Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ṣé o fẹ́ràn láti máa ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?

Tọkọtaya kan tó máa ń ka ìtàn ìgbésí ayé ẹyọ kan láràárọ̀ sọ pé: “Àwọn ìtàn yìí máa ń fún wa níṣìírí, wọ́n sì máa ń jẹ́ ká láyọ̀! Àwọn ìtàn náà máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwa náà lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ipò èyíkéyìí tá a bá wà.” Bọ́rọ̀ ṣe rí lára arábìnrin kan nìyẹn, ó sọ pé: “Àwọn ìtàn ìgbésí ayé tí mò ń kà máa ń tù mí nínú, ó ń mórí mi yá, ó sì máa ń mọ́kàn mi yọ̀. Ohun tó dáa làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ìtàn wọn ń mú kí n ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì ti jẹ́ kí n ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.”

Ìtàn ìgbésí ayé máa jẹ́ kó o fi ìgbésí ayé ẹ sin Jèhófà. Ó máa jẹ́ kó o borí ìrẹ̀wẹ̀sì, ó máa jẹ́ kó o lè fara da ìṣòro tó le gan-an, kó o sì máa láyọ̀. Àmọ́, ibo lo ti máa rí àwọn ìtàn náà?

  • Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ìkànnì jw.org tàbí nínú JW Library®.

  • Wá “Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower tàbí Watchtower Library.