O Lè Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Bí Kò Bá Tiẹ̀ Rọrùn
“Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.”
ORIN: 48, 95
1-3. Kí ni wòlíì tó wá láti Júdà yẹn kò ṣe, kí ló sì yọrí sí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
NÍGBÀ ìṣàkóso Jèróbóámù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà rán wòlíì kan láti ìlú Júdà pé kó lọ kéde ìdájọ́ mímúná fún Ọba Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà yìí. Wòlíì yìí fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Jèhófà sì dáàbò bò ó kí Jèróbóámù má bàa pa á.
2 Nígbà tí wòlíì yìí ń pa dà sílé, bàbá àgbàlagbà kan tó wá láti ìlú Bẹ́tẹ́lì pàdé rẹ̀. Bàbá náà sọ pé wòlíì Jèhófà ni òun, ó tan ọ̀dọ́kùnrin yẹn jẹ, ó sì mú kó ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Jèhófà fún un pé ‘kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní Ísírẹ́lì,’ bákan náà ‘kò gbọ́dọ̀ tún gba ọ̀nà tó gbà lọ pa dà.’ Inú Jèhófà ò dùn sí ohun tí wòlíì yìí ṣe, tórí náà bó ṣe ń lọ sílé, kìnnìún kan pàdé rẹ̀, ó sì pa á.
3 Kí nìdí tí wòlíì tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ yìí fi gbà kí bàbá yẹn tan òun jẹ? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ṣe ló gbàgbé pé ó yẹ kóun ṣì jẹ́ ‘amẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run òun rìn.’ (Ka Míkà 6:8.) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá ń bá Jèhófà rìn, onítọ̀hún á gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, á sì jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà. Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun máa bá Jèhófà Baba òun sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo. Wòlíì yẹn ò bá ti béèrè ohun tó yẹ kóun ṣe lọ́wọ́ Jèhófà kó tó ṣe é, àmọ́ Bíbélì ò sọ fún wa pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, ìkọjá àyè sì nìyẹn. Nígbà míì, àwa náà lè fẹ́ ṣe ìpinnu tó lágbára, a sì lè má mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, àá bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká má bàa ṣàṣìṣe.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni mọ̀wọ̀n ara wa àtàwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kéèyàn mọ̀ bóyá òun mọ̀wọ̀n ara òun àbí òun ò mọ̀wọ̀n ara òun? Kí ló máa mú ká mọ̀wọ̀n ara wa tí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa ń ṣẹlẹ̀, tó sì lè mú kó ṣòro fún wa láti mọ̀wọ̀n ara wa. A sì tún máa rí ohun tó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe nínú ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.
TÍ IPÒ WA BÁ YÍ PA DÀ
5, 6. Báwo ni Básíláì ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun?
5 Bí ipò nǹkan bá yí pa dà tàbí tí iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run bá yí pa dà, tá ò bá ṣọ́ra, a lè kọjá àyè wa. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára bàbá kan tó ń jẹ́ Básíláì tí Dáfídì ní kó wá máa gbé pẹ̀lú òun láàfin. Nǹkan iyì gbáà nìyẹn torí pé tó bá wà láàfin, kòríkòsùn lòun àti Dáfídì ì bá jẹ́. Àmọ́, Básíláì tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún yìí ò gbà láti gbé láàfin. Kí nìdí? Àgbàlagbà ni, torí náà ó sọ fún Dáfídì pé òun ò fẹ́ dẹ́rù pa á. Ìdí nìyẹn tí Básíláì fi ní kí Dáfídì mú Kímúhámù tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ dípò òun.
6 Torí pé Básíláì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Lóòótọ́ kò gbà láti gbé láàfin, àmọ́ kì í ṣe torí pé kò ní lè ṣe iṣẹ́ yẹn tàbí torí pé kò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni yọ òun lẹ́nu ní báyìí tóun ti dàgbà. Ó gbà pé nǹkan ò rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ àti pé ó níbi tágbára òun mọ. Kò fẹ́ ṣe ju ohun tágbára rẹ̀ gbé lọ. (Ka Gálátíà 6:4, 5.) Tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa dé ipò iwájú tàbí bá a ṣe máa gbayì ló gbà wá lọ́kàn, wẹ́rẹ́ báyìí ni ìgbéraga á wọ̀ wá lẹ́wù, àá sì máa figagbága pẹ̀lú àwọn míì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ wa lè má tẹ ohun tá à ń lé. (Gál. 5:26) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí ìmọ̀wọ̀n ara ẹni ló máa jẹ́ kí gbogbo wa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bá a ṣe ń lo àwọn ẹ̀bùn wa àti okun wa láti bọlá fún Ọlọ́run ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́.
7, 8. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká gbára lé òye tiwa?
7 Téèyàn bá gba àwọn àfikún iṣẹ́, ọlá àṣẹ tó ní lè pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìyẹn sì lè jẹ́ kó ṣòro fún un láti mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Nígbà tí Nehemáyà gbọ́ ìṣòro táwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní, ó gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà. (Neh. 1:4, 11) Jèhófà dáhùn àdúrà Nehemáyà. Ìdí sì ni pé Ọba Atasásítà sọ ọ́ di gómìnà àgbègbè Jerúsálẹ́mù kó lè ṣeé ṣe fún un láti ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò ọlá ni Nehemáyà wà, ó lówó ó sì lẹ́nu nílùú, kò gbára lé agbára rẹ̀ tàbí òye rẹ̀. Ó ń bá a lọ ní bíbá Ọlọ́run rìn. Gbogbo ìgbà ló ń ka Òfin Ọlọ́run kí Jèhófà lè tọ́ ọ sọ́nà. (Neh. 8:
8 Àpẹẹrẹ Nehemáyà jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò ní máa gbára lé òye rẹ̀ tó bá gba àfikún iṣẹ́ tàbí tí iṣẹ́ rẹ̀ bá yí pa dà nínú ètò Ọlọ́run. Báwo lẹnì kan ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé òye tàbí ìrírí rẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú ọ̀rọ̀ kan nínú ìjọ láì kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà. Àwọn míì sì lè ti Òwe 3:5, 6.) Nínú ayé, àwọn èèyàn máa ń wá bí wọ́n á ṣe wà nípò tó ga ju tàwọn míì lọ. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ, a kì í ronú pé a dáa ju àwọn míì lọ torí pé a láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbà pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wa, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.
TÍ WỌ́N BÁ ṢÀRÍWÍSÍ WA TÀBÍ TÍ WỌ́N YÌN WÁ
9, 10. Tí wọ́n bá ń ṣàríwísí wa, báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa á mọ́ra?
9 Kò sẹ́ni tí kì í dùn tí wọ́n bá ṣàríwísí rẹ̀, tírú ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, èèyàn lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ. Àmọ́ a kẹ́kọ̀ọ́ lára Hánà. Ọkọ Hánà fẹ́ràn rẹ̀ gan-an, àmọ́ Hánà ò rọ́mọ bí. Gbogbo ìgbà ló máa ń sunkún torí pé Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ máa ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Lọ́jọ́ kan tí Hánà ń gbàdúrà nínú àgọ́ ìjọsìn, Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ṣèèṣì fẹ̀sùn kàn án pé ó ti mutí yó. Ẹ rò ó wò ná, báwo ló ṣe máa rí lára Hánà? Kò fìyẹn pè, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ dá Élì lóhùn, kò sì bínú sí i. Hánà yin Jèhófà nínú àdúrà tó gbà, ó fọpẹ́ fún un, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ sì fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Kódà, àdúrà àtọkànwá tó gbà yẹn wà nínú Bíbélì.
10 Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, àá “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ìwà burúkú ló kún inú ayé Sátánì yìí, torí náà a gbọ́dọ̀ sapá káwọn èèyàn burúkú má bàa kó èèràn ràn wá. (Sm. 37:1) Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín àwa ará, ó máa ń dùn wá gan-an ju ká sọ pé ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣẹ̀ wá. Àmọ́, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù torí Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà . . . , ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:23) Jésù mọ̀ pé ti Jèhófà lẹ̀san. (Róòmù 12:19) Jèhófà rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká “má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe.”
11, 12. (a) Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, kí la ò ní ṣe táwọn èèyàn bá ń pọ́n wa ju bó ṣe yẹ lọ? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa tó bá dọ̀rọ̀ aṣọ wa, ìmúra wa àti ìwà wa?
11 Ohun tá a bá ṣe nígbà táwọn èèyàn bá ń pọ́n wa ju bó ṣe yẹ lọ ló máa fi hàn bóyá a mọ̀wọ̀n ara wa tàbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì tó fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní tí kò ronú kàn ni wọ́n fún un. Ó lẹ́wà bí egbin, wọ́n sì wá fi àwọn nǹkan aṣaralóge kẹ́ ẹ fún odindi ọdún kan. Jákèjádò ilẹ̀ Ọba Páṣíà ni wọ́n ti kó àwọn obìnrin jọ, gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ kí ọba gba tiwọn, àárín àwọn obìnrin yìí sì ni Ẹ́sítérì wà. Síbẹ̀, kò torí ìyẹn wá dẹni tó ń yájú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó ń bọ̀wọ̀ fúnni, ó sì tún jẹ́ onínúure kódà lẹ́yìn tí ọba yàn án pé kó jẹ́ olorì òun.
12 Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, irú aṣọ tá à ń wọ̀, ìmúra wa àti ìwà wa máa fi hàn pé a yẹ lẹ́ni téèyàn ń bọ̀wọ̀ fún. Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú tó dáa wò wá, kò dìgbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́nnu tàbí tá à ń ṣe àwọn nǹkan táwọn èèyàn á fi gba tiwa, ṣe ló yẹ ká ní ‘ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ìwà tútù.’ (Ka 1 Pétérù 3:3, 4; Jer. 9:23, 24) Ojú tá a fi ń wo ara wa máa hàn nínú bá a ṣe ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń ṣe sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, bá ò tiẹ̀ sọ ọ́ ní tààràtà, a lè dọ́gbọ́n máa sọ pé a ní àwọn àǹfààní kan táwọn míì ò ní tàbí pé a ní àwọn ìsọfúnni kan tí wọn ò ní, a sì lè máa ṣe bíi pé a sún mọ́ àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú jù wọ́n lọ. Ó sì lè jẹ́ pé àwa àtàwọn kan la jọ ṣe ohun kan láṣeyọrí, àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ bíi pé àwa nìkan la dá ṣe nǹkan náà. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìdí tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ohun tóun ń sọ ti wá, kì í ṣe ọgbọ́n orí òun àbí èrò òun.
TÁ A BÁ FẸ́ ṢÈPINNU
13, 14. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?
13 Nǹkan míì tó lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá a mọ̀wọ̀n ara wa ni ìgbà tó bá di pé ká ṣèpinnu. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Kesaréà, wòlíì Ágábù sọ fún un pé tó bá lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa mú un tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa á. Àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ ò fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù kú torí náà wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó má lọ. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò gbà. Kì í ṣe pé ó jọ ara rẹ̀ lójú tàbí pé ó ń bẹ̀rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó bá gbà lòun máa ṣe kóun lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun láṣeyọrí. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, wọ́n gba kámú, wọn ò sì dí i lọ́wọ́ mọ́.
14 Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, àá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání kódà tá ò bá mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Bí àpẹẹrẹ, bóyá a jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a lè máa ronú pé, tí n bá ṣàìsàn ńkọ́? Táwọn òbí mi tó ti ń dàgbà bá nílò àbójútó ńkọ́? Tí èmi náà bá dàgbà, ta ló máa tọ́jú mi? Kò sí bá a ṣe ṣèwádìí tó tá a máa rí gbogbo ìdáhùn tá à ń fẹ́ sáwọn ìbéèrè yìí. (Oníw. 8:
BÁ A ṢE LÈ MỌ̀WỌ̀N ARA WA
15. Tá a bá ń ṣàṣàrò nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká mọ̀wọ̀n ara wa?
15 Ní báyìí tá a ti mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó yẹ ká mọ àwọn ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́rin tá a lè ṣe. Ohun àkọ́kọ́ táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká sì máa bọlá fún Jèhófà ni pé ká máa ṣàṣàrò nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ipò rẹ̀. (Aísá. 8:13) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Ọlọ́run Olódùmarè là ń bá rìn, kì í ṣe áńgẹ́lì kan tàbí èèyàn kan. Mímọ̀ tá a mọ̀ bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká máa ‘rẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run.’
16. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká mọ̀wọ̀n ara wa?
16 Ohun kejì táá jẹ́ ká mọ̀wọ̀n ara wa ni pé ká máa ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà mú kí àwọn ẹ̀yà ara wa kan tá ò kà sí ní “ọlá tí ó pọ̀ jù lọ.” (1 Kọ́r. 12:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń bójú tó wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó níbi tágbára wa mọ. Kì í fi wá wé àwọn míì bẹ́ẹ̀ ni kì í pa wá tì tá a bá ṣàṣìṣe. Láìka iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Jèhófà sí, ọkàn wa máa ń balẹ̀ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.
17. Àǹfààní wo ló wà nínú ká máa wo ibi táwọn míì dáa sí?
17 Ohun kẹta ni pé ká ṣe bíi ti Jèhófà, ká máa wo ibi táwọn míì dáa sí, ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ mọyì iṣẹ́ táwa náà ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Kò yẹ kó jẹ́ pé àwa làwọn èèyàn á máa rí ṣáá tàbí pé àwa làá máa darí àwọn míì pé kí wọ́n ṣe tibí ṣe tọ̀hún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ wá sẹ́ni tó máa ń fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún un. (Òwe 13:10) Táwọn míì bá gba àwọn àfikún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, àá bá wọn yọ̀. Àá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe ń bù kún ‘gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé.’
18. Tá a bá ń fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa?
18 Ohun kẹrin táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ni pé ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, àá máa ṣèpinnu tó múnú rẹ̀ dùn. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá à ń gbàdúrà, tá a sì ń fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò, ẹ̀rí ọkàn wa á túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa. (1 Tím. 1:5) A tún gbọ́dọ̀ máa fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ‘parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa,’ á jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká sì tún ní àwọn ànímọ́ Kristẹni míì.
19. Kí ló máa mú ká jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà títí láé?
19 Àìgbọràn kan ṣoṣo tí wòlíì tó wá láti Júdà yẹn ṣe ló mú kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ àti ojúure Jèhófà. Àmọ́, ó ṣeé ṣe pé ká jẹ́ni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn rárá. Àwọn olóòótọ́ tó gbáyé láyé àtijọ́ àti lóde òní ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tá a sì ń bá Jèhófà rìn, bẹ́ẹ̀ náà làá túbọ̀ máa mọ̀wọ̀n ara wa. (Òwe 8:13) Iṣẹ́ yòówù ká máa ṣe nínú ètò Ọlọ́run báyìí, àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà rìn. Torí náà, mọyì àǹfààní tó o ní, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Jèhófà rìn títí láé.