú jẹ́ gan-an.” Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fúnra wa. Arábìnrin Naomi ní tiẹ̀ sọ pé: “Mi ò rò ó rí pé ọkọ mi lè ṣe ohun tó máa dùn mí tóyẹn. Torí náà, nígbà tó jẹ́wọ́ fún mi pé òun máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe tóun ò sì jẹ́ kí n mọ̀, ó ṣe mí bíi pé kò nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì dalẹ̀ mi.”
8. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá? (b) Tá a bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, àǹfààní wo la máa rí? (Wo àpótí náà “ Tí Ẹnì Kan Bá Ti Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Ẹ Ńkọ́?”)
8 A ò lè sọ pé káwọn èèyàn má ṣe ohun tó dùn wá, àmọ́ a lè kó ara wa níjàánu tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀. Ohun tó dáa jù tá a lè ṣe ni pé ká dárí jì wọ́n. Kí nìdí? Ìdí ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fẹ́ ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. Tá a bá ń bínú sẹ́ni tó ṣẹ̀ wá tá ò sì dárí jì í, ó lè mú ká ṣe ohun tí ò dáa, ó sì lè ṣàkóbá fún ìlera wa. (Òwe 14:17, 29, 30) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christine. Ó sọ pé: “Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn mí, inú mi kì í dùn, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti rẹ́rìn-ín. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, mi ò kì í jẹ oúnjẹ gidi. Mi ò kì í rórun sùn dáadáa, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti gbọ́kàn kúrò níbẹ̀, ìyẹn ti kó bá àjọṣe àárín èmi àti ọkọ mi àtàwọn ẹlòmíì.”
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká di ẹni tó ṣẹ̀ wá sínú?
9 Tẹ́ni tó ṣẹ̀ wá ò bá tiẹ̀ tọrọ àforíjì, a ṣì lè gbọ́kàn kúrò níbẹ̀ kí ẹ̀dùn ọkàn náà má bàa pa wá lára. Báwo la ṣe lè ṣe é? Georgette tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó gba àkókò kí ẹ̀dùn ọkàn yẹn tó lọ, àmọ́ mo pinnu pé mi ò ní di ọkọ mi àtijọ́ sínú mọ́. Ohun tí mo ṣe yẹn jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.” Tá ò bá di àwọn èèyàn sínú, kò ní jẹ́ ká foró yaró. Yàtọ̀ síyẹn, a ò ní ronú nípa ọ̀rọ̀ náà mọ́, àá sì máa láyọ̀. (Òwe 11:17) Àmọ́, kí lo máa ṣe tó bá ṣì ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lè dárí ji ẹni náà?
BÓ O ṢE LÈ GBỌ́KÀN KÚRÒ NÍBẸ̀
10. Kí nìdí tó fi máa ń gba àkókò ká tó lè gbé ọ̀rọ̀ kan kúrò lọ́kàn wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an, kí ló máa jẹ́ kó o gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn ẹ? Ọ̀kan lára ohun tó o lè ṣe ni pé kó o ṣiṣẹ́ kára láti borí ẹ̀dùn ọkàn ẹ, ó sì máa gba àkókò. Tẹ́nì kan bá fara pa gan-an tó sì ti gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, ó máa ń gba àkókò kí ojú ọgbẹ́ náà tó jinná. Lọ́nà kan náà, ó lè gba àkókò ká tó lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wa, ká sì dárí ji ẹni náà tọkàntọkàn.—Oníw. 3:3; 1 Pét. 1:22.
11. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú kó o dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́?
11 Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́. c Ann tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ bí àdúrà ṣe ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Mo bẹ Jèhófà pé kó dárí ji ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé wa torí ohun tó yẹ ká ṣe àmọ́ tá ò ṣe. Torí náà, mo kọ lẹ́tà sí bàbá mi àti ìyàwó wọn pé mo ti dárí jì wọ́n.” Ann sọ pé kò rọrùn fóun láti dárí jì wọ́n. Àmọ́, ó sọ pé: “Bí mo ṣe fara wé Jèhófà tí mo sì dárí ji bàbá mi àti ìyàwó wọn lè mú kí wọ́n wá mọ Jèhófà.”
12. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó o má sì wo bí nǹkan ṣe rí lára ẹ? (Òwe 3:5, 6)
12 Jèhófà ni kó o gbẹ́kẹ̀ lé, má wo bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. (Ka Òwe 3:5, 6.) Jèhófà mọ ọ̀nà tó dáa jù láti gbà bójú tó ọ̀rọ̀ wa. (Àìsá. 55:8, 9) Kò ní sọ pé ká ṣe ohun tó máa pa wá lára. Torí náà, tó bá sọ pé ká dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, a mọ̀ pé a máa jàǹfààní tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 40:4; Àìsá. 48:17, 18) Àmọ́ tá a bá ń wo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa, a ò ní lè dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Òwe 14:12; Jer. 17:9) Naomi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Mo kọ́kọ́ rò pé kò yẹ kí n dárí ji ọkọ mi torí pé ó wo àwòrán ìṣekúṣe. Ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá dárí jì í, ó lè tún un wò tàbí kó gbàgbé bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe dùn mí tó. Mo sì mọ̀ pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé bí Jèhófà tiẹ̀ mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, ìyẹn ò sọ pé kò fẹ́ kí n dárí jì í. Ó mọ bó ṣe ń ṣe mí, ó sì mọ̀ pé ó máa gba àkókò kí n tó lè gbé e kúrò lọ́kàn, síbẹ̀ ó fẹ́ kí n dárí jì í.” d
BÓ O ṢE LÈ NÍ ÈRÒ TÓ DÁA
13. Kí ni Róòmù 12:18-21 sọ pé ó yẹ ká ṣe?
13 Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá gan-an tá a sì ti dárí jì í, kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ náà kiri. Àmọ́ ohun kan wà tó tún yẹ ká ṣe. Ó yẹ ká wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà, pàápàá tó bá jẹ́ ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà lẹni náà. (Mát. 5:23, 24) Dípò ká máa bínú sẹ́ni náà ká sì dì í sínú, ńṣe ló yẹ ká fàánú hàn sí i, ká sì dárí jì í. (Ka Róòmù 12:18-21; 1 Pét. 3:9) Kí lá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀?
14. Kí ló yẹ ká sapá láti ṣe, kí sì nìdí?
14 Ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹni tó ṣẹ̀ wá ló yẹ ká máa fi wò ó. Ibi táwọn èèyàn dáa sí ni Jèhófà máa ń wò. (2 Kíró. 16:9; Sm. 130:3) Tó bá jẹ́ ibi táwọn èèyàn kù sí là ń wá, a máa rí i, tó bá sì jẹ́ ibi tí wọ́n dáa sí là ń wá, a máa ríyẹn náà. Àmọ́ tó bá jẹ́ ibi tí wọ́n dáa sí là ń wò, ó máa rọrùn fún wa láti dárí jì wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jarrod sọ pé: “Ó máa ń rọrùn fún mi láti dárí ji arákùnrin kan tí mo bá ń ronú nípa àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe, dípò kí n máa ronú nípa àṣìṣe ẹ̀.”
15. Kí nìdí tó fi yẹ kó o sọ fún ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ pé o ti dárí jì í?
15 Ohun pàtàkì míì tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o sọ fún ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ pé o ti dárí jì í. Kí nìdí? Wo ohun tí Naomi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ, ó ní: “Ọkọ mi bi mí pé, ‘Ṣé o ti dárí jì mí?’ Nígbà tí mo lanu pé kí n sọ fún un pé, ‘Mo dárí jì ẹ́,’ mi ò lè sọ ọ́ jáde. Àmọ́ mo mọ̀ lọ́kàn mi pé mi ò tíì dárí jì í. Nígbà tó yá, mo sọ fún un pé, ‘Mo dárí jì ẹ́.’ Ó yà mí lẹ́nu pé ọkọ mi da omi lójú, ara wá tù ú, inú tèmi náà sì dùn. Látìgbà yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán an, a sì pa dà di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.”
16. Kí lo kọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa dárí jini?
16 Jèhófà fẹ́ ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Kól. 3:13) Àmọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, ká sì gbọ́kàn kúrò níbẹ̀. Ìgbà yẹn la máa tó lè ní èrò tó dáa nípa ẹni náà.—Wo àpótí náà “ Ohun Mẹ́ta Tó O Lè Ṣe Láti Dárí Jini.”
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń DÁRÍ JINI
17. Kí nìdí tá a fi ń dárí ji àwọn èèyàn?
17 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú ká máa dárí ji àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn. Àkọ́kọ́, à ń fara wé Jèhófà Baba aláàánú, a sì ń múnú ẹ̀ dùn. (Lúùkù 6:36) Ìkejì, a mọyì ẹ̀ pé Jèhófà máa ń dárí jì wá. (Mát. 6:12) Ìkẹta, ara wa máa jí pépé, àjọṣe àwa àtàwọn èèyàn á sì gún régé.
18-19. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá?
18 Tá a bá dárí ji àwọn èèyàn, àwọn àǹfààní tá ò rò tẹ́lẹ̀ la máa rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àǹfààní tí Denise tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú rí. Níbẹ̀rẹ̀, kò mọ̀ pé ọkùnrin tó fa jàǹbá ọkọ̀ yẹn ti pinnu pé òun máa gbẹ̀mí ara òun lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ẹjọ́ òun tán. Àmọ́ nígbà tó rí i pé Denise dárí ji òun, inú ẹ̀ dùn gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
19 Ọ̀kan lára ohun tó máa ń ṣòro fún wa láti ṣe ni pé ká dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, àmọ́ ó lè jẹ́ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù nìyẹn. (Mát. 5:7) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fara wé Jèhófà, ká sì máa dárí jini.
ORIN 125 “Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Tírú nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe.
c Lọ sórí ìkànnì jw.org kó o sì wo àwọn fídíò orin wa míì yìí: “Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín,” “Máa Dárí Jini Látọkàn” àti “Jẹ́ Ká Pa Dà Di Ọ̀rẹ́.”
d Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì ń pani lára, Ìwé Mímọ́ ò sọ pé kí ọkọ tàbi aya kan kọ ẹnì kejì ẹ̀ sílẹ̀ nítorí ẹ̀.