Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?

“Ọlọ́run wa, àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì ń yin orúkọ rẹ alẹ́wàlógo.”​1 KÍRÓ. 29:13.

ORIN: 80, 50

1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn nǹkan tó ní?

Ọ̀LÀWỌ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run. Òun ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Jèhófà ló ni wúrà, fàdákà àti gbogbo ohun àdáyébá míì, ó sì ń lò wọ́n láti gbé gbogbo ohun alààyè ró. (Sm. 104:​13-15; Hág. 2:8) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe lo àwọn ohun àdáyébá lọ́nà ìyanu láti pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò.

2 Ogójì ọdún [40] ni Jèhófà fi pèsè mánà àti omi fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. (Ẹ́kís. 16:35) Torí náà, “wọn kò ṣaláìní nǹkan kan.” (Neh. 9:​20, 21) Jèhófà lo wòlíì Èlíṣà láti mú kí ìwọ̀nba òróró tí opó kan ní di rẹpẹtẹ lọ́nà ìyanu. Oore tí Ọlọ́run ṣe fún un yìí mú kó lè san gbogbo gbèsè tó jẹ, kódà owó tó kù lòun àti ọmọ rẹ̀ fi gbéra lẹ́yìn náà. (2 Ọba 4:​1-7) Jèhófà mú kí Jésù pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn, ó sì tún pèsè owó lọ́nà ìyanu nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀.​—Mát. 15:​35-38; 17:27.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àìlóǹkà ohun àmúṣorọ̀ ló wà níkàáwọ́ Jèhófà tó ń mú kí gbogbo ohun tó dá sórí ilẹ̀ ayé lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Síbẹ̀, ó ń rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká fi àwọn ohun ìní wa ti ìjọsìn rẹ̀ lẹ́yìn. (Ẹ́kís. 36:​3-7; ka Òwe 3:9.) Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká fi àwọn ohun ìní wa ta òun lọ́rẹ? Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ ṣe fi ohun ìní wọn ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn? Báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe ń lo owó tá a fi ń ṣètọrẹ lónìí? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.

KÍ NÌDÍ TÁ A FI Ń FÚN JÈHÓFÀ NÍ NǸKAN?

4. Kí nìdí tá a fi ń fún Jèhófà ní nǹkan?

4 Ìdí tá a fi ń fún Jèhófà ní nǹkan ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì mọyì rẹ̀ gan-an. Orí wa maá ń wú tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe torí tiwa. Nígbà tí Ọba Dáfídì ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì tí wọ́n fẹ́ kọ́, ó sọ pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní, torí náà kò sóhun tá a lè fún Jèhófà tí kì í ṣe pé òun ló kọ́kọ́ fún wa.​—Ka 1 Kíróníkà 29:​11-14.

5. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọrẹ ṣíṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn wa?

5 Ọrẹ ṣíṣe wà lára ìjọsìn wa sí Jèhófà. Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù gbọ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lọ́run ń sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣí. 4:11) Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà pé Jèhófà yẹ lẹ́ni tó yẹ ká fi gbogbo ọlá àti ògo fún, ká sì máa fún lóhun tó dáa jù? Jèhófà tipasẹ̀ Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa wá síwájú òun fún àjọyọ̀ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún. Torí pé ọrẹ ṣíṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn wọn tí wọ́n bá lọ síbi àjọyọ̀ yẹn, Jèhófà pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ “fara hàn níwájú [òun] lọ́wọ́ òfo.” (Diu. 16:16) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ó ṣe pàtàkì káwa náà máa fi ọrẹ ti ìjọsìn Jèhófà lẹ́yìn. Ìdí sì ni pé a mọyì iṣẹ́ ribiribi tí ètò Jèhófà ń ṣe àti pé apá pàtàkì lára ìjọsìn wa ni.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Ọrẹ ṣíṣe máa ń ṣe wá láǹfààní. Ó yẹ kó máa wù wá láti fúnni dípò ká máa wá bá a ṣe máa gba tọwọ́ àwọn èèyàn. (Ka Òwe 29:21.) Ẹ jẹ́ ká ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ báyìí: Ká sọ pé òbí kan máa ń fún ọmọ rẹ̀ lówó ìpápánu, àmọ́ tọ́mọ náà wá ń tọ́jú díẹ̀díẹ̀ pa mọ́ nínú rẹ̀ tó sì wá fi ra ẹ̀bùn fáwọn òbí rẹ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára àwọn òbí náà? Bákan náà, ọmọ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àmọ́ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lè fún àwọn òbí rẹ̀ lówó díẹ̀ kí wọ́n lè fi kún owó tí wọ́n fi ń bójú tó ilé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí yìí lè má retí pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa gbà á tìfẹ́tìfẹ́ torí ìyẹn máa jẹ́ kí ọmọ náà fi hàn pé òun mọyì gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe fún òun. Jèhófà náà mọ̀ pé tá a bá ń ṣe ọrẹ látinú àwọn nǹkan ìní wa, ó máa ṣe wá láǹfààní.

ỌRẸ ṢÍṢE NÍGBÀ ÀTIJỌ́

7, 8. Àpẹẹrẹ wo làwọn èèyàn Jèhófà láyé àtijọ́ fi lélẹ̀ tó bá di pé ká ṣe ọrẹ (a) fún àwọn iṣẹ́ pàtó kan? (b) láti ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn lónírúurú ọ̀nà?

7 Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn fi àwọn ohun ìní wọn ta Jèhófà lọ́rẹ. Àwọn ìgbà kan wà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ọrẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, Mósè ní káwọn èèyàn ṣe ọrẹ kí wọ́n lè kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ohun tí Ọba Dáfídì náà sì ṣe nìyẹn torí tẹ́ńpìlì tí wọ́n máa kọ́. (Ẹ́kís. 35:5; 1 Kíró. 29:​5-9) Nígbà ayé Ọba Jèhóáṣì, àwọn àlùfáà lo owó táwọn èèyàn dá láti fi tún ilé Jèhófà ṣe. (2 Ọba 12:​4, 5) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà táwọn ará gbọ́ pé àwọn Kristẹni bíi tiwọn nílò ìrànwọ́ torí ìyàn tó mú, wọ́n “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.”​—Ìṣe 11:​27-30.

8 Láwọn ìgbà míì, àwọn èèyàn Jèhófà fi owó ṣètìlẹ́yìn fáwọn tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Òfin Mósè sọ pé àwọn ọmọ Léfì kò ní gba ogún kankan bíi tàwọn ẹ̀yà yòókù. Ìdá mẹ́wàá ni wọ́n máa ń fún wọn, ìyẹn ló sì ń jẹ́ káwọn ọmọ Léfì gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìjọsìn. (Núm. 18:21) Bákan náà, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rí ìrànwọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn obìnrin “tí ń ṣèránṣẹ́ fún wọn láti inú àwọn nǹkan ìní wọn.”​—Lúùkù 8:​1-3.

9. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ṣe ọrẹ nígbà àtijọ́?

9 Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe ọrẹ yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ọrẹ láti kọ́ àgọ́ ìjọsìn nínú aginjù, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tí wọ́n mú wá láti ilẹ̀ Íjíbítì wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣètìlẹ́yìn. (Ẹ́kís. 3:​21, 22; 35:​22-24) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni kan ta ohun tí wọ́n ní, bí ilẹ̀ tàbí ilé, wọ́n sì kó owó náà fáwọn àpọ́sítélì. Àwọn àpọ́sítélì náà sì pín owó yìí fáwọn tó wà nípò àìní. (Ìṣe 4:​34, 35) Àwọn míì máa ń dìídì ya iye kan sọ́tọ̀ kí wọ́n lè fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 16:2) Kò sí àní-àní pé àtolówó àti tálákà ló ń ṣètìlẹ́yìn kí iṣẹ́ Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú.​—Lúùkù 21:​1-4.

ỌRẸ ṢÍṢE LÓDE ÒNÍ

10, 11. (a) Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé àtijọ́ tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́? (b) Báwo ló ṣe rí lára rẹ pé ò ń ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn?

10 Lóde òní, wọ́n lè sọ fún wa pé káwa náà ṣe ọrẹ fáwọn iṣẹ́ pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ìjọ yín nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Wọ́n sì lè fẹ́ ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yín. Ẹ̀ka ọ́fíìsì lè sọ fún wa pé ká fowó ṣètìlẹ́yìn torí àtiṣe àwọn àtúnṣe kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílẹ̀ wa, wọ́n sì lè ní ká ṣètìlẹ́yìn torí àpéjọ àgbègbè tá a fẹ́ ṣe tàbí torí àwọn ará wa tí àjálù dé bá. A tún máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn kí ètò Ọlọ́run lè bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ ní oríléeṣẹ́ wa àti ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì gbogbo. Ọrẹ tá à ń ṣe náà ni wọ́n fi ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn alábòójútó àyíká. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọ kọ̀ọ̀kan ti pinnu pé àwọn á máa fi iye kan pàtó ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn sì máa mú kí nǹkan rọrùn fáwọn ará wa kárí ayé.

11 Gbogbo wa pátá la lè ṣètìlẹ́yìn kí àwọn nǹkan ribiribi tí Jèhófà ń gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí lè máa lọ geerege. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọrẹ tá à ń ṣe la ò mọ ẹni tó ṣe é. Inú àwọn àpótí ọrẹ tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba la sábà máa ń fi ọrẹ náà sí, ó sì lè jẹ́ látorí ìkànnì jw.org/yo. Àwọn ọrẹ tá à ń ṣe lè má jọ àwa fúnra wa lójú. Síbẹ̀ àwọn ọrẹ tá a rò pé ó kéré yẹn àmọ́ tá à ń ṣe ní gbogbo ìgbà ló ń mú kí iṣẹ́ Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. Ọ̀rọ̀ àwọn ará wa títí kan àwọn tó wà láwọn ilẹ̀ tí ọrọ̀ ajé ti dẹnu kọlẹ̀ dà bíi tàwọn Kristẹni ní Makedóníà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà nínú “ipò òṣì paraku,” ṣe ni wọ́n ń pàrọwà pé kí wọ́n jẹ́ káwọn náà ṣètìlẹ́yìn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ tinútinú.​—2 Kọ́r. 8:​1-4.

12. Báwo ni ètò Jèhófà ṣe ń rí i dájú pé wọn ò ná owó tá à ń dá ní ìnákúnàá?

12 Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ olóòótọ́ àti olóye tó bá kan ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa lo àwọn ọrẹ tá à ń dá, wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. (Mát. 24:45) Wọ́n máa ń pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ fi àwọn ọrẹ náà ṣe, wọ́n á sì ṣe ohun náà lọ́nà tó yẹ. (Lúùkù 14:28) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìlànà wà táwọn tó ń bójú tó ọrẹ máa ń tẹ̀ lé tó ń jẹ́ kí wọ́n lè máa náwó táwọn èèyàn dá sórí nǹkan tí wọ́n tìtorí rẹ̀ dá a. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́sírà kó góòlù, fàdákà àtàwọn nǹkan míì tí ọba Páṣíà fi tọrẹ wá sí Jerúsálẹ́mù, tá a bá sì díwọ̀n gbogbo nǹkan yẹn, wọ́n lé ní mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún kan dọ́là [$100 million]. Ẹ́sírà gbà pé Jèhófà ni wọ́n fún láwọn nǹkan yẹn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo àwọn nǹkan yẹn gba ọ̀nà eléwu tí wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 8:​24-34) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ìjọ ṣe ọrẹ láti ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà nítorí ìyàn tó mú níbẹ̀, wọ́n sì kó o fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù rí i dájú pé àwọn tóun fi ọrẹ náà rán “ṣe ìpèsè aláìlábòsí, kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:​18-21.) Bíi ti Ẹ́sírà àti Pọ́ọ̀lù, ètò Jèhófà náà ní àwọn ìlànà tí kò lábùlà tí wọ́n ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣàkójọ àwọn ọrẹ tó ń wọlé, ká sì ná an síbi tó yẹ.

13. Kí nìdí tí ètò Jèhófà fi ṣe àwọn àtúnṣe kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

13 Ìdílé kan lè ṣe àwọn àtúnṣe kan kí ìnáwó wọn má bàa ga wọ́n lára tàbí kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà táá jẹ́ kí ìnáwó wọn dín kù kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà. Irú nǹkan yìí ni ètò Jèhófà náà ṣe. Ọ̀pọ̀ nǹkan tuntun ni ètò Jèhófà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èyí sì mú ká ná ju owó tó ń wọlé lọ láwọn àsìkò kan. Torí náà, ètò Ọlọ́run wá ronú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dín ìnáwó kù, wọ́n ṣàtúnṣe sáwọn nǹkan tá à ń ṣe kí wọ́n lè náwó tó ń wọlé sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù.

OHUN TÁ À Ń FI ỌRẸ ÀTINÚWÁ RẸ ṢE

Àwọn ọrẹ tá à ń ṣe la fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé (Wo ìpínrọ̀ 14 sí 16)

14-16. (a) Kí ni díẹ̀ lára nǹkan tá à ń fi ọrẹ rẹ ṣe? (b) Àwọn ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní látinú àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú náà ń pèsè?

14 Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti wà nínú ètò Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ló sọ pé àwọn ò tíì rí ìgbà kankan nínú ìtàn tí oúnjẹ tẹ̀mí pọ̀ yanturu tó báyìí. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí ìkànnì jw.org àti Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ṣe bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ti ní Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun láwọn èdè tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bákan náà, lọ́dún 2014 wọ 2015, àwọn pápá ìṣeré tó tóbi jù ní ìlú mẹ́rìnlá [14] kárí ayé la ti ṣe Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Kọ́kọ́ Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run!” Béèyàn bá gẹṣin nínú àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀, kò ní kọsẹ̀.

15 Ọ̀pọ̀ ló ń dúpẹ́ torí àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n ń rí gbà nínú ètò Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó ń sìn nílùú kan nílẹ̀ Éṣíà sọ̀rọ̀ nípa báwọn ṣe ń jàǹfààní látinú Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, wọ́n sọ pé: “Ìlú kékeré kan la ti ń sìn, torí náà, a máa ń gbàgbé bí ètò Jèhófà ṣe ń ṣe àwọn nǹkan nígbà míì. Àmọ́, tá a bá ti wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, a máa ń rántí pé ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni wá. Inú àwọn ará tó wà níbí máa ń dùn gan-an láti wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Tí wọ́n bá ti wò ó tán, wọ́n sábà máa ń sọ pé ṣe làwọn túbọ̀ ń sún mọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Inú wọn máa ń dùn gan-an pé àwọn wà nínú ètò tí Ọlọ́run ń darí.”

16 Ní báyìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń kọ́ tàbí tún ṣe kárí ayé. Nígbà táwọn ará kan lórílẹ̀-èdè Honduras bẹ̀rẹ̀ sí í lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fún wọn, wọ́n sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé a wà lára ìdílé Jèhófà a sì ń gbádùn bá a ṣe wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé, àwọn nǹkan yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan níbí.” Àwọn míì náà sọ bí inú wọn ṣe dùn tó lẹ́yìn tí wọ́n gba Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a tú sí èdè wọn. Bó sì ṣe rí lára àwọn kan nìyẹn lẹ́yìn tí ètò Ọlọ́run ṣètò ìrànwọ́ fún wọn nígbà àjálù. Bákan náà, inú àwọn ará máa ń dùn bí iṣẹ́ ìwàásù níbi térò pọ̀ sí ṣe ń méso jáde.

17. Báwo làwọn ohun tí ètò Jèhófà ń gbé ṣe ṣe fi hàn pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn?

17 Àwọn èèyàn ò mọ bá a ṣe ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí, pàápàá tí wọ́n bá gbọ́ pé ọrẹ àtinúwá nìkan là ń lò. Lẹ́yìn tí ọ̀gá ilé iṣẹ́ ńlá kan lọ ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tá a ti ń tẹ̀wé, ó yà á lẹ́nu pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló ń ṣe iṣẹ́ náà, ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣe é, a kì í sì í gbégbá ọrẹ tàbí tọrọ owó lọ́wọ́ ìjọba tàbí ẹnikẹ́ni. Kò gbà pé irú ẹ̀ ṣeé ṣe, a ò sì bá a jiyàn torí a mọ̀ pé ìtìlẹ́yìn Jèhófà ló ń jẹ́ kí iṣẹ́ náà di ṣíṣe.​—Jóòbù 42:2.

ÀWỌN ÌBÙKÚN TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń FÚN JÈHÓFÀ NÍ NǸKAN

18. (a) Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn? (b) Báwo la ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ wa àtàwọn ẹni tuntun káwọn náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀?

18 Jèhófà buyì kún wa bó ṣe fún wa láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ àgbàyanu yìí. Ó jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà tá a bá ń ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn. (Mál. 3:10) Jèhófà ti ṣèlérí pé ẹni tó jẹ́ ọ̀làwọ́ kò ní ṣaláìní láé, torí wọ́n máa ń sọ pé òkè òkè lọwọ́ afúnni ń gbé. (Ka Òwe 11:​24, 25.) Yàtọ̀ síyẹn, a máa láyọ̀ tá a bá ń fúnni torí pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Torí náà, àwọn ọmọ wa àtàwọn ẹni tuntun gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa fi owó àtàwọn nǹkan míì ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn àti pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wọ́n máa rí tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì yẹ kí wọ́n máa rí i nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe tiwa náà.

19. Báwo ni àpilẹ̀kọ yìí ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́?

19 Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Tá a bá fún un lára àwọn ohun ìní wa, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa. (1 Kíró. 29:17) Nígbà táwọn èèyàn ń ṣe ọrẹ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì, Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ lórí ṣíṣe tí wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, nítorí pé ọkàn-àyà pípé pérépéré ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà.” (1 Kíró. 29:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kí inú tiwa náà máa dùn bá a ṣe ń mú nínú àwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa, tá a sì fi ń ta á lọ́rẹ.