Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Àwọn Tó Ń Sin Ọlọ́run Àtàwọn Tí Kò Sìn Ín

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Àwọn Tó Ń Sin Ọlọ́run Àtàwọn Tí Kò Sìn Ín

“Ẹ ó sì . . . rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú.”​MÁL. 3:18.

ORIN: 127, 101

1, 2. Ìṣòro wo làwa èèyàn Ọlọ́run ń kojú lónìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

Ọ̀PỌ̀ nọ́ọ̀sì àtàwọn dókítà ló ń tọ́jú àwọn tó ní àrùn tó lè ranni. Ìdí sì ni pé wọ́n fẹ́ ṣèrànwọ́ fún wọn. Àmọ́ bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn dáàbò bo ara wọn kí àrùn náà má bàa ràn wọ́n. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ wa là ń gbé tá a sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tí ìwà àti ìṣe wọn lòdì sí ìlànà Bíbélì, èyí sì lè fa ìṣòro fáwa èèyàn Ọlọ́run.

2 Ìwà burúkú ló kúnnú ayé lónìí. Nínú lẹ́tà kejì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ onírúurú ìwà abèṣe táwọn èèyàn tí kò mọ Ọlọ́run á máa hù, kódà ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣe lá máa burú sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. (Ka 2 Tímótì 3:​1-5, 13.) Ó bani lẹ́rù pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń hu àwọn ìwà yìí, tá ò bá sì ṣọ́ra wọ́n lè kéèràn ràn wá. (Òwe 13:20) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìwà táwọn èèyàn ń hù àti bíyẹn ṣe yàtọ̀ sáwọn ànímọ́ rere táwa èèyàn Jèhófà ní. A tún máa rí bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa ká má bàa dà bíi wọn bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá jọ́sìn Ọlọ́run.

3. Àwọn wo ló ń hu ìwà tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Tímótì 3:​2-5?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” máa jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Ó wá sọ àwọn ìwà burúkú mọ́kàndínlógún [19] táwọn èèyàn á máa hù lásìkò náà. Àwọn ìwà tó mẹ́nu bà jọra pẹ̀lú èyí tó sọ nínú Róòmù 1:​29-31, àmọ́ lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì sọ àwọn nǹkan kan tá ò lè rí níbòmíì nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn náà, “nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . ” Èyí fi hàn pé tọkùnrin tobìnrin ló ń hu irú àwọn ìwà yìí. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń hùwà bẹ́ẹ̀ torí pé ìwà rere làwa Kristẹni ń hù.​—Ka Málákì 3:18.

OJÚ TÁ A FI Ń WO ARA WA

4. Ṣàlàyé irú èèyàn tá a lè pè ní awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.

4 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé àwọn èèyàn máa jẹ́ olùfẹ́ ara wọn àti olùfẹ́ owó, ó ní wọ́n tún máa jẹ́ ajọra-ẹni-lójú, onírera àti awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga. Ẹ̀mí yìí làwọn tó gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ máa ń ní, bóyá torí ohun tí wọ́n lè ṣe, ẹwà wọn, ọrọ̀ wọn tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ. Àwọn tó nírú ẹ̀mí yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ kí wọ́n sì máa gbógo fún àwọn. Ọ̀mọ̀wé kan sọ ohun tí agbéraga èèyàn máa ń ṣe, ó ní: “Ó ka ara rẹ̀ sí ọlọ́run kan, ó sì máa ń júbà ara rẹ̀.” Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé agbéraga èèyàn kì í fẹ́ kí ẹlòmíì gbéra ga tàbí fọ́nnu lójú òun.

5. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wo ló di agbéraga, ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Jèhófà kórìíra ìgbéraga. Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ojú gíga fíofío.” (Òwe 6:​16, 17) Ìgbéraga máa ń jẹ́ kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. (Sm. 10:4) Èṣù lẹni tó ń gbéra ga fìwà jọ. (1 Tím. 3:6) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti jẹ́ kí ìgbéraga wọ àwọn lẹ́wù. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni Ùsáyà ọba Júdà fi sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Bíbélì sọ pé “gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọba Hesekáyà náà hùwà ìgbéraga, àmọ́ ó tètè ronú pìwà dà.​—2 Kíró. 26:16; 32:​25, 26.

6. Kí làwọn nǹkan tó lè mú kí Dáfídì gbéra ga, àmọ́ kí nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?

6 Àwọn kan ń gbéra ga torí pé wọ́n lẹ́wà, wọ́n gbayì, wọ́n morin kọ, wọ́n lágbára tàbí torí pé wọ́n wà nípò gíga. Gbogbo nǹkan yìí ni Dáfídì ní, síbẹ̀ ó fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Lẹ́yìn tó pa Gòláyátì, Ọba Sọ́ọ̀lù ní kó fi ọmọ òun ṣaya, àmọ́ Dáfídì sọ pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn ẹbí mi, ìdílé baba mi, ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò fi di ọkọ ọmọ ọba?” (1 Sám. 18:18) Kí ló mú kí Dáfídì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Ó gbà pé torí pé Jèhófà “rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀” tó sì kíyè sí òun lòun fi ní agbára tóun sì ṣe àṣeyọrí. (Sm. 113:​5-8) Dáfídì mọ̀ pé kò sóhun tóun ní tí kì í ṣe pé Jèhófà ló fún òun.​—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 4:7.

7. Kí ló máa jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

7 Bíi ti Dáfídì, àwa èèyàn Jèhófà náà ń sapá ká lè máa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Ó jọ wá lójú gan-an pé Jèhófà tó jẹ́ Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 18:35) A máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kól. 3:12) A tún mọ̀ pé ìfẹ́ “kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́r. 13:4) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà. Bí aya kan ṣe lè jèrè ọkọ rẹ̀ nípasẹ̀ ìwà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà.​—1 Pét. 3:1.

BÁ A ṢE Ń ṢE SÁWỌN ÈÈYÀN

8. (a) Ojú wo làwọn kan fi ń wo àìgbọràn sáwọn òbí? (b) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé káwọn ọmọ máa ṣe?

8 Pọ́ọ̀lù sọ báwọn èèyàn á ṣe máa ṣe síra wọn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ó sọ pé lọ́jọ́ ìkẹyìn, àwọn ọmọ máa jẹ́ aṣàìgbọràn sí òbí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé, fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n ń mú káwọn èèyàn gbà pé irú ìwà yìí kò burú, ó ṣe kedere pé àìgbọràn kì í jẹ́ kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan wà nínú ìdílé. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Gíríìsì àtijọ́, tí ọmọ kan bá lu òbí rẹ̀, kò ní láǹfààní sáwọn ẹ̀tọ́ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ máa ń ní. Bákan náà, lábẹ́ òfin ilẹ̀ Róòmù, ẹni tó bá ṣíwọ́ lu bàbá rẹ̀ jẹ̀bi ìpànìyàn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì rọ àwọn ọmọ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn.​—Ẹ́kís. 20:12; Éfé. 6:​1-3.

9. Kí ló máa ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn sáwọn òbí wọn?

9 Táwọn ọmọ kò bá fẹ́ máa hùwà bí àwọn ọmọ aláìgbọràn tó kúnnú ayé, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ronú nípa àwọn nǹkan dáadáa táwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Táwọn ọmọ bá gbà pé Jèhófà Baba wa ọ̀run ló pàṣẹ pé káwọn jẹ́ onígbọràn, á rọrùn fún wọn láti máa ṣègbọràn. Táwọn ọmọ bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn òbí wọn, àwọn ọmọ míì náà á kọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn nílé. Táwọn òbí kò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn dénú, kò ní yá àwọn ọmọ wọn lára láti máa ṣègbọràn sí wọn. Lọ́wọ́ kejì, tí ọmọ kan bá mọ̀ pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun dénú, òun náà á máa ṣe ohun táá múnú wọn dùn tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún un. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Austin sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n ṣàìgbọràn sáwọn òbí mi kí n sì mú un jẹ, àmọ́ mo máa ń ṣègbọràn sí wọn dáadáa torí pé wọ́n ti máa ń ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ní kí n má ṣe àwọn nǹkan kan, wọn kì í ṣe apàṣẹwàá, a sì jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa. Mo mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi dénú, torí náà mo máa ń ṣe ohun táá múnú wọn dùn.”

10, 11. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ tó fi hàn pé àwọn èèyàn ò ní nífẹ̀ẹ́ àwọn míì? (b) Báwo ni ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní sáwọn míì ṣe lágbára tó?

10 Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ìwà abèṣe míì tó fi hàn pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn míì. Lẹ́yìn tó mẹ́nu kan àwọn “aṣàìgbọràn sí òbí,” ó sọ pé àwọn èèyàn máa jẹ́ aláìlọ́pẹ́. Èyí bá a mu torí pé àwọn aláìlọ́pẹ́ kì í mọyì oore táwọn míì ṣe fún wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún sọ pé àwọn èèyàn á jẹ́ aláìdúróṣinṣin. Wọ́n á jẹ́ aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, tó túmọ̀ sí pé wọn kì í wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Wọ́n tún máa jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti afinihàn, wọ́n á máa sọ̀rọ̀ burúkú lòdì sí àwọn èèyàn àti Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa jẹ́ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, ìyẹn àwọn tó ń sọ̀rọ̀ tó lè ba àwọn míì lórúkọ jẹ́. *

11 Àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé torí pé àwa máa ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn èèyàn. Ohun tá a mọ àwa èèyàn Jèhófà mọ́ nìyẹn látọjọ́ tó ti pẹ́. Jésù sọ pé ìfẹ́ aládùúgbò, tó jẹ́ apá kan ìfẹ́ a·ga’pe ni òfin kejì tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin Mósè lẹ́yìn ìfẹ́ fún Ọlọ́run tó jẹ́ àkọ́kọ́. (Mát. 22:​38, 39) Jésù tún sọ pé ìfẹ́ ni wọ́n máa fi dá àwọn ojúlówó Kristẹni mọ̀. (Ka Jòhánù 13:​34, 35.) Kódà, àwọn Kristẹni máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.​—Mát. 5:​43, 44.

12. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn míì?

12 Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Ó ń lọ láti ìlú kan sí òmíì, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ó la ojú afọ́jú, ó mú àwọn arọ, adẹ́tẹ̀ àti adití lára dá. Kódà, ó jí òkú dìde. (Lúùkù 7:22) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ torí aráyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló kórìíra rẹ̀. Jésù ṣàgbéyọ ìfẹ́ Jèhófà Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Lọ́nà kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé.

13. Báwo ni ìfẹ́ tá à ń fi hàn sáwọn èèyàn ṣe lè mú kí wọ́n wá sin Jèhófà?

13 Ìfẹ́ tá à ń fi hàn sáwọn èèyàn máa ń mú kí wọ́n wá sin Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè Thailand. Orí rẹ̀ wú nígbà tó rí báwọn ará ṣe ń fìfẹ́ hàn síra wọn ní àpéjọ àgbègbè kan tó lọ. Nígbà tó pa dà délé, ó ní káwọn Ẹlẹ́rìí wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn ìbátan rẹ̀, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tó lọ sí àpéjọ yẹn, ó ṣe iṣẹ́ Bíbélì Kíkà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá à ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ran àwọn ará ilé mi lọ́wọ́, títí kan àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ àtàwọn tí mò ń wàásù fún? Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn lèmi náà fi ń wò wọ́n?’

ÌKOOKÒ ÀTI Ọ̀DỌ́ ÀGÙNTÀN

14, 15. Ìwà ẹhànnà wo lọ̀pọ̀ ń hù, ìyípadà wo làwọn kan sì ti ṣe?

14 Àwọn ìwà míì tún wà táwọn èèyàn ayé ń hù tó fi yẹ káwa Kristẹni yẹra fún wọn. Bíbélì sọ pé àwọn tí kò mọ Ọlọ́run máa jẹ́ aláìní ìfẹ́ ohun rere. Wọ́n máa jẹ́ aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu àti òǹrorò. Kódà, àwọn kan máa jẹ́ olùwarùnkì, tàbí alágídí tí kì í gbọ́ tí kì í gbà.

15 Ọ̀pọ̀ tó ń hu ìwà ẹhànnà tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti yí pa dà tí wọ́n sì ń hùwà rere. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú ìyípadà yìí máa wáyé. (Ka Aísáyà 11:​6, 7.) Bíbélì sọ pé àwọn ẹranko ẹhànnà bí ìkookò àti kìnnìún ń gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹran agbéléjẹ̀ bí ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọmọ màlúù. Bíbélì sọ ìdí tí wọ́n á fi jọ máa gbé pọ̀, ó ní “ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísá. 11:9) Níwọ̀n bí àwọn ẹranko ò ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, á jẹ́ pé àwa èèyàn ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń ṣẹ sí lára.

Àwọn ìlànà Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Báwo ni Bíbélì ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn pa dà?

16 Ọ̀pọ̀ tó ń hùwà ẹhànnà bíi ti ìkookò tẹ́lẹ̀ ló ti wá dẹni pẹ̀lẹ́ báyìí. O lè ka ìrírí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” tó wà ní abala Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AYỌ̀ lórí ìkànnì jw.org/yo. Àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń sin Jèhófà kò dà bí àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsìn Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń ṣe bí èèyàn Ọlọ́run àmọ́ tí ìwà wọn kò bá ti Ọlọ́run mu rárá àti rárá. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan tó ń hùwà ẹhànnà tẹ́lẹ̀ ti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:​23, 24) Báwọn èèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń rídìí tó fi yẹ káwọn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í yí èrò wọn, ìwà wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà. Àwọn ìyípadà yẹn ò rọrùn, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

“YÀ KÚRÒ LỌ́DỌ̀ ÀWỌN WỌ̀NYÍ”

17. Kí la lè ṣe táwọn èèyàn ayé yìí kò fi ní kéèràn ràn wá?

17 Ṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín túbọ̀ ń ṣe kedere. Àwa tá à ń sin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kíyè sára gan-an kó má bàa di pé àwọn èèyàn ayé yìí á kéèràn ràn wá. Ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ìkìlọ̀ Bíbélì sílò pé ká yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí Bíbélì sọ nínú 2 Tímótì 3:​2-5. Ká sòótọ́, a ò lè sá fáwọn èèyàn ayé pátápátá torí pé a jọ ń gbé, a jọ ń ṣiṣẹ́, a sì jọ ń lọ síléèwé. Àmọ́ a lè pinnu pé a ò ní máa ronú bíi tiwọn, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní hùwà bíi tiwọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń bá àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kẹ́gbẹ́.

18. Báwo ni ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa ṣe lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà?

18 Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú káwọn míì wá sin Jèhófà. Máa wá ọ̀nà láti wàásù fáwọn èèyàn, kó o sì máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa sọ ohun tó tọ́ lásìkò tó yẹ. Ó yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà wa máa gbógo fún Ọlọ́run dípò àwa. Jèhófà ti fún wa ní ìtọ́ni pé ká “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:​11-14) Tá a bá ń fi ìtọ́ni Jèhófà sílò, àwọn èèyàn á kíyè sí wa, àwọn míì sì lè sọ pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”​—Sek. 8:23.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún “afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́” tàbí “olùfisùn” ni di·aʹbo·los. Ọ̀rọ̀ yìí ni Bíbélì lò fún Sátánì ẹni ibi tí ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́.