Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Àwòrán Ń Jẹ́ Ká Rántí Ohun Tá A Kọ́

Àwòrán Ń Jẹ́ Ká Rántí Ohun Tá A Kọ́

Ó lè ṣòro fún ẹ láti rántí àwọn ohun tó o kọ́, ọ̀pọ̀ lára wa nirú ẹ̀ sì máa ń ṣe. Àmọ́, ṣé o kíyè sí pé o máa ń tètè rántí àwọn àpèjúwe Jésù? Ìdí ni pé o lè fojú inú rí wọn, ìyẹn á sì jẹ́ kó o máa rántí. Lọ́nà kan náà, wàá rántí ọ̀pọ̀ ohun tó o kọ́ tó o bá lè fojú inú wò ó. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Bó o ṣe máa ṣe é ni pé kó o máa yàwòrán ohun tó ò ń kọ́ sórí ìwé.

Àwọn tó bá yàwòrán ohun tuntun tí wọ́n kọ́ máa ń rántí wọn dáadáa. Wọ́n máa ń rí i pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ibẹ̀ nìkan ni wọ́n ń rántí, wọ́n tún máa ń rántí ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀. Àwòrán tí wọ́n máa yà lè má rí rèǹtèrente, àmọ́ ó máa jẹ́ kí wọ́n rántí ohun tí wọ́n kọ́. Ẹ̀rí wà pé àwọn àgbàlagbà máa ń jàǹfààní gan-an tí wọ́n bá yàwòrán ohun tí wọ́n ń kọ́.

Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, o lè yàwòrán ohun tó o kọ́ sórí ìwé. Á yà ẹ́ lẹ́nu pé wàá rántí ohun tó pọ̀!