Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5

“Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Dandan fún Wa”

“Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Dandan fún Wa”

“Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa . . . kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́.”​—2 KỌ́R. 5:14, 15.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. (a) Tá a bá ń ronú nípa ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 TÍ ÈÈYÀN wa kan bá kú, àárò ẹ̀ máa ń sọ wá gan-an! Ó máa ń dùn wá gan-an tá a bá ń rántí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹni náà, pàápàá tó bá jẹ̀rora kó tó kú. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a máa ń pa dà láyọ̀ tá a bá ń rántí ohun tẹ́ni náà kọ́ wa, bó ṣe fún wa níṣìírí tàbí ohun tó sọ tó pa wá lẹ́rìn-ín.

2 Lọ́nà kan náà, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá wa gan-an tá a bá kà nípa bí Jésù ṣe jìyà tó sì kú. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, a sábà máa ń ronú nípa ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. (1 Kọ́r. 11:24, 25) Àmọ́, a tún máa ń láyọ̀ gan-an tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jésù ń ṣe báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, ó máa ń mórí wa wú. Torí náà, bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan yìí àti ìfẹ́ tí Jésù fi hàn sí wa, àá máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa.

À Ń TẸ̀ LÉ JÉSÙ TORÍ A MỌYÌ OHUN TÓ ṢE

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ìràpadà?

3 A máa mọyì ohun tí Jésù ṣe fún wa tá a bá ń ronú nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìdí tó fi kú. Ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé ló ń kọ́ àwọn èèyàn, a sì mọyì àwọn ẹ̀kọ́ yìí gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì ìràpadà torí ó jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù. Gbogbo àwọn tó bá gba Jésù gbọ́ tún nírètí láti gbé ayé títí láé, wọ́n sì máa rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. (Jòh. 5:28, 29; Róòmù 6:23) Ká sòótọ́, àwọn ohun rere tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún wa yìí ò tọ́ sí wa, kò sì sóhun tá a lè fi san oore tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa pa dà. (Róòmù 5:8, 20, 21) Àmọ́, a lè fi hàn pé a moore. Báwo la ṣe máa ṣe é?

Tó o bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ Màríà Magidalénì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 4-5)

4. Báwo ni Màríà Magidalénì ṣe fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ obìnrin Júù kan tó ń jẹ́ Màríà Magidalénì. Ìyà ń jẹ obìnrin yìí gan-an torí pé ẹ̀mí èṣù méje ló ń yọ ọ́ lẹ́nu. Ó ṣeé ṣe kó ti máa rò pé kò sọ́nà àbáyọ fóun. Ẹ wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn! Torí pé ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un, ó di ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó sì ń lo àkókò ẹ̀, okun ẹ̀ àtàwọn ohun ìní ẹ̀ láti fi ran Jésù lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Òótọ́ ni pé Màríà mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un gan-an, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kó má mọ̀ pé Jésù ṣì máa ṣe ohun tó dáa jùyẹn lọ fóun. Ìyẹn ni pé ó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé, “kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀” lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Síbẹ̀, Màríà ṣe ohun tó fi hàn pé ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un. Nígbà tí Jésù ń jìyà lórí òpó igi oró, Màríà dúró tì í, ó sì ń tu Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ wà níbẹ̀ nínú. (Jòh. 19:25) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Màríà àtàwọn obìnrin méjì míì gbé àwọn èròjà tó ń ta sánsán wá kí wọ́n lè fi pa òkú Jésù lára. (Máàkù 16:1, 2) Jèhófà san Màríà lẹ́san àwọn nǹkan tó ṣe yẹn. Ó láǹfààní láti rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, ó sì tún bá a sọ̀rọ̀. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ò nírú àǹfààní yẹn.​—Jòh. 20:11-18.

5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa?

5 Àwa náà lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti máa fi ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, a lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ilé tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà àti nígbà tí wọ́n bá ń tún wọn ṣe.

ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÚN JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ Ń JẸ́ KÁ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN

6. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù kú nítorí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?

6 Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà àti Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àwa náà máa nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Jòh. 4:10, 19) Ìfẹ́ tá a ní fún wọn jinlẹ̀ sí i nígbà tá a mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Ẹbọ ìràpadà Jésù yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti pè ẹ́ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ṣé inú ẹ ò dùn nígbà tó o mọ̀ pé ohun tó dáa tí Jèhófà rí lára ẹ ló mú kó pè ẹ́ àti pé nǹkan ńlá ni Jèhófà san kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀? Ṣé ìyẹn ò mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Jésù pọ̀ sí i? Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí mi máa sọ ọ́ di dandan pé kí n ṣe?’

Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti Kristi ń mú ká wàásù fún gbogbo ẹni tá a bá pàdé (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Bó ṣe wà nínú àwòrán yẹn, báwo ni gbogbo wa ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù? (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15; 6:1, 2)

7 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Jésù ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15; 6:1, 2.) Ọ̀nà kan tá à ń gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù ni pé à ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Gbogbo ẹni tá a bá rí la máa ń wàásù fún. A kì í sọ pé a ò ní wàásù fún ẹnì kan torí pé orílẹ̀-èdè tó ti wá, ẹ̀yà ẹ̀ àti ipò tó wà láwùjọ yàtọ̀ sí tiwa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń ṣiṣẹ́ fún Jèhófà nìyẹn torí ó fẹ́ “gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”​—1 Tím. 2:4.

8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?

8 A tún máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. (1 Jòh. 4:21) A máa ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, a sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. A máa ń tù wọ́n nínú tí èèyàn wọn bá kú, a máa ń bẹ̀ wọ́n wò tí wọ́n bá ń ṣàìsàn, a sì tún máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tù wọ́n nínú tí wọ́n bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (2 Kọ́r. 1:3-7; 1 Tẹs. 5:11, 14) Gbogbo ìgbà la máa ń gbàdúrà fún wọn torí a mọ̀ pé “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.”​—Jém. 5:16.

9. Ọ̀nà míì wo la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?

9 A tún máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, a máa ń dárí jì wọ́n bíi ti Jèhófà. Tí Jèhófà bá lè yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ kó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣé kò wá yẹ káwa náà dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? A ò ní fẹ́ dà bí ẹrú burúkú tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àkàwé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ọ̀gá rẹ̀ fagi lé gbèsè ńlá tó jẹ, ẹrú yẹn kọ̀ láti dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè tí ò tó nǹkan. (Mát. 18:23-35) Torí náà, tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan nínú ìjọ, ṣé o lè kọ́kọ́ lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹni yẹn, kí àlàáfíà lè wà kó o tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí? (Mát. 5:23, 24) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù gan-an.

10-11. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù? (1 Pétérù 5:1, 2)

10 Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù? Ọ̀nà pàtàkì kan ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ka 1 Pétérù 5:1, 2.) Jésù jẹ́ kí àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé ohun tó yẹ kó máa ṣe nìyẹn. Lẹ́yìn tó sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó fẹ́ kí Jésù mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ó dájú pé Pétérù máa ṣe ohunkóhun láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọ̀gá òun. Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòh. 21:15-17) Jálẹ̀ ìgbésí ayé Pétérù, ó fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an.

11 Ẹ̀yin alàgbà, báwo lẹ ṣe lè ṣe ohun tí Jésù sọ fún Pétérù tó bá dìgbà Ìrántí Ikú Kristi? Tó o bá lọ ń bẹ àwọn ará wò déédéé, tó o sì ń ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù nìyẹn. (Ìsík. 34:11, 12) Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ẹni tuntun tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi tó o bá fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀, kí wọ́n sì rí i pé ó yẹ káwọn náà wá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÚN KRISTI Ń MÚ KÁ NÍGBOYÀ

12. Tá a bá ń ronú nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká nígboyà? (Jòhánù 16:32, 33)

12 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Ka Jòhánù 16:32, 33.) Kí ló jẹ́ kí Jésù nígboyà nígbà táwọn ọ̀tá ń ta kò ó, tó sì tún jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú? Ó gbára lé Jèhófà ni. Torí Jésù mọ̀ pé wọ́n máa ta ko àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun náà, ó bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ wọn. (Jòh. 17:11) Báwo ni ohun tí Jésù sọ yìí ṣe jẹ́ ká nígboyà? Ó jẹ́ ká nígboyà torí a mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju àwọn ọ̀tá wa lọ. (1 Jòh. 4:4) Ó ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Torí náà, ó dájú pé tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa jẹ́ ká nígboyà láti borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù.

13. Báwo ni Jósẹ́fù ará Arimatíà ṣe fi hàn pé òun nígboyà?

13 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ará Arimatíà. Ẹni táwọn Júù bọ̀wọ̀ fún gan-an ni. Ó tún wà lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. Àmọ́ lásìkò tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Jósẹ́fù ò nígboyà. Jòhánù tiẹ̀ sọ pé ó “jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù.” (Jòh. 19:38) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere tí Jésù ń wàásù ẹ̀, kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù torí ó lè máa ronú pé àwọn èèyàn ò ní bọ̀wọ̀ fún òun mọ́. Èyí ó wù ó jẹ́, Bíbélì sọ fún wa pé Jósẹ́fù “fi ìgboyà wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.” (Máàkù 15:42, 43) Ní báyìí, Jósẹ́fù ò bẹ̀rù mọ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun.

14. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ń bẹ̀rù àwọn èèyàn?

14 Ṣé ìwọ náà máa ń bẹ̀rù àwọn èèyàn bíi ti Jósẹ́fù? Tó o bá wà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́, ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ nígbà míì láti sọ fáwọn èèyàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Ṣé torí o ò mọ ohun táwọn èèyàn máa rò nípa ẹ ni ò jẹ́ kó o di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi tàbí kó o ṣèrìbọmi? Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ nígboyà láti ṣe ohun tó fẹ́. Tó o bá ti ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà ẹ, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì túbọ̀ nígboyà.​—Àìsá. 41:10, 13.

AYỌ̀ TÁ A NÍ Ń MÚ KÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ

15. Lẹ́yìn tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, kí ni ayọ̀ tí wọ́n ní mú kí wọ́n ṣe? (Lúùkù 24:52, 53)

15 Nígbà tí Jésù kú, inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Ká sọ pé ìwọ náà wà níbẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Yàtọ̀ sí pé ọ̀rẹ́ wọn ti kú, ṣe ló tún ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò nírètí mọ́. (Lúùkù 24:17-21) Àmọ́ nígbà tí Jésù fara hàn wọ́n, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tóun fi gbọ́dọ̀ jìyà kóun sì kú àti báwọn nǹkan yẹn ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wọn. (Lúùkù 24:26, 27, 45-48) Nígbà tí Jésù fi máa pa dà sọ́run ní ogójì (40) ọjọ́ lẹ́yìn tó fara hàn wọ́n, ẹkún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti dayọ̀. Ìdí sì ni pé wọ́n mọ̀ pé Ọ̀gá àwọn ti jíǹde, ó sì máa ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Torí náà, ayọ̀ tí wọ́n ní yìí ń jẹ́ kí wọ́n yin Jèhófà, wọn ò sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù sú wọn.​—Ka Lúùkù 24:52, 53; Ìṣe 5:42.

16. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

16 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù? Jálẹ̀ ọdún la máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà, kì í ṣe àsìkò Ìrántí Ikú Kristi nìkan. Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, ó máa gba pé ká fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ló ti ṣe àtúnṣe àkókò tí wọ́n máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn kí wọ́n lè ráyè lọ sóde ìwàásù, kí wọ́n lọ sípàdé, kí wọ́n sì lè máa ráyè ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé. Kódà, àwọn kan ti pinnu pé àwọn ò ní ra àwọn nǹkan ìní táwọn kan kà sí pàtàkì, kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ tàbí kí wọ́n lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Lóòótọ́, ó yẹ ká ní ìfaradà ká tó lè máa sin Jèhófà nìṣó, àmọ́ Jèhófà ti ṣèlérí fún wa pé òun máa bù kún wa gan-an tá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.​—Òwe 10:22; Mát. 6:32, 33.

Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, ronú dáadáa lórí ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún ẹ (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí lo pinnu pé wàá ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ara wa ti wà lọ́nà láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí ní Tuesday, April 4. Àmọ́ kò yẹ kó o dúró dìgbà yẹn kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìgbésí ayé Jésù, ìdí tó fi kú àti ìfẹ́ tí òun àti Jèhófà fi hàn sí wa. Torí náà, lo àsìkò Ìrántí Ikú Kristi láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, o lè wáyè ka àtẹ náà “Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú” ní Àfikún B12 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, kó o sì ronú nípa ẹ̀. Tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì ohun tí Jésù ṣe, kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, kó o nígboyà, kó o sì láyọ̀. Lẹ́yìn náà, ronú nípa àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe láti fi hàn pé o mọyì ohun tí wọ́n ṣe. Ó dájú pé Jésù máa mọyì gbogbo ohun tó o bá ṣe láti rántí ẹ̀ nígbà Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí.​—Ìfi. 2:19.

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

a Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù, ìdí tó fi kú àti ìfẹ́ tóun àti Bàbá rẹ̀ fi hàn sí wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó fi hàn pé a mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ìràpadà àti ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, bá a ṣe lè jẹ́ onígboyà, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà.