Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1

‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2020: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . .  di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”​MÁT. 28:19.

ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún àwọn obìnrin tó wá sí ibojì Jésù, ìtọ́ni wo ni Jésù alára sì fún wọn?

OHUN kan ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ kùtù Nísàn 16, 33 Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn ohun tó ju wákàtí mẹ́rìndínlógójì (36) tí wọ́n ti sin Jésù, àwọn obìnrin mélòó kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbéra lọ síbi tí wọ́n tẹ́ òkú rẹ̀ sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń ṣọ̀fọ̀. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé táwọn bá débẹ̀, àwọn máa fi àwọn èròjà tó ń ta sánsán àti òróró onílọ́fínńdà pa ara rẹ̀, àmọ́ ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé wọn ò bá òkú náà nígbà tí wọ́n débẹ̀! Áńgẹ́lì kan yọ sí wọn, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pé Jésù ti jíǹde, ó wá fi kún un pé: “Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín. Ẹ máa rí i níbẹ̀.”​—Mát. 28:1-7; Lúùkù 23:56; 24:10.

2 Lẹ́yìn táwọn obìnrin yẹn kúrò ní ibojì náà, Jésù yọ sí wọn ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa rí mi.” (Mát. 28:10) Ó dájú pé ìtọ́ni pàtàkì kan wà tí Jésù fẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ torí pé ìyẹn ni ìpàdé àkọ́kọ́ tó ṣètò lẹ́yìn tó jíǹde.

ÀWỌN WO NI JÉSÙ PÀṢẸ YÌÍ FÚN?

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn míì ní Gálílì, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ‘lọ kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ (Wo ìpínrọ̀ 3 àti 4)

3-4. Kí nìdí tá a fi sọ pé kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì nìkan ni Jésù pa àṣẹ tó wà nínú Mátíù 28:19, 20 fún? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

3 Ka Mátíù 28:16-20. Níbi ìpàdé tí Jésù ṣètò yẹn, ó gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n máa ṣe jálẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, iṣẹ́ yìí kan náà la sì ń ṣe lónìí. Jésù sọ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.”

4 Gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ni Jésù fẹ́ kó máa wàásù. Kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ nìkan làṣẹ yẹn kàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ṣé òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nìkan ló wà níbi òkè kan ní Gálílì nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Ẹ rántí pé áńgẹ́lì tó yọ sáwọn obìnrin yẹn sọ fún wọn pé:  máa rí i [ní Gálílì].” Èyí fi hàn pé àwọn obìnrin yẹn wà lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà. Àmọ́, àwọn míì náà tún wà níbẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (1 Kọ́r. 15:6) Ibo ló ti ṣèpàdé pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún márùn-ún èèyàn?

5. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìpàdé tí Jésù ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Gálílì ni 1 Kọ́ríńtì 15:6 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

5 Ó dájú pé ìpàdé tí Mátíù orí 28 ròyìn pé Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ní Gálílì ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn. Báwo la ṣe mọ̀? Àkọ́kọ́, Gálílì lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti wá. Torí náà, òkè kan ní Gálílì ló máa bọ́gbọ́n mu pé kó ti pàdé pẹ̀lú adúrú èèyàn bẹ́ẹ̀ dípò ilé àdáni kan ní Jerúsálẹ́mù. Èkejì, Jésù ti pàdé pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tẹ́lẹ̀ nínú ilé àdáni kan ní Jerúsálẹ́mù. Torí náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nìkan ló fẹ́ gbéṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fún, ì bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó pàdé pẹ̀lú wọn ní Jerúsálẹ́mù dípò táá fi ní kí àwọn, àwọn obìnrin yẹn àtàwọn míì pàdé òun ní Gálílì.​—Lúùkù 24:33, 36.

6. Báwo ni Mátíù 28:20 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àṣẹ tí Jésù pa kan àwa náà lónìí, kí ló sì fi hàn pé à ń pa àṣẹ náà mọ́?

6 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí kẹta. Kì í ṣe àwọn Kristẹni tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìkan làṣẹ tí Jésù pa pé ká sọni dọmọ ẹ̀yìn kàn. Báwo la ṣe mọ̀? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lẹ́yìn tó pàṣẹ yẹn ló jẹ́ ká mọ̀, ó ní: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Bí Jésù ṣe sọ ọ́ náà ló rí, àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe bẹbẹ tó bá di pé ká wàásù ká sì sọni dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná! Àwọn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún!

7. Kí la máa jíròrò báyìí, kí sì nìdí?

7 Ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi. Àmọ́, àwọn kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé ò ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Wọ́n ń gbádùn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ wọn, àmọ́ wọn ò tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á ṣèrìbọmi. Tó o bá lẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dájú pé wàá fẹ́ kó máa fi ohun tó ń kọ́ sílò, wàá sì fẹ́ kó di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ bó o ṣe lè jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ àti bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí? Ìdí ni pé ó lè gba pé kó o pinnu bóyá kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró tàbí kó o ṣì máa bá a lọ.

RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ

8. Kí ló lè mú kó ṣòro láti dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ wa?

8 Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn jọ́sìn òun torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, a máa fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lóye pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. A fẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà ní “bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba àti ẹni tó ń dáàbò bo àwọn opó.” (Sm. 68:5) Bí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe túbọ̀ ń mọyì ìfẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni òtítọ́ á máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó lè ṣòro fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn torí pé bàbá tó bí wọn ò nífẹ̀ẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò kà wọ́n sí. (2 Tím. 3:1, 3) Torí náà, bó o ṣe ń bá wọn kẹ́kọ̀ọ́, máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Jẹ́ kí wọ́n lóye pé Baba wa ọ̀run fẹ́ kí wọ́n jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ọwọ́ wọn lè tẹ èrè náà. Kí lohun míì tá a lè ṣe?

9-10. Àwọn ìwé wo ló yẹ ká fi máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí sì nìdí?

9 Máa lo ìwé “Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?” àti “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.A dìídì ṣe ìwé méjèèjì yìí lọ́nà táá jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì dé ọkàn àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní orí kìíní ìwé Bíbélì Kọ́ Wa èèyàn á rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: Ṣé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àbí ìkà ni?, Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run táwa èèyàn bá ń jìyà? àti Ṣé o lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Kí la lè sọ nípa ìwé Ìfẹ́ Ọlọ́run? Ìwé yìí máa jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lóye bí wọ́n ṣe lè fi ìlànà Bíbélì sílò, kí wọ́n ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà. Láìka iye ìgbà tó ṣeé ṣe kó o ti fi ìwé méjèèjì yìí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, rí i dájú pé ò ń múra sílẹ̀ dáadáa tó o bá fẹ́ lọ kọ́ àwọn míì, kó o sì mọ ibi tó yẹ kó o tẹnu mọ́ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

10 Kí ni wàá ṣe tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá fẹ́ mọ̀ nípa ohun kan tá a jíròrò nínú àwọn ìwé wa míì, àmọ́ tí kò sí lára àwọn ìwé méjì tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? O lè fún un níṣìírí pé kó ka ìwé náà láyè ara ẹ̀, kẹ́ ẹ lè máa bá ìwé tẹ́ ẹ fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ.

Máa gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́, báwo lẹ ṣe lè jẹ́ kó mọ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì?

11 Máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dáa jù ni pé ẹ má jẹ́ kó pẹ́ sígbà tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ ẹ tó máa gbàdúrà níbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí, bóyá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó yẹ ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀ pé èèyàn ò lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìsí ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ohun táwọn ará kan máa ń ṣe kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ni pé wọ́n á ka Jémíìsì 1:5 tó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, wọ́n á bi akẹ́kọ̀ọ́ wọn pé, “Báwo la ṣe lè rí ọgbọ́n gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run?” Ó ṣeé ṣe kí akẹ́kọ̀ọ́ náà dáhùn pé àfi kéèyàn gbàdúrà.

12. Báwo ni wàá ṣe lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 139:​2-4 láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà?

12 Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ bó ṣe lè máa gbàdúrà. Fi dá a lójú pé Jèhófà ṣe tán láti gbọ́ àdúrà àtọkànwá rẹ̀. Jẹ́ kó mọ̀ pé tá a bá ń gbàdúrà, a lè sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà títí kan àwọn ohun téèyàn ò lè sọ fún ẹlòmíì. Ó ṣe tán, kò sóhun tó wà lọ́kàn wa tí Jèhófà ò mọ̀. (Ka Sáàmù 139:2-4.) A tún lè gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kóun lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kóun sì máa ronú lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé ó ti ṣe díẹ̀ tá a ti ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́. Bó tiẹ̀ mọ̀ pé àwọn àjọ̀dún kan ò bá Bíbélì mu, ó ṣì ń gbádùn àwọn nǹkan kan tí wọ́n ń ṣe nínú àjọ̀dún náà. Ó yẹ ká gbà á níyànjú pé kó sọ fún Jèhófà nípa ẹ̀, kó sì bẹ̀ ẹ́ pé àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí nìkan ni kó jẹ́ kó máa wu òun náà.​—Sm. 97:10.

Pe akẹ́kọ̀ọ́ rẹ wá sípàdé (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kó pẹ́ ká tó pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa wá sípàdé? (b) Kí la lè ṣe táá jẹ́ kára tu akẹ́kọ̀ọ́ wa tó bá wá sípàdé?

13 Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó pe akẹ́kọ̀ọ́ rẹ wá sípàdé. Ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa rí nípàdé àtohun tó máa gbọ́ á gbádùn mọ́ ọn débi pé á wù ú pé kó tẹ̀ síwájú. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án kó o sì rọ̀ ọ́ pé kó tẹ̀ lé ẹ wá sípàdé. O lè lọ fi mọ́tò gbé e nílé tàbí kó o ṣètò bó ṣe máa dé ìpàdé. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí ìwọ àtàwọn akéde míì jọ máa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ rẹ á dojúlùmọ̀ àwọn míì nínú ìjọ, ìyẹn á jẹ́ kó rẹ́ni fojú jọ, kára sì tù ú nígbàkigbà tó bá wá sípàdé.

RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ TẸ̀ SÍWÁJÚ NÍPA TẸ̀MÍ

14. Kí lá jẹ́ kó máa wu akẹ́kọ̀ọ́ wa láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?

14 Ohun tá a fẹ́ ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ wa máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:13) Tẹ́nì kan bá gbà pé ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àǹfààní tó máa rí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ló wà lọ́kàn ẹ̀. Àmọ́, bí òye rẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, á bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì máa ronú ọ̀nà tóun lè gbà ran àwọn míì lọ́wọ́, títí kan àwọn tó wà nínú ìjọ. (Mát. 22:37-39) Tó bá tó àsìkò, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo wa la láǹfààní láti fowó ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn.

Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe tó bá níṣòro (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ ohun tó yẹ kó ṣe tó bá níṣòro?

15 Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe tó bá níṣòro. Jẹ́ ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tó ti di akéde aláìṣèrìbọmi sọ fún ẹ pé ẹnì kan nínú ìjọ ṣẹ òun. Dípò tí wàá fi gbè sẹ́yìn èyíkéyìí nínú wọn, o ò ṣe ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ó lè pinnu pé òun á dárí ji ẹni náà kó sì gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí pẹ̀lú onítọ̀hún, á sì tipa bẹ́ẹ̀ “jèrè arákùnrin” rẹ̀. (Fi wé Mátíù 18:15.) Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ ohun tó máa sọ àti bó ṣe máa sọ ọ́. O lè kọ́ ọ bó ṣe máa lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Library®, Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìkànnì jw.org® kó lè mọ ọgbọ́n táá fi yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tó o bá dá a lẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì kó tó ṣèrìbọmi, á rọrùn fún un láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi.

16. Kí nìdí tó fi dáa kó o máa mú àwọn akéde míì dání tó o bá fẹ́ lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ?

16 Ní káwọn míì nínú ìjọ tẹ̀ lé ẹ lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, títí kan alábòójútó àyíká nígbà tó bá bẹ ìjọ yín wò. Kí nìdí? Láfikún sáwọn nǹkan tá a ti sọ ṣáájú, táwọn míì bá bá ẹ ṣiṣẹ́, wọ́n á lè ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ti ń wá bó ṣe máa jáwọ́ nínú sìgá mímu àmọ́ tó jẹ́ pé pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ ń já sí. O lè ní kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti borí sìgá mímu lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá tẹ̀ lé ẹ lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ á lè sọ àwọn ohun pàtó táá ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́. Tó bá ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà níṣojú ẹni tẹ́ ẹ jọ lọ, bóyá torí pé onítọ̀hún ní ìrírí jù ẹ́ lọ, o lè ní kó bá ẹ darí ẹ̀. Bó ti wù kó rí, tó o bá ń mú onírúurú ará lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ, á ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní gan-an. Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

ṢÉ KÍ N DÁ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ NÁÀ DÚRÓ?

17-18. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ronú lé kó o tó pinnu pé wàá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan dúró?

17 Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá tẹ̀ síwájú bó ṣe yẹ, ó lè gba pé kó o pinnu bóyá kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Àmọ́ kó o tó ṣèpinnu, ó yẹ kó o ronú nípa ibi tí òye akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ. Kò sẹ́ni méjì tí ipò wọn jọra, agbára wa ò sì rí bákan náà. Fún ìdí yìí, á dáa kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé akẹ́kọ̀ọ́ mi ń tẹ̀ síwájú débi tí agbára rẹ̀ gbé e dé?’ ‘Ṣé ó ti ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’ (Mát. 28:20) Ẹni náà lè má tètè ṣe gbogbo àyípadà tó yẹ kó ṣe, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ hàn pé ó ń tẹ̀ síwájú.

18 Kí lo lè ṣe tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kò bá fi bẹ́ẹ̀ mọyì ohun tó ń kọ́? Ká sọ pé ó ti parí ìwé Bíbélì Kọ́ Wa, bóyá ó tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìwé kejì, ìyẹn ìwé Ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ kò wá sípàdé rí, kódà kò wá sí Ìrántí Ikú Kristi rí! Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ torí àwọn ìdí tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Tó o bá ń kọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, á dáa kó o bá a sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. *

19. Kí lo máa sọ fún ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọyì ohun tó ń kọ́, kí ni wàá ṣe tó bá jẹ́ ohun míì ló ń dí i lọ́wọ́?

19 O lè béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Kí ló ń dá ẹ dúró látọjọ́ yìí tí kò jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú?’ Ó ṣeé ṣe kí akẹ́kọ̀ọ́ náà fèsì pé, ‘Mo gbádùn bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ mi ò lè di Ajẹ́rìí láé!’ Tó bá jẹ́ ohun tó sọ nìyẹn tó sì ti pẹ́ díẹ̀ tẹ́ ẹ ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, kò sídìí pé kó o tún máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè sọ ohun tó ń dí i lọ́wọ́ gan-an fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè sọ pé ẹ̀rù àtimáa wàásù láti ilé dé ilé ló ń ba òun. Ní báyìí tó ti sọ ìṣòro rẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti ràn án lọ́wọ́.

Má ṣe fi àkókò ṣòfò lọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Tá a bá lóye ohun tó wà nínú Ìṣe 13:​48, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ká dá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan dúró tàbí ká ṣì máa bá a lọ?

20 Ó ṣeni láàánú pé ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan dà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbà Ìsíkíẹ́lì. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì nípa àwọn èèyàn náà pé: “Wò ó! Lójú wọn, o dà bí orin ìfẹ́, tí wọ́n fi ohùn dídùn kọ, tí wọ́n sì fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ lọ́nà tó já fáfá. Wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé e.” (Ìsík. 33:32) Ó lè ṣòro fún wa láti sọ fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé a máa dá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró. Àmọ́, a ò rọ́jọ́ mú so lókùn torí pé “àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Dípò ká máa fi àkókò ṣòfò nídìí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò méso jáde, ẹ jẹ́ ká wá àwọn míì lọ, ìyẹn “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Ka Ìṣe 13:48.

Ó ṣeé ṣe káwọn míì wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tí wọ́n ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 20)

21. Kí ni Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020, kí ló sì máa mú ká ṣe?

21 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020 máa jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ó ń rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ nígbà tó ṣèpàdé pẹ̀lú wọn níbi òkè kan ní Gálílì, níbi tó ti sọ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . .  di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”​Mát. 28:19.

Ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn, ká sì ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 21)

ORIN 70 Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020 rọ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pé ká máa sọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn.” Gbogbo wa pátá ni àṣẹ tí Jésù pa yìí kàn. Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tí òtítọ́ á fi dọ́kàn wọn tí wọ́n á sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, a máa jíròrò ohun táá jẹ́ ká mọ̀ bóyá ká dá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan dúró tàbí ká ṣì máa bá a lọ.