Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5

“Ẹ Máa Lo Àkókò Yín Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ”

“Ẹ Máa Lo Àkókò Yín Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ”

“Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—ÉFÉ. 5:15, 16.

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo àkókò wa pẹ̀lú Jèhófà?

Ó MÁA ń wù wá láti wà pẹ̀lú àwọn èèyàn wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Àwọn tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn máa ń gbádùn àkókò tí wọ́n bá jọ wà pa pọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń gbádùn àkókò tí wọ́n bá wà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Gbogbo wa la sì máa ń mọyì àkókò tá a bá lò pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó máa ń wù wá láti lo àkókò wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà sí i, ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ronú lórí àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fáráyé àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àkókò tá a bá lò pẹ̀lú Jèhófà ṣeyebíye gan-an!​—Sm. 139:17.

2. Àwọn nǹkan wo ló lè gba àkókò wa?

2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń gbádùn àwọn àkókò tá a máa ń lò láti gbàdúrà sí Jèhófà, tá a sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó máa ń gba àkókò wa. Ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, ìyẹn ni kì í jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, bá a ṣe máa bójú tó ìdílé wa àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì lè gba àkókò wa débi pé a lè má ráyè gbàdúrà, ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́.

3. Àwọn nǹkan míì wo ló lè gba àkókò wa?

3 Àwọn nǹkan míì wà tá ò fura sí tó lè gba àkókò wa. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè gba àwọn nǹkan tí ò burú láyè láti gba àkókò tó yẹ ká fi jọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àkókò tá a fi ń ṣeré tàbí najú. Gbogbo wa la máa ń gbádùn àkókò tá a fi ń sinmi. Àmọ́ àwọn eré tó dáa lè gba àkókò wa débi pé àkókò tó máa ṣẹ́ kù fún ìjọsìn Ọlọ́run ò ní tó nǹkan. Torí náà, ó yẹ ká mọ̀ pé kò yẹ ká jẹ́ kí àkókò eré dí ìjọsìn Ọlọ́run lọ́wọ́.​—Òwe 25:27; 1 Tím. 4:8.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ ká fi àwọn nǹkan pàtàkì sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. A tún máa jíròrò bá a ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù láti jọ́sìn Jèhófà àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá lo àkókò wa lọ́nà tó dáa.

ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU; FI OHUN PÀTÀKÌ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

5. Báwo lohun tó wà nínú Éfésù 5:15-17 ṣe lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti yan ìgbésí ayé tó dáa jù lọ?

5Yan ìgbésí ayé tó dáa jù lọ. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń ronú nípa ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé ìgbé ayé wọn. Àmọ́, àwọn agbani-nímọ̀ràn níléèwé àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ sí yunifásítì kí wọ́n lè ríṣẹ́ táá máa mówó rẹpẹtẹ wọlé. Irú ẹ̀kọ́ ìwé bẹ́ẹ̀ lè gba ọ̀pọ̀ àkókò lọ́wọ́ wọn. Ṣùgbọ́n nínú ìjọ Kristẹni, àwọn òbí àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń rọ àwọn ọ̀dọ́ láti fi ìgbésí ayé wọn ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kí ló máa ran ọ̀dọ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa jù? Á jàǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá ka ohun tó wà nínú Éfésù 5:15-17, tó sì ṣàṣàrò lé e lórí. (Kà á.) Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́ kan bá ti ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Kí ni “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́”? Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ìpinnu tí mo bá ṣe? Báwo ni ohun tí mo bá pinnu ṣe máa jẹ́ kí n lo àkókò mi lọ́nà tó dáa jù?’ Rántí pé “àwọn ọjọ́ burú” àti pé ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí máa tó dópin. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ìgbésí ayé wa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn.

6. Ìpinnu wo ni Màríà ṣe, kí sì nìdí tí ìpinnu náà fi bọ́gbọ́n mu?

6Fi ohun pàtàkì sípò àkọ́kọ́. Tá a bá fẹ́ lo àkókò wa lọ́nà tó dáa, ó máa ń gba pé ká wo àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, ká sì yan èyí tó yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí Jésù lọ kí Màríà àti Màtá nílé wọn. Torí pé inú Màtá dùn láti gba Jésù lálejò, ìyẹn ló jẹ́ kó fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti se àsè ńlá fún un. Àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ jókòó sọ́dọ̀ Jésù, ó sì ń gbọ́ ohun tó ń sọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Màtá fẹ́ ṣe ò burú rárá, Jésù sọ pé Màríà ní tiẹ̀ “yan ìpín tó dáa jù.” (Lúùkù 10:38-42, àlàyé ìsàlẹ̀) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Màríà lè gbàgbé oúnjẹ tí wọ́n jẹ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó dájú pé kò lè gbàgbé ohun tó kọ́ lọ́dọ̀ Jésù. Bí Màríà ṣe mọyì àkókò tó lò pẹ̀lú Jésù, bẹ́ẹ̀ làwa náà mọyì àkókò tá à ń lò pẹ̀lú Jèhófà. Báwo la ṣe lè lo àkókò yẹn lọ́nà tó dáa jù?

MÁA LO ÀKÓKÒ RẸ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ LỌ́NÀ TÓ DÁA JÙ LỌ

7. Kí nìdí tó fi yẹ ká wáyè láti máa gbàdúrà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣàṣàrò?

7Mọ̀ dájú pé apá kan ìjọsìn wa ni àdúrà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àṣàrò. Tá a bá ń gbàdúrà, Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa là ń bá sọ̀rọ̀ yẹn. (Sm. 5:7) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe là ń gba “ìmọ̀ Ọlọ́run” tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n. (Òwe 2:1-5) Àṣàrò máa ń jẹ́ ká ronú lórí ohun tá a kọ́ nípa Jèhófà, irú bí àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn nǹkan àgbàyanu tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ọ̀nà tó dáa jù lọ nìyẹn tá a lè gbà lo àkókò wa. Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe é bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí?

Tó o bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kó o wá ibi tó pa rọ́rọ́ (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

8. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe lo àkókò rẹ̀ nínú aginjù?

8Tó bá ṣeé ṣe, wá ibi tó pa rọ́rọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó lo ogójì (40) ọjọ́ ní aginjù. (Lúùkù 4:1, 2) Nítorí pé ibi tó pa rọ́rọ́ ni Jésù wà ní aginjù, ìyẹn ló jẹ́ kó lè gbàdúrà sí Jèhófà, kó sì ṣàṣàrò lórí ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe. Ohun tí Jésù ṣe yẹn ló ràn án lọ́wọ́ láti kojú àdánwò tó kojú lẹ́yìn náà. Kí lo lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jésù? Tó bá jẹ́ pé inú agbo ilé ńlá lò ń gbé, ó lè má rọrùn fún ẹ láti rí ibì kan tó pa rọ́rọ́ nínú ilé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè wá ibòmíì tó pa rọ́rọ́ níta. Ohun tí Arábìnrin Julie máa ń ṣe nìyẹn tó bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Inú yàrá kékeré kan lòun àti ọkọ ẹ̀ ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé. Ìyẹn kì í jẹ́ kó rọrùn fún un láti gbàdúrà láìsí ìdíwọ́. Julie sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń lọ sí ọgbà ìgbafẹ́ níbi tí mo ti lè dá wà, kí n lè pọkàn pọ̀ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀ dáadáa.”

9. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Jésù máa ń dí, báwo ló ṣe fi hàn pé òun mọyì àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà?

9 Ọwọ́ Jésù máa ń dí gan-an. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa ń wọ́ tẹ̀ lé e láti ibì kan sí ibòmíì torí pé wọ́n máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà kan, ‘gbogbo ìlú kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn’ kí wọ́n lè rí i. Síbẹ̀, Jésù rí i dájú pé òun wáyè láti gbàdúrà sí Jèhófà. Kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù jáde lọ “síbi tó dá” kó lè bá Bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ lóun nìkan.​—Máàkù 1:32-35.

10-11.Mátíù 26:40, 41 ṣe sọ, ìmọ̀ràn pàtàkì wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nínú ọgbà Gẹ́tísémánì, àmọ́ kí ni wọ́n ṣe?

10 Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ ikú Jésù, nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ń parí lọ, Jésù tún wá ibì kan tó pa rọ́rọ́ kó lè ṣàṣàrò, kó sì gbàdúrà. Ó rí ibì kan tó pa rọ́rọ́ nínú ọgbà Gẹ́tísémánì. (Mát. 26:36) Ìgbà yẹn ló fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní ìmọ̀ràn pàtàkì kan pé kí wọ́n máa gbàdúrà.

11 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi máa dénú ọgbà Gẹ́tísémánì, ilẹ̀ ti ṣú gan-an, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀gànjọ́ òru. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé ‘kí wọ́n máa ṣọ́nà,’ ó sì lọ gbàdúrà. (Mát. 26:37-39) Àmọ́ bí Jésù ṣe ń gbàdúrà, ṣe ni wọ́n sùn lọ. Nígbà tí Jésù rí i pé wọ́n ń sùn, ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘máa ṣọ́nà, kí wọ́n sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.’ (Ka Mátíù 26:40, 41.) Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ti ṣe wàhálà púpọ̀, ó sì ti rẹ̀ wọ́n, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé “ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù lọ gbàdúrà tó sì tún pa dà wá, àmọ́ nígbà tó dé, ó rí i pé wọ́n ń sùn dípò kí wọ́n máa gbàdúrà.​—Mát. 26:42-45.

Ṣé o lè ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti gbàdúrà nígbà tí kò tíì rẹ̀ ẹ́? (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Kí la lè ṣe láwọn ìgbà tá ò bá lè gbàdúrà torí pé a ti ṣe wàhálà púpọ̀ tó sì ti rẹ̀ wá?

12Yan àkókò tó tọ́. Nígbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti gbàdúrà torí pé a ti ṣe wàhálà púpọ̀, ó sì ti rẹ̀ wá. Tó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, mọ̀ dájú pé ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Àmọ́ kí lo lè ṣe? Ó ti mọ́ àwọn kan lára láti máa gbàdúrà sí Jèhófà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sùn lálẹ́. Àmọ́ wọ́n ti wá rí i pé kí ilẹ̀ tó ṣú nígbà tí kò tíì rẹ̀ wọ́n ni ìgbà tó dáa jù láti gbàdúrà. Àwọn míì ti rí i pé ipò táwọn wà nígbà táwọn bá ń gbàdúrà kì í jẹ́ kí àdúrà sú àwọn, ó sì máa ń jẹ́ káwọn pọkàn pọ̀. Tí àníyàn bá gbà ẹ́ lọ́kàn tàbí tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mú ẹ láti gbàdúrà ńkọ́? Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. Ó dájú pé Bàbá wa aláàánú máa mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ.​—Sm. 139:4.

Ṣé wàá lè ṣe é, kó o má fèsì ọ̀rọ̀ tàbí lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù ẹ nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 13-14)

13. Báwo ni ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣe lè pín ọkàn wa níyà nígbà tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà?

13Má jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ níyà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Àdúrà nìkan kọ́ lohun tó ń jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ àwa àti Jèhófà lágbára. Àwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa wá sípàdé déédéé. Kí lo lè ṣe tí wàá fi lo àkókò tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtèyí tó o fi wà nípàdé lọ́nà tó dáa? Bi ara ẹ pé ‘Àwọn nǹkan wo ló máa ń pín ọkàn mi níyà ti mo bá wà nípàdé àti nígbà tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’ Ṣé kì í ṣe pé àwọn èèyàn máa ń pè mí tí wọ́n sì máa ń fi lẹ́tà àti ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi tàbí sórí ẹ̀rọ ìgbàlódé míì tí mo ní? Lónìí, àìmọye èèyàn ló ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé torí pé ó wúlò gan-an. Àwọn kan tó ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé téèyàn bá fi fóònù tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ́dọ̀ nígbà to ń ṣe nǹkan, ó lè pín ọkàn onítọ̀hún níyà. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé: “Tọ́kàn èèyàn bá pín yà, ọkàn ẹ̀ ò ní sí nídìí nǹkan tó ń ṣe. Nǹkan míì lonítọ̀hún á máa rò.” Láwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè wa, kó tó di pé ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀, a máa ń rán wa létí pé ká pa fóònù wa tàbí ká yí i sílẹ̀ kó má bàa dí àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe yẹ ká fi fóònù dí ara wa lọ́wọ́ tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tá à bá ń gbàdúrà.

14.Fílípì 4:6, 7 ṣe sọ, báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pọkàn pọ̀?

14Bẹ Jèhófà kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pọkàn pọ̀. Tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ń rìn gbéregbère nígbà tó ò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà tó o wà nípàdé, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ọkàn ẹ ò bá balẹ̀ tàbí tó ò ń ṣàníyàn, ó lè má rọrùn fún ẹ láti pọkàn pọ̀ nígbà tó o bá ń jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ níyà. Torí náà, gbàdúrà pé kí àlàáfíà Ọlọ́run máa ṣọ́ ọkàn àti “agbára ìrònú” rẹ.​—Ka Fílípì 4:6, 7. 

ÀKÓKÒ TÁ À Ń LÒ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ MÁA Ń ṢE WÁ LÁǸFÀÀNÍ

15. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń lo àkókò ẹ pẹ̀lú Jèhófà?

15 Tó o bá ń lo àkókò ẹ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀, tó ò ń fetí sí i, tó o sì ń ronú nípa ẹ̀, wàá jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. Àwọn àǹfààní wo lo máa rí? Àkọ́kọ́, ó máa jẹ́ kó o ṣe ìpinnu tó dáa. Bíbélì fi dá wa lójú pé “ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Torí náà, bó o ṣe ń lo àkókò rẹ pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n, wàá túbọ̀ gbọ́n. Wàá túbọ̀ mọ bó o ṣe máa múnú Jèhófà dùn àti bó o ṣe máa yẹra fún ohun tó lè mú un bínú.

16. Báwo ni àkókò tá à ń lò pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́?

16 Ìkejì, wàá túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́. Tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè sún mọ́ Jèhófà. Bá a bá ṣe ń bá Bàbá wa ọ̀run sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un á máa pọ̀ sí i. Ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lẹ́kọ̀ọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Ó sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa, ìyẹn sì mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.​—Jòh. 17:25, 26.

17. Báwo ni àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?

17 Ìkẹta, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó o bẹ Ọlọ́run pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, kó tù ẹ́ nínú, kó sì tì ẹ́ lẹ́yìn. Bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ ẹ ń lágbára sí i. (1 Jòh. 5:15) Kí lohun míì tó lè mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára? Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni. Ìdí ni pé “ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Àmọ́ ṣá o, ká tó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ohun tá a máa ṣe ju ká kàn ní ìmọ̀ lọ. Kí ni nǹkan míì tó yẹ ká ṣe?

18. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa ṣàṣàrò.

18 Ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹni tó kọ Sáàmù 77. Ìdààmú bá a torí ó rò pé òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ti pàdánù ojú rere Jèhófà. Àwọn nǹkan tó ń rò yìí ni ò jẹ́ kó lè sùn lóru. (Ẹsẹ 2-8) Kí ló wá ṣe? Ó sọ fún Jèhófà pé: “Màá ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ, màá sì ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí o ṣe.” (Ẹsẹ 12) Ó dájú pé onísáàmù náà mọ ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ sẹ́yìn, àmọ́ ó ṣì ń ṣiyèméjì pé: “Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣojú rere ni, àbí, ṣé ìbínú rẹ̀ ti dínà àánú rẹ̀ ni?” (Ẹsẹ 9) Onísáàmù náà ronú lórí iṣẹ́ Jèhófà, ó sì mọ̀ pé Jèhófà ti fàánú àti ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn ẹ̀ sẹ́yìn. (Ẹsẹ 11) Kí ni gbogbo àṣàrò tó ṣe yẹn yọrí sí? Ó wá dá onísáàmù náà lójú pé Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn Ẹ̀ tì. (Ẹsẹ 15) Lọ́nà kan náà, ìgbàgbọ́ tìẹ náà á máa lágbára sí i tó o bá ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ àtohun tó ti ṣe fún ìwọ náà.

19. Àǹfààní míì wo la máa rí tá a bá ń lo àkókò pẹ̀lú Jèhófà?

19 Ìkẹrin, èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ tó ju gbogbo àwọn ànímọ́ yòókù lọ lá jẹ́ kó o máa ṣègbọràn sí Jèhófà, kó o yááfì àwọn nǹkan kan kó o lè múnú rẹ̀ dùn, kó o sì fara da àdánwò èyíkéyìí. (Mát. 22:37-39; 1 Kọ́r. 13:4, 7; 1 Jòh. 5:3) Torí náà, kò sí ohun tó ṣeyebíye ju ìfẹ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà àti bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀!​—Sm. 63:1-8.

20. Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè máa lo àkókò rẹ pẹ̀lú Jèhófà lọ́nà tó dáa?

20 Rántí pé àdúrà, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò wà lára ìjọsìn wa. Bíi ti Jésù, wá ibi tó pa rọ́rọ́ tó o bá fẹ́ lo àkókò pẹ̀lú Jèhófà. Yẹra fún ohunkóhun tó lè pín ọkàn ẹ níyà. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pọkàn pọ̀ nígbà tó o bá ń ṣe ìjọsìn. Torí náà, tó o bá ń lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa ní báyìí, Jèhófà máa jẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ títí láé nínú ayé tuntun.​—Máàkù 4:24.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà ni ọ̀rẹ́ wa tó dáa jù lọ. A mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń wù wá ká túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè mọ ẹnì kan. Bákan náà ló rí téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí gan-an lóde òní, báwo la ṣe lè wáyè ká lè sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run? Àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?