Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4

Ohun Tí Ètò Ráńpẹ́ Kan Kọ́ Wa Nípa Jésù Ọba Wa

Ohun Tí Ètò Ráńpẹ́ Kan Kọ́ Wa Nípa Jésù Ọba Wa

“Èyí túmọ̀ sí ara mi. . . . Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi.’”​—MÁT. 26:​26-28.

ORIN 16 Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé ọ̀nà tó rọrùn tí kò sì gbàfiyèsí ni Jésù gbà ṣe ìrántí ikú rẹ̀? (b) Àwọn ànímọ́ Jésù wo la máa gbé yẹ̀ wò?

Ó DÁJÚ pé tí wọ́n bá ní kó o sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, kò sí àní-àní pé wàá ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tá a máa ń ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí Jésù lò lọ́jọ́ yẹn ò tó nǹkan. Síbẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣe pàtàkì gan-an. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ‘Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ètò yẹn lọ́nà tí kò gba àfiyèsí?’

2 Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ni rọrùn lóye, ó ṣe kedere, kò sì lọ́jú pọ̀ rárá. (Mát. 7:​28, 29) Lọ́nà kan náà, àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè máa rántí * ikú rẹ̀ rọrùn gan-an kò sì lọ́jú pọ̀. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn nǹkan tí Jésù lò fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ká sì tún wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó sọ àtohun tó ṣe. Ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó nígboyà, ó sì tún nífẹ̀ẹ́. Bákan náà, a máa jíròrò bá a ṣe lè fara wé e.

JÉSÙ LẸ́MÌÍ ÌRẸ̀LẸ̀

Búrẹ́dì àti wáìnì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ń mú ká rántí pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì ti di Ọba ní ọ̀run báyìí (Wo ìpínrọ̀ 3 sí 5)

3. Bó ṣe wà nínú Mátíù 26:​26-28, kí nìdí tá a fi lè sọ pé ohun tí Jésù lò fún ìrántí ikú rẹ̀ mọ níwọ̀n, kí sì làwọn ohun tó lò ṣàpẹẹrẹ?

3 Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ níṣojú àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11) tó jẹ́ olóòótọ́. Ohun tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ló fi ṣe ètò ráńpẹ́ náà. (Ka Mátíù 26:​26-28.) Ó lo búrẹ́dì tí kò ní ìwúkàrà àti wáìnì tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe Ìrékọjá tán. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ohun èlò méjèèjì náà ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ pípé àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó máa fi rúbọ nítorí wọn. Ó dájú pé kò ní ya àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́nu pé ọ̀nà ráńpẹ́ ni Jésù gbà fi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí lọ́lẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

4. Báwo ni ìmọ̀ràn tí Jésù fún Màtá ṣe jẹ́ ká rídìí tí Jésù fi lo ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ fún ìrántí ikú rẹ̀?

4 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní oṣù díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Jésù lọ sílé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ìyẹn Lásárù, Màtá àti Màríà. Níbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ dípò kí Màtá jókòó tì wọ́n, kùrùkẹrẹ bó ṣe máa se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún Jésù ló ń ṣe. Èyí mú kí Jésù tọ́ ọ sọ́nà, ó sì fún un nímọ̀ràn pé kò pọn dandan kó filé pọntí fọ̀nà rokà. (Lúùkù 10:​40-42) Ìtọ́ni yìí kan náà ni Jésù fúnra ẹ̀ fi sílò ní wákàtí díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀. Dípò kí Jésù ṣètò oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ìrántí ikú rẹ̀, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ló ṣètò. Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jésù?

5. Kí ni ètò ráńpẹ́ tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́, báwo ló sì ṣe bá ohun tó wà nínú Fílípì 2:​5-8 mu?

5 Gbogbo ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé fi hàn pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. (Mát. 11:29) Jésù mọ̀ pé ẹbọ tó ṣe pàtàkì jù lọ lòun fẹ́ fẹ̀mí ara òun rú àti pé Jèhófà máa jí òun dìde, á sì fi òun sípò tó ga lọ́run. Láìka gbogbo èyí sí, Jésù ò pe àfiyèsí sí ara ẹ̀, kò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa filé pọntí fọ̀nà rokà láti fi rántí ikú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa fi ètò ráńpẹ́ náà rántí òun lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. (Jòh. 13:15; 1 Kọ́r. 11:​23-25) Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe agbéraga. Inú wa dùn gan-an pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wà lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Ọba wa ní.​—Ka Fílípì 2:​5-8.

6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù nígbà tá a bá kojú ìṣòro?

6 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. (Fílí. 2:​3, 4) Àpẹẹrẹ kan lohun tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Ó mọ̀ pé òun máa tó kú ikú oró, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ló gbà á lọ́kàn torí ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣọ̀fọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ kẹ́yìn, ó fún wọn ní ìtọ́ni àti ìṣírí, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (Jòh. 14:​25-31) Kò sí àní-àní pé Jésù fi ọ̀rọ̀ àwọn míì ṣáájú tiẹ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa!

JÉSÙ LO ÌGBOYÀ

7. Báwo ni Jésù ṣe lo ìgboyà kété lẹ́yìn tó fi ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀?

7 Kété lẹ́yìn tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé ó ní ìgboyà. Kí ló ṣe? Jésù gbà láti ṣe ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́ kó ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án pé ó jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì, wọ́n á sì pa á. (Mát. 26:​65, 66; Lúùkù 22:​41, 42) Síbẹ̀, ó jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú kó lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kó sì fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jésù tún múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún ohun tí wọ́n máa tó fojú winá rẹ̀.

8. (a) Kí ni Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́? (b) Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe lo ìgboyà lẹ́yìn ikú rẹ̀?

8 Jésù tún lo ìgboyà ní ti pé ohun táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nílò ló gbájú mọ́ dípò kó máa ronú nípa ohun tó máa kojú. Lẹ́yìn tó jẹ́ kí Júdásì jáde, ó fi ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀. Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó ṣe yẹn máa rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó máa tó di ẹni àmì òróró létí àǹfààní tí ẹbọ ìràpadà ṣe wọ́n àti àǹfààní tí wọ́n ní láti wọnú májẹ̀mú tuntun. (1 Kọ́r. 10:​16, 17) Kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè rí èrè yìí gbà, Jésù sọ ohun tí òun àti Baba rẹ̀ fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Jòh. 15:​12-15) Jésù tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n máa dojú kọ àdánwò. Ó wá tọ́ka sí àpẹẹrẹ tiẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n “mọ́kànle!” (Jòh. 16:​1-4a, 33) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìgboyà hàn bíi ti Jésù. Wọ́n dúró ti ara wọn nígbà ìṣòro láìka ohun tó lè ná wọn sí.​—Héb. 10:​33, 34.

9. Báwo la ṣe lè lo ìgboyà bíi ti Jésù?

9 Bákan náà lónìí, àwa náà ń lo ìgboyà bíi ti Jésù. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nígbà míì, wọ́n lè ju àwọn ará wa sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún wọn, kódà tó bá gba pé ká gbèjà wọn. (Fílí. 1:14; Héb. 13:19) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa fi ìgboyà wàásù nìṣó. (Ìṣe 14:3) Bíi ti Jésù, a ti pinnu pé àá máa wàásù nìṣó báwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ta kò wá tàbí tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa. Àmọ́ nígbà míì, ẹ̀rù lè bà wá, kí ọkàn wa sì pami. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí la lè ṣe?

10. Kí ló yẹ ká ṣe láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, kí sì nìdí?

10 Tá a bá ń ronú nípa àǹfààní tí ìràpadà Jésù ṣe wá, àá túbọ̀ nígboyà. (Jòh. 3:16; Éfé. 1:7) Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ohun kan wà tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà náà. Ohun náà ni pé ká máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi ká sì máa ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ikú Jésù. Nígbà tá a bá wá pé jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àá túbọ̀ lóye ohun tí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún, àá sì túbọ̀ mọyì ìràpadà tí Jésù ṣe. Tá a bá mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa àti àǹfààní tí ìràpadà yẹn ṣe àwa àtàwọn míì, ìrètí wa á túbọ̀ dájú, àá sì lè fara da àdánwò èyíkéyìí láìbẹ̀rù.​—Héb. 12:3.

11-12. Kí la ti rí kọ́ níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí?

11 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tí Jésù fi lọ́lẹ̀ ń jẹ́ ká rántí ìràpadà tó ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ àtàtà tí Jésù ní, bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà. Ní báyìí, Jésù ni Àlùfáà Àgbà wa, ó sì ń lo àwọn ànímọ́ yìí bó ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí wa lọ́dọ̀ Jèhófà. (Héb. 7:​24, 25) Ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ṣe, a gbọ́dọ̀ máa ṣe Ìrántí Ikú rẹ̀ bó ṣe pa á láṣẹ. (Lúùkù 22:​19, 20) A máa ń ṣe èyí ní àyájọ́ ọjọ́ tó bọ́ sí Nísàn 14, èyí sì ni ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ́dún.

12 Ànímọ́ míì tún wà tá a lè kọ́ lára Jésù tá a bá wo ọ̀nà ráńpẹ́ tó gbà ṣètò ìrántí ikú rẹ̀, ànímọ́ yìí ló sì mú kó kú fún wa. Kódà ànímọ́ yìí làwọn èèyàn mọ Jésù mọ́ nígbà tó wà láyé. Ànímọ́ wo nìyẹn?

JÉSÙ NÍ ÌFẸ́

13. Báwo ni Jòhánù 15:9 àti 1 Jòhánù 4:​8-10 ṣe jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn ṣe jinlẹ̀ tó, àwọn wo ló sì jàǹfààní nínú ìfẹ́ yìí?

13 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, Jésù sì gbé ìfẹ́ yìí yọ nínú gbogbo ohun tó ṣe. (Ka Jòhánù 15:9; 1 Jòhánù 4:​8-10.) Ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jésù gbà fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí wa ni bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí “àgùntàn mìíràn,” gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú ìfẹ́ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa nípasẹ̀ ìràpadà náà. (Jòh. 10:16; 1 Jòh. 2:2) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá wo àwọn nǹkan ìṣàpẹẹrẹ tí Jésù lò fún ìrántí ikú rẹ̀, àá rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì gba tiwa rò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Jésù ṣètò ìrántí ikú rẹ̀ lọ́nà táá mú kó rọrùn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa ṣe é bọ́dún ṣe ń gorí ọdún àti láwọn ipò tó yàtọ̀ síra (Wo ìpínrọ̀ 14 sí 16) *

14. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

14 Dípò kí Jésù tẹ́ tábìlì lọ rẹ-rẹ-rẹ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ló lò láti fi ṣe ètò náà, èyí sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn. Ìdí ni pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn ọmọlẹ́yìn yìí máa bá ara wọn ní onírúurú ipò táá sì pọn dandan pé kí wọ́n ṣe Ìrántí Ikú Kristi, kódà àwọn míì máa ṣe é nínú ẹ̀wọ̀n. (Ìṣí. 2:10) Ǹjẹ́ wọ́n pa àṣẹ Jésù mọ́ lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

15-16. Ọgbọ́n wo làwọn kan dá láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi bí nǹkan ò tiẹ̀ rọgbọ?

15 Títí dòní, àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń sapá gan-an ká lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A máa ń tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kódà lábẹ́ àwọn ipò tí kò rọrùn rárá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arákùnrin Harold King wà nínú àhámọ́ kan nílẹ̀ Ṣáínà, ó ronú ọ̀nà tó lè gbà ṣe Ìrántí Ikú Kristi nínú ipò tó wà yẹn. Àwọn ohun tó ní lọ́wọ́ ló dọ́gbọ́n lò fún àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. Bákan náà, ó ṣírò ọjọ́ tí Ìrántí Ikú Kristi máa bọ́ sí. Nígbà tí àkókò sì tó, ó kọrin, ó gbàdúrà, ó sì sọ àsọyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ló wà nínú àhámọ́ náà.

16 Àpẹẹrẹ míì ni tàwọn arábìnrin wa tí wọ́n wà ní àtìmọ́lé nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ṣe ni wọ́n fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́ torí pé ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni wọ́n nílò, ó rọrùn fún wọn láti ṣe é ní bòókẹ́lẹ́. Wọ́n sọ pé: “Gbogbo wa dúró yíká àpótí kékeré kan tá a tẹ́ aṣọ funfun lé, orí ẹ̀ sì làwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà wà. Àbẹ́là la tàn torí pé tá a bá tan iná gílóòbù, wọ́n lè rí wa. . . . A lo àǹfààní yẹn láti pa dà jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé a máa lo gbogbo okun wa láti dá orúkọ mímọ́ rẹ̀ láre.” Àbí ẹ ò rí i pé àwọn arábìnrin yìí nígbàgbọ́! A dúpẹ́ pé Jésù ṣètò ìrántí ikú rẹ̀ lọ́nà tó máa rọrùn fún wa láti ṣe kódà lábẹ́ àwọn ipò tí kò rọgbọ. Ó sì dájú pé ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.

17. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

17 Bí Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń sún mọ́, á dáa kí kálukú bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ fìwà jọ Jésù tó bá di pé kí n máa fìfẹ́ hàn? Ṣé ire àwọn míì máa ń jẹ mí lọ́kàn, àbí tara mi nìkan ni mò ń rò? Ṣé mi ò máa retí pé káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ, àbí mo máa ń gba tiwọn rò?’ Ǹjẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa fara wé Jésù ká sì máa gba tàwọn míì rò.​—1 Pét. 3:8.

Ẹ FI ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

18-19. (a) Kí ló dá wa lójú? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe?

18 Láìpẹ́ a ò ní ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́. Tí Jésù bá “dé” nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa kó gbogbo “àwọn àyànfẹ́” tó ṣẹ́ kù lọ sí ọ̀run. Tíyẹn bá ti ṣẹlẹ̀, a ò ní ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́.​—1 Kọ́r. 11:26; Mát. 24:31.

19 Tá ò bá tiẹ̀ ṣe Ìrántí Ikú Kristi mọ́, ó dájú pé àá ṣì máa rántí ètò pàtàkì tí Jésù fi lọ́lẹ̀ yìí. Á jẹ́ ká máa rántí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ga jù lọ, ìgboyà àti ìfẹ́ tí Jésù fi hàn. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àwọn tó ti máa ń pésẹ̀ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa máa ròyìn bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà láàyè nígbà yẹn. Ní báyìí ná, ká tó lè jàǹfààní nínú ètò yìí, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká nígboyà, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn míì bíi ti Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí ojú rere Jèhófà, á sì bù kún wa títí láé.​—2 Pét. 1:​10, 11.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

^ ìpínrọ̀ 5 Láìpẹ́, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tàbí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ètò ráńpẹ́ tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn túbọ̀ mú kó ṣe kedere pé Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó nígboyà, ó sì nífẹ̀ẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò báwa náà ṣe lè gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ ká sì fìwà jọ Jésù.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tá a bá sọ pé à ń ṣe ìrántí ẹnì kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ṣe là ń ṣe ohun pàtàkì kan ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tẹ́ni náà ṣe tàbí ohun tó ṣẹlẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Àwòrán àwọn tó ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní; àwọn tó ṣe é ní nǹkan bí ọdún 1880; àwọn tó ṣe é nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì àtàwọn tó ń ṣe é lóde òní ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà nílẹ̀ olóoru kan ní South America.