Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3

Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?

Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?

“Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.”​—ÒWE 4:23.

ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-3. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ Sólómọ́nì, báwo sì ni Jèhófà ṣe bù kún un? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

Ọ̀DỌ́ ni Sólómọ́nì nígbà tó di ọba Ísírẹ́lì. Kò pẹ́ sígbà tó gorí oyè ni Jèhófà fara hàn án lójú àlá tó sì sọ fún un pé: ‘Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.’ Sólómọ́nì dáhùn pé ọ̀dọ́ ni òun àti pé òun ò ní ìrírí. Ó wá sọ pé kí Jèhófà fún òun ní “ọkàn-àyà ìgbọràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn” Jèhófà. (1 Ọba 3:​5-10) Ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ gan-an. Abájọ tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ Sólómọ́nì! (2 Sám. 12:24) Inú Ọlọ́run dùn sí ohun tí Sólómọ́nì béèrè débi pé ó fún un ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye.”​—1 Ọba 3:12.

2 Ní gbogbo àkókò tí Sólómọ́nì fi fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó rí ìbùkún gbà. Bí àpẹẹrẹ, òun ló láǹfààní àtikọ́ tẹ́ńpìlì  “fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (1 Ọba 8:20) Jèhófà fún un ní ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó gbajúmọ̀ gan-an. Bákan náà, àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tó sọ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn ìwé mẹ́ta tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ni ìwé Òwe.

3 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ náà, ọkàn fara hàn nínú ìwé Òwe. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 4:23 sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” Kí lọ̀rọ̀ náà, ọkàn túmọ̀ sí nínú ẹsẹ yìí? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àá tún dáhùn àwọn ìbéèrè méjì míì. Àkọ́kọ́: Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa dìbàjẹ́? Ìkejì: Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa? Àwọn ìbéèrè méjì yìí ṣe pàtàkì gan-an, torí tá a bá mọ ìdáhùn sí wọn, àá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

KÍ NI ỌKÀN TÓ YẸ KÓ O DÁÀBÒ BÒ?

4-5. (a) Báwo ni Sáàmù 51:6 ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí ọkàn túmọ̀ sí? (b) Báwo la ṣe lè fi bíbójútó ìlera wa nípa tara wé bíbójútó ìlera wa nípa tẹ̀mí?

4 Nínú Òwe 4:​23, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà ọkàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a jẹ́ nínú. (Ka Sáàmù 51:6.) Lédè míì, ọkàn ń tọ́ka sí èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Ó ṣe kedere pé ẹni tá a jẹ́ nínú ni ọkàn ń tọ́ka sí, kì í ṣe ohun tá a jẹ́ lóde tàbí ohun táwọn èèyàn gbà pé a jẹ́.

5 Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ìlera ṣàkàwé bó ṣe yẹ kára èèyàn le nípa tẹ̀mí. Àkọ́kọ́, kára èèyàn lè jí pépé, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó sì máa ṣe eré ìmárale déédéé. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé tá a bá fẹ́ dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé lóòótọ́ la nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Èyí gba pé ká máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ká sì máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn míì. (Róòmù 10:​8-10; Ják. 2:26) Ìkejì, ẹnì kan lè máa ta kébékébé, kó sì rò pé koko lara òun le, síbẹ̀ kó jẹ́ pé onírúurú àrùn ló ti kọ́lé sí i lára. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan lè máa ṣe tibí ṣe tọ̀hún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó sì gbà pé ìgbàgbọ́ òun lágbára, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti gbà á lọ́kàn. (1 Kọ́r. 10:12; Ják. 1:​14, 15) Ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń wá láti sọ èrò ọkàn wa dìbàjẹ́. Àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n wo ló máa ń dá gan-an? Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa?

BÍ SÁTÁNÌ ṢE LÈ SỌ ỌKÀN WA DÌBÀJẸ́

6. Kí ni Sátánì fẹ́ ká ṣe, ọgbọ́n wo ló sì ń dá ká lè ṣe ohun tó fẹ́?

6 Ọgbọ́n bí àwa èèyàn á ṣe máa ronú ká sì máa hùwà bíi tiẹ̀ ni Sátánì ń dá. Ọlọ̀tẹ̀ ni, kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Jèhófà rárá àti rárá, ó sì tún jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Àmọ́ o, Sátánì ò lè fipá mú wa láti máa ronú ká sì máa hùwà bíi tiẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ń dá onírúurú ọgbọ́n kó lè rí wa mú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti sọ dìbàjẹ́ ló yí wa ká. (1 Jòh. 5:19) Ó fẹ́ ká máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé ẹgbẹ́ búburú ni wọ́n, wọ́n sì lè ba ìwà ọmọlúwàbí wa jẹ́ tàbí kí wọ́n mú ká máa ronú, ká sì máa hùwà bíi tiwọn. (1 Kọ́r. 15:33) Ohun tó fi rí Ọba Sólómọ́nì mú nìyẹn. Sólómọ́nì fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin tó jẹ́ abọ̀rìṣà, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín wọ́n mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.​—1 Ọba 11:3.

Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ kí Sátánì má bàa sọ ọkàn rẹ dìbàjẹ́? (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Ọ̀nà míì wo ni Sátánì ń gbà tan èrò rẹ̀ kálẹ̀, kí sì nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára?

7 Sátánì máa ń lo àwọn fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n láti tan èrò rẹ̀ kálẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ìtàn aládùn tí wọ́n ń gbé jáde máa ń gbádùn mọ́ni, àmọ́ wọ́n tún máa ń dọ́gbọ́n kọ́ni láti máa ronú kéèyàn sì máa hùwà bíi tàwọn èèyàn ayé. Jésù náà lo ìtàn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ ìtàn nípa ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere àti ti ọmọkùnrin kan tó filé sílẹ̀ tó sì ná ogún rẹ̀ ní ìná àpà. (Mát. 13:34; Lúùkù 10:​29-37; 15:​11-32) Àmọ́, àwọn ìtàn aládùn táwọn èèyàn ayé ń gbé jáde kì í ṣeni láǹfààní, ṣe ni wọ́n máa ń sọ ọkàn ẹni dìbàjẹ́. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n ló burú o. Àwọn kan wà tó gbádùn mọ́ni, a sì lè rí nǹkan kọ́ nínú wọn láìsọ ọkàn wa dìbàjẹ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká kíyè sára. Torí náà, nígbàkigbà tá a bá ń wo fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé wọn ò máa dọ́gbọ́n sọ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́rùn?’ (Gál. 5:​19-21; Éfé. 2:​1-3) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá kíyè sí i pé fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan ń gbé èrò Sátánì lárugẹ? Ṣe ni kó o sá, bí ìgbà tó ò ń sá fún àrùn tó ń ranni!

8. Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo ọkàn àwọn ọmọ wọn?

8 Ẹ̀yin òbí, iṣẹ́ ńlá rèé fún yín, ó di dandan pé kẹ́ ẹ dáàbò bo àwọn ọmọ yín kí Sátánì má bàa sọ ọkàn wọn dìbàjẹ́. Bí àpẹẹrẹ, kò sí àní-àní pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe kí àwọn ọmọ yín má bàa kó àrùn. Fún ìdí yìí, ẹ máa ń tọ́jú ilé yín dáadáa, tí ohunkóhun bá sì wà tó lè mú kí ẹ̀yin tàbí àwọn ọmọ yín ṣàìsàn, ó dájú pé ṣe lẹ máa ń kó wọn dànù. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kẹ́ ẹ dáàbò bo àwọn ọmọ yín, kí àwọn fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn géèmù àtàwọn ìkànnì ayé má bàa gbin èrò Sátánì sí wọn lọ́kàn. Ẹ̀yin ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún láti bójú tó àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. (Òwe 1:8; Éfé. 6:​1, 4) Torí náà, ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ àwọn òfin tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé, ìyẹn àwọn òfin tó bá ìlànà Bíbélì mu. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ irú fíìmù tí wọ́n lè wò àtèyí tí wọn ò gbọ́dọ̀ wò, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:37) Báwọn ọmọ yín ṣe ń dàgbà, ẹ kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ béèyàn ṣe ń fi ìlànà Jèhófà pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Héb. 5:14) Bó ti wù kó rí, ẹ fi sọ́kàn pé kì í ṣe ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ lẹ́nu nìkan lẹ fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n tún ń kẹ́kọ̀ọ́ lára yín.​—Diu. 6:​6, 7; Róòmù 2:21.

9. Èrò wo ni Sátánì ń gbé lárugẹ, àkóbá wo sì nirú èrò bẹ́ẹ̀ máa ń fà?

9 Sátánì tún máa ń fẹ́ ká máa tẹ̀ lé ọgbọ́n èèyàn dípò ọgbọ́n Ọlọ́run. (Kól. 2:8) Àpẹẹrẹ kan ni èrò kan tí Sátánì ń gbé lárugẹ pé owó ni kókó àti pé ẹni tó lówó ló rí ayé wá. Àwọn tó nírú èrò yìí lè rí towó ṣe, àwọn míì sì lè má rí towó ṣe tí wọ́n á fi kú. Èyí ó wù kó jẹ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ lè kóni síyọnu. Ìdí sì ni pé eré owó nirú wọn máa ń sá, gbogbo ohun tó bá gbà ni wọ́n sì máa ń ṣe torí kí wọ́n lè lówó. Wọn kì í bìkítà nípa ìdílé wọn àti ìlera wọn, kódà wọn kì í rí ti Ọlọ́run rò tó bá dọ̀rọ̀ owó. (1 Tím. 6:10) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run tó ń kọ́ wa ká lè ní èrò tó tọ́ nípa owó.​—Oníw. 7:12; Lúùkù 12:15.

BÁWO LA ṢE LÈ DÁÀBÒ BO ỌKÀN WA?

Bíi tàwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn aṣọ́bodè ayé àtijọ́, máa wà lójúfò kó o sì gbé ìgbésẹ̀ kí èrò Sátánì má bàa sọ ọkàn rẹ dìbàjẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11) *

10-11. (a) Tá a bá máa dáàbò bo ọkàn wa, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Kí làwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣe láyé àtijọ́, báwo la ṣe lè fi iṣẹ́ tí ẹ̀rí ọkàn wa ń ṣe wé tàwọn ẹ̀ṣọ́?

10 Tá a bá máa dáàbò bo ọkàn wa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, ká sì gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara láti dáàbò bo ara wa. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “fi ìṣọ́ ṣọ́” tàbí dáàbò bò nínú Òwe 4:23 rán wa létí iṣẹ́ táwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣe. Lásìkò Ọba Sólómọ́nì, orí ògiri ìlú làwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń wà tí wọ́n á máa ṣọ́ ohun tó ń lọ, tí wọ́n bá sì kó fìrí ewu, wọ́n á ké jáde kí àwọn aráàlú lè mọ̀. Àpẹẹrẹ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó yẹ ká ṣe kí Sátánì má bàa sọ ọkàn wa dìbàjẹ́.

11 Láyé àtijọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣọ́bodè ìlú. (2 Sám. 18:​24-26) Bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dáàbò bo ìlú, wọ́n máa ń rí i pé ẹnubodè ìlú wà ní títì pa nígbàkigbà táwọn ọ̀tá bá sún mọ́ tòsí. (Neh. 7:​1-3) Bákan náà lónìí, Sátánì máa ń wọ́nà àtidarí ọkàn wa, èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Àmọ́, ẹ̀rí ọkàn * tá a fi Bíbélì kọ́ máa ń ṣiṣẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó máa ń kìlọ̀ fún wa nígbà tí Sátánì bá gbé ìṣe rẹ̀ dé. Torí náà, nígbàkigbà tí ẹ̀rí ọkàn wa bá kìlọ̀ fún wa, ó yẹ ká tẹ́tí sí i, ká sì ti ilẹ̀kùn ọkàn wa pa.

12-13. Kí ló lè máa wù wá láti ṣe, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe?

12 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa kí Sátánì má bàa sọ èrò wa dìbàjẹ́. Jèhófà ti kọ́ wa pé ‘kí a má ṣe mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí láàárín wa.’ (Éfé. 5:3) Àmọ́, kí la máa ṣe tí àwọn ọmọ ilé ìwé wa tàbí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá dá ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe sílẹ̀? A mọ̀ pé ó yẹ ká ‘kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀.’ (Títù 2:12) Fún ìdí yìí, ẹ̀rí ọkàn wa tó dà bí ẹ̀ṣọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í kìlọ̀ fún wa. (Róòmù 2:15) Ìbéèrè náà ni pé ṣé a máa tẹ́tí sí i? Ó lè ṣe wá bíi pé ká tẹ́tí sóhun táwọn èèyàn náà ń sọ tàbí pé ká wo àwòrán tí wọ́n ń wò. Dípò tá a fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká ti ilẹ̀kùn ọkàn wa pa, ká yí ìjíròrò náà pa dà tàbí ká fibẹ̀ sílẹ̀ láìjáfara.

13 Ó gba ìgboyà tá ò bá fẹ́ káwọn ojúgbà wa mú ká máa ronú tàbí hùwà bíi tiwọn. Ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá wa, á sì fún wa lókun àti ọgbọ́n tá a nílò láti borí ètekéte Sátánì. (2 Kíró. 16:9; Aísá. 40:29; Ják. 1:5) Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe láti máa dáàbò bo ọkàn wa nìṣó?

WÀ LÓJÚFÒ

14-15. (a) Kí ló yẹ ká máa ṣí ilẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ fún, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Òwe 4:​20-22 táá jẹ́ ká túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà? (Tún wo àpótí náà, “ Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣàṣàrò.”)

14 Ká lè dáàbò bo ọkàn wa, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè sọ ọkàn wa dìbàjẹ́, àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ ṣí ọkàn wa sílẹ̀ káwọn nǹkan rere lè wọnú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká pa dà sórí àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn aṣọ́bodè tá a sọ lẹ́ẹ̀kan. Àwọn aṣọ́bodè máa ń ti ilẹ̀kùn pa kí àwọn ọ̀tá má bàa wọlé, àmọ́ láwọn ìgbà míì wọ́n máa ń ṣílẹ̀kùn káwọn èèyàn lè kó oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì wọlé. Àbí kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣí ilẹ̀kùn náà rárá? Ó dájú pé ebi máa pa àwọn ará ìlú. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa ṣí ilẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ kí èrò Ọlọ́run lè wọlé, kó sì máa darí wa.

15 Èrò Jèhófà ló wà nínú Bíbélì, torí náà tá a bá ń kà á, ṣe là ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa ronú, bó ṣe yẹ kí nǹkan rí lára wa àti bó ṣe yẹ ká máa hùwà. Báwo la ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà? Ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà. Arábìnrin kan sọ pé: “Kí n tó ka Bíbélì, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè rí ‘àwọn ohun àgbàyanu’ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Sm. 119:18) Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò. Tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Bíbélì, tá a sì ń ṣàṣàrò, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á jinlẹ̀ lọ́kàn wa, àá sì máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.​—Ka Òwe 4:​20-22; Sm. 119:97.

16. Báwo ni ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ láǹfààní?

16 Ọ̀nà míì tá a lè gbà jẹ́ kí èrò Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà ni pé ká máa wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW®. Tọkọtaya kan sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà fi ètò oṣooṣù yẹn dáhùn àdúrà wa! Wọ́n máa ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí, wọ́n sì máa ń gbé wa ró tínú wa ò bá dùn tàbí tó ń ṣe wá bíi pé kò sẹ́ni tó rí tiwa rò. Ìgbà gbogbo la máa ń gbádùn àwọn orin ètò JW tá à ń pè ní Àwọn Orin Wa Míì. A máa ń gbádùn wọn tá a bá ń se oúnjẹ, tá a bá ń tún ilé ṣe tàbí tá a kàn jókòó tá à ń mu tíì.” Ká sòótọ́, àwọn ètò yẹn ń mú ká dáàbò bo ọkàn wa. Wọ́n ń kọ́ wa láti máa ronú bíi ti Jèhófà, ká má sì fàyè gba èrò Sátánì.

17-18. (a) Bó ṣe wà nínú 1 Àwọn Ọba 8:​61, àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa sílò? (b) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ọba Hesekáyà? (d) Bíi ti àdúrà Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 139:​23, 24, kí làwa náà lè gbàdúrà fún?

17 Tá a bá ń ṣe ohun tó tọ́, tá a sì rí àǹfààní tó wà níbẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. (Ják. 1:​2, 3) Inú wa máa dùn torí pé ohun tá à ń ṣe ń mú kí Jèhófà fi wá yangàn pé ọmọ òun ni wá, ìyẹn sì ń mú ká túbọ̀ pinnu pé ìfẹ́ rẹ̀ làá máa ṣe. (Òwe 27:11) Tí Sátánì bá gbé ìṣe rẹ̀ dé, àǹfààní nìyẹn jẹ́ láti fi hàn pé tọkàntọkàn la fi ń sin Jèhófà Baba wa ọ̀run. (Sm. 119:113) Bákan náà, a ti pinnu pé bíná ń jó bí ìjì ń jà, àá máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́, ìfẹ́ rẹ̀ làá sì máa ṣe.​—Ka 1 Àwọn Ọba 8:61.

18 Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè ṣàṣìṣe? Rárá o, torí pé aláìpé ni wá. Tá a bá ṣàṣìṣe, ẹ jẹ́ ká rántí àpẹẹrẹ Ọba Hesekáyà. Ó ṣàṣìṣe, àmọ́ ó ronú pìwà dà, ó sì sin Jèhófà pẹ̀lú “ọkàn-àyà pípé pérépéré” jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Aísá. 38:​3-6; 2 Kíró. 29:​1, 2; 32:​25, 26) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fàyè gba èrò Sátánì rárá àti rárá. Ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká ní “ọkàn-àyà ìgbọràn.” (1 Ọba 3:9; ka Sáàmù 139:​23, 24.) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá ń dáàbò bo ọkàn wa.

ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àbí àá jẹ́ kí Sátánì tàn wá débi tá a fi máa kẹ̀yìn sí Jèhófà? Kì í ṣe bí ìdẹwò Sátánì ṣe lágbára tó ló máa pinnu, bí kò ṣe bá a ṣe dáàbò bo ọkàn wa tó. Kí ni ọ̀rọ̀ náà, ọkàn túmọ̀ sí bó ṣe wà nínú Bíbélì? Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa dìbàjẹ́? Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 11 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè ṣàyẹ̀wò ohun tá à ń rò, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ohun tá à ń ṣe, ká sì pinnu bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ohun tí Jèhófà fi jíǹkí wa yìí ni Bíbélì pè ní ẹ̀rí ọkàn. (Róòmù 2:15; 9:1) Ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ máa ń mú ká ronú lórí ìlànà Jèhófà, bó ṣe wà nínú Bíbélì, ká sì lò ó láti fi mọ̀ bóyá èrò wa, ọ̀rọ̀ wa tàbí ìṣe wa dára tàbí kò dára.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Bí arákùnrin kan ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n, àwòrán ìṣekúṣe ṣàdédé yọjú. Ọwọ́ rẹ̀ ló kù sí láti pinnu ohun tó máa ṣe.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Ẹ̀ṣọ́ kan rí i pé àwọn ọ̀tá ń bọ̀ ní ẹnubodè. Ó ké sí àwọn aṣọ́bodè tó wà nísàlẹ̀ pé kí wọ́n ti ilẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.