ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ January 2020

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti March 2–April 5, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020 máa jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn.

O Lè Jẹ́ “Orísun Ìtùnú” Fáwọn Míì

Wo àwọn ànímọ́ mẹ́ta táá jẹ́ kó o lè dúró ti àwọn tó níṣòro kó o sì tù wọ́n nínú.

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Ó sì Mọyì Ẹ Gan-an!

Nígbàkigbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí àìsàn, ìṣòro àtijẹ àtimu tàbí torí ara tó ń dara àgbà, ká máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì sóhun náà tó lè yà wá ya ìfẹ́ Jèhófà, Baba wa ọ̀run.

“Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”

Báwo lẹnì kan ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí yan òun tàbí pé ẹni àmì òróró lòun? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá yan ẹnì kan?

A Máa Bá Yín Lọ

Ojú wo ló yẹ kó o fi wo ẹni tó jẹ búrẹ́dì tó sì mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi? Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú tí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i?