ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
Tó O Bá Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Wàá Borí Ìbẹ̀rù
ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2024: “Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí, mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—SM. 56:3.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kọ́ bá a ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì borí ẹ̀rù tó ń bà wá.
1. Kí ló lè mú kẹ́rù bà wá nígbà míì?
GBOGBO wa lẹ̀rù máa ń bà nígbà míì. Àmọ́ ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn tó ti kú, kò sì yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù àtohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n a ṣì ń gbé ní àkókò tá à ń rí “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù,” irú bí ogun, ìwà ọ̀daràn àti àìsàn. (Lúùkù 21:11) Yàtọ̀ síyẹn, a lè máa bẹ̀rù èèyàn àtàwọn aláṣẹ ìjọba tó ń ṣenúnibíni sí wa tàbí àwọn ará ilé wa tó ń ta ko ìjọsìn tòótọ́. Àwọn kan ń bẹ̀rù pé àwọn ò ní lè fara da ìṣòro tó ń bá wọn fínra tàbí èyí tó máa dé lọ́jọ́ iwájú.
2. Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì nígbà tó wà ní Gátì.
2 Àwọn ìgbà kan wà tí ẹ̀rù ń ba Dáfídì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù fẹ́ pa á, ó sá lọ sí Gátì nílẹ̀ àwọn Filísínì. Kò pẹ́ tí Ákíṣì ọba Gátì fi mọ̀ pé Dáfídì ni jagunjagun tó lákíkanjú tí wọ́n kọrin yìn pé ó pa “ẹgbẹẹgbàárùn-ún” lára àwọn Filísínì. Ìyẹn mú kí ‘ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba Dáfídì gan-an.’ (1 Sám. 21:10-12) Ó ń bẹ̀rù ohun tí Ọba Ákíṣì máa ṣe fóun. Àmọ́, báwo ni Dáfídì ṣe borí ẹ̀rù tó ń bà á yìí?
3. Bí Sáàmù 56:1-3, 11 ṣe sọ, báwo ni Dáfídì ṣe borí ẹ̀rù tó ń bà á?
3 Nínú Sáàmù 56, Dáfídì sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tó wà ní Gátì. Sáàmù yẹn sọ ohun tó ń ba Dáfídì lẹ́rù, ó sì tún sọ bó ṣe borí ohun tó ń bà á lẹ́rù. Nígbà tẹ́rù ń ba Dáfídì, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ka Sáàmù 56:1-3, 11.) Ó fọkàn tán Jèhófà pátápátá. Jèhófà sì ran Dáfídì lọ́wọ́, ó jẹ́ kó rí ọgbọ́n dá sọ́rọ̀ náà, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹni tó ń ṣiwèrè! Ohun tí Dáfídì ṣe yìí rí ọba náà lára, torí náà, kò gbà pé ó lè ṣe òun ní jàǹbá, ìyẹn sì jẹ́ kí Dáfídì ráyè sá lọ.—1 Sám. 21:13–22:1.
4. Báwo la ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Ṣàpèjúwe ẹ̀.
4 Àwa náà lè borí ẹ̀rù tó ń bà wá tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àmọ́ báwo la ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, pàápàá tẹ́rù bá ń bà wá? Wo àpèjúwe yìí ná. Tó o bá mọ̀ pé àìsàn kan ń ṣe ẹ́, àyà ẹ lè kọ́kọ́ já. Àmọ́ tó o bá fọkàn tán dókítà ẹ, ara ẹ máa balẹ̀, torí dókítà yẹn ti tọ́jú àwọn tó nírú àìsàn yẹn rí dáadáa. Tó bá fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo àlàyé ẹ, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé ó mọ àìsàn tó ń ṣe ẹ́ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, tó bá sọ bó ṣe tọ́jú àwọn ẹlòmíì tára wọn sì yá, á dá ẹ lójú pé ara ìwọ náà máa yá. Lọ́nà kan náà, àwa náà máa túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá ń ro àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn nǹkan tó ń ṣe báyìí pẹ̀lú àwọn nǹkan tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ohun tí Dáfídì ṣe nìyẹn. Bá a ṣe ń gbé díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí ẹ̀ láti kọ nínú Sáàmù 56 yẹ̀ wò, máa ro bó o ṣe máa túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o lè borí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́.
ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ TI ṢE
5. Kí ni Dáfídì ń rò tó fi lè borí ẹ̀rù tó ń bà á? (Sáàmù 56:12, 13)
5 Nígbà tí ẹ̀mí Dáfídì ṣì wà nínú ewu, àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe ló ń rò. (Ka Sáàmù 56:12, 13.) Bí Dáfídì ṣe máa ń ronú nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà míì wà tó máa ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá. Ìyẹn sì máa ń rán an létí bí Jèhófà ṣe lágbára tó àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. (Sm. 65:6-9) Dáfídì tún máa ń ronú nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn ẹlòmíì. (Sm. 31:19; 37:25, 26) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ronú dáadáa nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe fún òun náà. Àtikékeré ni Jèhófà ti ń tọ́jú Dáfídì, tó sì ń dáàbò bò ó. (Sm. 22:9, 10) Ẹ ò rí i pé àwọn nǹkan tí Dáfídì ń rò yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!
6. Tẹ́rù bá ń bà wá, kí ló máa jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
6 Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe?’ Ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá “fara balẹ̀ kíyè sí” bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú àwọn ẹyẹ àti òdòdó bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò dá wọn ní àwòrán ẹ̀, tí wọn ò sì lè jọ́sìn ẹ̀, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e pé á bójú tó àwa náà. (Mát. 6:25-32) Tún wo ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn tó ń sìn ín. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹnì kan nínú Bíbélì tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára gan-an tàbí kó o ka ìtàn ìgbésí ayé ìránṣẹ́ Jèhófà kan lóde òní. a Yàtọ̀ síyẹn, ronú nípa bí Jèhófà ṣe bójú tó ẹ. Báwo ló ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o fi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Jòh. 6:44) Báwo ló ṣe dáhùn àdúrà ẹ? (1 Jòh. 5:14) Àǹfààní wo ni ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń ṣe ẹ́ lójoojúmọ́?—Éfé. 1:7; Héb. 4:14-16.
7. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì ṣe ran Vanessa lọ́wọ́ tẹ́rù ò fi bà á mọ́?
7 Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Vanessa b lórílẹ̀-èdè Haiti tó dẹ́rù bà á gan-an. Ọkùnrin kan ládùúgbò ẹ̀ máa ń pè é lórí fóònù, ó sì máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lójoojúmọ́ pé káwọn máa fẹ́ra àwọn. Vanessa ò gbà rárá. Àmọ́, ọkùnrin náà yarí, ó sì ń halẹ̀ mọ́ ọn pé òun á ṣe é léṣe. Vanessa sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an.” Kí ni Vanessa ṣe tẹ́rù ò fi bà á mọ́? Ó ṣe àwọn nǹkan kan láti dáàbò bo ara ẹ̀. Alàgbà kan bá a fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí. Ó tún ronú nípa bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ láyé àtijọ́. Vanessa sọ pé: “Ẹni tí mo kọ́kọ́ rántí ni wòlíì Dáníẹ́lì. Wọ́n jù ú sínú ihò kìnnìún tébi ń pa bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n parọ́ mọ́ ọn ni. Síbẹ̀, Jèhófà dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn kìnnìún yẹn. Mo bẹ Jèhófà pé kó gba èmi náà lọ́wọ́ ọkùnrin yẹn. Lẹ́yìn tí mo ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù ò bà mí mọ́.”—Dán. 6:12-22.
ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE BÁYÌÍ
8. Kí ló dá Dáfídì lójú? (Sáàmù 56:8)
8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì wà nínú ewu nígbà tó wà ní Gátì, kò jẹ́ kí ẹ̀rù ba òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ń ṣe fún un lákòókò yẹn ló ń rò. Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà ń tọ́ òun sọ́nà, ó ń dáàbò bo òun, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára òun. (Ka Sáàmù 56:8.) Àwọn ọ̀rẹ́ Dáfídì, irú bíi Jónátánì àti Àlùfáà Àgbà Áhímélékì ràn án lọ́wọ́, wọ́n sì tì í lẹ́yìn gbágbáágbá. (1 Sám. 20:41, 42; 21:6, 8, 9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Sọ́ọ̀lù fẹ́ pa Dáfídì, ó sá lọ, ó sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ó dá a lójú pé Jèhófà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí òun, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára òun.
9. Kí ni Jèhófà máa ń kíyè sí lára wa tá a bá ń jìyà?
9 Tó o bá níṣòro tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, rántí pé Jèhófà mọ ìṣòro náà, ó sì mọ bó ṣe rí lára ẹ. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe ìyà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ ní Íjíbítì nìkan ni Jèhófà rí, ó tún mọ̀ pé “wọ́n ń jẹ̀rora.” (Ẹ́kís. 3:7) Dáfídì kọ ọ́ lórin pé Jèhófà rí “ìpọ́njú” àti “ìdààmú ńlá” tó bá òun. (Sm. 31:7) Kódà nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run ń jìyà, “ìdààmú bá òun náà” bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi fà á. (Àìsá. 63:9) Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, ó sì ń wù ú pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́.
10. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro èyíkéyìí?
10 Tó o bá níṣòro kan tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, o lè má rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kí lo lè ṣe? Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí bó ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. (2 Ọba 6:15-17) Lẹ́yìn náà, bi ara ẹ pé: Ṣé àsọyé kan tàbí ìdáhùn kan wà tí mo gbọ́ nípàdé tó fún mi lókun? Ṣé ìwé, fídíò tàbí àwọn orin wa míì wà tó fún mi níṣìírí? Ṣé ẹnì kan ti sọ̀rọ̀ tó fi mí lọ́kàn balẹ̀ tàbí ka ẹsẹ Bíbélì kan tó tù mí nínú? Tá ò bá ṣọ́ra, a lè gbàgbé bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn ìwé pẹ̀lú fídíò ètò Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Ẹ̀bùn ńlá làwọn nǹkan yìí sì jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Àìsá. 65:13; Máàkù 10:29, 30) Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Àìsá. 49:14-16) Wọ́n sì fi hàn pé ó yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé e.
11. Kí ló ran Arábìnrin Aida lọ́wọ́ láti borí ẹ̀rù tó ń bà á?
11 Arábìnrin Aida tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gà kíyè sí bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ nígbà tó níṣòro kan. Torí pé òun ni àkọ́bí, àwọn òbí ẹ̀ fẹ́ kó di olówó kó bàa lè gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ àti tiwọn. Àmọ́ nígbà tí Aida jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn kó lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ mọ́. Àwọn ará ilé ẹ̀ bínú gan-an, wọ́n sì pẹ̀gàn ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí pé mi ò ní lè tọ́jú àwọn òbí mi, kò sì ní sẹ́ni tó máa gba tèmi. Kódà mo dá Jèhófà lẹ́bi pé ó jẹ́ káyé mi rí báyìí.” Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló gbọ́ àsọyé kan nípàdé. Ó sọ pé: “Ẹni tó sọ àsọyé náà rán wa létí pé ohun yòówù kó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa, Jèhófà mọ̀ ọ́n. Díẹ̀díẹ̀ ni ìmọ̀ràn táwọn alàgbà àtàwọn ará fún mi jẹ́ kí n mọ̀ dájú pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, mo túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, ọkàn mi sì wá balẹ̀ torí pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi.” Nígbà tó yá, Aida rí iṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ bó ṣe ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó sì tún rówó tọ́jú àwọn òbí àtàwọn èèyàn míì. Ó sọ pé: “Mo ti kọ́ bí mo ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Ní báyìí, tí mo bá ti gbàdúrà, kò síbẹ̀rù mọ́.”
KÍ NI JÈHÓFÀ MÁA ṢE LỌ́JỌ́ IWÁJÚ?
12. Kí ni Sáàmù 56:9 sọ pé ó dá Dáfídì lójú?
12 Ka Sáàmù 56:9. Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nǹkan míì tí Dáfídì ṣe láti borí ẹ̀rù tó ń bà á. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí ẹ̀ wà nínú ewu, ó ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún òun lọ́jọ́ iwájú. Dáfídì mọ̀ pé àsìkò tó tọ́ ni Jèhófà máa gba òun sílẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà ti sọ pé Dáfídì ló máa jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:1, 13) Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ohun tí Jèhófà ṣèlérí máa ṣẹ.
13. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe fún wa?
13 Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún ẹ? A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá pé kí ìṣòro má dé bá wa. c Síbẹ̀, ìṣòro yòówù kó dé bá wa nísinsìnyí, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò nínú ayé tuntun. (Àìsá. 25:7-9) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti jí àwọn òkú dìde, láti wò wá sàn, kó sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá wa run.—1 Jòh. 4:4.
14. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ronú nípa ẹ̀?
14 Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ronú nípa ìgbà tí Sátánì ò ní sí mọ́, tí Jèhófà máa fi àwọn olódodo rọ́pò àwọn èèyàn burúkú, tá á sì mú àìpé wa kúrò bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Àwòrán tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè ọdún 2014 jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa ronú lórí àwọn nǹkan tá à ń retí. Bàbá kan jíròrò ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:1-5 pẹ̀lú ìdílé ẹ̀, ó sì sọ ọ́ lọ́nà míì bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nínú Párádísè ló ń sọ. Ó sọ pé: “Inú ayé tuntun ni inú wa ti máa dùn jù. Àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, wọ́n máa mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n máa nírẹ̀lẹ̀, wọ́n á máa yin Ọlọ́run, àwọn ọmọ á máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu, wọ́n á máa moore, wọ́n á jẹ́ olóòótọ́, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an, àwọn èèyàn á máa gbọ́ ara wọn yé, wọ́n á máa sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn ẹlòmíì, wọ́n á ní ìkóra-ẹni-níjàánu, wọ́n máa níwà tútù, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ohun rere, wọ́n á ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, wọ́n á máa fòye báni lò, wọn ò ní máa gbéra ga, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dípò ìgbádùn, wọ́n á máa fọkàn sin Ọlọ́run, irú àwọn èèyàn yìí ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́.” Ṣé ìwọ àti ìdílé ẹ tàbí àwọn ará míì jọ máa ń sọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun?
15. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba Tanja, kí ló mú kó jẹ́ olóòótọ́?
15 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Tanja tó ń gbé ní North Macedonia. Àwọn òbí ẹ̀ ta kò ó gan-an nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ bó ṣe ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú mú kó jẹ́ olóòótọ́ nígbà tẹ́rù ń bà á. Ó sọ pé: “Àwọn kan lára nǹkan tó ń bà mí lẹ́rù pé ó lè ṣẹlẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Gbogbo ìgbà tí mo bá dé láti ìpàdé ni mọ́mì mi máa ń nà mí. Àwọn òbí mi sọ pé àwọn máa pa mí tí mo bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Nígbà tó yá, wọ́n lé Tanja kúrò nílé. Kí ló wá ṣe? Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú pé tí mo bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, títí láé ni màá máa láyọ̀. Mo tún máa ń ronú nípa èrè tí Jèhófà máa fún mi nínú ayé tuntun láti fi dípò àwọn ohun tí mo pàdánù nínú ayé yìí àti bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Jèhófà bá mú gbogbo nǹkan burúkú kúrò.” Tanja ò bọ́hùn, ó sì jẹ́ olóòótọ́. Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti rí ibi tó máa gbé. Ní báyìí, Tanja ti fẹ́ arákùnrin olóòótọ́ kan, àwọn méjèèjì sì jọ ń ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún.
TÚBỌ̀ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ BÁYÌÍ
16. Kí ló máa jẹ́ ká nígboyà táwọn nǹkan tí Lúùkù 21:26-28 sọ tẹ́lẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ?
16 Nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn èèyàn “máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù.” Àmọ́, àwa èèyàn Ọlọ́run ò ní bẹ̀rù, a sì máa dúró ṣinṣin. (Ka Lúùkù 21:26-28.) Kí ni ò ní jẹ́ ká bẹ̀rù? A ò ní bẹ̀rù torí a ti kọ́ bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tanja tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí òun ti jẹ́ kóun borí àwọn ìṣòro tó le gan-an. Ó sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí òkè ìṣòro tí Jèhófà ò lè sọ di pẹ̀tẹ́lẹ̀, kó sì bù kún wa. Nígbà míì, ó máa ń dà bíi pé agbára wà lọ́wọ́ àwọn kan, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọn ò lágbára tó Jèhófà.”
17. Báwo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2024 ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
17 Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè máa bà wá lẹ́rù. Àmọ́, bíi ti Dáfídì, a ò ní jẹ́ kẹ́rù bà wá. Àdúrà tí Dáfídì gbà sí Jèhófà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2024, ó ní: “Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí, mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Sm. 56:3) Ohun tí ìwé ìwádìí kan sọ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé Dáfídì “ò máa ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tó ń bà á lẹ́rù tàbí nípa àwọn ìṣòro ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Olùdáǹdè tó máa gbà á sílẹ̀.” Torí náà, máa ronú nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún yìí láwọn oṣù tó ń bọ̀ pàápàá nígbà tẹ́rù bá ń bà ẹ́. Wáyè láti ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn, àwọn nǹkan tó ń ṣe báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè sọ bíi ti Dáfídì pé: “Ìwọ [Ọlọ́run] ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.”—Sm. 56:4.
BÁWO LO ṢE LÈ BORÍ ÌBẸ̀RÙ TÓ O BÁ Ń RONÚ NÍPA . . .
-
àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe?
-
àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe báyìí?
-
àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?
ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
a O lè kà nípa àwọn ohun tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára tó o bá lọ sórí jw.org, kó o tẹ “tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn” tàbí “ìrírí” sínú àpótí tá a fi ń wá ọ̀rọ̀. O tún lè wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Tẹ̀ lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” tàbí “Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí JW Library®.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
d ÀWÒRÁN: Dáfídì ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe fún òun lágbára láti pa bíárì kan, bí Áhímélékì ṣe ran òun lọ́wọ́ àti bí Jèhófà ṣe máa jẹ́ kóun di ọba.
e ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tó gbà gbọ́ ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, bí lẹ́tà táwọn ará ń kọ sí i ṣe ń fún un lókun àti bí Jèhófà ṣe máa fún un ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè.