ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3
ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin
Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
“[Jèhófà] ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ.”—ÀÌSÁ. 33:6.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ohun tá a lè ṣe ká lè jàǹfààní bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.
1-2. Àwọn ìṣòro wo làwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ní?
ÌṢÒRO tó le gan-an lè yí ìgbésí ayé wa pa dà lójijì. Bí àpẹẹrẹ, àyẹ̀wò fi hàn pé arákùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Luis a ní àrùn jẹjẹrẹ tó le gan-an. Dókítà sọ fún un pé lẹ́yìn oṣù díẹ̀, ó máa kú. Monika àti ọkọ ẹ̀ jọ ń sin Jèhófà, wọ́n sì jọ máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọsìn Jèhófà. Lọ́jọ́ kan, Monika gbọ́ pé ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ alàgbà lójú síta, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó di dandan kí arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ tó ń jẹ́ Olivia sá kúrò nílé ẹ̀ nítorí ìjì líle tó fẹ́ jà ládùúgbò wọn. Nígbà tó fi máa pa dà sílé, ó rí i pé ìjì ti ba ilé ẹ̀ jẹ́ gan-an. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ìgbésí ayé gbogbo àwọn tá a mẹ́nu kàn yìí ti yí pa dà pátápátá. Ṣérú àwọn nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí tó sì yí ìgbésí ayé ẹ pa dà lójijì?
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a máa ń níṣòro, a sì máa ń ṣàìsàn bíi tàwọn yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń fara da àtakò àti inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn tó kórìíra àwa èèyàn Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro, ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè láyọ̀, ká ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i kódà nígbà tí ìṣòro bá mu wá lómi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin tí Jèhófà máa ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.
JÈHÓFÀ Á MÁA ṢỌ́ Ẹ
3. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wa, kí ló lè ṣòro fún wa láti ṣe?
3 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti ronú lọ́nà tó tọ́, ká sì ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ọkàn wa lè gbọgbẹ́ gan-an. Àníyàn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé à ń rìn gba inú èéfín kọjá, a ò sì rí ọ̀ọ́kán ká lè mọ ibi tá a máa gbà. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn arábìnrin méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan nígbà tí wọ́n níṣòro. Olivia sọ pé: “Lẹ́yìn tí ìjì líle yẹn ba ilé mi jẹ́, ṣe ló dà bíi pé ayé mi ti dojú rú.” Nígbà tí Monika ń sọ̀rọ̀ nípa bí ọkọ ẹ̀ ṣe dalẹ̀ ẹ̀, ó ní: “Mi ò lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ yẹn ṣe dùn mí tó. Ṣe ló dà bí ìgbà tẹ́nì kan gún mi lọ́bẹ. Kódà mi ò lè ṣe àwọn nǹkan kéékèèké tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Mi ò gbà pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí mi láéláé.” Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe tó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìṣòro ńlá bá dé bá wa?
4. Ní Fílípì 4:6, 7, kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa?
4 Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní àlàáfíà tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” (Ka Fílípì 4:6, 7.) Àlàáfíà yìí jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà yìí “kọjá gbogbo òye,” ó sì ju gbogbo ohun téèyàn lè rò lọ. Ṣé ìgbà kan wà tó o ní ìdààmú ọkàn, àmọ́ tọ́kàn ẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lẹ́yìn tó o gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn? “Àlàáfíà Ọlọ́run” ló mú kíyẹn ṣeé ṣe.
5. Báwo ni àlàáfíà Ọlọ́run ṣe ń ṣọ́ ìrònú àti ọkàn wa?
5 Ẹsẹ Bíbélì yẹn kan náà sọ pé àlàáfíà Ọlọ́run á “máa ṣọ́” tàbí dáàbò bo “ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.” Àwọn ológun ló máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ṣọ́,” ó sì ń tọ́ka sí àwọn sójà tó máa ń dáàbò bo ìlú kan káwọn ọ̀tá má bàa gbógun wọlé. Ọkàn àwọn ará ìlú táwọn sójà ń ṣọ́ máa ń balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn tó ń ṣọ́ ìlú wà ní ẹnubodè. Lọ́nà kan náà, tí àlàáfíà Ọlọ́run bá ń ṣọ́ ọkàn àti ìrònú wa, ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé kò séwu fún wa. (Sm. 4:8) Bíi ti Hánà, tí ìṣòro wa ò bá tiẹ̀ yanjú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkàn wa ṣì lè balẹ̀. (1 Sám. 1:16-18) Tí ọkàn wa bá sì balẹ̀, a máa ronú bó ṣe tọ́, àá sì ṣèpinnu tó dáa.
6. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní àlàáfíà Ọlọ́run? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ohun tó yẹ ká ṣe. Tá a bá níṣòro, ó yẹ ká ké pe Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè ṣe é? Gbàdúrà títí tó o fi máa rí àlàáfíà Ọlọ́run. (Lúùkù 11:9; 1 Tẹs. 5:17) Luis tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ ohun tóun àti ìyàwó ẹ̀ Ana ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ pé oṣù díẹ̀ ló kù kí Luis kú. Ó sọ pé: “Nírú àsìkò yìí, ó máa ń ṣòro gan-an láti ṣèpinnu lórí irú ìtọ́jú téèyàn máa gbà àtàwọn nǹkan míì. Àmọ́ àdúrà tá a gbà ló jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ lásìkò tí nǹkan nira yẹn.” Luis àti ìyàwó ẹ̀ sọ pé àwọn gbàdúrà sí Jèhófà léraléra pé kó jẹ́ kọ́kàn àwọn balẹ̀, kó sì fún àwọn lọ́gbọ́n láti ṣe ìpinnu tó dáa. Jèhófà sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Tó o bá níṣòro, máa gbàdúrà nígbà gbogbo, wàá rí i pé Jèhófà máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀.—Róòmù 12:12.
JÈHÓFÀ MÁA FI Ẹ́ LỌ́KÀN BALẸ̀
7. Báwo ni nǹkan ṣe máa ń rí lára wa tá a bá níṣòro tó le?
7 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Tá a bá níṣòro tó le gan-an, bí nǹkan ṣe rí lára wa àti bá a ṣe ń ronú lè yàtọ̀ sí bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí atẹ́gùn ṣe máa ń bi ọkọ̀ ojú omi síbí sọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro ṣe lè jẹ́ ká ṣinú rò. Ana tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé lẹ́yìn tí ọkọ òun kú, ìrònú òun kì í pa pọ̀. Ó sọ pé: “Tó bá ti ń ṣe mí bíi pé ayé mi ti dojú rú, mo máa ń káàánú ara mi. Kódà inú máa ń bí mi pé ọkọ mi kú.” Yàtọ̀ síyẹn, Ana máa ń dá wà, nǹkan sì máa ń tojú sú u tó bá fẹ́ ṣèpinnu lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ pé Luis ọkọ ẹ̀ ló máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń ṣe é bíi pé ó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí ìjì ń bì síbí bì sọ́hùn-ún. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tí ìṣòro wa bá ti ń kọjá ohun tá a lè fara dà?
8. Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú ní Àìsáyà 33:6?
8 Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Ka Àìsáyà 33:6.) Tí ìjì bá ń bì lu ọkọ̀ òkun kan, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í fì síbí fì sọ́hùn-ún, ìyẹn sì léwu gan-an. Kí ọkọ̀ náà má bàa fì síbí fì sọ́hùn-ún mọ́, wọ́n ṣe àwọn nǹkan sábẹ́ ọkọ̀ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ méjèèjì. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe náà kì í jẹ́ kí ọkọ̀ náà fì ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn tó wà nínú ẹ̀ balẹ̀. Àmọ́ ìgbà tí àwọn nǹkan yẹn máa ń ṣiṣẹ́ jù ni ìgbà tí ọkọ̀ náà bá ń lọ síwájú. Lọ́nà kan náà, Jèhófà máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí.
9. Báwo làwọn nǹkan tá a fi ń ṣèwádìí ṣe lè jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ nígbà ìṣòro? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Ohun tó yẹ ká ṣe. Tó o bá níṣòro tó le gan-an, máa gbàdúrà, máa lọ sípàdé, kó o sì máa wàásù déédéé. Òótọ́ ni pé o ò ní lè ṣe tó bó o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ máa rántí pé Jèhófà ò fẹ́ kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Fi wé Lúùkù 21:1-4.) Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tá a sọ pé kó o máa ṣe yẹn, ó yẹ kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà ti lo ètò rẹ̀ láti ṣe àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ nígbà ìṣòro. Kó o lè rí ohun tó o fẹ́, o lè lo ohun tá a fi ń ṣèwádìí, irú bíi JW Library® àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Monika tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣèwádìí lòun lò nígbà tóun rí i pé ìṣòro òun ti ń le sí i. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèwádìí nípa “ìbínú.” Nígbà míì, ó ṣèwádìí nípa “ìwà ọ̀dàlẹ̀” tàbí “ìdúróṣinṣin.” Ó máa ń ka àwọn nǹkan yìí títí ọkàn ẹ̀ á fi balẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, ọkàn mi ò balẹ̀. Àmọ́ bí mo ṣe ń ṣe ìwádìí náà sí i, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà gbá mi mọ́ra. Bí mo ṣe ń ka àwọn nǹkan yẹn, mo wá rí i pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi, ó sì ń ràn mí lọ́wọ́.” Jèhófà máa ran ìwọ náà lọ́wọ́ kọ́kàn ẹ lè balẹ̀ nígbà ìṣòro.—Sm. 119:143, 144.
JÈHÓFÀ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
10. Báwo ni nǹkan ṣe máa ń rí lára wa lẹ́yìn tí ìṣòro tó le bá dé bá wa?
10 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Lẹ́yìn tí ìṣòro tó le bá dé bá wa, àwọn ìgbà kan wà tí nǹkan lè tojú sú wa, tá ò sì ní lè ronú lọ́nà tó tọ́. Ọ̀rọ̀ wa lè dà bíi ti sárésáré kan tó ṣèṣe, tó sì ń tiro. Ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ tá à ń fìrọ̀rùn ṣe tẹ́lẹ̀ tàbí káwọn nǹkan tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sú wa, bẹ́ẹ̀ sì rèé a máa ń gbádùn àwọn nǹkan náà tẹ́lẹ̀. Bíi ti Èlíjà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká ṣáà máa sùn, ká má sì dìde lójú oorun. (1 Ọba 19:5-7) Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
11. Nǹkan míì wo ni Jèhófà máa ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́? (Sáàmù 94:18)
11 Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Ka Sáàmù 94:18.) Bí sárésáré tó ṣèṣe ṣe nílò ìrànlọ́wọ́ tó bá fẹ́ rìn láti ibì kan sí ibòmíì, bẹ́ẹ̀ náà la nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè máa tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Nírú àkókò yẹn, Jèhófà fi dá wa lójú pé: “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Àìsá. 41:13) Ọba Dáfídì rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Nígbà tó níṣòro táwọn ọ̀tá sì gbógun tì í, ó sọ fún Jèhófà pé: “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń tì mí lẹ́yìn.” (Sm. 18:35) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́?
12. Àwọn wo ni Jèhófà lè lò láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
12 Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń lo àwọn èèyàn láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Dáfídì rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ Jónátánì ọ̀rẹ́ ẹ̀ wá a lọ kó lè tù ú nínú, kó sì fún un níṣìírí. (1 Sám. 23:16, 17) Bákan náà, Jèhófà lo Èlíṣà láti ran Èlíjà lọ́wọ́. (1 Ọba 19:16, 21; 2 Ọba 2:2) Lónìí, Jèhófà lè lo ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa tàbí àwọn alàgbà láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká yẹra fáwọn èèyàn. Ó lè wù wá pé ká dá wà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́?
13. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, kí ló yẹ ká ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Ohun tó yẹ ká ṣe. Rí i dájú pé o ò yẹra fáwọn èèyàn. Tá a bá yẹra fáwọn èèyàn, ó lè jẹ́ ká máa ronú nípa ara wa nìkan àti ìṣòro tá a ní. Ìyẹn sì lè jẹ́ kó nira fún wa láti ṣe ìpinnu tó tọ́. (Òwe 18:1) Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì lè wà tó máa gba pé ká dá wà, pàápàá tó bá jẹ́ pé àjálù ńlá ló ṣẹlẹ̀ sí wa. Àmọ́ tó bá ti ń pẹ́ jù, a lè má rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí Jèhófà fẹ́ lò láti ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, bó ti wù kí ìṣòro wa le tó, ẹ jẹ́ káwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́. Gbà pé àwọn ni Jèhófà ń lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Òwe 17:17; Àìsá. 32:1, 2.
JÈHÓFÀ MÁA TÙ Ẹ́ NÍNÚ
14. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kẹ́rù bà wá?
14 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Àwọn ìgbà kan wà tẹ́rù lè máa bà wá. Nínú Bíbélì, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ìdààmú bá wọn, tí jìnnìjìnnì sì bò wọ́n nítorí àwọn ọ̀tá tàbí nítorí àwọn nǹkan míì. (Sm. 18:4; 55:1, 5) Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ ilé ìwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ìdílé wa tàbí ìjọba lè máa ta kò wá. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀rù lè máa bà wá pé a máa kú nítorí àìsàn tó ń ṣe wá. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe wá bíi ti ọmọ kékeré kan tó rò pé kò sẹ́ni tó máa ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀?
15. Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa ní Sáàmù 94:19?
15 Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe. Jèhófà máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń mára tù wá. (Ka Sáàmù 94:19.) Ohun tó wà nínú ẹsẹ yìí jẹ́ ká rí bí ẹ̀rù ṣe máa ba ọmọdébìnrin kan tí ò lè sùn nítorí ààrá tó ń sán. Ẹ jẹ́ ká fojú inú wo bí bàbá ọmọ náà ṣe wọlé wá bá a, tó sì gbá a mọ́ra títí tó fi sùn lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ààrá náà ṣì ń sán, bí bàbá ẹ̀ ṣe gbá a mọ́ra jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀. Bíi ti ọmọdébìnrin yìí, táwa náà bá níṣòro tó ń dẹ́rù bà wá, a lè jẹ́ kí Jèhófà gbá wa mọ́ra títí tọ́kàn wa fi máa balẹ̀. Báwo la ṣe lè rí irú ìtùnú bẹ́ẹ̀ gbà lọ́dọ̀ Jèhófà?
16. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tù wá nínú, kí ló yẹ ká ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ohun tó yẹ ká ṣe. Máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì déédéé. (Sm. 77:1, 12-14) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tíṣòro bá dé, ẹni tí wàá kọ́kọ́ ronú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni Bàbá rẹ ọ̀run. Sọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún Jèhófà àtohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Lẹ́yìn náà máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá rí i pé Jèhófà máa tù ẹ́ nínú. (Sm. 119:28) Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, o lè ka àwọn ibì kan nínú Bíbélì, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ wàá rí ìtùnú gbà. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìwé Jóòbù, Sáàmù, Òwe àtàwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù orí kẹfà. Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, tó o sì ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ déédéé, ó máa tù ẹ́ nínú.
17. Kí ló dá wa lójú?
17 Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró tì wá nígbà ìṣòro, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 23:4; 94:14) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò wá, òun máa jẹ́ kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ fún wa, òun máa ràn wá lọ́wọ́, òun sì máa tù wá nínú. Àìsáyà 26:3 sọ nípa Jèhófà pé: “O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá; o máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin, torí pé ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.” Torí náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó o sì máa lo àwọn nǹkan tó ń pèsè láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá pa dà lókun nígbà ìṣòro.
KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?
-
Ìgbà wo la nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà jù?
-
Àwọn nǹkan mẹ́rin wo ni Jèhófà máa ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìdààmú bá bá wa?
-
Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, kí ló yẹ ká ṣe?
ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.