Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára òkúta kan láyé àtijọ́ ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?
ÒKÚTA kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí láti nǹkan bí ọdún 700-600 Ṣ.S.K., wà ní Bible Lands Museum ní Jerúsálẹ́mù. Ibojì kan tó wà nítòsí Hebron ní Ísírẹ́lì ni wọ́n ti rí òkúta náà. Ohun tí wọ́n kọ sára ẹ̀ ni pé: “Kí Yahweh Sabaot mú ègún wá sórí Hagaf ọmọ Hagav.” Báwo ni ohun tí wọ́n kọ sára òkúta yìí ṣe fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì? Lára ohun tí wọ́n kọ sára òkúta yẹn ni YHWH, ìyẹn Jèhófà lédè Hébérù àtijọ́. Èyí jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń lò ó dáadáa láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n rí láwọn ibojì kan fi hàn pé àwọn tó máa ń sá síbẹ̀ tàbí tí wọ́n máa ń pàdé níbẹ̀ sábà máa ń kọ orúkọ Ọlọ́run àtàwọn orúkọ míì tó ní orúkọ Ọlọ́run sára ògiri.
Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Rachel Nabulsi láti University of Georgia ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára àwọn òkúta àtijọ́ yìí, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n kọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn YHWH sára àwọn òkúta àtijọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan sì ni èyí kọ́ wa. . . . Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ yìí fi hàn pé YHWH ṣe pàtàkì gan-an sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Júdà láyé àtijọ́.” Èyí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn YHWH lédè Hébérù fara hàn nínú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn orúkọ ìgbàanì ló ní orúkọ Yahweh nínú.
Ohun tí “Yahweh Sabaot” tí wọ́n kọ sára òkúta náà túmọ̀ sí ni “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.” Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe orúkọ Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa ń lò, wọ́n tún sábà máa ń lo “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Abájọ tí wọ́n fi lo ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta (283) ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Inú ìwé Àìsáyà, Jeremáyà àti Sekaráyà ló sì ti fara hàn jù.