ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
Jèhófà Ní Ìfẹ́ Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Sí Ẹ
“Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an.”—JÉM. 5:11.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe máa ń jẹ́ ká sún mọ́ ọn, kó sì jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. A tún máa rí bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe ń jẹ́ kó bójú tó wa dáadáa, kó sì jẹ́ kára tù wá.
1. Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá ń ronú nípa Jèhófà?
ṢÉ O ti ronú rí nípa bí Jèhófà ṣe rí? Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá ń gbàdúrà sí i? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Jèhófà, onírúurú ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ẹ̀. Bíbélì pe Jèhófà ní “oòrùn àti apata,” ó sì tún pè é ní “iná tó ń jóni run.” (Sm. 84:11; Héb. 12:29) Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó sọ pé Jèhófà dà bí òkúta sàfáyà, ó tún sọ pé ó dà bí ohun kan tó ń dán yanran àti òṣùmàrè tó mọ́lẹ̀ yòò. (Ìsík. 1:26-28) Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a fi ṣàpèjúwe Jèhófà yìí wú wa lórí gan-an, ó sì tún lè mú kẹ́rù ẹ̀ máa bà wá.
2. Kí ló lè mú káwọn kan má fẹ́ sún mọ́ Jèhófà?
2 Torí pé a ò lè rí Jèhófà, ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn kan rò pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn láé nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ó sì lè jẹ́ torí pé bàbá tó bí wọn ò fìfẹ́ hàn sí wọn. Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe mú kó ṣòro fáwọn kan láti sún mọ́ ọn. Àmọ́ torí pé ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, ó jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ dáadáa tóun ní nínú Bíbélì.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó?
3 Ọ̀rọ̀ kan tá a lè fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ ni ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Jèhófà jẹ́ ìfẹ́. Ìfẹ́ ló sì fi máa ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa lágbára gan-an, kódà ó máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Mát. 5:44, 45) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ìfẹ́ tó ní sí wa. Bá a bá ṣe ń kọ́ nípa Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ làá máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ sí i.
JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ WA GAN-AN
4. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ̀ pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 “Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an.” (Jém. 5:11) Nínú Bíbélì, ó fi ara ẹ̀ wé ìyá kan tó máa ń fìfẹ́ hàn sí ọmọ ẹ̀. (Àìsá. 66:12, 13) Ẹ fojú inú wo ìyá kan tó ń fìfẹ́ bójú tó ọmọ ẹ̀ kékeré. Ó máa ń gbé e jókòó sórí ẹsẹ̀ ẹ̀, á sì máa fohùn jẹ́jẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Tó bá ń sunkún, ìyá ẹ̀ máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, tí ibì kan bá sì ń dùn ún, ìyá ẹ̀ máa tọ́jú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fìfẹ́ bójú tó wa. Onísáàmù kan sọ pé: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”—Sm. 94:19.
5. Báwo ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ṣe rí lára ẹ?
5 Adúróṣinṣin ni Jèhófà. (Sm. 103:8) Tá a bá ṣàṣìṣe, kì í pa wá tì. Léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó dun Jèhófà, síbẹ̀ nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, ó fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wọn, ó ní: “O ti wá ṣeyebíye ní ojú mi, a dá ọ lọ́lá, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Àìsá. 43:4, 5) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ò tíì yí pa dà. Gbogbo ìgbà ló máa ń fìfẹ́ hàn sí wa. Kódà tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe ńlá, Jèhófà kì í pa wá tì. Tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, àá rí i pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ wa. Ó ṣèlérí pé òun ‘máa dárí jì wá fàlàlà.’ (Àìsá. 55:7) Bíbélì sọ pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, “àsìkò ìtura . . . látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀” máa dé bá wa.—Ìṣe 3:19.
6. Kí ni Sekaráyà 2:8 kọ́ wa nípa Jèhófà?
6 Ka Sekaráyà 2:8. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó sì ṣe tán láti dáàbò bò wá. Tí inú wa ò bá dùn, inú Jèhófà náà kì í dùn. Torí náà, tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ‘dáàbò bò wá bí ọmọlójú ẹ̀,’ ó dájú pé ó máa gbọ́ tiwa. (Sm. 17:8) Ẹ̀yà ara tó gbẹgẹ́, tó sì ṣeyebíye gan-an ni ojú wa. Torí náà, bí Jèhófà ṣe fi wá wé ẹyinjú ẹ̀ dà bí ìgbà tó ń sọ pé, ‘Ẹni tó bá hùwà ìkà sí ẹ̀yin èèyàn mi ń hùwà ìkà sóhun tó ṣeyebíye sí mi.’
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
7 Jèhófà fẹ́ kó dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Àmọ́ ó mọ̀ pé nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn, ó lè máa ṣe wá bíi pé bóyá ló nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn nǹkan kan sì lè máa ṣẹlẹ̀ sí wa báyìí tó lè mú ká rò pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa? Ohun tó máa jẹ́ ká mọ̀ ni tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí Jésù, àwọn ẹni àmì òróró àti gbogbo wa lápapọ̀.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE FI HÀN PÉ ÒUN NÍFẸ̀Ẹ́ WA
8. Kí ló mú kó dá Jésù lójú pé Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun?
8 Àìmọye ọdún ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an. Ọ̀rẹ́ àwọn méjèèjì ló pẹ́ jù láyé àtọ̀run. Ní Mátíù 17:5, Jèhófà fi bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó hàn. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jèhófà ò kàn sọ pé, ‘Ẹni tí mo tẹ́wọ́ gbà rèé.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká mọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó, ìdí nìyẹn tó fi pè é ní “Ọmọ mi, àyànfẹ́.” Jèhófà mọyì Jésù, pàápàá torí pé ó ṣe tán láti fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé. (Éfé. 1:7) Jésù ò ṣiyèméjì pé lóòótọ́ ni Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sì dá a lójú háún-háún pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Léraléra ni Jésù sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun.—Jòh. 3:35; 10:17; 17:24.
9. Ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹni àmì òróró? Ṣàlàyé. (Róòmù 5:5)
9 Jèhófà tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹni àmì òróró. (Ka Róòmù 5:5.) Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà, ‘tú jáde.’ Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé a tún lè pe ọ̀rọ̀ yìí ní “dà jáde sórí wa bí omi.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tá a fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ẹni àmì òróró yìí bá a mu gan-an! Ó dá àwọn ẹni àmì òróró lójú pé ‘Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́’ àwọn. (Júùdù 1) Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!” (1 Jòh. 3:1) Àmọ́, ṣé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́? Rárá o, Jèhófà ti fi hàn pé gbogbo wa lòun nífẹ̀ẹ́.
10. Kí lohun tó ga jù lọ tí Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ?
10 Kí lohun tó ga jù lọ tí Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? Ìràpadà ni. Kò tíì sẹ́ni tó fi irú ìfẹ́ yìí hàn láyé àtọ̀run! (Jòh. 3:16; Róòmù 5:8) Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kú fún aráyé ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, ká sì lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (1 Jòh. 4:10) Bá a bá ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jèhófà àti Jésù san láti rà wá pa dà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Gál. 2:20) Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó gbà kí Jésù san ìràpadà, àmọ́ ìdí pàtàkì tó fi ṣe é ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe yọ̀ǹda ohun tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ jìyà, kó sì kú nítorí wa.
11. Kí la kọ́ nínú Jeremáyà 31:3?
11 Àwọn nǹkan tá a ti jíròrò jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nìkan ni, ó tún ń jẹ́ ká mọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Ka Jeremáyà 31:3.) Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Fi wé Diutarónómì 7:7, 8.) Kò sóhun náà, kò sì sẹ́ni tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Báwo ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ yìí ṣe rí lára ẹ? Ka Sáàmù 23, kó o sì rí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, tó sì bójú tó o àti bí Jèhófà ṣe máa ṣe ohun kan náà fún ẹ.
BÁWO NI ÌFẸ́ TÍ JÈHÓFÀ NÍ SÍ Ẹ ṢE RÍ LÁRA Ẹ?
12. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé Sáàmù 23?
12 Ka Sáàmù 23:1-6. Àwọn ọ̀rọ̀ orin tó wà nínú Sáàmù 23 jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. Dáfídì tó kọ Sáàmù yìí ṣàlàyé bí ìfẹ́ tó wà láàárín òun àti Jèhófà tó ń ṣọ́ ọ bí Olùṣọ́ àgùntàn ṣe lágbára tó. Ọkàn Dáfídì balẹ̀ bó ṣe jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ kó gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ojoojúmọ́ ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ òun. Kí ló mú kó dá a lójú?
13. Kí nìdí tó fi dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa bójú tó òun?
13 “Èmi kì yóò ṣaláìní.” Dáfídì gbà pé Jèhófà bójú tó òun dáadáa torí gbogbo ìgbà ni Jèhófà pèsè ohun tó nílò. Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì gbádùn bóun àti Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́, ó sì tún rí ojúure ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá a lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa bójú tó òun. Dáfídì gbà pé ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní sóun máa jẹ́ kóun borí ìṣòro yòówù kóun ní, ó sì máa jẹ́ kóun láyọ̀, kóun sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Sm. 16:11.
14. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó wa?
14 Jèhófà máa ń fìfẹ́ bójú tó wa tí ìṣòro ńlá bá dé bá wa. Nǹkan tojú sú Arábìnrin Claire a tó sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ohun tó lé ní ogún (20) ọdún nígbà tí oríṣiríṣi ìṣòro dé bá ìdílé ẹ̀. Àìsàn rọpárọsẹ̀ ṣe Bàbá ẹ̀, wọ́n yọ àbúrò ẹ̀ obìnrin nínú ìjọ, okòwò wọn run, wọ́n sì pàdánù ilé wọn. Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ bójú tó wọn? Claire sọ pé: “Jèhófà ń pèsè ohun tí ìdílé wa nílò lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà pèsè ohun tá a nílò kọjá ohun tá a rò! Mo máa ń rántí àwọn ìgbà tí Jèhófà fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí mi, mo sì mọyì ẹ̀. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún mi yẹn ló jẹ́ kí n máa fayọ̀ sìn ín nìṣó láwọn ìgbà tí ìṣòro míì yọjú.”
15. Kí ló mú kí ara tu Dáfídì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 “Ó tù mí lára.” Nígbà míì, nǹkan máa ń tojú sú Dáfídì nítorí àwọn ìṣòro tó ní àti àdánwò tó dé bá a. (Sm. 18:4-6) Síbẹ̀, ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí i àti bó ṣe bójú tó o tù ú lára. Jèhófà darí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ti rẹ̀ lọ sí “ibi ìjẹko tútù” àti “ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.” Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí ló fún Dáfídì lókun, tó sì jẹ́ kó máa fayọ̀ sìn ín nìṣó.—Sm. 18:28-32.
16. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ ṣe tù ẹ́ lára?
16 Bákan náà lónìí, “ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé” láwọn ìgbà tá a níṣòro. (Ìdárò 3:22; Kól. 1:11) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Rachel. Ẹ̀dùn ọkàn bá a nígbà tí ọkọ ẹ̀ fi í sílẹ̀, tó sì tún fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà. Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Jèhófà lo àwọn ará láti fìfẹ́ hàn sí mi. Ó jẹ́ káwọn ará dúró tì mí, wọ́n gbé oúnjẹ wá fún mi, wọ́n tẹ àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tó gbé mi ró ránṣẹ́ sí mi, a jọ rẹ́rìn-ín pa pọ̀, wọ́n sì ń rán mi létí pé Jèhófà ń bójú tó mi. Torí náà, gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fi àwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ mi jíǹkí mi.”
17. Kí nìdí tí Dáfídì ò fi “bẹ̀rù ewukéwu”?
17 “Mi ò bẹ̀rù ewukéwu, nítorí o wà pẹ̀lú mi.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí Dáfídì wà nínú ewu, ó láwọn ọ̀tá tó lágbára, wọ́n sì pọ̀. Síbẹ̀ torí pé ó mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, Jèhófà sì dáàbò bò ó. Dáfídì mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà wà pẹ̀lú òun, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀ nígbà ìṣòro. Ìdí nìyẹn tó fi kọrin pé: “[Jèhófà] gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù.” (Sm. 34:4) Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà kan wà tí ẹ̀rù ba Dáfídì, àmọ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí i mú kó borí ìbẹ̀rù náà.
18. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ ṣe ń fún ẹ lókun tẹ́rù bá ń bà ẹ́?
18 Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe ń fún wa lókun tẹ́rù bá ń bà wá? Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Susi ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára òun àti ọkọ ẹ̀ nígbà tí ọmọ wọn ọkùnrin gbẹ̀mí ara ẹ̀, ó ní: “Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan lójijì, ayé máa sú onítọ̀hún, á sì dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Àmọ́ torí a mọ̀ pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí wa, ọkàn wa balẹ̀.” Rachel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lálẹ́ ọjọ́ kan tí inú mi bà jẹ́ gan-an, tẹ́rù ń bà mí, tọ́kàn mi ò sì balẹ̀, mo sunkún, mo sì gbàdúrà sókè sí Jèhófà. Lójú ẹsẹ̀, mo rí i pé Jèhófà jẹ́ kára tù mí, ọkàn mi sì balẹ̀ bíi ti ọmọ kan tí ìyá ẹ̀ mára tù, mo sì sùn lọ. Mi ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé.” Alàgbà kan tó ń jẹ́ Tasos lo ọdún mẹ́rin lẹ́wọ̀n torí pé kò wọṣẹ́ ológun. Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí i tó sì bójú tó o? Ó sọ pé: “Jèhófà pèsè gbogbo ohun tí mo nílò, kódà ó ṣe ju ohun tí mo rò lọ. Ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé mo lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Bákan náà, Jèhófà fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kí n lè máa láyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n nira. Ìyẹn jẹ́ kó dá mi lójú pé bí mo bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe jàǹfààní oore rẹ̀ tó. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.”
SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN TÓ NÍ ÌFẸ́ JẸ̀LẸ́ŃKẸ́ SÍ Ẹ
19. (a) Torí a mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kí nìyẹn máa ń jẹ́ ká sọ fún un tá a bá ń gbàdúrà? (b) Èwo ló wù ẹ́ jù lára àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ẹ? (Wo àpótí náà, “ Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa.”)
19 Àwọn ìrírí tá a ti sọ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà “Ọlọ́run ìfẹ́” wà pẹ̀lú wa! (2 Kọ́r. 13:11) Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí wa ká.’ (Sm. 32:10) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó ń bójú tó wa, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ fún un pé kó túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí wa. A lè sọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún un, kó sì dá wa lójú pé ó mọ ohun tá a fẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́.—Sm. 145:18, 19.
20. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn?
20 Bó ṣe máa ń wù wá pé ká yáná nígbà tí òtútù bá mú wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá kí Jèhófà fìfẹ́ hàn sí wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lágbára gan-an, ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni. Jẹ́ kínú ẹ máa dùn torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbà kí Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí wa, ká sì máa sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà”!—Sm. 116:1.
KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?
-
Ṣàlàyé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ.
-
Kí nìdí tó fi dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an?
-
Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹ ṣe rí lára ẹ?
ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.