Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1

“Má Wò Yí Ká, Nítorí Èmi Ni Ọlọ́run Rẹ”

“Má Wò Yí Ká, Nítorí Èmi Ni Ọlọ́run Rẹ”

“Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”​—AÍSÁ. 41:10.

ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 41:10 ṣe ṣe Arábìnrin Yoshiko láǹfààní? (b) Torí àwọn wo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí wà lákọọ́lẹ̀?

ARÁBÌNRIN olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Yoshiko gbọ́ ìròyìn burúkú kan. Dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀ sọ fún un pé kò lè lò ju oṣù mélòó kan lọ táá fi kú. Báwo lọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára rẹ̀? Arábìnrin Yoshiko rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó fẹ́ràn gan-an, ìyẹn Aísáyà 41:10. (Kà á.) Dípò kó káyà sókè, ṣe ló sọ fún dókítà náà pé ọkàn òun balẹ̀ torí pé Jèhófà di òun lọ́wọ́ mú. * Ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ló mú kí arábìnrin wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìmikàn. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kan náà lè mú kí ọkàn wa balẹ̀ tá a bá tiẹ̀ kojú àwọn ìṣòro tó lágbára. Kóhun tá a sọ yìí lè dá wa lójú, a máa jíròrò ìdí tí Jèhófà fi gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀ yìí.

2 Nígbà tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ṣe ló fi ń tu àwọn Júù tó máa lọ sígbèkùn Bábílónì nínú. Àmọ́ o, kì í ṣe torí àwọn Júù yẹn nìkan ni Jèhófà ṣe mú kí ọ̀rọ̀ yẹn wà lákọọ́lẹ̀, ó tún fẹ́ kó ṣàǹfààní fáwọn tó ń sìn ín látìgbà yẹn títí dòní. (Aísá. 40:8; Róòmù 15:4) Ní báyìí, à ń gbé láwọn “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Torí náà, a nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú ìwé Aísáyà ju ti ìgbàkígbà rí lọ.​—2 Tím. 3:1.

3. (a) Àwọn ìlérí wo ló wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2019, ìyẹn Aísáyà 41:10? (b) Kí nìdí tá a fi nílò àwọn ìlérí yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun tí Jèhófà sọ nínú Aísáyà 41:10: (1) Jèhófà máa wà pẹ̀lú wa, (2) òun ni Ọlọ́run wa àti (3) ó máa ràn wá lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé a nílò àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú tàbí ìlérí yìí * torí pé wọ́n á jẹ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro wa láìbọ́hùn bíi ti Arábìnrin Yoshiko. Ojoojúmọ́ layé yìí ń burú sí i, bẹ́ẹ̀ sì rèé inú ẹ̀ là ń gbé. Kódà a rí àwọn kan lára wa táwọn ìjọba ń fojú pọ́n. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìlérí yìí wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

“MO WÀ PẸ̀LÚ RẸ”

4. (a) Ìlérí wo la máa kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni Jèhófà sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? (d) Báwo ni ohun tí Jèhófà sọ ṣe rí lára rẹ?

4 Ìlérí àkọ́kọ́ tí Jèhófà ṣe ni pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ.” * Bí Jèhófà ṣe ń kíyè sí wa tó sì ń fìfẹ́ hàn sí wa jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ló wà pẹ̀lú wa. Ẹ gbọ́ ohun tó sọ tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé kò fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Jèhófà sọ pé: “Ìwọ ṣe iyebíye ní ojú mi, a kà ọ́ sí ẹni tí ó ní ọlá, èmi fúnra mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Aísá. 43:4) Kò sóhun náà láyé àti lọ́run tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ àtimáa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín. Adúróṣinṣin ni Jèhófà, kò sì ní yẹhùn. (Aísá. 54:10) Ìfẹ́ tó ní sí wa máa ń jẹ́ ká nígboyà. Ó dájú pé ó máa dáàbò bo àwa náà bó ṣe dáàbò bo Ábúrámù (Ábúráhámù) ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jèhófà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Ábúrámù. Èmi jẹ́ apata fún ọ.”​—Jẹ́n. 15:1.

Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro tó dà bí odò àtèyí tó dà bí iná (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6) *

5-6. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kò ní dá wa dá àwọn ìṣòro wa? (b) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Arábìnrin Yoshiko?

5 A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní dá wa dá àwọn ìṣòro wa. Ohun tó jẹ́ kó dá wa lójú ni ìlérí tó ṣe fáwa èèyàn rẹ̀ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o gba inú omi kọjá, èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ dájúdájú; bí o bá sì gba inú àwọn odò kọjá, wọn kì yóò kún bò ọ́. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o rin inú iná kọjá, kì yóò jó ọ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ iná pàápàá kì yóò wì ọ́.” (Aísá. 43:2) Kí làwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

6 Kì í ṣe pé Jèhófà ń ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ ká kojú ìṣòro rárá. Dípò bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ kí àwọn ìṣòro tó dà bí “odò” bò wá mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí èyí tó dà bí “ọwọ́ iná” jó wa run. Ó fi dá wa lójú pé òun máa wà pẹ̀lú wa, òun á sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti la àwọn ìṣòro náà kọjá. Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ tá a bá kojú ìṣòro, àá sì lè jẹ́ adúróṣinṣin, kódà lójú ikú. (Aísá. 41:13) Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn ní ti Arábìnrin Yoshiko tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ọmọbìnrin rẹ̀ sọ pé: “Bí ọkàn màámi ṣe balẹ̀ wú wa lórí gan-an. Ó ṣe kedere sí wa pé Jèhófà mú kí wọ́n ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Títí dọjọ́ ikú wọn ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ fáwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn aláìsàn míì.” Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ arábìnrin yìí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì gbà pé ó ‘máa wà pẹ̀lú wa,’ a ò ní bẹ̀rù, àá sì fìgboyà kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.

“ÈMI NI ỌLỌ́RUN RẸ”

7-8. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú kejì tá a máa gbé yẹ̀ wò, kí ló sì túmọ̀ sí? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn pé: “Má wò yí ká”? (d) Kí ló wà nínú Aísáyà 46:​3, 4 tó fi àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kàn balẹ̀?

7 Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ ìdánilójú kejì tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ, ó ní: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká má wò yí ká? Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò fún “wò yí ká” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “kéèyàn máa ṣàníyàn tàbí kó máa bẹ̀rù kó sì máa bojú wẹ̀yìn bíi pé ewu kan ń bọ̀.” Ó tún lè túmọ̀ sí pé “kéèyàn máa wò rá-rà-rá bíi pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu.”

8 Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fáwọn Júù tó máa lọ sígbèkùn Bábílónì pé kí wọ́n má ṣàníyàn? Torí ó mọ̀ pé ohun kan máa ṣẹlẹ̀ táá mú kẹ́rù ba àwọn tó ń gbé ní Bábílónì. Kí ló máa fa ìbẹ̀rù yìí? Tó bá ku díẹ̀ kí àádọ́rin (70) ọdún táwọn Júù máa lò nígbèkùn parí, àwọn ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà máa gbógun ja ìlú Bábílónì. Jèhófà máa lo àwọn ọmọ ogun yìí láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. (Aísá. 41:​2-4) Nígbà táwọn ará Bábílónì àtàwọn orílẹ̀-èdè míì tó ń gbé lágbègbè yẹn rí i pé àwọn ọ̀tá ti ń kógun bọ̀, wọ́n ń fi ara wọn lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì ń sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára.’ Wọ́n tún ṣe kún àwọn òrìṣà wọn torí wọ́n rò pé àwọn òrìṣà yẹn á dáàbò bò wọ́n. (Aísá. 41:​5-7) Àmọ́, Jèhófà fi àwọn Júù tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ pé: ‘Ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi. Má wò yí ká tàbí ṣàníyàn, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.’ (Aísá. 41:​8-10) Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Ohun tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ kó dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé òun ò gbàgbé wọn àti pé òun ni Ọlọ́run wọn, àwọn náà sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ó tún sọ fún wọn pé òun máa dáàbò bò wọ́n, òun sì máa “pèsè àsálà” fún wọn. Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ kọ́kàn àwọn Júù náà balẹ̀.​—Ka Aísáyà 46:​3, 4.

9-10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù? Ṣàpèjúwe.

9 Ojoojúmọ́ ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé, ìyẹn sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣàníyàn. Ká sòótọ́, àwọn ìṣòro yìí ò yọ àwa náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sídìí fún wa láti bẹ̀rù torí Jèhófà sọ fún wa pé: “Èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe ń fi wá lọ́kàn balẹ̀?

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Jim àti Ben wà nínú ọkọ̀ òfúrufú kan náà. Bí wọ́n ṣe ń lọ, ṣe ni ìjì ń bi ọkọ̀ òfúrufú náà sọ́tùn-ún àti sósì. Bí ìjì náà ṣe ń bì lu ọkọ̀ náà, wọ́n gbọ́ tẹ́nì kan sọ̀rọ̀ láti inú ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ pé: “Ẹ de bẹ́líìtì yín dáadáa, ìjì ṣì máa bì lu ọkọ̀ yìí fúngbà díẹ̀.” Àyà Jim wá bẹ̀rẹ̀ sí í já. Ẹni tó ń wa ọkọ̀ òfúrufú náà tún sọ pé: “Ẹ má bẹ̀rù, èmi awakọ̀ yín ló ń bá yín sọ̀rọ̀.” Ni Jim bá gbọnrí, ó sì sọ pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni awakọ̀ yìí ń sọ ná?” Àmọ́ ó kíyè sí i pé ọkàn Ben balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Jim wá bi í pé: “Kí ló dé tẹ́rù ò fi bà ẹ́ rárá?” Ben rẹ́rìn-ín, ó sì sọ pé: “Bàbá mi ló ń tu ọkọ̀ yìí, mo sì mọ̀ wọ́n dáadáa!” Ben tún sọ pé: “Jẹ́ kí n sọ nǹkan díẹ̀ fún ẹ nípa bàbá mi. Tó o bá mọ̀ wọ́n, ó dájú pé ọkàn tìẹ náà á balẹ̀.”

11. Kí la rí kọ́ látinú àpèjúwe Jim àti Ben?

11 Kí la rí kọ́ látinú àpèjúwe yìí? Bíi ti Ben, ọkàn tiwa náà balẹ̀ torí pé a mọ Jèhófà Baba wa ọ̀run dáadáa. Ó dá wa lójú pé bí ìṣòro tiẹ̀ ń bì lù wá bí ìjì, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè kógo já láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Aísá. 35:4) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni jìnnìjìnnì ń bá torí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Aísá. 30:15) Bíi ti Ben, ó yẹ ká jẹ́ káwọn míì mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ìyẹn á jẹ́ kó dá wọn lójú pé ìṣòro yòówù kó dé, Jèhófà á dúró tì wọ́n.

‘MÀÁ FÚN Ọ LÓKUN, MÀÁ SÌ RÀN Ọ́ LỌ́WỌ́’

12. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú kẹta tá a máa gbé yẹ̀ wò? (b) Kí ni “apá” Jèhófà ń rán wa létí?

12 Ọ̀rọ̀ ìdánilójú kẹta tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ni pé: “Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” Ṣáájú ìgbà yẹn ni Aísáyà ti sọ bí Jèhófà ṣe máa fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun, ó ní: “Jèhófà . . . yóò wá, àní gẹ́gẹ́ bí alágbára, apá rẹ̀ yóò sì máa ṣàkóso fún un.” (Aísá. 40:10) Bíbélì sábà máa ń lo “apá” láti ṣàpẹẹrẹ agbára. Torí náà, bí Aísáyà ṣe sọ pé ‘apá Jèhófà máa bá a ṣàkóso’ ń rán wa létí pé Ọba alágbára ńlá ni Jèhófà. Ó fi agbára rẹ̀ tí kò láàlà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nígbà àtijọ́, bó sì ṣe ń ṣe títí dòní nìyẹn: Ó ń fún wa lókun, ó sì ń dáàbò bò wá torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé e.​—Diu. 1:​30, 31; Aísá. 43:10.

Kò sí ohun ìjà èyíkéyìí tó máa borí ọwọ́ agbára Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 12 sí 16) *

13. (a) Ìgbà wo ní pàtàkì ni Jèhófà máa ń fún wa lókun? (b) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe tó fún wa lókun tó sì mú ká nígboyà?

13 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fún wa lókun, àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn ọ̀tá bá ń ṣenúnibíni sí wa. Láwọn ilẹ̀ kan lónìí, àwọn ọ̀tá máa ń wá gbogbo ọ̀nà láti dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Síbẹ̀, ẹ̀rù kì í bà wá. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa fún wa lókun, òun á sì mú ká nígboyà nígbà tó ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí.” (Aísá. 54:17) Ìlérí yìí rán wa létí àwọn kókó pàtàkì mẹ́ta kan.

14. Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ń ta kò wá?

14 Àkọ́kọ́, a mọ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá. (Mát. 10:22) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni gan-an sáwọn ọmọlẹ́yìn òun láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Mát. 24:9; Jòh. 15:20) Ìkejì, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn ọ̀tá máa kórìíra wa nìkan ni, kódà wọ́n á lo ohun ìjà lóríṣiríṣi láti bá wa jà. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń bà wá lórúkọ jẹ́, wọ́n máa ń parọ́ burúkú mọ́ wa, wọ́n sì máa ń fojú pọ́n wa. (Mát. 5:11) Jèhófà kì í dá àwọn ọ̀tá yìí lẹ́kun pé kí wọ́n má bá wa jà. (Éfé. 6:12; Ìṣí. 12:17) Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù. Kí nìdí?

15-16. (a) Kí ni kókó kẹta tó yẹ ká fi sọ́kàn, báwo sì ni Aísáyà 25:​4, 5 ṣe ti kókó yìí lẹ́yìn? (b) Kí ni Aísáyà 41:​11, 12 sọ pé ó máa gbẹ̀yìn àwọn tó ń bá wa jà?

15 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí kókó kẹta tó yẹ ká fi sọ́kàn. Jèhófà ṣèlérí pé “ohun ìjà yòówù” tí wọ́n bá fi bá wa jà “kì yóò ṣe àṣeyọrí.” Bí ògiri ilé ṣe máa ń dáàbò boni lọ́wọ́ ìjì òjò, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ “ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀.” (Ka Aísáyà 25:​4, 5.) Ó dájú pé àwọn ọ̀tá wa kò ní lè pa wá run.​—Aísá. 65:17.

16 Jèhófà jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé òun nígbà tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn tó “ń gbaná jẹ mọ́” wa. (Ka Aísáyà 41:​11, 12.) Itú yòówù káwọn ọ̀tá wa pa tàbí bó ti wù kí ogun tí wọ́n ń bá wa jà gbóná tó, ibì kan náà ló máa já sí: Gbogbo ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run pátápátá ló máa di “aláìjámọ́ nǹkan kan, wọn yóò sì ṣègbé.”

OHUN TÁÁ MÚ KÁ TÚBỌ̀ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mọ púpọ̀ sí i nípa Jèhófà, àá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e (Wo ìpínrọ̀ 17 àti 18) *

17-18. (a) Báwo ni Bíbélì kíkà ṣe máa mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2019, báwo ló ṣe máa mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?

17 Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i làá túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà mọ Jèhófà dáadáa ni pé ká máa fara balẹ̀ ka Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà. Inú Bíbélì la ti rí àkọsílẹ̀ bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́. Àwọn àkọsílẹ̀ yẹn mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwa náà lónìí.

18 Wòlíì Aísáyà sọ àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin kan ká lè mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà ń dáàbò bò wá. Ó pe Jèhófà ní olùṣọ́ àgùntàn, ó sì fi àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wé àgùntàn. Aísáyà sọ nípa Jèhófà pé: “Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.” (Aísá. 40:11) Tá a bá nímọ̀lára pé Jèhófà ń fi ọwọ́ agbára rẹ̀ gbá wa mọ́ra, ọkàn wa máa balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá. Kí ọkàn wa lè balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tá à ń kojú sí, ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti yan Aísáyà 41:10 gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ọdún 2019, ó sọ pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, ó dájú pé á fún ẹ lókun kó o lè kojú àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn fún ọdún 2019 sọ ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ bí àwọn nǹkan burúkú bá tiẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé tàbí tá a bá kojú ìṣòro. A máa jíròrò kókó mẹ́ta yìí àti ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀. Ronú jinlẹ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí. Há a sórí tó bá ṣeé ṣe fún ẹ. Á fún ẹ lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tó lè dìde lọ́jọ́ iwájú.

^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tẹ́nì kan bá ṣèlérí fún wa, ṣe lonítọ̀hún ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa ṣe ohun tí òun sọ láìyẹhùn. Àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa mú kí ọkàn wa balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí.

^ ìpínrọ̀ 4 Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbólóhùn náà, “Má fòyà” fara hàn nínú Aísáyà 41:​10, 13 àti 14. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì làwọn ẹsẹ yẹn lo “èmi” láti tọ́ka sí Jèhófà. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè tẹ kókó pàtàkì kan mọ́ wa lọ́kàn, ìyẹn ni pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, ọkàn wa máa balẹ̀, a ò sì ní bẹ̀rù.

^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Àwọn tó wà nínú ìdílé kan ń kojú onírúurú ìṣòro. Ẹnì kan ń ṣàìsàn, àwọn míì sì ń kojú ìṣòro níbi iṣẹ́, nílé ìwé àti lóde ẹ̀rí.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Àwọn ọlọ́pàá já wọnú ilé táwọn ará wa ti ń ṣèpàdé, àmọ́ àwọn ará wa ò gbọ̀n jìnnìjìnnì.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Tá a bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, àá lè fara da ìṣòro.