ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
“Mo Dá Wà, àmọ́ Jèhófà Wà Pẹ̀lú Mi”
Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló lè mú ká dá wà. Díẹ̀ lára ẹ̀ ni téèyàn wa bá kú, téèyàn bá kó lọ sí agbègbè tuntun tàbí ìgbà tí ò sí èèyàn lọ́dọ̀ wa. Àwọn nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí mi. Àmọ́, tí mo bá rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ láyé mi, mo rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà wà pẹ̀lú mi. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀ fún yín.
ÀWỌN ÒBÍ MI JẸ́ ÀPẸẸRẸ RERE
Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni bàbá àti màmá mi, wọn ò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré. Àmọ́ nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, àwọn méjèèjì sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sìn ín tọkàntọkàn. Iṣẹ́ káfíńtà ni bàbá mi ń ṣe wọ́n sì máa ń gbẹ́ ère Jésù, àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n lo ìmọ̀ káfíńtà tí wọ́n ní láti fi tún ìsàlẹ̀ ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì wa ṣe, wọ́n sì sọ ọ́ di Ilé Ìpàdé àkọ́kọ́ ní San Juan del Monte. Ó wà lágbègbè kan ní Manila tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Philippines.
Lẹ́yìn tí wọ́n bí mi ní 1952, wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bí wọ́n ṣe kọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́rin àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́ta. Bí mo ṣe ń dàgbà, bàbá mi sọ fún mi pé kí n máa ka orí Bíbélì kan lójoojúmọ́, oríṣiríṣi ìwé ètò Ọlọ́run ni wọ́n sì fi kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn òbí mi máa ń gba àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì lálejò sílé wa. Ìrírí táwọn arákùnrin yìí máa ń sọ máa ń múnú wa dùn gan-an, ó sì jẹ́ ká fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣáájú láyé wa.
Àwọn òbí mi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, mo sì kọ́ ohun tó pọ̀ lára wọn. Lẹ́yìn tí màmá mi ṣàìsàn, tí wọ́n sì kú, èmi àti bàbá mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1971. Àmọ́ lọ́dún 1973 nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún (20) ọdún, bàbá mi náà kú. Nígbà tí mo pàdánù àwọn méjèèjì, gbogbo nǹkan tojú sú mi, mo sì dá wà. Àmọ́ ìrètí tó ‘dájú tó sì fìdí múlẹ̀’ tó wà nínú Bíbélì ló jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. (Héb. 6:19) Kò pẹ́ tí bàbá mi kú ni mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní erékùṣù Coron, ní ìpínlẹ̀ Palawan.
MO DÁ WÀ NÍGBÀ ÌṢÒRO LẸ́NU IṢẸ́ MI
Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni mí nígbà tí mo dé erékùṣù Coron. Torí pé ìlú ńlá ni mo dàgbà sí, ẹnu yà mí gan-an nígbà tí mo rí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ síná ìjọba, kò fi bẹ́ẹ̀ sómi, ohun ìrìnnà ò sì pọ̀ lérékùṣù náà. Àwọn ará tó wà níbẹ̀ ò pọ̀, kò sì sí aṣáájú-ọ̀nà tá a lè jọ máa ṣiṣẹ́, torí náà nígbà míì mo máa ń dá wàásù.
Lóṣù àkọ́kọ́ tí mo débẹ̀, àárò àwọn ará ilé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sọ mí gan-an. Tó bá dalẹ́, mo máa ń gbójú sókè wo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, omi á wá lé ròrò sí mi lójú. Ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n fi iṣẹ́ mi sílẹ̀ kí n sì pa dà sílé.Láwọn àsìkò tí mo dá wà yẹn, mo máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Mo máa ń rántí àwọn nǹkan tí mo kà nínú Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run, ó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Mo sábà máa ń rántí ohun tó wà ní Sáàmù 19:14. Mo mọ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ “Àpáta mi àti Olùràpadà mi” tí mo bá ṣàṣàrò nípa nǹkan tó fẹ́, irú bí iṣẹ́ àgbàyanu ẹ̀ àti àwọn ànímọ́ ẹ̀. Àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kan tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Iwọ Ko Si Ni Iwọ Nìkan Láé” a ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Mo kà á ní àkàtúnkà. Ká sòótọ́, mo dá wà, àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú mi láwọn àkókò yẹn, ìyẹn sì fún mi láyè láti máa gbàdúrà, kí n máa kẹ́kọ̀ọ́, kí n sì máa ṣàṣàrò.
Kò pẹ́ tí mo dé Coron ni mo di alàgbà. Torí pé èmi nìkan ni alàgbà tó wà níbẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Mo tún máa ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àbí ẹ ò rí i pé mi ò dá wà mọ́ torí ọwọ́ mi dí gan-an!
Mo gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tí mo ṣe ní Coron. Àwọn kan lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi nígbà tó yá. Àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó mú kí nǹkan nira. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tí mo máa ń rìn látàárọ̀ títí dọ̀sán kí n tó dé ibi tí màá ti wàásù, mi ò sì ní mọ ibi tí màá sùn sí. Ọ̀pọ̀ erékùṣù kéékèèké wà lára àwọn ibi tá a ti máa ń wàásù, ọkọ̀ ojú omi ni mo sì sábà máa ń wọ̀ débẹ̀. Ìgbà míì wà tí ìjì líle máa ń jà, bẹ́ẹ̀ sì rèé mi ò mọ odò wẹ̀! Àmọ́, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ jálẹ̀ gbogbo àkókò tí nǹkan nira yẹn. Nígbà tó yá mo wá mọ̀ pé ńṣe ni Jèhófà ń múra mi sílẹ̀ de àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
MO LỌ SÌN NÍ PAPUA NEW GUINEA
Ní 1978, wọ́n rán mi lọ sí Papua New Guinea tó wà ní àríwá Ọsirélíà. Òkè pọ̀ gan-an ní Papua New Guinea, orílẹ̀-èdè yìí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé àwọn èèyàn tí kò tó mílíọ̀nù mẹ́ta ń sọ èdè tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) lọ. Àmọ́, inú mi dùn pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbébẹ̀ ń sọ èdè Píjìn Melanesia, tí wọ́n ń pè ní Tok Pisin.
Wọ́n ní kí n dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì fúngbà díẹ̀. Ìjọ náà wà ní Port Moresby tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn náà, mo lọ síjọ tó ń sọ èdè Tok Pisin, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè náà. Mo máa ń lo ohun tí mo kọ́ nínú èdè náà tí mo bá ń wàásù, ìyẹn sì jẹ́ kí n tètè mọ èdè náà sọ. Kò pẹ́ rárá tí mo fi sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn lédè Tok Pisin. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé kò tíì pé ọdún kan tí mo dé Papua New Guinea ni wọ́n ní kí n di alábòójútó àyíká láwọn ìjọ tó ń sọ èdè Tok Pisin, àwọn agbègbè táwọn ìjọ náà wà sì tóbi gan-an.
Torí pé àwọn ìjọ tó wà lágbègbè yẹn jìnnà síra gan-an, ó gba pé kí n máa rìnrìn àjò káàkiri kí n lè ṣètò ọ̀pọ̀ àpéjọ àyíká. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò mi, ó ń ṣe mí bíi pé mo dá wà torí pé àlejò ni mí lórílẹ̀-èdè náà, mi ò gbọ́ èdè wọn, mi ò sì mọ àṣà ìbílẹ̀ wọn. Mi ò lè wọ mọ́tò lọ sáwọn ìjọ tí mo fẹ́ bẹ̀ wò torí pé òkè
pọ̀ níbẹ̀, ọ̀nà wọn sì rí gbágungbàgun. Torí náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń wọkọ̀ òfúrufú tí mo bá fẹ́ rìnrìn àjò. Nígbà míì, èmi nìkan ló máa ń wà nínú ọkọ̀ òfúrufú tí ẹ́ńjìnnì ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ dáa. Bí ọkàn mi kì í ṣe balẹ̀ tí mo bá wọkọ̀ ojú omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi kì í balẹ̀ tí mo bá wà nínú ọkọ̀ òfúrufú.Torí pé àwọn èèyàn tó ní fóònù ò pọ̀ lágbègbè yẹn, lẹ́tà ni mo máa ń kọ tí mo bá fẹ́ bá àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, kí wọ́n tó rí lẹ́tà tí mo kọ sí wọn, màá ti dé, ìyẹn sì máa ń gba pé kí n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè ibi tí ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti rí àwọn ará, inú wọn máa ń dùn, wọ́n máa ń tọ́jú mi dáadáa, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n rí i pé ìsapá mi ò já sásán. Ní gbogbo àsìkò yẹn, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà, mo sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.
Ní ìpàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ ní erékùṣù Bougainville, tọkọtaya kan wá bá mi, wọ́n rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n sì bi mí pé: “Ṣé ẹ rántí wa?” Mo rántí pé mo wàásù fún tọkọtaya náà nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Port Moresby. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ nígbà tí mo fẹ́ kúrò níbẹ̀, mo ní kí arákùnrin kan máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn méjèèjì ti ṣèrìbọmi báyìí! Ọ̀kan lára ohun rere tí Jèhófà ṣe fún mi nìyẹn lọ́dún mẹ́ta tí mo lò ní Papua New Guinea.
ÌDÍLÉ KÉKERÉ TÓ Ń ṢIṢẸ́ TÓ PỌ̀
Kí n tó kúrò ní erékùṣù Coron lọ́dún 1978, mo mọ arábìnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Adel, ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn gan-an. Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni, ó sì ń dá tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Samuel àti Shirley. Lákòókò yẹn, ó tún ń tọ́jú màmá ẹ̀ tó ti dàgbà. Ní May 1981, mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Philippines kí n lè gbé Adel níyàwó. Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, à ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, a sì ń bójú tó ìdílé wa.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ní ìdílé, lọ́dún 1983 ètò Ọlọ́run ní kí n pa dà máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán mi lọ sí Erékùṣù Linapacan ní agbègbè Palawan. Ìdílé wa ṣí lọ síbi àdádó yìí, àmọ́ kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, màmá Adel kú, àmọ́ ohun tó jẹ́ ká lè fara da àdánù náà ni pé iṣẹ́ ìwàásù la gbájú mọ́. A bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Linapacan, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú. Kò pẹ́ rárá tá a fi rí i pé ó yẹ ká ní Ilé Ìpàdé. Torí náà, a kọ́ Ilé Ìpàdé kékeré kan. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta péré tá a débẹ̀, inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí i pé àwọn àádọ́fà (110) ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn tá a kúrò níbẹ̀.
Ní 1986, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ sí erékùṣù Culion níbi tí àgọ́ àwọn adẹ́tẹ̀ wà. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n sọ Adel di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ẹ̀rù kọ́kọ́ máa ń bà wá láti wàásù fáwọn adẹ́tẹ̀. Àmọ́, àwọn ará tó wà níbẹ̀ fọkàn wa balẹ̀ pé àwọn tó ní àrùn náà ti gba ìtọ́jú tó yẹ, torí náà kò fi bẹ́ẹ̀ séwu. Àwọn kan lára wọn máa ń wá sípàdé nílé arábìnrin kan. Kò pẹ́ tí ara wa fi balẹ̀ láti máa sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn tó rò pé Ọlọ́run ò rí tiwọn rò, tí aráyé sì ń sá fún yìí, a sì ń gbádùn iṣẹ́ náà. Inú wa dùn pé àwọn tó ní àìsàn tó le yìí ń láyọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n Lúùkù 5:12, 13.
mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, kò ní sí àìsàn náà mọ́.—Báwo lara àwọn ọmọ wa ṣe mọlé nígbà tá a dé Culion? Èmi àti Adel ní káwọn arábìnrin méjì wá láti Coron kí wọ́n lè máa gbé ọ̀dọ̀ wa. Ọ̀dọ́ ni wọ́n, ìyẹn á sì jẹ́ káwọn ọmọ wa láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Inú Samuel àti Shirley ọmọ wa àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin náà máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. Àwọn ọmọdé tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀, èmi àti Adel sì ń kọ́ òbí àwọn ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́. Kódà nígbà tó yá, à ń kọ́ ìdílé mọ́kànlá (11) lẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tá a débẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, torí náà a dá ìjọ tuntun sílẹ̀.
Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, èmi nìkan ni alàgbà tó wà lágbègbè náà. Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí n máa darí ìpàdé ní Culion lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwa mẹ́jọ tá a ti ń wàásù la sì máa ń pé jọ síbẹ̀. Wọ́n tún ní kí n máa lọ darí ìpàdé ní abúlé tí wọ́n ń pè ní Marily, àwọn ará mẹ́sàn-án táwọn náà ti ń wàásù ló wà níjọ yẹn, mo sì máa ń rìnrìn àjò wákàtí mẹ́ta lórí omi kí n tó lè débẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé, ọ̀pọ̀ wákàtí la fi máa ń rìn gba àwọn agbègbè olókè lọ sí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Halsey ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá sínú òtítọ́ ní Marily àti Halsey, a sì kọ́ Ilé Ìpàdé sí ìlú méjèèjì. Ohun táwọn ará ní Linapacan ṣe nígbà tí wọ́n kọ́ Ilé Ìpàdé làwọn ará ní Marily àti Halsey ṣe. Àwọn ará ìjọ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló pèsè ọ̀pọ̀ lára nǹkan tá a fi kọ́lé náà, wọ́n sì tún ṣiṣẹ́ kára níbẹ̀. Ilé Ìpàdé tó wà ní Marily lè gba ọgọ́rùn-ún méjì (200) èèyàn, ó sì tún fẹ̀ débi pé a lè ṣe àpéjọ àyíká níbẹ̀.
INÚ MI BÀ JẸ́, MO DÁ WÀ, ÀMỌ́ MO PA DÀ LÁYỌ̀
Ní 1993 táwọn ọmọ wa ti dàgbà, èmi àti Adel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Philippines. Lẹ́yìn náà lọ́dún 2000, mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere, wọ́n ní kí n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí n lè máa kọ́ àwọn ará nílé ẹ̀kọ́ náà. Ó ń ṣe mí bíi pé iṣẹ́ yìí ju agbára mi lọ, àmọ́ ìgbà gbogbo ni Adel ń tì mí lẹ́yìn. Ó máa ń rán mi létí pé Jèhófà máa fún mi lágbára tí màá fi ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún mi Fílí. 4:13) Ohun tó jẹ́ kí Adel sọ bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà ń ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ẹ̀ láṣeyọrí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ẹ̀ ò le.
yìí. (Nígbà tí mo ṣì ń dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ lọ́dún 2006, àyẹ̀wò ilé ìwòsàn fi hàn pé Adel ní àìsàn Parkinson. Jìnnìjìnnì bò wá! Nígbà tí mo dábàá pé ká fiṣẹ́ wa sílẹ̀ ká lè ráyè tọ́jú ẹ̀, ó sọ pé, “Jọ̀ọ́ wá dókítà tó lè bá mi wo àìsàn mi, mo sì mọ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ wa nìṣó.” Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, Adel ṣì ń ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó, kò sì ráhùn. Nígbà tí kò lè rìn mọ́, ó máa ń jókòó sórí kẹ̀kẹ́ aláìlera, á sì máa wàásù. Nígbà tí ò lè sọ̀rọ̀ púpọ̀ mọ́, ó máa ń sọ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì tó bá ń dáhùn nípàdé. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń fọ̀rọ̀ ránsẹ́ sí Adel títí tó fi kú lọ́dún 2013. Wọ́n máa ń sọ fún un pé àwọn mọyì ìfaradà ẹ̀ àti pé àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́. Olólùfẹ́ mi dúró tì mí gbágbáágbá, ó sì ju ọgbọ̀n (30) ọdún lọ tá a fi wà pa pọ̀, àmọ́ nígbà tó kú, inú mi bà jẹ́, mo sì dá wà.
Ohun tí Adel fẹ́ ni pé kí n máa ṣiṣẹ́ ìsìn mi nìṣó, ohun tí mo sì ṣe nìyẹn. Mo gbájú mọ́ iṣẹ́ náà, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n dá wà mọ́. Láti ọdún 2014 sí 2017, wọ́n ní kí n máa bẹ àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Tagalog wò láwọn orílẹ̀-èdè tá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lábẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo bẹ àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Tagalog wò lórílẹ̀-èdè Taiwan, Amẹ́ríkà àti Kánádà. Lọ́dún 2019, mo darí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere lédè Gẹ̀ẹ́sì lórílẹ̀-èdè Íńdíà àti Thailand. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí jẹ́ kí n láyọ̀ gan-an. Mo wá rí i pé bí mo ṣe gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lásìkò tí nǹkan nira yẹn ló múnú mi dùn jù lọ.
JÈHÓFÀ Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́ NÍGBÀ GBOGBO
Tí mo bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ibi tí wọ́n rán mi lọ, mo máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tó wà níbẹ̀ débi pé kì í rọrùn fún mi láti fi wọ́n sílẹ̀ tí mo bá fẹ́ kúrò níbẹ̀. Nírú àkókò yẹn, mo máa ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Mo máa ń rí ọwọ́ Jèhófà lára mi nígbà gbogbo, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n lè fara mọ́ ìyípadà tó bá wáyé nínú iṣẹ́ mi. Ní báyìí, mò ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Philippines. Ara mi ti mọlé nínú ìjọ tuntun tí mo wà, àwọn ará ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an, wọ́n sì ń tọ́jú mi. Mo tún ń fi Samuel àti Shirley yangàn torí wọ́n nígbàgbọ́ bíi màmá wọn.—3 Jòh. 4.
Mo ti rí àwọn àdánwò nígbèésí ayé mi títí kan bí àìsàn tó le ṣe fìyà jẹ olólùfẹ́ mi tó sì pa á. Oríṣiríṣi nǹkan ni mo ti fara dà. Síbẹ̀, mo rí i pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ọwọ́ Jèhófà “kò kúrú” rárá láti ràn wá lọ́wọ́, ó sì máa ń fún wa lókun, kódà tá a bá wà ní àdádó. (Àìsá. 59:1) Jèhófà, Àpáta mi ti wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ìgbésí ayé mi, mo sì ń dúpẹ́ oore tó ṣe fún mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo dá wà, Jèhófà wà pẹ̀lú mi.