Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
Ọ̀PỌ̀ àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ wà lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí onítara tó ń sìn láwọn ilẹ̀ tí àìní gbé pọ̀. Àwọn kan lára wọn ti ń sìn lórílẹ̀-èdè míì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà yẹn tí wọ́n fi pinnu láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì? Kí ni wọ́n ti rí kọ́ bí wọ́n ṣe ń sìn lórílẹ̀-èdè míì? Báwo ni ìgbésí ayé wọn ṣe rí lónìí? Díẹ̀ lára àwọn arábìnrin yìí sọ ìrírí wọn fún wa. Tó bá jẹ́ pé arábìnrin tí ò tíì lọ́kọ ni ẹ́, tó sì wù ẹ́ láti lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ aláyọ̀ náà, ó dá wa lójú pé wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀rọ̀ táwọn arábìnrin tó nírìírí yìí sọ. Ká sòótọ́, gbogbo wa pata la máa jàǹfààní látinú ìrírí wọn.
TÓ BÁ Ń ṢE Ẹ́ BÍI PÉ O Ò NÍ LÈ ṢE É
Tó bá jẹ́ pé o kò tíì lọ́kọ, ǹjẹ́ o máa ń ronú pé, ‘ṣé màá lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì?’ Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Anita tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin [70] ọdún náà rò pé òun ò ní lè ṣe é. Orílẹ̀-èdè England ló dàgbà sí, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18]. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ràn kí n máa kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, àmọ́ mi ò rò ó rí pé mo lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Mi ò kọ́ èdè míì rí, mi ò sì rò pé mo létí èdè. Torí náà, nígbà tí wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ńṣe làyà mi là gààràgà. Ó yà mí lẹ́nu pé irú èmi yìí ni wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àmọ́ mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Tí Jèhófà bá ní mo lè ṣe é, èmi náà á gbìyànjú.’ Ohun tí mò ń sọ yìí ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún báyìí. Látìgbà yẹn ni mo ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Japan.” Anita wá fi kún un pé: “Mo máa ń sọ fáwọn arábìnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ pé, ‘Ẹ gbé báàgì yín kẹ́ ẹ jẹ́ ká jọ gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.’ Inú mi sì dùn láti sọ pé ọ̀pọ̀ ló ti ṣe bẹ́ẹ̀.”
BÓ O ṢE LÈ ṢỌKÀN AKIN
Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tó ti sìn lórílẹ̀-èdè míì ló jẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ lọ́ra láti gbé ìgbésẹ̀ yẹn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi pinnu láti lọ?
Arábìnrin Maureen tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún sọ pé: “Nígbà tí mò ń dàgbà, ohun tó wù mí ni pé kí n máa ran àwọn míì lọ́wọ́.” Nígbà tó pé ọmọ ogún [20] ọdún, ó kó lọ sí ìlú Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà níbi tí wọ́n ti nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà púpọ̀ sí i. Ó sọ pé: “Nígbà tó yá, wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àmọ́ ẹ̀rù bà mí torí wọ́n lè rán mi lọ sí ilẹ̀ àjèjì tí mi ò ti mọ ẹnikẹ́ni. Àti pé màmá mi ló ń tọ́jú bàbá mi tó ń ṣàìsàn, mi ò sì fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀. Mi ò lè ka iye ọjọ́ tí mo fi ń bẹ Jèhófà lálaalẹ́ pẹ̀lú omijé pé kó tọ́ mi sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí mo ṣàlàyé ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn fáwọn òbí mi, wọ́n ní kí n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Mo tún rí bí
àwọn ará ìjọ ṣe dúró ti àwọn òbí mi. Bí mo ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ náà jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀. Èyí ló sì jẹ́ kí n múra tán láti lọ.” Àtọdún 1979 ni Maureen ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ó sì ṣe é fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún. Ní báyìí, Arábìnrin Maureen ń tọ́jú màmá rẹ̀ ní Kánádà, ó sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Arábìnrin Maureen sọ nípa gbogbo ọdún tó fi sìn lórílẹ̀-èdè míì, ó ní: “Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń pèsè ohun tí mo nílò lásìkò tí mo nílò rẹ̀ gan-an.”Ìgbà tí Arábìnrin Wendy wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Ọsirélíà, ó sì ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún báyìí. Ó sọ pé: “Ojú máa ń tì mí, àyà mi sì máa ń já tí mo bá fẹ́ bá ẹni tí mi ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Àmọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ kí n nígboyà láti bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀, bó ṣe di pé ojú kì í tì mí mọ́ nìyẹn. Yàtọ̀ sí pé ojú kì í tì mí mọ́, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tún kọ́ mi láti gbára lé Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Arábìnrin kan tí kò lọ́kọ tó sì ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Japan fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún sọ pé kí n wá ká jọ ṣiṣẹ́ ìwàásù ní Japan fún oṣù mẹ́ta. Bí mo ṣe bá a ṣiṣẹ́ tún jẹ́ kó túbọ̀ wù mí láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì.” Nígbà tó di nǹkan bí ọdún 1985, Arábìnrin Wendy kó lọ sí Vanuatu, ìyẹn erékùṣù kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì kìlómítà sí ìlà oòrùn Ọsirélíà.
Arábìnrin Wendy ṣì ń báṣẹ́ lọ ní Vanuatu, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè ló sì ti ń sìn báyìí. Ó sọ pé: “Mò ń láyọ̀ bí mo ṣe ń rí i tí wọ́n ń dá àwọn ìjọ tuntun àti àwùjọ sílẹ̀ láwọn àgbègbè yìí. Àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ fún mi pé èmi náà tiẹ̀ ṣe ìwọ̀nba díẹ̀ nínú iṣẹ́ Jèhófà lágbègbè yìí.”
Arábìnrin Kumiko náà ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún. Nígbà tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Japan, ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà dábàá pé kí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Nepal. Arábìnrin Kumiko sọ pé: “Arábìnrin yìí ń rọ̀ mí ṣáá pé ká lọ, àmọ́ mo ní mi ò lọ. Ohun tó ń ṣe mí ni pé bóyá ni màá lè kọ́ èdè tuntun, àti pé bóyá ni mo lè gbé ibòmíì. Yàtọ̀ síyẹn, mi ò lówó tó tó láti fi rìnrìn-àjò lọ sórílẹ̀-èdè míì. Mo ṣáà ń ro gbogbo ẹ̀, kò pẹ́ sígbà yẹn ni mọ́tò kọ lù mí lórí alùpùpù mi, wọ́n sì gbé mi lọ sílé ìwòsàn. Bí mo ṣe wà nílé ìwòsàn, mò ń ronú pé: ‘Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, ta ló mọ ohun tó tún máa ṣẹlẹ̀ sí mi? Tí àìsàn kan bá lọ gbé mi dè báyìí, mi ò ní lè lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè míì nìyẹn. Ṣé èmi náà ò tiẹ̀ lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì bó tiẹ̀ jẹ́ fún ọdún kan péré?’ Mo wá bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè lọ.” Lẹ́yìn tí Kumiko kúrò nílé ìwòsàn, ó lọ sí Nepal kó lè mọ bí ibẹ̀ ṣe rí, nígbà tó yá, òun àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kúkú wá kó lọ síbẹ̀.
Nígbà tí Arábìnrin Kumiko ronú lórí nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tó ti lò ní Nepal, ó ní: “À ṣé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lásán ni gbogbo ìṣòro tí mò ń rò nígbà yẹn, wọn ò tó nǹkan tó yẹ kó máa kó mi lọ́kàn sókè. Inú mi dùn gan-an pé mo wá sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ń kọ́ ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́, ńṣe làwọn bíi márùn-ún sí mẹ́fà tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò máa wá bá wa níbẹ̀ káwọn náà lè gbọ́ ohun tá à ń sọ. Kódà, àwọn ọmọ kéékèèké máa ń wá bá mi pé kí n fún àwọn ní ìwé kékeré kan tó ń sọ nípa Bíbélì. Inú mi dùn gan-an láti wàásù lágbègbè yìí, torí pé àwọn èèyàn máa ń gbọ́ ìwàásù dáadáa.”
BÍ WỌ́N ṢE BORÍ ÌṢÒRO
Àwọn arábìnrin akínkanjú tí kò lọ́kọ yìí náà dojú kọ àwọn ìṣòro kan. Àmọ́, kí ni wọ́n ṣe?
Arábìnrin Diane tó wá láti Kánádà ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún, ó sì ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ogún [20] ọdún lórílẹ̀-èdè Ivory Coast (tá a mọ̀ sí Côte d’Ivoire báyìí). Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti fi ìdílé mi sílẹ̀. Mo wá bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà níbi tí mo ti ń sìn. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó ń jẹ́ Jack Redford sọ fún wa pé, tá a bá kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn ohun tá a máa rí lè yà wá lẹ́nu, pàápàá tá a bá rí bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn èèyàn. Ó wá sọ fún wa pé: ‘Àwọn èèyàn náà ni kẹ́ ẹ gbájú mọ́, ẹ má jẹ́ kí ipò tẹ́ ẹ bá wọn lé yín sá. Ojú wọn ni kẹ́ ẹ máa wò. Kẹ́ ẹ máa kíyè sí bí inú wọn ṣe ń dùn láti gbọ́ òtítọ́ Bíbélì.’ Ohun tí mo ṣe gan-an nìyẹn, èyí sì fún mi láyọ̀. Tí mo bá ń wàásù fáwọn èèyàn náà, mo máa ń rí i lójú wọn pé ọ̀rọ̀ yẹn ń múnú wọn dùn.” Kí ló tún ran Arábìnrin Diane lọ́wọ́ tára ẹ̀ fi mọlé níbi tó ti ń sìn? Ó sọ pé: “Mo sún mọ́ àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, mo sì ń láyọ̀ bí mo ṣe rí i tí wọ́n ń di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ibí ti wá di ilé mi báyìí. Bí Jésù ṣe sọ, mo tún ti ní ọ̀pọ̀ bàbá, màmá, arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ètò Jèhófà.”
Arábìnrin Anne ti lé lẹ́ni ogójì [40] ọdún, ilẹ̀ Asia ló ti ń sìn níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Ó sọ pé: “Mo ti sìn níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ìwà wọn yàtọ̀ sí tèmi ni mo sì bá gbé. Èyí máa ń fa àìgbọ́ra-ẹni-yé nígbà míì. Tó bá ti ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, mo máa ń sapá láti sún mọ́ wọn kí n lè túbọ̀ lóye wọn. Mo tún sapá kí n lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kí n sì máa gba tiwọn rò. Inú mi dùn pé gbogbo ìsapá mi ò já sásán, mo sì ti láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó ń mú kí n lè máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi.”
Orílẹ̀-èdè Jámánì ni Arábìnrin Ute tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún ti wá. Lọ́dún 1993, ètò Ọlọ́run ní kó lọ
máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Madagascar. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀, mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti kọ́ èdè wọn. Ooru tó wà níbẹ̀ kò bá mi lára mu, àrùn ibà ò sì jẹ́ kí n gbádùn títí kan àwọn kòkòrò àti aràn. Àmọ́, àwọn ará ò fi mí sílẹ̀. Àwọn arábìnrin, àwọn ọmọ wọn àtàwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ kí n gbọ́ èdè náà dáadáa. Arábìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ló máa ń tọ́jú mi tára mi ò bá yá. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn fún un nínú àdúrà. Màá wá ṣe sùúrù kó dá mi lóhùn, nígbà míì mo lè dúró fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ó sì lè jẹ́ ọ̀pọ̀ oṣù pàápàá kó tó dáhùn àdúrà mi. Kí n sòótọ́, kò sí ìṣòro tí Jèhófà ò bá mi yanjú.” Arábìnrin Ute ti lò tó ọdún mẹ́tàlélógún [23] níbi tó ti ń sìn ní Madagascar.JÈHÓFÀ BÙ KÚN WỌN
Bíi tàwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ tó ń sìn lórílẹ̀-èdè míì sọ pé iṣẹ́ náà ń mú ìbùkún wá. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí gbà?
Orílẹ̀-èdè Jámánì ni Arábìnrin Heidi ti wá. Ó ti lé lẹ́ni àádọ́rin [70] ọdún báyìí, ó sì ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire láti ọdún 1968. Ó sọ pé: “Ohun tó ń fún mi láyọ̀ jù ni bí mo ṣe ń rí i tí àwọn tó dà bí ọmọ fún mi nínú ètò Jèhófà ń ‘bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.’ Àwọn kan tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí, àwọn míì sì ti di alàgbà. Ọ̀pọ̀ wọn máa ń pè mí ní Màmá tàbí Màmá àgbà. Ńṣe ni ìdílé ọ̀kan lára àwọn tó di alàgbà yìí mú mi bí màmá wọn. Torí náà, mo lè sọ pé Jèhófà ti fún mi ní àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ-ọmọ.”
Arábìnrin Karen tó wá láti orílẹ̀-èdè Kánádà ti lé lẹ́ni àádọ́rin [70] ọdún, ó sì ti sìn fún ohun tó lé lógún [20] ọdún ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa lo ara mi fáwọn míì, kí n túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn, kí n sì túbọ̀ máa ṣe sùúrù. Bákan náà, bí mo ṣe ń bá àwọn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ ti jẹ́ kí n túbọ̀ lóye àwọn èèyàn dáadáa. Mo wá rí i pé oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè gbà ṣe nǹkan. Yàtọ̀ síyẹn, inú mi dùn pé mo ti wá ní àwọn ọ̀rẹ́ kárí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wa wà báyìí, síbẹ̀ okùn ọ̀rẹ́ wa kò já.”
Arábìnrin Margaret ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, orílẹ̀-èdè England ló ti wá, ó sì ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Laos. Ó sọ pé: “Àǹfààní tí mo ní láti sìn lórílẹ̀-èdè míì ti jẹ́ kí n rí bí Jèhófà ṣe ń fa onírúurú èèyàn láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sínú ètò rẹ̀. Ohun tí mo rí yìí túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ mi lókun gan-an, ó sì túbọ̀ jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀ àti pé àwọn ohun tó ní lọ́kàn máa ṣẹ.”
Àbí ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá làwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ yìí ń ṣe bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lórílẹ̀-èdè míì! Ó yẹ ká gbóríyìn fún wọn gan-an. (Oníd. 11:40) Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ṣe ni iye wọn ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. (Sm. 68:11) Wá bi ara rẹ pé, ṣé èmi náà lè ṣètò ara mi kí n lè ṣe bíi tàwọn arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá tọ́ ọ wò, ‘wàá sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà.’