ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3
Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn ti Àgùntàn Mìíràn Ń Yin Jèhófà àti Kristi
“Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”—ÌFI. 7:10.
ORIN 14 Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ni àsọyé kan tí wọ́n sọ ní àpéjọ agbègbè ọdún 1935 mú kí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe?
ÌDÍLÉ kan wà tí wọ́n jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ní ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì, wọ́n sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin wọn nígbà tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1926. Bíi ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yòókù nígbà yẹn, ọ̀dọ́kùnrin yìí náà máa ń jẹ búrẹ́dì, ó sì máa ń mu wáìnì lọ́dọọdún nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àmọ́, èrò ẹ̀ yí pa dà nígbà tó gbọ́ àsọyé mánigbàgbé kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá.” Arákùnrin J. F. Rutherford ló sọ àsọyé yìí lọ́dún 1935 ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Òye tuntun wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ní àpéjọ yẹn?
2. Àlàyé wo ni Arákùnrin Rutherford ṣe nínú àsọyé rẹ̀?
2 Nínú àsọyé tí Arákùnrin Rutherford sọ, ó ṣàlàyé àwọn tó jẹ́ “ọ̀pọlọpọ enia” (Bíbélì Mímọ́) tàbí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó wà nínú Ìfihàn 7:9. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà máa lọ sí ọ̀run bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ bíi ti àwọn ẹni àmì òróró. Arákùnrin Rutherford fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà kò ní lọ sọ́run. Àmọ́ wọ́n jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn ti Kristi *, tó máa la “ìpọ́njú ńlá náà” já, tí wọ́n á sì gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:14) Jésù ṣèlérí pé: “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí; mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòh. 10:16) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà làwọn àgùntàn mìíràn yìí, wọ́n sì nírètí àtiwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Mát. 25:31-33, 46) Ẹ jẹ́ ká wá wo bí òye tuntun yìí ṣe yí èrò ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà pa dà, títí kan ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.—Sm. 97:11; Òwe 4:18.
ÒYE TUNTUN TÓ YÍ ÈRÒ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN PA DÀ
3-4. Ní àpéjọ agbègbè ọdún 1935, èrò wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn wá ní nípa ìrètí wọn, kí sì nìdí?
3 Bí àsọyé náà ṣe ń lọ, olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ fún àwọn tó péjọ pé: “Kí gbogbo àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé jọ̀wọ́ dìde dúró.” Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) làwọn tó wá sí àpéjọ yẹn. Ọ̀kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn sọ pé àwọn tó dìde dúró ju ìdajì lọ. Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Rutherford kéde pé: “Ẹ wò ó! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà nìyí!” Làwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ kíkankíkan, inú wọn sì ń dùn. Ó wá ṣe kedere sí àwọn tó dìde dúró pé àwọn ò lọ sọ́run àti pé Ọlọ́run ò fẹ̀mí yan àwọn. Lọ́jọ́ kejì àpéjọ náà, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti ogójì (840) làwọn tó ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ lára wọn sì wà lára àwọn àgùntàn mìíràn.
4 Lẹ́yìn àsọyé náà, ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn míì pinnu pé àwọn ò ní máa jẹ búrẹ́dì, àwọn ò sì ní mu wáìnì mọ́ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gidi ni wọ́n fi hàn, kódà ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe lọ́dún 1935 ni ìgbà tí mo jẹ búrẹ́dì, tí mo sì mu wáìnì kẹ́yìn. Ó wá yé mi pé mi ò sí lára àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn láti lọ sọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, mo sì wà lára àwọn tó máa sọ ayé di Párádísè.” (Róòmù 8:16, 17; 2 Kọ́r. 1:21, 22) Àtìgbà yẹn ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn ti ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé.
5. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tí ò jẹ búrẹ́dì, tí ò sì mu wáìnì mọ́ níbi Ìrántí Ikú Kristi?
5 Ojú wo ni Jèhófà fi wo àwọn tí ò jẹ búrẹ́dì, tí wọn ò sì mu wáìnì mọ́ níbi Ìrántí Ikú Kristi lẹ́yìn ọdún 1935? Tí Kristẹni kan lónìí tó ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi bá wá rí i pé òun kì í ṣe ẹni àmì òróró ńkọ́? (1 Kọ́r. 11:28) Àwọn kan máa ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ yìí torí wọ́n ronú pé ọ̀run làwọn ń lọ. Tí wọ́n bá gbà tọkàntọkàn pé àṣìṣe làwọn ṣe, tí wọn ò jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ náà mọ́, tí wọ́n sì ń fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó, ó dájú pé Jèhófà máa kà wọ́n mọ́ àwọn àgùntàn mìíràn. Bí wọn ò tiẹ̀ jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ náà, wọ́n ṣì máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi torí pé wọ́n mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wọn.
ÌRÈTÍ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
6. Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn áńgẹ́lì?
6 Ní báyìí tí ìpọ́njú ńlá ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀, á dáa ká túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìfihàn orí 7 sọ nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn. Jésù pàṣẹ pé kí àwọn áńgẹ́lì tó di atẹ́gùn mẹ́rin tó ń fa ìparun mú má tíì fi í sílẹ̀. Lédè míì, ó ní kí wọ́n ṣì dì í mú ṣinṣin títí àwọn ẹni àmì òróró á fi gba èdìdì ìkẹyìn, tó túmọ̀ sí pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n. (Ìfi. 7:1-4) Jèhófà máa san wọ́n lẹ́san torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, á sì mú kí wọ́n di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (Ìfi. 20:6) Inú Jèhófà àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lọ́run máa dùn gan-an nígbà tí ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) bá pé tí wọ́n sì gba èrè wọn lọ́run.
7. Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 7:9, 10, àwọn wo ni Jòhánù tún rí nínú ìran, kí sì ni wọ́n ń ṣe? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
7 Lẹ́yìn tí Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ ọba àti àlùfáà, ó tún rí àwọn míì tó múnú ẹ̀ dùn, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já. “Ogunlọ́gọ̀ èèyàn” yìí yàtọ̀ sí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) torí pé wọ́n pọ̀ gan-an, a ò sì mọye tí wọ́n máa jẹ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. (Ka Ìfihàn 7:9, 10.) Wọ́n “wọ aṣọ funfun,” ní ti pé wọ́n wà “láìní àbààwọ́n” nínú ayé Sátánì, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Kristi. (Jém. 1:27) Wọ́n polongo pé ohun tí Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ṣe ló mú káwọn rí ìgbàlà. Bákan náà, wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ dání, tó fi hàn pé tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n gbà pé Jésù ni Ọba tí Jèhófà yàn.—Fi wé Jòhánù 12:12, 13.
8. Kí ni gbogbo àwọn ọmọ Jèhófà tó wà lọ́run ṣe bó ṣe wà nínú Ìfihàn 7:11, 12?
8 Ka Ìfihàn 7:11, 12. Kí làwọn tó wà lọ́run ṣe nígbà tí wọ́n rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà? Jòhánù rí i pé inú gbogbo àwọn ọmọ Jèhófà tó wà lọ́run ló ń dùn, wọ́n sì ń yin Ọlọ́run lógo nígbà tí wọ́n rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà. Ó dájú pé inú gbogbo wọn máa dùn nígbà tí ìran náà bá ní ìmúṣẹ, tí ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà la ìpọ́njú ńlá já, tí wọ́n sì fẹsẹ̀ rìn wọnú ayé tuntun.
9. Bí Ìfihàn 7:13-15 ṣe sọ, kí làwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn ń ṣe báyìí?
9 Ka Ìfihàn 7:13-15. Jòhánù sọ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà “ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì rí ojúure Jèhófà. (Àìsá. 1:18) Ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí ni àwọn Kristẹni tó yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Jòh. 3:36; 1 Pét. 3:21) Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n lè dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa ṣe “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru” lórí ilẹ̀ ayé nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Kódà ní báyìí, àwọn ló ń fìtara kópa tó pọ̀ jù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú tiwọn.—Mát. 6:33; 24:14; 28:19, 20.
10. Kí ló dá àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà lójú, ìlérí wo ni wọ́n sì máa rí ìmúṣẹ rẹ̀?
10 Ó dá àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó la ìpọ́njú ńlá náà já lójú pé Ọlọ́run máa bójú tó wọn. Torí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ sì máa fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.” Ìlérí tí àwọn àgùntàn mìíràn ti ń retí tipẹ́tipẹ́ máa wá nímùúṣẹ, pé: “[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìfi. 21:3, 4.
11-12. (a) Àwọn ìbùkún wo ni Ìfihàn 7:16, 17 sọ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn máa gbádùn? (b) Kí làwọn àgùntàn mìíràn máa ń ṣe nígbà Ìrántí Ikú Kristi, kí sì nìdí?
11 Ka Ìfihàn 7:16, 17. Ní báyìí, ebi ń pa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan nítorí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ tàbí nítorí ogun. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti ju àwọn míì sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́, inú àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn ń dùn torí wọ́n mọ̀ pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé èṣù yìí run, ebi ò ní pa àwọn mọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara torí ọ̀pọ̀ oúnjẹ ló máa wà. Nígbà tí Jèhófà bá pa ayé èṣù yìí run, ó máa dáàbò bo àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn, kò sì ní jẹ́ kí ‘ooru tó ń jóni’ gbẹ tó dà sórí àwọn orílẹ̀-èdè kàn wọ́n. Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá parí, Jésù máa darí àwọn tó là á já lọ síbi “àwọn ìsun omi ìyè” àìnípẹ̀kun. Rò ó wò ná: Ìrètí àgbàyanu ló ń dúró de àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé nínú gbogbo àwọn tó gbé láyé, àwọn nìkan ni ò ní tọ́ ikú wò, wọ́n sì lè má kú láé!—Jòh. 11:26.
12 Ìrètí àgbàyanu tí àwọn àgùntàn mìíràn ní mú kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù nígbà gbogbo. Lóòótọ́ Ọlọ́run ò yàn wọ́n láti lọ sí ọ̀run, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó fojú bù wọ́n kù tàbí pé kò mọyì wọn. Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn ló ń yin Jèhófà àti Kristi. Ọ̀nà kan tí wọ́n sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi.
FI GBOGBO ỌKÀN Ẹ YIN JÈHÓFÀ NÍGBÀ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
13-14. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa máa pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
13 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, tí ẹgbẹ̀rún kan èèyàn bá kóra jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, tipátipá la fi máa rí ẹnì kan tó máa jẹ búrẹ́dì táá sì mu wáìnì náà. Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìjọ ni kò ní ẹni àmì òróró kankan. Ó ṣe kedere nígbà náà pé àwọn tó máa gbé láyé ló pọ̀ jù lára àwọn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kí wá nìdí tí wọ́n fi ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi? Ṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí àwọn tó lọ síbi ìgbéyàwó ọ̀rẹ́ wọn. Ìdí tí wọ́n fi lọ ni pé wọ́n fẹ́ kí tọkọtaya náà mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn sì máa dúró tì wọ́n. Lọ́nà kan náà, àwọn àgùntàn mìíràn máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Kristi àtàwọn ẹni àmì òróró, àwọn sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àgùntàn mìíràn tún ń fi hàn pé àwọn mọrírì ẹbọ ìràpadà Kristi torí wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ló
máa jẹ́ káwọn lè wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.14 Ìdí pàtàkì míì táwọn àgùntàn mìíràn fi ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ni pé wọ́n ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù. Nígbà tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (1 Kọ́r. 11:23-26) Torí náà, àwọn àgùntàn mìíràn á ṣì máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi títí dìgbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá lọ sọ́run. Kódà, àwọn àgùntàn mìíràn máa ń pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá sí Ìrántí Ikú Kristi.
15. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti yin Jèhófà àti Kristi nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
15 Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń fi orin àti àdúrà yin Ọlọ́run àti Kristi. Àkòrí àsọyé tá a máa gbọ́ lọ́dún yìí ni “Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Ọlọ́run àti Jésù Ṣe fún Ọ?” Àsọyé yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Jèhófà àti Kristi. Tí wọ́n bá ti ń gbé búrẹ́dì àti wáìnì náà kiri, a máa ń rántí ohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ara Jésù àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. A máa ń rántí pé ńṣe ni Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ kú nítorí wa ká lè rí ìyè. (Mát. 20:28) Kò sí àní-àní pé gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.
MÁA DÚPẸ́ LỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ FÚN ÌRÈTÍ TÓ O NÍ
16. Kí ni àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn fi jọra?
16 Láwọn ọ̀nà kan, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn jọra. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan ju èkejì lọ, àwọn méjèèjì ló ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ó ṣe tán, ohun kan náà ló ná Jèhófà láti ra àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn pa dà, ìyẹn ẹ̀mí Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì ni pé àwọn kan ń lọ sọ́run, àwọn kan sì máa wà lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Kristi. (Sm. 31:23) Ká má sì gbàgbé pé Jèhófà lè fún èyíkéyìí nínú àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ láti gbé nǹkan ribiribi ṣe, yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn.
17. Kí làwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé ń fojú sọ́nà fún?
17 Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bí Kristẹni kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró ló ti ní ìrètí àtilọ sọ́run. Jèhófà ló fi ìrètí yìí sí wọn lọ́kàn. Wọ́n máa ń ronú nípa ìrètí yìí, wọ́n máa ń gbàdúrà nípa ẹ̀, ara wọn sì máa ń wà lọ́nà láti rí èrè náà gbà. Kódà, wọn ò mọ bí ara wọn ṣe máa rí gan-an nígbà tí wọ́n bá dé ọ̀run. (Fílí. 3:20, 21; 1 Jòh. 3:2) Síbẹ̀, wọ́n ń fojú sọ́nà láti rí Jèhófà, Jésù, àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹni àmì òróró yòókù, kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wọn nínú Ìjọba ọ̀run.
18. Kí làwọn àgùntàn mìíràn ń fojú sọ́nà fún?
18 Àwọn àgùntàn mìíràn ń fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì lohun tó ń wu gbogbo èèyàn torí bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. (Oníw. 3:11) Wọ́n ń fojú sọ́nà sí ìgbà tí wọ́n máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. Wọ́n ń retí ìgbà tí ara wọn á jí pépé, tí wọ́n á kọ́ ilé ara wọn, tí wọ́n á gbin ọgbà, tí wọ́n á sì bímọ. (Àìsá. 65:21-23) Wọ́n ń retí ìgbà tí wọ́n á lè lọ sí ọ̀pọ̀ ibi láyé, tí wọ́n á rí àwọn òkè ńláńlá, àwọn igbó kìjikìji àti alagbalúgbú omi. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ohun tó máa múnú wọn dùn jù ni pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà á máa lágbára sí i láti ọjọ́ dé ọjọ́.
19. Kí ni Ìrántí Ikú Kristi máa mú ká ṣe, ìgbà wo la sì máa ṣe é lọ́dún yìí?
19 Ìrètí àgbàyanu ni Jèhófà fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jer. 29:11) Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, gbogbo wa máa yin Jèhófà àti Kristi fún ohun tí wọ́n ṣe ká lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. Kò sí àní-àní pé Ìrántí Ikú Kristi ni ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù fáwa Kristẹni tòótọ́. Ìrọ̀lẹ́ Saturday, March 27, 2021 la máa ṣe é lọ́dún yìí, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Lọ́dún yìí, ọ̀pọ̀ ló máa lè kóra jọ fún Ìrántí Ikú Kristi láìsí ìdíwọ́. Àwọn míì máa ṣe é láìka àtakò sí. Àwọn míì sì máa ṣe é bí wọ́n tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n. Bí Jèhófà, Jésù àtàwọn ọmọ rẹ̀ yòókù tó wà lọ́run ṣe ń bojú wolẹ̀ wò wá, ǹjẹ́ kí gbogbo ìjọ, àwọn àwùjọ àti gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbádùn Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí o!
ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
^ ìpínrọ̀ 5 Ọjọ́ pàtàkì ni March 27, 2021 jẹ́ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Alẹ́ ọjọ́ yẹn la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn tí Jésù pè ní “àgùntàn mìíràn” ló máa pọ̀ jù lára àwọn tó máa kóra jọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Òye wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nípa àgùntàn mìíràn lọ́dún 1935? Ìrètí wo làwọn àgùntàn mìíràn ń fojú sọ́nà fún lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá? Bákan náà, báwo ni wọ́n ṣe ń yin Jèhófà àti Kristi nígbà Ìrántí Ikú Kristi bí wọn ò tiẹ̀ jẹ nínú búrẹ́dì tí wọn ò sì mu nínú wáìnì náà?
^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àwọn àgùntàn mìíràn ni àwọn tó ń tẹ̀ lé Kristi, wọ́n sì nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àtìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti ń kó lára wọn jọ. Apá kan lára àwọn àgùntàn mìíràn ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn. Àwọn yìí máa wà láàyè nígbà tí Jésù bá ṣèdájọ́ aráyé nígbà ìpọ́njú ńlá, wọ́n á sì la ìpọ́njú ńlá náà já.