ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
A Pinnu Pé A Ò Ní Kọ Iṣẹ́ Tí Jèhófà Bá Fún Wa
LỌ́DÚN 1971 nígbà tá a wà lórílẹ̀-èdè Taiwan, ìjì líle kan tó jà mú kí odò tá a fẹ́ sọdá kún fún ẹrẹ̀. Àgbàrá omi náà le débi pé, ó hú àwọn òkúta ńláńlá. Nígbà tí èmi, Harvey ọkọ mi àti ẹni tó ń kọ́ wa lédè Amis dé etí odò náà, ẹ̀rù bà wá gan-an. Àwọn ará tó wà lódì kejì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé báwo la ṣe máa sọdá, bẹ́ẹ̀ làyà wọn ń já bí wọ́n ṣe ń wò wá. Ohun tá a kọ́kọ́ ṣe ni pé, a gbé mọ́tò wa sẹ́yìn ọkọ̀ míì tó tóbi. Àmọ́ a ò rókùn fi dè é mọ́lẹ̀. Torí náà, ṣe lọkọ̀ yẹn rọra ń wọ́ lọ nínú àgbàrá yẹn. Ṣe ló dà bíi pé a ò ní dé òdì kejì mọ́, bẹ́ẹ̀ là ń gbàdúrà sí Jèhófà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a gúnlẹ̀ láyọ̀. Ibi tá a ti wá jìnnà gan-an sórílẹ̀-èdè Taiwan, àmọ́ kí ló gbé wa débẹ̀? Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé wa fún yín.
BÁ A ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́
Harvey ló dàgbà jù nínú ọmọkùnrin mẹ́rin táwọn òbí ẹ̀ bí. Ìlú Midland Junction, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà làwọn òbí ẹ̀ ń gbé nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àsìkò yẹn ni ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ láwọn ọdún 1930. Harvey nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ìyẹn sì mú kó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14). Kò pẹ́ sígbà yẹn lohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó pinnu pé òun ò ní kọ iṣẹ́ tí Jèhófà bá ní kóun ṣe. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n ní kó ka Ilé Ìṣọ́ nípàdé, àmọ́ ó sọ pé òun ò ní lè ṣe é torí pé òun ò tóótun. Arákùnrin tó ń bá Harvey sọ̀rọ̀ náà wá sọ fún un pé, “Tí ẹnì kan nínú ètò Jèhófà bá ní kó o ṣe ohun kan, ẹni náà gbà pé o tóótun ni!”—2 Kọ́r. 3:5.
Orílẹ̀-èdè England ni èmi, ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bàbá mi ta kò wá gan-an nígbà yẹn, àmọ́ nígbà tó yá àwọn náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò fọwọ́ sí i, mo ṣèrìbọmi kí n tó pé ọmọ ọdún mẹ́wàá. Mo wá pinnu pé màá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, màá sì di míṣọ́nnárì. Àmọ́ bàbá mi sọ pé àwọn ò lè gbà kí n ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àfi tí n bá pé ọmọdún mọ́kànlélógún (21). Kò wù mí kí n dúró dìgbà yẹn, torí náà nígbà tí mo pé ọmọdún mẹ́rìndínlógún (16), mo kó lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi
obìnrin tó ń gbé ní Ọsirélíà, bàbá mi náà sì fọwọ́ sí i. Nígbà tí mo wá pé ọmọdún méjìdínlógún (18), mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni mo ti pàdé Harvey, ó sì wu àwa méjèèjì pé ká ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1951, lẹ́yìn tá a sì jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún méjì, ètò Ọlọ́run sọ ọkọ mi di alábòójútó àyíká. Agbègbè Western Australia ni àyíká wa wà, ibẹ̀ sì tóbi gan-an. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń wakọ̀ gba àwọn aṣálẹ̀ tó gbẹ, tí ò sì sẹ́ni tó ń gbébẹ̀.
ỌWỌ́ WA TẸ OHUN TÁ A FẸ́
Lọ́dún 1954, wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Inú wa dùn gan-an torí a mọ̀ pé ọwọ́ wa máa tó tẹ ohun tá a fẹ́. Ọkọ̀ ojú omi la wọ̀ lọ sílùú New York, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́nà tó jinlẹ̀. Èdè Sípáníìṣì wà lára ohun tá a máa kọ́ nílé ẹ̀kọ́ yẹn, àmọ́ kò rọrùn fún Harvey torí kò mọ “r” pè dáadáa.
Lọ́jọ́ kan, àwọn olùkọ́ wa ṣèfilọ̀ pé ẹni tó bá wù láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè Japan lè wá forúkọ sílẹ̀ láti kọ́ èdè Japanese. Àmọ́ a pinnu pé a máa jẹ́ kí ètò Jèhófà yan ibi tá a máa lọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Arákùnrin Albert Schroeder tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa gbọ́ pé a ò forúkọ wa sílẹ̀, ó sọ fún wa pé: “Á dáa kẹ́ ẹ ṣì lọ rò ó.” Nígbà tí Arákùnrin Schroeder rí i pé a ò kọ orúkọ wa sílẹ̀, ó sọ fún wa pé: “Èmi àtàwọn olùkọ́ tó kù ti forúkọ yín sára àwọn tó máa kọ́ èdè Japanese, torí náà ẹ lọ máa múra sílẹ̀.” Kò tiẹ̀ nira rárá fún ọkọ mi láti kọ́ èdè Japanese.
Nígbà tá a dé Japan lọ́dún 1955, ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) akéde péré ló wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà. A ò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà púpọ̀ nígbà yẹn. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni ọkọ mi, ọdún méjì ló sì gbà lọ́wọ́ mi. Ìlú Kobe ni wọ́n rán wa lọ, ọdún mẹ́rin la sì lò níbẹ̀. Inú wa dùn nígbà tí wọ́n ní ká pa dà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, àwọn ìjọ tó wà nítòsí ìlú Nagoya la sì ń bẹ̀ wò. A gbádùn iṣẹ́ wa gan-an, a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, a gbádùn oúnjẹ tí wọ́n ń sè fún wa, ìlú náà sì tù wá lára. Kò pẹ́ sígbà yẹn làǹfààní míì tún yọ láti fi hàn pé a ò ní kọṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa.
A KOJÚ ÀWỌN ÌṢÒRO KAN LẸ́NU IṢẸ́ TUNTUN TÁ A GBÀ
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tá a ti wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Japan bi wá * Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, a gbádùn iṣẹ́ wa gan-an lórílẹ̀-èdè Japan, torí náà kò rọrùn fún wa láti lọ. Àmọ́ ọkọ mi ti pinnu pé òun ò ní kọ iṣẹ́ tí Jèhófà bá gbé fún òun, torí náà a gbà láti lọ.
bóyá a máa fẹ́ lọ sìn ní Taiwan níbi táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amis ń gbé. Ìdí ni pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amis kan ti di apẹ̀yìndà, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Taiwan sì nílò arákùnrin kan tó gbọ́ èdè Japanese láti ran àwọn ará tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́.Nígbà tá a dé Taiwan ní November 1962, ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kànléláàádọ́rin (2,271) làwọn àkéde tó wà níbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára wọn sì jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Amis. Àmọ́, a ní láti kọ́ èdè Chinese. Ìwé kan ṣoṣo péré la ní tá a lè fi kọ́ èdè Chinese, ẹni tó sì ń kọ́ wa ò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, síbẹ̀ a kọ́ èdè náà.
Kò pẹ́ tá a dé Taiwan ni ètò Ọlọ́run sọ ọkọ mi di ìránṣẹ́ ẹ̀ka. Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, torí náà ó ṣeé ṣe fún ọkọ mi láti ṣe iṣẹ́ tó ní ní ọ́fíìsì, kó sì tún ṣèbẹ̀wò sí àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Amis fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láàárín oṣù. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó agbègbè látìgbàdégbà, ìyẹn sì gba pé kó máa sọ àsọyé láwọn àpéjọ. Ká sọ pé èdè Japanese ni ọkọ mi fi sọ àwọn àsọyé rẹ̀, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amis á lóye ẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ìjọba ti ṣòfin pé èdè Chinese nìkan ni káwọn ẹlẹ́sìn máa lò tí wọ́n bá kóra jọ. Ó wá di dandan pé kí ọkọ mi máa sọ àsọyé ní èdè Chinese bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè náà, arákùnrin míì á sì wá tú u sí èdè Amis.
Òfin ológun ni wọ́n ń lò ní Taiwan nígbà yẹn, torí náà àwọn ará gbọ́dọ̀ gbàṣẹ kí wọ́n tó lè ṣe àpéjọ. Kò rọrùn láti rí ìwé àṣẹ gbà torí àwọn ọlọ́pàá máa ń fòní-dòní fọ̀la-dọ́la. Táwọn ọlọ́pàá ò bá tíì fún ọkọ mi ní ìwé àṣẹ lọ́sẹ̀ àpéjọ yẹn, ṣe ló máa ń jókòó tì wọ́n lọ́rùn ní àgọ́ ọlọ́pàá títí tó fi máa rí i gbà. Torí pé àwọn ọlọ́pàá ò fẹ́ kí àjèjì wá jókòó tì wọ́n lọ́rùn, kíá ni wọ́n máa ń fún un ní ìwé àṣẹ náà.
ÌGBÀ ÀKỌ́KỌ́ TÍ MO GUN ÒKÈ
Láwọn ọ̀sẹ̀ tá a bá bẹ ìjọ wò, a sábà máa ń rìn fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bá a ṣe ń gun òkè, bẹ́ẹ̀ làá máa wọ́ odò. Mo rántí ìgbà tí mo kọ́kọ́ gun òkè. Lẹ́yìn tí mo jẹun díẹ̀ láàárọ̀, a wọkọ̀ kan láago márùn-ún ààbọ̀ (5:30) ìdájí lọ sí abúlé kan tó jìnnà gan-an. Lẹ́yìn náà, a wọ́ odò ńlá kan kọjá, a sì pọ́n òkè ńlá kan. Kí n sòótọ́, òkè yẹn nira láti gùn.
Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, àwọn ará ìjọ ni ọkọ mi bá ṣiṣẹ́, èmi nìkan sì ń dá ṣiṣẹ́ ní abúlé kan táwọn tó ń sọ èdè Japanese ń gbé. Nígbà tó di bí aago kan, ebi pa mí débi pé òòyì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi. Nígbà tí màá fi rí ọkọ mi, kò sí ará kankan nítòsí. Ọkọ mi ti fún àwọn kan ní ìwé ìròyìn, ó sì gba ẹyin tútù mẹ́ta, ó wá kọ́ mi bí mo ṣe lè dá ihò sórí ẹyin kí n sì fà á mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù mí, mo dà á mu, ọkọ mi náà sì dàkan mu. Ta ló máa wá mu ẹyin kẹta? Èmi lọkọ mi fún torí kò ní lè gbé mi sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà tí n bá dákú.
MO WẸ̀ NÍTA GBANGBA
Ní àpéjọ àyíká kan tá a ṣe, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí mi tó ṣàjèjì. Ilé arákùnrin kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba la dé sí. Torí pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amis fẹ́ràn kéèyàn máa wẹ̀, ìyàwó alábòójútó àyíká ṣètò omi tá a máa fi wẹ̀ fún wa. Ọwọ́ ọkọ mi dí gan-an lásìkò yẹn, torí náà ó ní kí n kọ́kọ́ lọ wẹ̀. Wọ́n gbé garawa omi gbígbóná kan fún wa, garawa omi tútù kan àti bàsíà kan tí ò lómi nínú. Ó yà mí lẹ́nu pé ìta gbangba níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba níbi tí àwọn arákùnrin ti ń múra sílẹ̀ fún àpéjọ ni wọ́n ti ní kí n wẹ̀. Mo ní kí wọ́n fún mi ní aṣọ tí mo lè ta, àmọ́ ọ̀rá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kékeré kan ló fún mi, kódà àwọn èèyàn lè rí mi látinú ẹ̀. Ó ṣe mí bíi kí n lọ sẹ́yìn ilé lọ wẹ̀, àmọ́ àwọn pẹ́pẹ́yẹ tó wà níbẹ̀ ṣe tán àtiṣá mi jẹ tí n bá sún mọ́ wọn. Mo wá sọ fúnra mi pé: ‘Àwọn arákùnrin yẹn ò rí tèmi rò, wọn ò tiẹ̀ ní kíyè sí i pé mò ń wẹ̀. Tí n bá sì ní mi ò ní wẹ̀, àwọn ará máa bínú.’ Ni mo bá yáa domi sára, bí mo ṣe wẹ̀ nìyẹn o!
ÈTÒ ỌLỌ́RUN ṢE ÌWÉ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ AMIS
Ọkọ mi kíyè sí i pé àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Amis ò tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí torí pé ọ̀pọ̀ wọn ni ò mọ̀wé kà, kò sì sí ìwé kankan lédè wọn. Nígbà tó jẹ́ pé èdè Amis ti ṣeé kọ sílẹ̀, a ronú pé á dáa káwọn ará kọ́ bí wọ́n ṣe lè ka èdè wọn. Iṣẹ́ yìí ò rọrùn rárá, àmọ́ nígbà tó yá, àwọn ará kọ́ bí wọ́n ṣe lè ka èdè wọn, èyí sì mú kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà láyè ara wọn. Ní nǹkan bí ọdún 1966, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé jáde lédè Amis. Nígbà tó sì dọdún 1968, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́.
Àmọ́, ìjọba ò fàyè gba pé kéèyàn tẹ ìwé jáde lédè míì àyàfi Chinese. Torí náà, onírúurú ọ̀nà la máa ń gbà tẹ Ilé Ìṣọ́ lédè Amis. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó jẹ́ pé èdè Mandarin-Chinese àti Amis la fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́. Tẹ́nikẹ́ni bá fẹ́ fura sí wa, ṣe ló máa ń dà bíi pé à ń fi ìwé yẹn kọ́ àwọn èèyàn lédè Chinese. Àtìgbà yẹn ni ètò Ọlọ́run ti ń tẹ onírúurú ìwé jáde lédè Amis káwọn èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Ìṣe 10:34, 35.
ÀKÓKÒ ÌFỌ̀MỌ́
Láwọn ọdún 1960 àti 1970, ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Amis nìgbésí ayé wọn ò bá ìlànà Bíbélì mu. Torí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn kan máa ń ṣèṣekúṣe, wọ́n máa ń mutí yó, àwọn míì máa ń lo tábà tàbí kí wọ́n jẹ ẹ̀pà bẹ́tẹ́lì. Ọ̀pọ̀ ìjọ lọkọ mi bẹ̀ wò kó lè ran àwọn ará lọ́wọ́ láti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan yẹn. Àsìkò tá à ń bẹ àwọn ìjọ yẹn wò lohun tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀.
Àwọn ará tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe tán láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni ò ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì bani nínú jẹ́ gan-an. Kódà láàárín ogún (20) ọdún péré, iye àwọn akéde tó wà ní Taiwan já wálẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,450) sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900). Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa gan-an. Síbẹ̀, a mọ̀ pé Jèhófà ò ní bù kún wa tá ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. (2 Kọ́r. 7:1) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ará jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú yẹn, kódà ní báyìí, Jèhófà ti mú kí àwọn akéde tó wà ní Taiwan lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,000).
Lẹ́yìn ọdún 1980, a rí i pé àwọn ará tó ń sọ èdè Amis ti tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí, èyí wá mú kí ọkọ mi lè lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń sọ èdè Chinese. Ó ti ran àwọn ọkọ àwọn arábìnrin mélòó kan lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì múnú ẹ̀ dùn gan-an. Mo rántí bí inú ẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yìí gbàdúrà sí Jèhófà fúngbà àkọ́kọ́. Inú tèmi náà dùn pé mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ti wá mọ Jèhófà. Kódà, inú mi dùn pé èmi àti méjì lára àwọn ọmọ ẹnì kan tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Taiwan.
ỌKỌ MI KÚ
Ìbànújẹ́ bá mi ní January 1, 2010 nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa ọkọ mi lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59) tá a ti ṣègbéyàwó. Nǹkan bí ọgọ́ta (60) ọdún ló lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àárò ẹ̀ ṣì máa ń sọ mí gan-an. Inú mi dùn gan-an pé a jọ ṣiṣẹ́ nígbà táwọn akéde ò tíì pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tí ètò Ọlọ́run rán wa lọ. A kọ́ èdè Japanese àti Chinese bí ò tiẹ̀ rọrùn, kódà ọkọ mi mọ̀ ọ́n kọ.
Ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé á dáa kí n pa dà sí Ọsirélíà torí pé mo ti dàgbà. Mo kọ́kọ́ ronú pé, ‘Mi ò fẹ́ kúrò ní Taiwan.’ Àmọ́ mo rántí ohun tí ọkọ mi máa ń sọ pé a ò gbọ́dọ̀ kọ iṣẹ́ tí ètò Jèhófà bá fún wa, torí náà mo lọ. Ìgbà tó yá ni mo rí i pé ó dáa bí mo ṣe lọ.
Ní báyìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia ni mo ti ń ṣiṣẹ́, mo sì máa ń bá ìjọ jáde òde ẹ̀rí lópin ọ̀sẹ̀. Ní Bẹ́tẹ́lì, mo máa ń mú àwọn tó bá wá ṣèbẹ̀wò rìn yí ká pàápàá àwọn tó ń sọ èdè Japanese àti Chinese torí mo gbọ́ èdè wọn. Mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde tí màá sì rí Harvey ọkọ mi ọ̀wọ́n tí kì í kọ iṣẹ́ tí Jèhófà bá fún un.—Jòh. 5:28, 29.
^ ìpínrọ̀ 14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Chinese ni wọ́n ń sọ báyìí lórílẹ̀-èdè Taiwan, èdè Japanese ni wọ́n ti máa ń sọ. Torí náà, èdè Japanese ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Taiwan ń sọ.