ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2
ORIN 19 Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ́dún?
“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—LÚÙKÙ 22:19.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí Ìrántí Ikú Kristi fi ṣe pàtàkì, bá a ṣe lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ yẹn àti bá a ṣe lè pe àwọn èèyàn wá síbẹ̀.
1. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi ló ṣe pàtàkì jù lọ́dún? (Lúùkù 22:19, 20)
ỌJỌ́ Ìrántí Ikú Kristi ló ṣe pàtàkì jù lọ fáwa èèyàn Jèhófà lọ́dún. Ọjọ́ yẹn nìkan ni Jésù dìídì pa láṣẹ pé káwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa rántí. (Ka Lúùkù 22:19, 20.) Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń jẹ́ ká fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.
2. Kí ni díẹ̀ lára ìdí tá a fi máa ń fojú sọ́nà fún Ìrántí Ikú Kristi?
2 Ìrántí Ikú Kristi máa ń jẹ́ ká ronú nípa bí ìràpadà ṣe ṣeyebíye tó. Ó máa ń jẹ́ ká rántí onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ó tún máa ń jẹ́ káwa àtàwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láǹfààní láti “fún ara wa ní ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ló máa ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. Kódà, ìyẹn ti mú káwọn kan pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà nígbà tí wọ́n rí báwọn ará ṣe gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Bákan náà, ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó bá wá síbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn máa ń gbọ́ àtohun tí wọ́n máa ń rí máa ń mú kó wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Abájọ tí Ìrántí Ikú Kristi fi ṣe pàtàkì gan-an sí wa!
3. Báwo ni Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń mú káwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan kárí ayé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Tún ronú nípa bí Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń mú káwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan kárí ayé. Lọ́jọ́ yẹn, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Gbogbo wa máa ń gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí bí ìràpadà ti ṣe pàtàkì tó. A máa ń kọ orin ìyìn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àá gbé búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà kiri, àá sì ṣe “àmín” tọkàntọkàn ní ìgbà mẹ́rin tá a máa ń gbàdúrà níbẹ̀. Láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún (24), gbogbo ìjọ kárí ayé ti máa ṣe ohun kan náà. Ṣé o lè fojú inú wo bí inú Jèhófà àti Jésù ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń rí i tá a wà níṣọ̀kan, tá a sì ń bọlá fún wọn lọ́jọ́ yẹn?
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi? Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi? Báwo la ṣe lè pe àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ wá síbẹ̀? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn máa jẹ́ ká múra sílẹ̀ de ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí.
BÁWO LA ṢE LÈ MÚRA ỌKÀN WA SÍLẸ̀ FÚN ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI?
5. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa bí ìràpadà ṣe ṣeyebíye tó? (Sáàmù 49:7, 8) (b) Kí lo kọ́ nínú fídíò Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?
5 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà múra ọkàn wa sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi ni pé ká ronú lórí bí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ṣe ṣeyebíye tó. Kò sí bí àwa fúnra wa ṣe lè ra ara wa pa dà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ka Sáàmù 49:7, 8; tún wo fídíò náà, Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?) a Nǹkan ńlá ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n san kí Jésù lè fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Róòmù 6:23) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ohun ńlá tí Jèhófà àti Jésù san yìí, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọyì ìràpadà náà. Torí náà, a máa jíròrò díẹ̀ lára ohun ńlá tí Jèhófà àti Jésù san kí wọ́n lè pèsè ìràpadà. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà?
6. Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà?
6 Ìràpadà ni ohun téèyàn san láti fi ra nǹkan pa dà. Ádámù ni ẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dá sáyé, ẹni pípé sì ni nígbà tí Ọlọ́run dá a. Nígbà tó dẹ́ṣẹ̀, ó pàdánù àǹfààní tó ní láti wà láàyè títí láé, ìyẹn sì kan gbogbo àtọmọdọ́mọ ẹ̀ náà. Ká lè rí ohun tí Ádámù sọ nù gbà pa dà, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ. Jálẹ̀ ìgbà tí Jésù fi wà láyé, “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, kò sì sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.” (1 Pét. 2:22) Torí náà, nígbà tí Jésù kú, ẹni pípé ni bíi ti Ádámù kí Ádámù tó dẹ́ṣẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí ẹbọ tí Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ rú bá ohun tí Ádámù gbé sọ nù mu rẹ́gí.—1 Kọ́r. 15:45; 1 Tím. 2:6.
7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àdánwò tí Jésù borí nígbà tó wà láyé?
7 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe kódà nígbà tó nira láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jésù wà ní kékeré, ó máa ń gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé lẹ́nu bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni. (Lúùkù 2:51) Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, kò jẹ́ kí ohun táwọn ojúgbà ẹ̀ ń ṣe mú kó ṣàìgbọràn sáwọn òbí ẹ̀ tàbí kó má ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Nígbà tó sì dàgbà, ó borí ìdẹwò Sátánì kódà nígbà tó sọ pé kó ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 4:1-11) Ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé kí Jésù ṣẹ̀ sí Jèhófà kó má bàa lè san ìràpadà.
8. Àwọn àdánwò míì tó le wo ni Jésù fara dà?
8 Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé, ó fara da àwọn àdánwò míì tó le. Àwọn ọ̀tá ẹ̀ ṣenúnibíni sí i, wọ́n sì fẹ́ pa á. (Lúùkù 4:28, 29; 13:31) Yàtọ̀ síyẹn, ó fara da àìpé àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ torí pé wọ́n máa ń ṣe ohun tó dùn ún. (Máàkù 9:33, 34) Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ ẹ̀, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á, wọ́n dá a lóró, wọ́n sì dójú tì í. (Héb. 12:1-3) Ní gbogbo àkókò tó fi fara da àwọn ìṣòro yìí, Jèhófà ò gbà á sílẹ̀. b—Mát. 27:46.
9. Báwo ni ẹbọ tí Jésù fi ara ẹ̀ rú ṣe rí lára wa? (1 Pétérù 1:8)
9 Ká sòótọ́, ohun kékeré kọ́ ni Jésù ṣe láti san ìràpadà. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tó fi ara ẹ̀ rúbọ fún wa, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Ka 1 Pétérù 1:8.
10. Kí ni Jèhófà san kó lè rà wá pa dà?
10 Kí ni Jèhófà san kó lè rà wá pa dà? Kí ni Jèhófà yááfì kí Jésù lè san ìràpadà? Bí àárín bàbá àti ọmọ tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn ṣe máa ń gún régé, bẹ́ẹ̀ náà ni àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù ṣe rí. (Òwe 8:30) Ẹ̀yin náà ẹ wo bó ṣe máa dun Jèhófà tó bó ṣe ń rí ìyà tí wọ́n fi jẹ Jésù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù fara dà á. Kò sí àní-àní pé ó dun Jèhófà gan-an bó ṣe ń rí i tí wọ́n hùwà ìkà sí Ọmọ ẹ̀, bí wọn ò ṣe gbà pé òun ni Mèsáyà, tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́.
11. Sọ àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká mọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n pa Jésù.
11 Àwọn òbí tọ́mọ wọn kú máa ń mọ ẹ̀dùn ọkàn burúkú tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fà. Ó dá wa lójú háún pé àjíǹde máa wáyé, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé a ò ní lẹ́dùn ọkàn tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ohun tá a sọ yìí jẹ́ ká rí bó ṣe rí lára Jèhófà bó ṣe ń wo Ọmọ ẹ̀ tó ń jìyà lọ́jọ́ tí wọ́n pa á lọ́dún 33 S.K. c—Mát. 3:17.
12. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi?
12 Láti ìsinsìnyí títí dìgbà tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, o ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín? Lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn ìwé míì tí ètò Ọlọ́run ṣe tó ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa kókó yìí. d Yàtọ̀ síyẹn, rí i pé o lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà fún Ìrántí Ikú Kristi tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Tó bá sì dọjọ́ yẹn, má gbàgbé láti wo fídíò àkànṣe Ìjọsìn Òwúrọ̀ tá a ṣe fún Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, á jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi.—Ẹ́sírà 7:10.
RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ JÀǸFÀÀNÍ
13. Kí ló yẹ ká kọ́kọ́ ṣe tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi?
13 Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi? Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká pè wọ́n wá. Yàtọ̀ sáwọn tá a pàdé lóde ìwàásù, ó yẹ ká tún kọ orúkọ àwọn míì tá a fẹ́ pè wá. Ó lè jẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn míì tá a mọ̀. Tí ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi ò bá tiẹ̀ pọ̀ lọ́wọ́ wa, a lè fi ìlujá ẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn. A ò lè sọ, ọ̀pọ̀ lára wọn lè wá.—Oníw. 11:6.
14. Táwa fúnra wa bá fún àwọn èèyàn ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, kí ló lè mú kí wọ́n ṣe?
14 Tíwọ fúnra ẹ bá fún àwọn èèyàn ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ó ṣeé ṣe kí wọ́n wá. Ó ya arábìnrin kan lẹ́nu gan-an nígbà tí ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún un pé òun máa tẹ̀ lé e lọ sí Ìrántí Ikú Kristi. Kí nìdí tó fi yà á lẹ́nu? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni arábìnrin yìí ti pe ọkọ ẹ̀ wá, àmọ́ kò wá rí. Kí ló mú kí ọkọ arábìnrin yìí sọ pé òun máa wá lọ́tẹ̀ yìí? Ó sọ pé “alàgbà kan tí mo mọ̀ ló fún mi ní ìwé tí wọ́n fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi.” Ọkọ arábìnrin yẹn wá lọ́dún yẹn, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ló sì fi wá.
15. Kí ló yẹ ká rántí tá a bá ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi?
15 Rántí pé àwọn tá a pè wá sí Ìrántí Ikú Kristi lè ní ìbéèrè, pàápàá tí wọn ò bá tíì wá sípàdé wa rí. Á dáa ká ti ronú nípa àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi wá àti bá a ṣe máa dá wọn lóhùn. (Kól. 4:6) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè béèrè pé: ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?’ ‘Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó?’ ‘Irú aṣọ wo la gbọ́dọ̀ wọ̀?’ ‘Ṣé a máa sanwó ká tó wọlé?’ ‘Ṣé wọ́n máa gbégbá ọrẹ?’ Tá a bá fẹ́ pe ẹnì kan wá sí Ìrántí Ikú Kristi, a lè bi í pé, “Ṣé ẹ ò ní ìbéèrè kankan?” kó o sì dáhùn ìbéèrè tó bá bi ẹ́. A tún lè fi fídíò Ìrántí Ikú Jésù àti Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? han ẹni náà kó lè mọ àwọn nǹkan tá a máa ń ṣe nípàdé wa. Yàtọ̀ síyẹn, a lè rí àwọn kókó pàtàkì tá a lè sọ fún ẹni náà ní orí 28 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
16. Àwọn ìbéèrè míì wo làwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi máa ń béèrè?
16 Àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi fúngbà àkọ́kọ́ máa ń béèrè àwọn ìbéèrè míì. Wọ́n máa ń béèrè pé kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ló jẹ búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sì mu wáìnì náà, láwọn ìgbà míì sì rèé, kì í sẹ́ni tó jẹ ẹ́ rárá? Wọ́n tún lè béèrè pé ìgbà mélòó la máa ń ṣe é lọ́dún? Wọ́n tún máa ń béèrè pé ṣé báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe gbogbo ìpàdé wa nìyẹn? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń dáhùn ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè yìí nínú àsọyé tá a máa ń sọ níbi Ìrántí Ikú Kristi, ó ṣì máa ń gba pé ká túbọ̀ ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn tó wá fúngbà àkọ́kọ́. Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wàá rí díẹ̀ lára ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù?” Torí náà, a fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, nígbà Ìrántí Ikú Kristi àti lẹ́yìn náà láti ran “àwọn olóòótọ́ ọkàn” lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní.—Ìṣe 13:48.
RAN ÀWỌN ALÁÌṢIṢẸ́MỌ́ LỌ́WỌ́
17. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́? (Ìsíkíẹ́lì 34:12, 16)
17 Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:12, 16.) Ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, rí i pé o kàn sí gbogbo àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Pè wọ́n wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Tí wọ́n bá wá, fìfẹ́ kí wọn káàbọ̀. Lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi, rí i pé o ṣì ń kàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—1 Pét. 2:25.
18. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́? (Róòmù 12:10)
18 Gbogbo àwọn ará ìjọ ló lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a finúure hàn sí wọn, tá a sì bọ̀wọ̀ fún wọn. (Ka Róòmù 12:10.) Ẹ máa rántí pé ó lè ṣòro fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí láti pa dà máa wá sípàdé. Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa bà wọ́n pé àwọn ará máa fojú tí ò dáa wo àwọn. e Torí náà, má bi wọ́n ní ìbéèrè tó máa kó ìtìjú bá wọn, má sì sọ ohunkóhun tó máa dùn wọ́n. (1 Tẹs. 5:11) Ó ṣe tán, arákùnrin àti arábìnrin wa ni wọ́n. Inú wa sì dùn pé a ti fẹ́ jọ máa sin Jèhófà pa pọ̀ báyìí.—Sm. 119:176; Ìṣe 20:35.
19. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
19 Inú wa dùn pé Jésù ní ká máa rántí ikú òun lọ́dọọdún, a sì mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, àwa àtàwọn tó bá lọ máa jàǹfààní. (Àìsá. 48:17, 18) Á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù. Ó tún máa ń jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. A tún lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ohun rere tí wọ́n máa gbádùn nítorí ìràpadà tí Jésù san. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí torí ọjọ́ yẹn ló ṣe pàtàkì jù lọ́dún!
BÁWO LA ṢE LÈ . . .
-
múra ọkàn wa sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi?
-
ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní?
-
ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?
ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà
a Lo àpótí tá a fi ń wá nǹkan lórí jw.org láti wá àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ April 2021.
c Wo ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, orí 23, ìpínrọ̀ 8-9.
d Wo àpótí náà “ Àwọn Nǹkan Tó O Lè Ṣèwádìí Nípa Ẹ̀.”
e Wo àwòrán àti àpótí náà “ Ojú Wo Làwọn Ará Fi Wò Wọ́n?” Ojú ń ti arákùnrin kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ láti wọnú Ilé Ìpàdé, àmọ́ ó fìgboyà wọlé. Àwọn ará fìfẹ́ kí i káàbọ̀, ó sì gbádùn ìpàdé náà gan-an.
f ÀWÒRÁN: Táwa èèyàn Jèhófà lápá ibì kan láyé bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́wọ́, àwọn ará tó wà láwọn apá ibòmíì láyé á ṣì máa múra sílẹ̀ láti lọ ṣe tiwọn.